Ìfẹ́ ti Ọlọ́run
Mo fì tayọ̀tayọ̀ jẹrìí pé Olùgbàlà Jésù Krístì ni ìfẹ́ ti Ọlọ́run náà. Ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa jẹ́ pípé, ti araẹni, àti pípẹ́ títí.
Ní ìgbà ẹ̀rùn kan bí a ṣe nrin ìrìnàjò ní agbègbè àrọ́ko kan, ẹbí wa lo àṣálẹ́ kan ní sísùn ní ita gbangba lábẹ́ sánmọ̀ tí kò ní ìkùùku. Kedere tí ó ṣeé rí ní òkè wa ni Ọ̀nà Milky títóbi náà, tí ó kún fún àkàìníye àwọn ìràwọ̀ àti ìràwọ̀ tí ó ntajáde lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nígbàtí a ní ìyanilẹ́nu sí ọlánlá ìṣẹ̀dá ti Ọlọ́run, a ní ìmọ̀lára àsopọ̀ ọ̀wọ̀ kan sí I. Àwọn ọmọ wa tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́, tí wọ́n dàgbà ní Hong Kong, kò tíì ní ìrírí ohunkóhun bíi èyí rí ṣaájú. Wọ́n fi pẹ̀lú àìmọ̀kan bèérè bóyá a ngbé lábẹ́ sánmọ̀ kannáà nílé. Mo gbìyànjú láti ṣàlàyé fún wọn pé sánmọ̀ kannáà ni, ṣùgbọ́n ìbàjẹ́ inú afẹ́fẹ́ àti ìmọ́lẹ̀ níbití a ngbé ndí wa lọ́wọ́ kúrò ní rírí àwọn ìràwọ̀ wọ̀nyí bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n wà níbẹ̀.
Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ wa pé “ìgbàgbọ́ ni ìdánilójú nípa àwọn ohun tí à nretí, ẹ̀rí àwọn ohun tí a kò rí” Nígbàtí àwọn ìdààmú yíyọnilẹ́nu àti àwọn ìdánwò tẹ̀rẹ́stríà bá bo ìríran ti ẹ̀mí wa, nígbàtí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, a ngba ìdánilójú kedere nípa jíjẹ́ òtítọ́ Wọn àti nípa àníyàn Wọn fún wa.
Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, wòlíì Léhì rí “igi kan, èyítí èso rẹ̀ wuni láti mú inú ẹni dùn” àti tí ó “dùn julọ, tayọ ohun gbogbo.” Nígbàtí ó tọ́ èso náà wò, ọkàn rẹ̀ kún pẹ̀lú ayọ̀ nlá, ó sì fẹ́ kí ẹbí rẹ̀ tọ́ ọ wò bákannáà. A kọ́ ẹ̀kọ́ pé igi yìí dúró fún “ìfẹ́ ti Ọlọ́run,” àti pé bíi Léhì, àwa náà le gba ẹ̀rí aláyọ̀ kan nípa Ọlọ́run nígbàtí a bá pè É sínú ayé wa.
Jésù Krístì ṣe àkótán ìfẹ́ Baba Ọ̀run fún wa. Nípasẹ̀ ẹbọ ọrẹ ètùtù Rẹ̀, Ó gba àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sí orí Ara Rẹ̀ a sì pa á lára nítorí àìṣedẽdé wa. Ó ti fúnrarẹ̀ gba àwọn ìrora wa mọ́ra, ó gbé àwọn ìbànújẹ́ wa, ó sì gba àwọn àìsàn áti ìrora wa sí orí Ara Rẹ̀. Ó nrán Ẹ̀mí Mímọ́ láti tù wá nínú, àti pé nínú àwọn èso ti Ẹ̀mí ni ayọ̀, àlàáfíà, àti ìgbàgbọ́ wà, èyítí í maá kún wa pẹ̀lú ìrètí àti ìfẹ́.
Nígbàtí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ àrọ́wọ́tó sí gbogbo ènìyàn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nfi ìtara wá a kiri, nígbàtí àwọn míràn ní ìfẹ́ inú láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọn kò gbàgbọ́ pé àwọn yẹ fún un. Àwọn míràn nfi dandan gbìyànjú láti so mọ́ ọ. Àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn wòlíì Olúwa kọ́ wa pé a lè fi léraléra ní ìrírí ìfẹ́ Ọlọ́run nígbàti, nípasẹ̀ oore ọ̀fẹ́ Jésù Krístì, a bá nfi léraléra ronúpìwàdà, dáríjì nítoótọ́, tiraka láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, tì a sì nsin àwọn ẹlòmíràn. A nní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run nígbàtí a bá nṣe àwọn nkan ti ó nfà wá súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀, bí irú sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ lójojúmọ́ nípasẹ̀ àdúrà àti àṣàrò ìwé mímọ́, àti dídáwọ́ dúró ní ṣíṣe àwọn ohun tí yíó mú wa jìnnà kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀, bí irú jíjẹ́ agbéraga, oníjà, àti ọlọ́tẹ̀.
