Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ní Ìwajú Wa Gangan
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


14:0

Ní Ìwajú Wa Gangan

Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ndàgbà ní àwọn ọmọ ìjọ àti ẹbí, míṣọ̀n àti òjíṣẹ́ ìhìnrere, ilé-ìjọsìn àti tẹ́mpìlì.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo ní ìmoore gidi láti wà pẹ̀lú yín. A ní ìfẹ́ yín; a fi ìmoore hàn fún yín; a sì ní ìmọ̀lára dídi alábùkúnfún nípa àwọn àdúrà yín.

Ààrẹ Russell M. Nelson sọ ní ìpàdé àpapọ̀ tó kọjá pé: “Ṣé ẹ rí ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní iwájú yín gangan? Mo gbàdúrà pé a kò ní sọ ọlánlá àkokò yí nù! Olúwa nyára kánkán ṣíṣẹ́ Rẹ̀ nítòótọ́.”

Mímú Iṣẹ Rẹ̀ Yára Kánkán. “Yára kánkán” ni ọ̀rọ̀ kan tí ó ṣe pàtàkì. Ó ndá àbá rírìn kíákíá, mú yára, àní àti kánmọ́kánmọ́. Nínú ìdàgbà Ìjọ àti ètò Krístì, ìyára kánkán ni ó nṣẹlẹ̀. Gbogbo wa sì jẹ́ ara rẹ̀.

Ní Oṣù Kẹ́rin 1834, ní Kirtland, Ohio, Wòlíì Joseph Smith kó gbogbo àwọn tí wọ́n di oyè-àlùfáà mú jọ sínú ilé-ẹ̀kọ́ kékeré kan nípa ẹsẹ̀ mẹ́rìnlá igun-mẹ́rin (mità mẹ́rin àti ìdámẹ́ta). A lè fi àwọn dọ́sìnì ti ilé-ẹ̀kọ́ wọnnì sínú gbàgede ìpàdé àpapọ̀ yí, pẹ̀lú yàrá láti dásí. Joseph Smith wípé, “Iye àwọn Oyè-àlùfáà díẹ̀ nìkan ni a rí nihin ní alẹ́ yí, ṣùgbọ́n Ìjọ yí yíò kún Àríwá àti Gúsù Amẹ́ríkà—yíò kún ayé.”

Àsọtẹ́lẹ̀ náà ndi mímúṣẹ “ní iwájú wa gangan.” Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ndàgbà ní àwọn ọmọ ìjọ àti ẹbí, àwọn míṣọ̀n àti òjíṣẹ́ ìhìnrere, ilé-ìjọsìn àti tẹ́mpìlì, àti ní ìforúkọ̀ sílẹ̀ nínú àwọn idanilẹkọ wa, àwọn ilé-ẹ̀kọ́, àti unifásítì káàkiri gbogbo ayé.

A fi ímoore hàn láti wà ní ilẹ̀-ayé nígbàtí Ìjọ npọ síi ní iye àti ipa, ṣùgbọ́n nípàtàkì jùlọ nínú ọkàn àti ìgbésí ayé àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀. A mọ̀ wá bí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì. À npín àwọn ẹ̀rí wa nípa rẹ̀, Ìjọ Rẹ, àwọn ọ̀nà Rẹ̀, àti ipa ọ̀nà májẹ̀mú rẹ̀. A jẹ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà wa.

Mo ní ìyálẹ́nu ní ohun tí Ààrẹ Nelson pè ní “ọlánlá ti àkokò yí” ó sì nfi ìjìnlẹ̀ ìmoore sí Olúwa hàn fún iṣẹ́ Rẹ̀. Mo gbà wá níyànjú láti dúró ní gíga bí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀, ẹlẹri ojúkojú sí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà, ti àtijọ́ àti òde òní pẹ̀lú.

