Ètò Ìtọ́sọ́nà Ọ̀run wa
Bí a ṣe ndojú ìgbé ayé wa kọ Jésù Krístì, a yíò rí ọ̀nà wa sí ilé, a yíò máa faradà á dé òpin, a yíò sì máa yọ̀ dé òpin.
Jésù Krístì yí ìgbésí ayé mi padà nígbà tí mo ṣe ìrìbọmi ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ní Frutillar olùfẹ́ mi, ní orílẹ̀-èdè Chile. Ní àkokò náà, ìṣẹ mi mu mi la okun, àwọn òdo, àti àwọn adágún ti Patagonia rírẹwà ti Chile. Lẹ́hìn ìrìbọmi, mo rí iṣẹ́ àti ìgbésí ayé mi lọ́nà titun, ní mímọ̀ lootọ pé “ohun gbogbo nfi hàn pé Ọlọ́run wà.”
Ní ìṣẹ̀dá, ẹja salmon ní a bí nínú orísun ti àwọn odò. Ní ààyè díẹ̀ nínú ìgbé ayé wọn, wọ́n nílò láti wẹ̀ sí ìsàlẹ̀ láti dé ọ̀dọ̀ òkun, níbití wọ́n ó ti rí ìbọ́ni àti àwọn ipò pàtàkì fún ìdàgbàsókè wọn.
Ṣùgbọ́n òkun tún jẹ́ ibi ewu níbi tí àwọn apanirun máa nsá sí, níbi tí àwọn apẹja ti ngbìyànjú láti mú ẹja salmon pẹ̀lú ìwọ̀n ìkọ́ tó farajọ oúnjẹ ṣùgbọ́n tí wọn kìí bọ wọn. Bí salmon bá lè la àwọn ìhalẹ̀mọ́ni wọ̀nyí já, wọ́n á múra tán láti lo ètò ìtọ́sọ́nà alágbára láti padà sí ibi kan náà tí wọ́n bí wọn sí, tí wọ́n sì dojú kọ àwọn ìpèníjà titun àtàwọn ìṣòro míràn tó farapẹ́ẹ. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì ti ṣe ìwádìí ìhùwàsí àṣíkiri wọn fún àwọn ọdún àti pé wọ́n ṣàwárí pé wọ́n ló irú máàpù òòfà kan, tó jọra sí GPS, láti darí wọn sí òpin ìrìn àjò wọn pẹ̀lú kòngẹ́ yíyanilẹ́nu.
Gbogbo wa lè padà lọ́jọ́ kan sílé ọ̀run láti ibití a ti wá. Àti bíi ẹja salmon, a ní máàpù òòfà tiwa, tàbí Ìmọ́lẹ̀ Krístì, láti darí wa síbẹ̀. Jésù kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.”
Bí a ṣe ndojú ìgbé ayé wa kọ Jésù Krístì, a yíò rí ọ̀nà wa sí ilé, a yíò máa faradà á dé òpin, a yíò sì máa yọ̀ dé òpin. Ààrẹ Nelson kọ́ni pé, “ayọ̀ tí à nímọ̀lára rẹ̀ ní díẹ̀ íṣe pẹ̀lú àwọn ipò ti ìgbé ayé wa àti pé ohungbogbo ní íṣe pẹ̀lú ìfojúsùn àwọn ìgbé ayé wa.”
Ìṣẹ̀dá Àtọ̀runwá àti Kádàrá Wa
Láti inú ìkéde ẹbí a kà pé “olúkúlùkù [wa] jẹ́ ọmọ ẹ̀mí olùfẹ́ ọ̀wọ́n ti àwọn òbí ti ọ̀run, àti pé, bí ó ti rí bẹ́ẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìwà àtọ̀runwá àti kádàrá. … Ní ìṣaájú-ayé ikú, àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ẹ̀mí mọ Ọlọ́run, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run gẹ́gẹ́bí Baba Ayérayé wọn, wọ́n sì gba ètò Rẹ̀ nípa èyí tí àwọn ọmọ Rẹ̀ lè fi gba àgọ́ ara kí wọ́n sì jèrè ìrírí orí ilẹ̀ ayé láti tẹ̀ síwájú sí jíjẹ́pípé àti nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín mọ́ kádàrá tọ́run gẹ́gẹ́bí ajogún ìyè ayérayé.”
Ṣaájú ìbí Rẹ̀ ní ayé ikú, Jésù Krístì farahàn Mósè ó sì bá a sọ̀rọ̀ ní ipò Baba. Ó sọ fún Mósè pé òun ní iṣẹ́ nlá kan fún òun láti ṣe. Lakoko ìpàdé náà, Olúwa pè é ní “ọmọ mi” ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.
Lẹ́hìn ìrírí náà, Sátánì wá láti dán an wò, ó ní, “Mósè, ọmọ ènìyàn, jọ́sìn mi.”