Ààrẹ Russell M. Nelson ti pè wá láti “mú àwọn pàntí àtijọ́ inú ayé wa kúrò, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà” àti láti “fi ìrúnú sí ẹ̀gbẹ́ kan.” Ó ti gbà wá níyànjú láti gbé àwọn ìpìlẹ̀ ti-ẹ̀mí wa ga dáradára” nípasẹ̀ “fífi ìgbésí ayé wa sí ààrin oókan [Olùgbàlà] àti lé orí àwọn ìlànà àti májẹ̀mú tẹ́mpìlì Rẹ̀.” Ó ṣèlérí pé “bí a ti npa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wa mọ́, à njèrè àyè títóbijù sí agbára ìfúnnilókun ti Olúwa. … À nní ìrírí ìfẹ́ mímọ́ ti Jésù Krístì àti Baba wa Ọ̀run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀!”
Mo ní ọ̀rẹ́ kan ẹnití o jẹ́ alábùkúnfún pẹ̀lú ẹ̀bí rírẹwà kan àti iṣẹ́ tó dára. Èyí yípadà nígbàtí àìlera kan mú kí ó má lè ṣiṣẹ́, èyítí ìkọ̀sílẹ̀ tẹ̀lé. Àwọn ọdún láti ìgbà náà ti nira, ṣùgbọ́n ìfẹ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn májẹ̀mú tí ó ti dá pẹ̀lú Ọlọ́run ti gbé e ró. Ní ọjọ́ kan ó gbọ́ pé ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti tún ìgbéyàwó ṣe ó sì ti bèèrè láti fagilé fífi èdìdi dì tẹ́mpìlì wọn. Ó ní ìdààmú àti ìdàmú ọkàn. Ó wá àlàáfíà àti òye nínú ilé Olúwa. Ní ọjọ́ tó tẹ̀lé ìbẹ̀wò rẹ̀, mo gba ọ̀rọ̀ tó tẹ̀lé yí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀:
“Mo ni ìrírí yíyanilẹ́nu nínú tẹ́mpìlì ní alẹ́ àná. Mo rò pé ó farahàn pé mo ṣì mú ìbínú diẹ̀ dàní. … Mo mọ̀ pé mo níláti yípadà, mo sì ti ngbàdúrà ní gbogbo ọ̀sẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. … Ní alẹ́ àná nínú tẹ́mpìlì mo ní ìmọ̀lára pé Ẹ̀mí mú ìbínú náà kúrò nínú ọkàn mi. … Ó jẹ́ ìtura tó bẹ́ẹ̀ láti di òmìnira kúrò nínú rẹ̀. … Ẹrù ìbànújẹ́ kan ti ara ti ó nrìn mí mọ́lẹ̀ ni ó ti di gbígbé.”
Nígbàtí ó ṣì ní àwọn ìpèníjà rẹ̀ síbẹ̀, ọ̀rẹ́ mi mọ iyì ìrírí náà nínú ilé Olúwa níbití agbára ìtúsílẹ̀ ti ìfẹ́ Ọlọ́run ti ràn án lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára sísúnmọ́ Ọlọ́run síi, níní ìrètí síi nípa ìgbé aye, àti dídín àníyàn kù nipa ọjọ́ iwájú.
Nígbàtí a bá ní ìrírí ìfẹ́ Ọlọ́run, a lè gbé àwọn ẹrù wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn kí á sì jọ̀wọ́ ara wa pẹ̀lú sùúrù àti pẹ̀lú ọ̀yàyà sí ìfẹ́ Rẹ̀. A ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run yíó rántí àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ pẹ̀lú wa, yíó bẹ̀ wá wò nínú àwọn ìpọ́njú wa, yíó sì gbà wá kúrò ní oko ẹrú. A ó ní ìfẹ́ inú bákannáà láti pín ayọ̀ tí a mọ̀lára pẹ̀lú ẹbí àti àwọn olùfẹ́ wa. Bí ó ti rí pẹ̀lú ẹbí Léhì, ẹnìkọ̀ọ̀kan ní òmìnira láti yàn bóyá láti kópa nínú èso náà tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n ànfààní wa ni láti fẹ́ràn, láti pín, àti láti pè ní ọ̀ná tí àwọn tí a fẹ́ràn yíó fi ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run.
Láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run, a nílò láti ṣe ìmúdàgbà àwọn ìwà bíi ti Krístì nínú ara wa bíi ìrẹ̀lẹ̀, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ìyọ́nú, àti sùúrù, kí a sì ṣèrànwọ́ láti yí àwọn ẹlòmíràn sí ìhà Olùgbàlà nípasẹ̀ títẹ̀lé àwọn òfin nlá méjì wọnnì ti fífẹ́ Ọlọ́run àti fífẹ́ ọmọnìkejì wa.
Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin wa tiraka pẹ̀lú jijẹ́ ti ara kan àti ìmọyì-araẹni ní àwọn ọdún ọ̀dọ́-langba rẹ̀. Ìyàwó mi àti èmi gbàdúrà láti mọ bí a ó ti ràn án lọ́wọ́ a sì ṣetán láti ṣe ohunkóhun tí Olúwa bá fẹ́ kí a ṣe. Ní ọjọ́ kan mo ní ìmọ̀lára ìṣílétí láti béèrè lọ́wọ́ ààrẹ iyejú àwọn alàgbà bí ó bá mọ ẹnìkan nínú ipò àìní tí mo lè bẹ̀wò pẹ̀lú ọmọkùnrin mi. Lẹ́hìn ìrònú díẹ̀, ó ní kí a ṣe ìbẹ̀wò sí arábìnrin kan pẹ̀lú àwọn ìpèníjà ìlera nlá, áti pé pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da láti ọ̀dọ̀ ààrẹ ẹ̀ka, kí a máa mú oúnjẹ Olúwa wá fún un ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Inú mi dùn ṣùgbọ́n bákannáà mo ṣàníyàn nípa bí ọmọkùnrin mi yíó ti ṣe sí ìfarajì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ yí.
Ní ìbẹ̀wò wa àkọ́kọ́, ọkàn wa ní ìrora fún arábìnrin ọ̀wọ́n yìí, bí ó ti wà nínú ìrora lemọ́lemọ́. Ó fi ìmoore hàn gidi fún oúnjẹ Olúwa náà, a sì gbádùn ṣíṣe àbẹ̀wò pẹ̀lú òun àti ọkọ rẹ̀. Lẹ́hìn àwọn àbẹ̀wò díẹ̀, ní Ọjọ́ Ìsinmi kan mo lọ síbìkan èmi ko sì le bá ọmọ mi lọ ṣùgbọ́n mo rán an létí nípa iṣẹ́ wa. Nígbàtí mo padà sílé, èmi kò le dúró láti gbọ́ bí àbẹ̀wò náà ti lọ. Ọmọkùnrin mi fèsì pé òun kò rò pé àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní kíláàsì ti ṣe ohun tó dára bí èyí. Ó sì fẹ̀ẹ́ lójú nipa sísọ pé òun mú arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti ṣèrànwọ́, àti pé oúnjẹ Olúwa náà lọ dáradára, ṣùgbọ́n arábìnrin ọ̀wọ́n yi ti ní ìbànujẹ́ ní ààrin ọ̀sẹ̀ nítorípé ó ti pe àwọn ọ̀rẹ́ sí ilé rẹ̀ láti wo àwọn eré ìtàgé, ṣùgbọ́n ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán rẹ̀ kò ṣiṣẹ́. Ọmọ mi sọ pé òun wá orí ìlà ayélujára, ó rí ohun tó fa ìṣoro náà, ó si yanjú rẹ̀ fún un lójú ẹ̀sẹ̀. Ó ní ìmọ̀lára pé òun wúlò, inú rẹ̀ dùn, àti pé ẹnìkan ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú òun láti ṣe ohun tó mú ọjọ́ rẹ̀ dára síi. Ó ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run fún un.
Pẹ̀lú àwọn aápọn rẹ dídárajùlọ sí ìgbé ayé kò bá lọ déédé, bí ẹ bá ní ìmọ̀lára pé a kò gbọ́ àwọn àdúrà rẹ, tàbí ẹ kò ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run, jọ̀wọ́ mọ̀ pé gbogbo ìgbésẹ̀ ló ṣe pàtàkì àti pé, dàjúdájú bíi àwọn ìràwọ̀ tó wà lókè wa, Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì mọ̀ ọ́, wọ́n ngbọ́, wọ́n sì fẹ́ràn rẹ.