Àwọn alárìíwísí wà tí wọ́n kígbe, “‘Wòó nihin!’ àti … ‘Wòó lọhun!’” gẹ́gẹ́bí wọ́n ti ṣe ní àkokò ti Wòlíì Joseph Smith. Bákannáà, wọ́n jẹ́ wọn yíò sì jẹ́ ṣùgbọ́n àkọsílẹ̀ lásán nínú iṣẹ́ akọni yí. Ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ Joseph Smith: “Kò sí ọwọ́ àìmọ́ tí ó lè dá iṣẹ́ náà dúró ní lilọsíwájú; ìnúnibíni lè jà ràìnràìn, … ṣùgbọ́n òtítọ́ Ọlọ́run yíò lọ síwájú pẹ̀lú ìgboyà, tọlátọlá, àti ní òmìnira, títí tí yío fi wọnú gbogbo ìpín ilẹ̀-ayé, bẹ gbogbo ibi gíga wò, gbá gbogbo orílẹ̀-èdè, àti láti dún ní gbogbo ètí, títí tí gbogbo èrò Ọlọ́run a fi di ṣíṣe parí, àti tí Jèhófàh nlá yíò wípé iṣẹ́ náà ti ṣetán.”

Nínú ìyànsíṣẹ́ mi ní ọdún yí, mo ti ní ijoko ìlà iwájú sí Olúwa ní ìyára kánkán iṣẹ́ Rẹ̀. Ìjọ nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì ní ọ̀nà àìlèrò, tí ó nfún àwọn ọmọ ìjọ ní ànfàní kan láti jọ́sìn nínú ilé Olúwa. Èkejì, iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti kíkójọ àwọn iye àkọsílẹ̀ sí agbo Àgùtàn Rere, Jésù Krístì. Àti ẹ̀kẹ́ta, ẹ̀kọ́ Ìjọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣètò wà ní gíga ọ̀tun nínú àwọn ìkọ́ni ti àwọn wọnnì tí wọ́n “nwá Jésù yí.”

Ní òní Ìjọ ní àwọn tẹ́mpìlì 367 ní onírurú ìpele àwòrán, kíkọ́, tàbí iṣẹ́. Àti fún èrèdí wo? Ìdáhùn sí ìkéde lórí tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan: “Ìwàmímọ́ sí Olúwa.” Tẹ́mpìlì nṣí ọ̀nà sí àwọn ìbùkún gígajùlọ tí Baba ní Ọ̀run ti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan lára wa. Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, à nyára kánkán sí ìwàmímọ́ wa bí a ti ngbé ní yíyẹ tẹ́mpìlì, bí a ti njọ́sìn nínú ilé Olúwa, àti pé bí a ti ndá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run fún arawa àti ní ìtìlẹhìn àwọn babanlá wa ní ẹ̀gbẹ́ míràn ti ìkelè.

Ààrẹ Nelson ti wípé: “Àwọn ìkọlù ọ̀tá npọ̀ si ní àlékún gidi, ní kíkankíkan àti ní onírurú. Inílò wa láti wà nínú tẹ́mpìlì déédé kò tíì pò tó èyí rí. Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti fi ojú àdúrà wo bí ẹ ti nlo àkokò yín.” Nínú ilé Rẹ̀ a lè ní ìmọ̀lára mímọ́ àti àláfíà kíkọjá àmi ti wíwà níwájú.

Alàgbà àti Arábìnrin Rasband ní Tẹ́mpìlì .Mendoza Argentina

Ní ọdún tó kọjá, mo ní ànfàní láti ṣe àkóso ní ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Mendoza Argentina. Nínú ọ̀rọ̀ mi, mo tọ́ka sí àsọtẹ́lẹ̀ Melvin J. Ballard ti 1926 pé iṣẹ́ Olúwa yíò dàgbà díẹ̀díẹ̀ fún àkokò kan ní Gúsù Amẹ́ríkà, “gẹ́gẹ́bí igi óákù kan ti ndàgbà kúrò nínú Àsálà. Kò ní dàgbà sókè ní ọjọ́ kan,” ṣùgbọ́n ẹgbẹgbẹẹ̀rún yíò darapọ̀ mọ́ Ìjọ, àti pé àwọn orílẹ̀-èdè Gúsù Amẹ́ríkà yíò di “agbára kan nínú Ìjọ.” Mo rí pé àsọtẹ́lẹ̀ náà ndi mímúṣẹ ní iwájú mi gangan.

