Ìrànlọ́wọ́ Àtọ̀runwá fún Ayé Kíkú
Ètò Baba wa Ọ̀run npèsè àwọn ìrànlọ́wọ́ míràn láti tọ́ wa sọ́nà nínú àwọn ìrìnàjò ayé ikú wa.
1.
Nípasẹ̀ wòlíì Joseph Smith, Olúwa fi àwọn ohun díẹ̀ hàn nípa ìṣíwájú ayé wa. Níbẹ̀ à wà bí àwọn ọmọ ẹ̀mí Ọlọ́run. Nítorí Ọlọ́run ní ìfẹ́ láti ran àwọn ọmọ Rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní ìlọsíwájú, Ó pinnu láti dá ayé kan sílẹ̀ lórí èyítí a lè gba ara kan, kẹkọ nípa ìrírí, mú àwọn ìhùwàsí àtọ̀runwá gbèrú, kí a sì dán wa wò láti ri bóyá àwa yíò pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Àwọn tí wọ́n bá yege yíò ní “àfikún ògo lórí wọn láé àti títíláé” (Ábráhámù 3:26).
Láti gbé àwọn ipò ti ètò tọ̀run kalẹ̀, Olọ́run yan Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Níkanṣoṣo láti jẹ́ Olùgbàlà wa. Lúsíférì, ẹnití àbá yíyàn rẹ̀ yíò pa agbára òmìnira ènìyàn run, di Sátánì a sì “jùú sí ìsàlẹ̀.” A le dànù sí ilẹ̀ ayé a sì fi ànfàní ara kíkú dùn ún, Sátánì ni a sì fi ààyè gbà láti dánniwò “láti tànjẹ àti láti mú ènìyàn fọ́jú, àti láti darí wọn lọ sí ìgbèkùn bí ìfẹ́ inú rẹ̀, àní bí iye àwọn tí kò fetísí ohùn [Ọlọ́run]” (Mósè 4:4).
Pàtàkì sí ètò nlá Ọlọ́run fún ìdàgbà ayé ikú ti àwọn ọmọ Rẹ̀ ni fún wọn láti ní ìrirí “àtakò nínú ohun gbogbo” (2 Nefi 2:11). Gẹ́gẹ́bí iṣan ara wa kò fi lè gbèrú tàbí di mímúdúró láìsí ìgára ní ìlòdì sí òfin ìwálẹ̀, bẹ́ẹ̀ni ìdàgbà ayé ikú nílò ènìyàn láti gára ní ìlòdì sí àwọn àdánwò Sátánì àti àtakò ayé ikú míràn. Nípàtàkì jùlọ fún ìdàgbà ti-ẹ̀mí ni ìnílò láti yàn ní àárín rere àti ibi. Àwọn tí wọ́n yan rere yíò ní ìlọsíwájú sí kádàrá ayérayé wọn. Àwọn tí wọ́n yan ibi—bí gbogbo ènìyàn yíò ti ṣe ní oríṣiríṣi àwọn àdánwò ti ayé ikú—yíò nílò ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà, èyí tí olùfẹ́ni Ọlọ́run ṣe àpẹrẹ láti pèsè.
ll.
Nípa bẹ́ẹ̀, ìrànlọ́wọ́ lílágbára jùlọ Ọlọ́run ti ayé ikú ni ìpèsè ti Olùgbàlà Rẹ̀, Jésù Krístì, tí yíò jìyà láti san oye náà àti láti pèsè ìdáríjì fún ìrònúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀. Ètùtù àánú àti ológo náà ṣe àlàyé ìdí tí ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù fi jẹ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ ti ìhiǹrere. Ètùtù Rẹ̀ “mú àjínde òkú wá sí ìmúṣẹ” (Álmà 42:23), ó sì “ṣe ètùtù fún [àwọn] ẹ̀ṣẹ̀ aráyé” (Álmà 34:8), nínú gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tí a ti rónúpìwàdà fún tí ó sì nfún wa ní agbára Olùgbàlà láti rànwálọ́wọ́ nínú àwọn àìlera ayé ikú wa.