Ní àkókò kan nígbàtí àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ wà nínú ọkọ̀ ti wọn njẹ́ “gbígbá kiri [nípasẹ̀] àwọn ìgbì náà,” Olùgbàlà rìn sí ìhà ọ̀dọ̀ wọn lórí omi ó sì fi dá wọn lójú, wípé, “Ẹ tújúká, Èmi ni, ẹ máṣe bẹ̀rù.” Nígbàtí Pétérù fẹ́ rìn tọ Olùgbàlà lọ lórí omi, Jésù ṣẹ́wọ́ sí i, wípé, “Wá.” Àti pé nígbàtí Pétérù ju ìfojúsùn rẹ̀ nù ti ó sì bẹ̀rẹ̀sí rì, lójúkannáà Olùgbàlà na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti mú un tí ó sì darí rẹ̀ sí ibi ààbò bi ó ti nwípé, “Ìwọ onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì?”
Nígbàtí afẹ́fẹ́ bá dojúkọ wa nínú ìgbé ayé wa, njẹ́ a ṣetán láti tújúká kí a sì ní ìgboyà bí? Báwo ni a ṣe le rántí pé Olùgbàlà kò kọ̀ wá sílẹ̀ àti pé Ó wà nítòsí wa bóyá ni àwọn ọ̀ná tí a kò tíi mọ̀ báyìí? Njẹ́ a ṣetán làti lọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ pàápàá nígbàtí ipa ọ̀nà níwájú wa dàbí pé kò ṣeéṣe? Àti pé ní àwọn ọ̀nà wo ni Òun ti ngbé wa lọ sí ibi ààbò nígbàtí a bá kùnà? Báwo ni a ṣe lè máa fi pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wo Òun nínú gbogbo èrò; laìsí iyèméjì tàbí ẹ̀rù?
Bí o bá fẹ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi nínú ayé rẹ, njẹ́ mo lè pé yín láti gba àwọn ohun tó tẹ̀le wọ̀nyí yẹ̀wò:
-
Ìkínní, ẹ máa dúró díẹ̀ lóòrè-kóòrè láti rántí pé ẹ jẹ́ ọmọ Ọlọ́run kí ẹ sì ronú àwọn nkan tí ẹ̀ ndupẹ́ fún.
-
Èkejì, ẹ máa gbàdúrà lójojúmọ́, ní sísọ fún Baba Ọ̀run láti ràn yín lọ́wọ́ mọ ẹni náà ní àyíka yín tí ó nílò láti nímọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀.
-
Ìkẹta, ẹ béèrè ní tòótọ́ ohun tí ẹ le ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́ láti nímọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run.
-
Àti ìkẹrin, ẹ gbé ìgbésẹ̀ lásìkò lórí ìmísí tí ẹ bá gbà.
Bí a bá ngbàdúrà déédé tí a sì nbéèrè ní ìgbẹnusọ àwọn ẹlòmíràn, Ọlọ́run yíó fi àwọn ènìyàn tí a lè ràn lọ́wọ́ hàn wá. Bí a bá sì gbé ìgbésẹ̀ lásìkò, a lè di ọ̀nà nípasẹ̀ èyítí Òun ó fi dáhùn àwọn àdúrà wọn. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ní àkókò, a ó gba àwọn ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa, a ó sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run nínú ayé tiwa.
Ni oṣù díẹ̀ sẹ́hìn bí a ti nrin ìrìnàjò ní Vietnam, ìyàwó mi àti èmi wà nínú ọkọ̀ ofurufú kan tí ó gbéra nínú ìjì nlá. Ìdààmú náà pọ̀ jọjọ, àwọn ìkùùku dúdú, òjò púpọ̀, àti mọ̀nà-mọ́ná ni a lè rí láti inú fèrèsé wa. Lẹ́hìn gígun òkè fún ìgbà pípẹ́ àti líle, nígbẹ̀hìn ọkọ̀ ofurufú wa gòkè tayọ àwọn ìkùùku ìjì náà ó sì yọ sí ibi ológo yìí. A ránwa létí lẹ́ẹ̀kansíi nípa Bàbá wa Ọ̀run àti Jésù Krístì a sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ nlá Wọn fún wa.
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n bíi ẹnìkan tí ó ti ní ìrírí ìfẹ́ Ọlọ́run, mo fi tayọ̀tayọ̀ jẹ́rìí pé Olùgbàlà Jésù Krístì ni ìfẹ́ ti Ọlọ́run. Ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa jẹ́ pípé, ti araẹni, àti pípẹ́ títí. Bí a ti nfi pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tẹ̀lé E, njẹ́ kí a lè kún fún ìfẹ́ Rẹ̀ kí a sì lè jẹ́ ilé-ìmọ́lẹ̀ ti yíó tọ́ àwọn ẹlòmíràn sí ìfẹ́ Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.