Mósè fèsì sí ìdánwò náà nípa rírántí ìwà àtọ̀runwá rẹ̀, ní sísọ pé: “Ta ni ìwọ? Nítorí kíyèsí i, ọmọ Ọlọ́run ni èmí.” Òtítọ́ dá Mósè sílẹ̀ lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ọ̀tá.
Arákùnrin àti arábìnrin, àwọn ìkọ́ ti ayé ikú jẹ tóòtọ́. Wọ́n sábà máa nfani lọ́kàn mọ́ra, ṣùgbọ́n àfojúsùn kan ṣoṣo ni wọ́n nwá; láti fàwá kúrò nínú ipa ọ̀nà àwọn omi ìyè tó nṣamọ̀nà sí Baba àti ìyè ayérayé.
Mo mọ bí àwọn ìkọ́ ti ayé ikú ṣe lè jẹ tòótọ́. Ní ọjọ́ ìsinmi kan, bíi ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yí padà, mo nkọ́ kíláàsì àlùfáà nígbàtí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò dáni lójú kan dìde. Mo tiraka láti parí ẹ̀kọ́ mi. Mo bínú, mo sì nímọ̀lára pé èmi ni ẹni tí wọ́n jẹ níyà. Láìsọ ọ̀rọ̀ kan, mo kọrí sí ọ̀nà àbájáde náà, pẹ̀lú èrò náà pé èmi kì yíò padà sí ìjọ fún ìgbà díẹ̀.
Ní àkokò náà gan-an olùdìmú oyè-àlùfáà olùkẹ́dùn kan dúró níwájú mi. Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ pè mí láti pọkàn pọ̀ sórí Krístì kì í ṣe ipò tí a ti nírìírí nínú kíláàsì. Bí mo ṣe wo ẹ̀hìn lórí ìrírí náà pẹ̀lú rẹ̀, ó sọ fún mi pé òun gbọ́ ohùn kan tí ó sọ fún òun pé, “Máa tẹ̀ lé e; ó ṣe pàtàkì fún mi.”
Ẹ̀yin ọ̀rẹ̀ mi, gbogbo wa jẹ́ pàtàkì fún Un. Ààrẹ Nelson kọ́ni pé, ”nítorí májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run, Òun kò ní ṣàárẹ̀ láé nínú àwọn ìyànjú Rẹ̀ láti rànwá lọ́wọ́, a kò sì ní tán sùúrù tó kún fún àánú Rẹ̀ pẹ̀lú wa láé.” Ìṣẹ̀dà àtọ̀runwá àti ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run fún wa lẹtọ láti gba ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá.
Ìnílò Ìbọ́ni Náà
Gẹ́gẹ́ bóṣe yẹ kí ẹja salmon jẹ́ bíbọ́ nínú òkun kó tó lè dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa bọ́ ara wa nípa tẹ̀mí ká má bàa kú nítorí àìjẹunrekánú nípa tẹ̀mí. Àdúrà, àwọn Ìwé Mímọ́, tẹ́mpìlì, àti lílọ sáwọn ìpàdé ọjọ́ Ìsinmi ṣe pàtàkì nínú oúnjẹ tẹ̀mí wa.
Ní Oṣù Kọkànlá 1956, Ricardo Garcia, pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀ àti àwọn míràn, wọ inú omi ìrìbọmi ní Chile, ní dídi ọmọ ìjọ àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè mi. Ní ọjọ́ kan péré ṣáájú ikú rẹ̀, ó polongo níwájú àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé, “Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere pè mí láti wá ìdùnnú pẹ̀lú ẹbí mi. Mo jẹ́ onídùnnú ọkùnrin kan. Sọ fún gbogbo ènìyàn ní Chile ìhìnrere ni ìdùnnú.”
Lẹ́hìn tí a ti bọ́ ọ pẹ̀lú ìhìnrere Jésù Krístì, Ricardo ya gbogbo ìgbésí-ayé rẹ̀ sí mímọ́ láti sin Ọlọ́run àti ẹnìkéjì rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́. Apẹẹrẹ jíjẹ́ ọmọẹ̀hín rẹ̀ ti bùkún àwọn ìrandíran, pẹ̀lú èmí. Wòlíì Joseph Smith kọ́ni pé “Ọkùnrin kan tí ó kún fún ìfẹ́ Ọlọ́run, kò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú bíbùkún fún ẹbí rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ó tàn ká gbogbo ayé, tí ó nṣàníyàn láti bùkún fún gbogbo ìran ènìyàn.