Kíkọjá ológo ti pípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti a ṣẹ̀ rẹ́ tí a sì nrí dídáríjì fún, ètò ti olùfẹ́ni Baba ní Ọ̀run npèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀bùn míràn láti dá ààbò bò wá, pẹ̀lú dídá ààbò bò wa kúrò nínú ṣíṣẹ̀ ní ìgbà àkọ́kọ́. Ayé ikú wa nbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú baba àti ìyá kan nígbàgbogbo. Ní ìbójúmu, méjèèjì wà, pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti tọ́ ìdàgbà wa sọ́nà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àìsí wọn jẹ́ ara àtakò tí a gbọ́dọ̀ borí.
lll.
Ètò Baba wa Ọ̀run npèsè àwọn ìrànlọ́wọ́ míràn láti tọ́ wa sọ́nà nínú àwọn ìrìnàjò ayé ikú wa. Èmi ó sọ̀rọ̀ mẹ́rin lára ìwọ̀nyí. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe dì mí mú sí nọ́mba mẹ́rìn mi, nítorí àwọn ìrànlọ́wọ́ wọ̀nyí nṣẹ́ léra. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ààbò àánú míràn wà ní àfikún sí ìwọ̀nyí.
Ìkínní, Mo sọ̀rọ̀ nípa Ìmọ́lẹ̀ tàbí Ẹ̀mí Krístì. Nínú ìkọ́ni nla nínú ìwé Mórónì, Mórónì ṣe àyọsọ baba rẹ̀ pé “Ẹ̀mí Krístì ni a fún gbogbo ènìyàn, kí wọ́n lè mọ rere kúrò nínú ibi” (Moroni 7:16). A ka èyí kannáà nínú àwọn ìfihàn òde òní:
“Ẹ̀mí ni ó sì nfi ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó bá wá sí inú ayé, èyí tí ó fetísílẹ̀ sí ohùn ti Ẹ̀mí” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:46).
“Nítorí Ẹ̀mí mi ni a rán jáde sínú ayé láti fi òye yé àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti oníròbìnújẹ́, àti sí ìdálẹ́bi àwọn aláìwà bí Ọlọ́run” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 136:33).
Ààrẹ Joseph Fielding Smith ṣe àlàyé àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí: “Olúwa kò fi ènìyàn sílẹ̀ (nígbàtí a bíi sínú ayé) láìní ìránlọ́wọ́, ní yíyí láti rí ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn … ni a bí láti gba ìtọ́nisọ́nà, ìkọ́ni, àmọ̀ràn ti Ẹ̀mí Krístì tàbí Ìmọ́lẹ̀ ti Òtítọ́.”
Ìkejì nlá lára àtìlẹhìn tí a pèsè láti ọwọ́ Olúwa ni láti ràn wá lọ́wọ́ ní yíyan ohun tí ó tọ́ ni ìṣùpọ̀ ìbáṣepọ̀ àwọn ìdarí tọ̀run nínú ìwé-mímọ́ bí ara ètò ìgbàlà (ètò ìdùnnú). Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin, ìlànà, àti májẹ̀mú.
Àwọn òfin ntúmọ̀ ipa ọ̀nà tí Baba wa Ọ̀run ti fàmì sí fún wa láti ní ìlọsíwájú sí ìyè ayérayé. Àwọn ènìyàn tí wọ́n rò àwọn òfin bí ọ̀nà tí Ọlọ́run npinnu ẹni tí yíò fìyà jẹ kùnà láti ní òye èrèdí ètò ìdùnnú ìfẹ́ni Ọlọ́run. Ní ipa ọ̀nà náà, à nyọrí díẹ̀díẹ̀ ní ìbáṣepọ̀ tí a nílò pẹ̀lú Olùgbàlà a sì nyege fún ọ̀pọ̀ agbára Rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ ní ọ̀nà wa lọ sí ìbi tí Ọlọ́run nfẹ́ fún gbogbo wa. Baba wa Ọ̀run nfẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ padà sí ìjọba sẹ̀lẹ́stíà, níbití Ọlọ́run àti Olùgbàlà wa ngbé, àti láti ní irú ayé ti àwọn tí wọ́n ngbé ní ìjọba sẹ̀lẹ́stíà.