Mendoza, àsálà kékeré nígbàkan, ti di igi óákù títóbi. Ìdàgbà náà ni à ntúnṣe káàkiri ìpín ilẹ̀ ayé àti erékùṣù òkun.

A rí tí Olúwa nyára kánkán iṣẹ́ rẹ̀ nínú àwọn míṣọ̀n. Ní 2024, àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ẹgbẹ̀rún ọgọ́rin ni wọ́n nsìn ní àwọn míṣọ̀n irínwóléàádọ́ta. Mẹ́rindínlógójì lára àwọn wọnnì jẹ́ àwọn míṣọ̀n titun. Ní ọdún tó kọjá ìṣẹ́ ìránṣẹ́ mú ó ju mẹ́jọ̀lé ní ọgọ́ọ̀rún mẹ́ta ọmọ ìjọ titun wá sínú Ìjọ. Ju àwọn iye lọ, ẹ̀mí ti ìkójọ náà nmú àwọn ẹ̀mí wá sọ́dọ̀ Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀.

Mo ronú nípa àwọn Àpóstélì Brigham Young àti Heber C. Kimball, ní 1839 tí wọ́n gbéra bí àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere lọ sí erékùṣù British. Wọ́n ṣàìsàn; wọ́n fi àwọn ẹbí wọn sílẹ̀ nínú àárẹ̀ àti aláìní. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, àwọn méjì náà gun ọkọ̀ akẹ́rù, àti pé nígbà tí wọ́n ṣì wà ní ìrí àwọn olólùfẹ́ wọn, Heber wípé, “Jẹ́ kí a dìde kí a fún wọn ní ìwúrí.” Àwọn méjì náà tiraka dìde lórí ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì kígbe, “Hurrah, hurrah fún Ísráẹ́lì.”

Pípàdé pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ní Lima, Peru.

Mo rí irú ìyárí kannáà fún iṣẹ́ Olúwa ní Líma, Peru, nígbàtí mo pàdé àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere láti Gbàgede Idanilẹkọ àwọn Òjíṣẹ́ Ìhìnrere àti àwọn míṣọ̀n ní Líma. Ìwo ìyanu lèyì! Mo rí ìyará kánkán ní iwájú mi gangan. Àwọn míṣọ̀n méje ni ó wà nísisìyí ní ìlú Lima nìkan.

Ní òpin ìpàdé wa, àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ní ìyàlẹ́nu pàtàkì fún mi. Wọ́n dìde wọ́n sì ṣe ìwúrí, “Hurrah fún Ísráẹ́lì.” Èmi kò ní gbàgbé àkokò náà láé; Mo ní ìfẹ́ kí gbogbo yín lè ti wà níbẹ̀. Ní iwájú mi gangan ni àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere tí wọ́n ti yà “àwọn ohun ayé yí sọ́tọ̀” láti sin Olúwa kí wọ́n sì ṣèrànwọ́ yárá kánkán sí bíbọ̀ Rẹ̀.

A rí Olúwa tí ó nyára kánkán sí àwọn ànfàní ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ ìjọ àní àti àwọn tí kìí ṣe ọmọ ìjọ ní àyíká ayé. Ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó mú wa yàtọ̀ bí Ìjọ kan ni àtẹnumọ́ wa lórí ẹ̀kọ́. Olúwa pàṣẹ ní kùtùkùtù àwọn ọjọ́ Ìmúpadàbọ̀sípò láti “wá ẹ̀kọ́, àní nípa àṣàrò àti nípa ìgbàgbọ́ bákannáà.” Èyí nṣẹlẹ̀ ní òní ó si yẹ fún ìró aruwo “Hurrah.”