Padà sí Ilé Ọ̀run Wa
Jinlẹ̀ nínú ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni ìfẹ́-inú láti padà sí ilé wa ti ọ̀run, Jésù Krístì sì ni ètò ìtọ́sọ́nà ti ọ̀run wa. Òun ni ọ̀nà náà. Ìrúbọ Rẹ̀ mú kí ó ṣeéṣe láti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run. Ní kété tí a bá ṣe àwọn májẹ̀mú, a yíò rí arawa ní lílúwẹ̀ nígbà míràn dojúkọ ìgbì. Ewu, ìjákulẹ̀, ìdánwò, àti ìpọ́njú yíò dán ìgbàgbọ́ àti okun ẹ̀mí wa wò. Bèèrè fún Ìrànlọ́wọ́. Jésù Krístì lóye àti pé ó ní ìtara nígbàgbogbo láti pín àwọn ẹrù wa.
Rántí pé a mọ̀ Ọ́n sí “ọkùnrin tí ó ní ìrora, tí ó sì mọ ìbànújẹ́.” Olùgbàlà kọ́ni pé, “Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.” Ẹbọ ètùtù Rẹ̀ fàyègba ìdárí ẹ̀ṣẹ̀ wá débi pé Òun kò rántí wọn mọ́.
A lè má gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ wa pátápátá gẹ́gẹ́bí ara ikẹkọ ayé ikú nítorí a yíò rántí pé a ò ní tún wọn ṣe mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, a yíò rántí Rẹ̀ bí a ṣe gba oúnjẹ Olúwa ni ilé ìjọsìn ní gbogbo ọjọ́ Ìsinmi. Ìlànà yìí jẹ́ apákan pàtàkì nínú ìjọsìn àti ìdàgbàsókè ẹ̀mí. Ayọ̀ nwá nígbàtí a ní òye wípé èyí kìí ṣe ọjọ́ míràn nìkan. “A dá Ọjọ́ Ìsinmi fún ènìyàn” pẹ̀lú èrò láti fún wa ní ìsinmi kúrò nínú ayé àti láti tún ara àti ẹ̀mí wa ṣe.
A tùn rántí Rẹ̀ nígbàtí a bá lọ sí tẹ́mpìlì—ilé Olúwa. Àwọn tẹ́mpìlì fún wa ní ìmọ̀ ti o jinlẹ̀ nípa Jésù Krístì gẹ́gẹ́bí gbùngbùn májẹ̀mú tí ó darí wa lọ́ síye ayérayé, “tí ó tóbi jùlọ nínú … àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run.”
Lílọ́ tẹ́mpìlì ti fún mi ní ìtùnú àti ìrètí nla nípa kádàrá ayérayé wa. Mo ti ní ìrírí àwọn ìsopọ̀ ọ̀run pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkelè náà. Mo ti ri àwọn ìṣẹ ìyanu ìwòsàn ní ìgbèsì ayé àwọn ọmọ mi kékeré, méjì nínú wọn ngbé pẹ̀lú àwọn àìsàn àìfojúrì tí ó nílò ìtọ́jú ojoójúmọ́ fún ìyókù ìgbésí ayé yí.
Ẹbí wa nyọ̀ bí a ṣe npín nípa ètò ìdùnnú. Ojú àwọn ọmọ mi máa ntàn nígbàtí wọ́n bá gbọ́ pé, ọpẹ́ sí Jésù Krístì, “ìpọ́njú wọn yíò jẹ́ fún ìṣẹ́jú díẹ̀.” A nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wa jinlẹ̀, a sì mọ̀ pé lọ́jọ́ kan, bí Ààrẹ Jeffrey R. Holland ṣe kọ́ni, wọn “yíò dúró níwájú wa ní ìṣelógo àti títóbi, pípé ní ti ara àti ọkàn.” Àwọn májẹ̀mú wa mú wa sún mọ́ Ọlọ́run débi mímú kí ohun tí kò lè ṣeéṣe ṣeéṣe, ní kíkún gbogbo ààyè òkùnkùn àti iyèméjì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ àti àláfíà.
Ọpẹ́ fún Jésù Krístì, ìrètí wà àti àwọn ìdí gbígbékalẹ̀dáradára láti tẹ̀síwájú níní ìfẹ́, gbígbàdúrà, àti ṣíṣe àtìlẹhìn àwọn wọnnì tí a bíkìtà nípa.
Mo mọ̀ pé Ó wà láàyè. Ó mọ̀ wá, àti pé Ó nifẹ wa. Òun ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè ayé.
Mo pe gbogbo wa lónìí láti fi Jésù Krístì àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ ṣe gbùngbùn ayé wa. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yíò rànwá lọ́wọ́ láti yẹra fún jíjẹ ìkọ́ ìdánwò, ìkọ̀sẹ̀, àti àánú ara-ẹni. A yíò dúró bí àwọn tẹ́mpìlì—mímọ́, dídúróṣinṣin àti láìyẹsẹ̀. A yíò kojú ìjì náà, a yíò rí ọ̀nà wa sí ilé, a yíò máa faradà á dé òpin, a yíò sì máa yọ̀ dé òpin. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.