Àwọn ìlànà àti májẹ̀mú ni ara àṣẹ tí ó ntúmọ̀ ipa ọ̀nà sí ìyè ayérayé. Àwọn ìlànà, àti àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí a dá pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ wọn, ni àwọn ìgbésẹ̀ tí a nílò tí ó sì ṣe pàtàkì lẹgbẹ ipa ọ̀nà. Mo fẹ́ràn láti ronú nípa ojúṣe àwọn májẹ̀mú bí fífi ìyẹn hàn lábẹ́ ètò Ọlọ́run, àwọn ìbùkún gígajùlọ Rẹ̀ ni a fún àwọn tí wọ́n ṣe ìlérí ní iwájú láti pa àwọn òfin kan àti àwọn tí wọ́n npa àwọn ìlérí wọ̀nnì mọ́.
Àwọn ìrànlọ́wọ́ tí Ọlọ́run nfúnni fún ṣíṣe àwọn yíyàn tótọ́ ni àwọn ìfihàn Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹmí Mímọ́ ni ẹni kẹta ti Ajọ-olórí- Ọlọ́run. Ìṣe Rẹ̀, tí a túmọ̀ nínú ìwé-mímọ́, ni láti jẹri nípa Baba àti Ọmọ, láti kọ́ wa, láti mú gbogbo àwọn ohun wá sí ìrántí wa, àti láti tọ́ wa sọ́nà sínú gbogbo òtítọ́. Àwọn ìwé-mímọ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ ti àwọn ìfihàn Ẹ̀mí Mímọ́, bí irú ẹ̀rí ti ẹ̀mí ní ìfèsì sí ìbèèrè nípa òtítọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ìfihàn kan ni a kò níláti dàrú mọ́ ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí à nfúnni ní títẹ̀lé ìrìbọmi.
Ọ̀kan lára àwọn ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run tó ṣe pàtàkì jùlọ fún àwọn ọmọ olóòtítọ́ Rẹ̀ ni ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Pàtàkì ẹ̀bùn yí ni ó hàn nínú òtítọ́ pé a fúnni pẹ̀lú àṣẹ lẹ́hìn ìrònúpìwàdà àti ìrìbọmi nípa omi, “àti lẹ́hìnnáà [àwọn ìwé-mímọ́ ṣe àlàyé] ni ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín nípa iná àti nípa Ẹ̀mí ímọ́” (2 Nefi 31:17). Àwọn ẹni tí wọ́n ní ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀—tí wọ́n sì ntún wíwẹ̀mọ́ wọn ṣe déédé nípa ìrònúpìwàdà ojojúmọ́ àti gbígbé gẹ́gẹ́bí májẹ̀mú tí wọ́n dá nípasẹ̀ ìlànà oúnjẹ Olúwa—yege fún ìlérí tí Ẹ̀mí Mímọ́, kí Ẹ̀mí Olúwa, “lè wà … pẹ̀lú wọn nígbàgbogbo” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77).
Báyìí, Ààrẹ Joseph F. Smith kọ́ni pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò “fi òyè fún ọkàn àwọn ènìyàn ní ìkàsí sí àwọn ohun Ọlọ́run, láti mu dá wọn lójú ní àkokò ìyípadà wọn nípa ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run Baba wọn, kí ẹ̀rí ìbánigbé sì lè wà nínú wọn bí ojúgbà nínú ayé, ní ṣíṣe bí ó ti dájú tí ó sì tọ́nà ní ààbò sínú gbogbo òtítọ́ àti kíkún wọn ní ọjọ́ sí ọjọ́ pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú, pẹ̀lú ìdarísí láti ṣe rere sí gbogbo ènìyàn, láti jìyà àṣìṣe sànju láti ṣe àṣìṣe, láti jẹ́ onínúrere àti alaanu, ìrọ́jú àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́. Gbogbo ẹni tí ó ní ẹ̀bùn àìlóye yí, píálì iyebíye nlá yí, ti pòhùngbẹ nínú òdodo. Láìsí ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́,” Ààrẹ Smith parí rẹ̀ pé,”kò sí alára kíkú kankan tí ó lè rìn nínú ọ̀nà tààra àti tóóró.”