Lọ́wọ́lọ́wọ́ àwọn akẹkọ tó ju 800,000 káríayé ti forúkọ sílẹ̀ nínú idanilẹkọ àti ilẹ́-ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn, ìforúkọ sílẹ̀ tó ga jùlọ nínú ìwé-ìtàn Ìjọ. Àwọn ọ̀dọ́ wa nkọ́rajọ ní onírurú àwọn ọ̀nà, láti kílásì kùtùkùtù òwúrọ̀, ojú-ọjọ́, àti kílásì ìrọ̀lẹ́ sí orí ayélujára àti ẹ̀kọ́ ní-ilé. Wọ́n jẹ́ àwọn àjagun alágbára àti olódodo, tí wọ́n njèrè okun láti ọ̀dọ̀ ara wọn bí wọ́n ti nkọ́ nípa Jésù Krístì, tẹ̀le, tí wọ́n sì njẹ́ ẹ̀rí Rẹ̀ bí Ọmọ Ọlọ́run.

Sísọ̀rọ̀ sí àwọn akẹkọ idanilẹkọ àti ilé-ẹ̀kọ́.

Ní ìgbà Ìṣubú tó kọjá mo sọ̀rọ̀ ní ìfọkànsìn kan ní gbàgede tó kún fún àwọn akẹkọ idanilẹkọ àti ilé-ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn àti àwọn òbí wọn ní Unifásítì ti Utah. Wíwá wọn sọ púpọ̀ nípa ìfẹ́ wọn láti mọ̀ àti láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Ọ̀rọ̀ mi sí àwọn akẹkọ wọnnì hàn kedere: Fún Olúwa ni àkokò ìdọ́gba. Mo gbà wọ́n lámọ̀ràn láti mú ẹkọ́ wọn dọ́gba pẹ̀lú ìkọ́ni òtítọ́ gígajù, àní ẹ̀kọ́ nípa “Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”

Mo bèèrè irúkannáà lọ́wọ́ gbogbo ènìyàn ní òní: Ohunkóhun tí ó wà lórí láti ṣe àtòsílẹ̀, ẹ fun ní àkokò dídọ́gba, kìí ṣe ìdásí àkokò, sí Olúwa nínú àṣàrò araẹnì ìwé mímọ́, àṣàrò ẹbí ti Wá, Tẹ̀lé Mi, àdúrà, Ìpè Ìjọ, ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, jíjọ́sìn nínú tẹ́mpìlì, àti jíjíròrò àwọn ohun Ọlọ́run. Olúwa àti Olùgbàlà wa wípé, “Kọ́ nípa mi … ìwọ yíò sì wá ìsinmi fún ọkàn rẹ̀.” Ẹ dì I mú nípa ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Kí ẹ sì fun Un ní àkokò ìdọ́gbà.

Ààrẹ Nelson ti wípé: “Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín. Ẹ fún Un ní ìpín dáadáa ti àkokò yín. Bí ẹ ti nṣe é, ẹ kíyèsí ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ sí ipa dídára ti-ẹ̀mí yín.”

A rí ipa náà tí ó nga si ní àwọn idanilẹkọ, ilé-ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn, àti unifásítì Ìjọ. Ní àyíká wọ̀nyí, Olúwa ni ààyò. Bẹ́ẹnì Ó níláti wà nínú ìgbésí ayé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.

Agbègbè míràn tí ó fi dídé ìdàgbà ẹ̀kọ́ nínú Ìjọ hàn ni BYU–Pathway Káríayé. Káàkiri ayé, fíforúkọ̀ sílẹ̀ ti kọjá ẹgbẹ̀rún máàrúnléní-àádọ́rin ó sì ntẹ̀síwájú láti dàgbà si kíákíá. Púpọ̀jùlọ jẹ́ ọmọ ìjọ, àwọn tí wọ́n sì ju ìdá-mẹ́tà wà ní Áfríkà. Pathway jẹ́ ohun gbogbo nípa ààyè sí ẹ̀kọ́. Píparí àwọn ẹ̀kọ́ náà túmọ̀ sí iṣẹ́ ṣíṣe, àti ààyè sí iṣẹ́ ṣíṣe túmọ̀ sí ìgbé ayé dídára fún ẹbí àti àwọn ànfàní síi láti sin Olúwa.

Pípàdé pẹ̀lú àwọn olórí ní Uganda.

Nígbàtí mò nní ìpàdé pẹ̀lú àwọn olórí èèkàn ní Uganda, mo kọ́ pé gbogbo àwọn àjọ ààrẹ èèkàn ti forúkọsílẹ̀ ní BYU–Pathway. Bí a ti nmúrasílẹ̀ tó níti ara àti ti ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ni a ó lè tú ìmọ̀ àtakò ẹ̀tàn ọ̀tá dànù. Ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù: “Èṣù, bí kìniún ti ndọdẹ, tí ó nrìn kiri, ó nwá ẹnití yíò pajẹ.”

Mo damọ̀ pé ní àárín àwọn ìròhìn rere ti ìhìnrere, àwọn kàn wà tí wọ́n nlàkàkà, tí wọ́n ní àwọn ìpènijà ìgbàgbọ́, iyèméjì, àti àwọn ìbèèrè tí ó dàbí kò ní àwọn ìdáhùn. Ẹ̀yin arákùnrin àti ẹ̀yin arábìnrin, Jésù Krístì ni ìdáhùn. Ẹ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. Ẹ wá ọwọ́ Rẹ̀ nínú ayé yín. Ẹ Fetísílẹ̀ sí I! “Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín dààmú,” Ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ ní àwọn wákàtí Rẹ̀ tí ó kẹ́hìn ṣíwájú Gethsemane, ṣíwájú kí ó tó gbé àgbélèbú Rẹ̀ kọjá àwọn òpópónà Jérúsálẹ́mù, ṣíwájú Golgotha, níbití Ó ti parí ìrúbọ ètùtù Rẹ̀—ohun tí Òun nìkan, Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo Ọlọ́run, lè ṣe.

Ẹ mọ̀ pé Ó ní òye. Ó gbé gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀, àṣìṣe, òṣì, àti àwọn ọjọ́ búburú gidi wa lé orí Ararẹ̀, kí a lè gbé lẹ́ẹ̀kansi pẹ̀lú Baba ní Ọ̀run nínú ayé àìlópin. Ó ti wípé, “Wò mi nínú gbogbo èrò, máṣe ṣiyèméjì, máṣe bẹ̀rù.” Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì lè gbé yín ga ó sì lè wo ìpalára ẹ̀mí yín sàn. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé E ẹ̀yin ó sì mú ìpadàbọ̀ yín yá kánkán sí “apá ìfẹ́ Rẹ̀.”

Mo tẹnumọ àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì alààyè wa lẹ́ẹ̀kansi: “Ṣé ẹ ri ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní iwájú yín gangan? Mo gbàdúrà pé a kò ní sọ ọlánlá àkokò yí nù! Olúwa nyára kánkán ṣíṣẹ́ Rẹ̀ nítòótọ́.” Njẹ́ kí àwa bí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn ti ọjọ́ wa kígbe, “Hùrráh fún Ísráẹ́lì,” bí a ti nmúrasílẹ̀ fún píadàbọ́ Olúwa àti Olùgbàlà wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Olúwa Jésù Krístì Yíò Wá Lẹ́ẹ̀kansi,” Làìhónà, Nov. 2024, 121; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 88:73: Kíyèsi, èmi yíò mú kí iṣẹ́ mi yá kánkán ní àkokò rẹ̀.”

  2. Ìkọ́ni àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph Smith (2007), 137.

  3. Russell M. Nelson, “Olúwa Jésù Krístì Yíò Wá Lẹ́ẹ̀kansi,” 121; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 88:73: “Kíyèsi, èmi yíò mú kí iṣẹ́ mi yá kánkán ní àkokò rẹ̀.”

  4. Ìwé-ìtàn—Josefu Smith 1:8.

  5. Joseph Smith, nínú Ìwé-ìtàn 1838–1856, vol. C-1, 1285, josephsmithpapers.org.

  6. Ẹ́térì 12:41.

  7. Ọ̀rọ̀ híha “Ìwàmímọ́ sí Olúwa” ni ó wà ní ìta gbogbo tẹ́mpìlì ti Ìjọ. Púpọ̀jùlọ bákannáà pẹ̀lú gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “The House of the Lord.”

  8. Russell M. Nelson, “Dída Alápẹrẹ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,” Ẹ́nsáìnì tàbí Làìhónà, Nov. 2018, 114.