IV.
Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrànlọ́wọ́ alágbára láti tọ́ wa sọ́nà nínú ìrìnàjò ayé ikú wa, ó jẹ́ ìjánikulẹ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ gan dúró ní àìmúrasílẹ̀ fún ìpàdé yíyàn wọn láti pàdé Olùgbàlà àti Olùràpadap, Jésù Krístì. Òwe Rẹ̀ nípa àwọn wúndíá mẹwa, tí a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lemọ́lemọ́ gidi nínú ìpàdé àpapọ̀ yí, dá àbá pé lára àwọn tí a pè láti pàdé Rẹ̀, ìlàjì ni yíò múrasílẹ̀.
Gbogbo wa mọ àwọn àpẹrẹ èyí: awọn òjíṣẹ́ ìhìnrere tó padàbọ̀ tí wọ́n ti da ìdàgbà ti ẹ̀mí wọn rú nípa àwọn àkokò àìní-aàpọn, ọ̀dọ́ tí wọ́n ti fi ìdagbà ti ẹ̀mí wọn wéwu nípa kíkùnà láti kópa nínú àwọn ìṣe àti ìkọ́ni Ìjọ, àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti ti yíyàn sí Oyè-àlùfáà Mẹ́lkisedẹ́kì wọn síwájú, àwọn ọkùnrin àti obìnrin—nígbàmíràn àtẹ̀lé àwọn akọni olùlànà tàbí àwọn òbí yíyẹ—tí wọ́n ti kúrò ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú ti dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ nínú tẹ́mpìlì mímọ́.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú àwọn ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀ nṣẹlẹ̀ nígbàtí àwọn ọmọ ìjọ bá kùnà láti tẹ̀lé ètò ìmúdúró ìpìnlẹ̀ ti ẹ̀mí ti àdúrà araẹni, àṣàrò ìwé-mímọ́ déédé, àti ìrònúpìwàdà léraléra. Ní ìlòdì sí, àwọn kan pa àtúnṣe ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti àwọn májẹ̀mú wọn tì nípa ṣíṣe àbápín oúnjẹ́ Olúwa. Àwọ́n kan wípé Ìjọ kìí pàdé àwọn àìní wọn; àwọn wọnnì nrọ́pò ohun tí wọ́n rò bí ó jẹ́ àwọn ìnílò ọjọ́ ọ̀la wọn ṣíwájú ohun tí Olúwa ti pèsè nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìkọ́ni àti ànfààní fún ìṣẹ́-ìsìn pàtàkì wa sí àwọn ẹlòmíràn.
Ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ni àwọn ojutu fún irú àwọn ìṣìnà bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́bí Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti kọ́ni, Olúwa “ nbùkún ó sì nmú àwọn tí wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ ṣe rere” (Helaman 12:1). Níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ni kókó ìnílò fún gbogbo àwọn tí wọ́n kún òṣùwọ̀n àwọn òfin Ọlọ́run àti ìkọ́ni àwọn wòlíì Rẹ̀ ní ìlòdì sí àwárí àìpẹ́ àti ọgbọ́n ènìyàn.
Mo ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrànlọ́wọ́ aye ikú tí olùfẹ́ni Baba ní Ọ̀run ti fúnni láti ran àwọn ọmọ Rẹ̀ lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ipá wa nínú ètò tọ̀run yí ni láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run àti wíwá àti lílo àwọn ìrànlọ́wọ́ tọ̀run wọ̀nyí, pẹ̀lú àfiyèsí jùlọ ni Ètùtù ti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, Jésù Krístì. A gbàdúrà pé a ó kọ́ni a ó sì gbé ìgbé ayé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.