  9. Melvin J. Ballard, nínú Melvin R. Ballard, Melvin J. Ballard: Alágbàwí fún Òdodo (1966), 84.

  10. Wo Mary Richards, Àwọn Ìròhìn Ìjọ pódíkástì, ìran 217, “Alàgbà W. Mark Bassett àti David N. Weidman Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ìjọ lórí Mímú Ojúṣe Iṣẹ́ Ìhìnrere Gbòòrò Si,” Àwọn Ìròhìn Ìjọ, Dec. 3, 2024, thechurchnews.com.

  11. Wo “Ìjọ Jésù Krístì Yíò Dá àwọn Míṣọ̀n Titun Mẹ̀rìndínlógójì sílẹ̀ ní 2024,” Newsroom, Nov. 1, 2023, newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

  12. Ìwífúnni tí a pèsè nípasẹ̀ Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ìjọ. Ní 2022, oye àwọn ìrìbọmi olùyípadà ju 212,172. Ní 2023, ó pọ̀ si dé 251,763. Ní 2024, 308,682 ẹnìkọ̀ọ̀kan ni a rìbọmi.

  13. Ààrẹ Gordon B. Hinckley wípé: “Èmi kò nílò láti rán yín léti pé èrò èyí nínú èyítí à nṣiṣẹ́ kìí ṣe èrò kan lásán. Èrò ti Krístì ni. Ìjọba Ọlọ́run Baba wa Ayérayé ni. Gbígbé Síónì kalẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé ni” (“Àsíá Kan Sí Àwọn Orílẹ̀-èdè,” Ẹ́nsáìnì, Nov. 1989, 53).

  14. Orson F. Whitney, Ìgbé ayé Heber C. Kimball: Àpóstélì kan, Baba àti Olùdásílẹ̀ Míṣọ̀n British (1888), 276.

  15. Ìwífúnni tí a pèsè nípasẹ̀ Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ìjọ.

  16. Ìyírọ̀pada Joseph Smith, Matteu 6:38 (nínú Matteu 6:33, footnote a).

  17. Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 88:118.

  18. Wo Tad Walch, “Enrollment growth at Latter-day Saint universities rebuts narrative about young adults losing faith,” Deseret NewsNov. 23, 2024.

  19. Wo Rachel Sterzer Gibson, “Fún Olúwa ní ‘àkokò dídọ́gba,’ Alàgbà Rasband egbani-níyànjú nígbà ìfọkànsìn sí 10,000 ọ̀dọ́ a`ti ọ̀dọ́ a`gbà,” Ìrohìn ÌjọOct. 14, 2024.

  20. Máttéù 16:16.

  21. Matteu 11:29.

  22. Russell M. Nelson, “Ipa Agbára ti Ẹ̀mí,” Liahona, May 2022, 99.

  23. Wo Walch, “Ìdàgbà Ìforúkọ Sílẹ̀ ní àwọn Unifásítì,” Deseret News, Nov. 23, 2024, deseret.com.

  24. 1 Pétérù 5:8.

  25. Russell M. Nelson, “Ìdáhùn náà ni Jésù Krístì Nígbagbogbo,” Liahona, May 2023, 127–28.

  26. Johannu 14:27.

  27. Wo Máttéù 26:36–38.

  28. Wo Lúku 23:26; Jòhánnù 19:17.

  29. Wo Johannu 19:17; 1 Nefi 11:33; 3 Nefi 27:14–15.

  30. Wo Álmà 7:14; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 76:41–42.

  31. Wo Mósè 1:39.

  32. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:36

  33. Wo Mórónì 9:25.

  34. Wo Ìwé Orin 147:3; Jacob 2:8.

  35. Wo Ìwé Òwe 3:5.

  36. 2 Néfì 1:15.

  37. Russell M. Nelson, “Olúwa Jésù Krístì Yíò Wá Lẹ́ẹ̀kansi,” 121, àfikún àtẹnumọ́; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 88:73: “Kíyèsi, èmi yíò mú kí iṣẹ́ mi yá kánkán ní àkokò rẹ̀.”