Ṣíṣìkẹ́ Ìgbésí Ayé
Ayé jẹ́ apákan iyebíye jùlọ ti ètò pípé Baba wa, àti pé nípa àṣẹ Rẹ̀ à nṣìkẹ́ à sì ndá ààbò bo ìyè.
Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, kọ́ wa, “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn mi, tí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.”
Bíṣọ́ọ̀pù kan ní Utah láìpẹ́ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú mi nípa ìtújáde ìfẹ́ kan nínú wọ́ọ̀dù rẹ̀ fún ọ̀dọ́mọbìnrin kan àti ẹbí rẹ̀. Nínú oríṣiríṣi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ rírẹwà, àwọn òbí náà pinnu láti padà sọ́dọ̀ Olùgbàlà àti Ìjọ Rẹ̀. Ní ìgbà àkokò tí wọ̀n jìnnà sí Ìjọ, ọ̀dọ́mọbìnrin wọn wà pẹ̀lú ọ̀dọ́mọkùnrin kan. Ní ìpadàbọ̀, ọmọbìnrin iyebíye yí ní ìmọ̀lára ìfẹ́ nlánlá láti ọ́dọ́ Baba rẹ̀ Ọ̀run ní ìgbà ìpàdé ẹ̀rí ti àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin kan. Ó pinnu láti gbé àwọn òfin náà ní kíkún síi. Ó kọ pé, “Mo bẹ̀rẹ̀ ètò ìrònúpìwàdà pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù mi.”
Láìpẹ́ lẹ́hìnnáà, ó ṣe àìsàn. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Àyẹ̀wò [kan] fihàn … pé mo ti lóyún. Mo … bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. … Baba mi wé mi nínú apá rẹ̀ ó sì mu dá mi lójú pé ohun gbogbo [yíò] dára. … Ọ̀rẹ́kùnrin mi … ní kí npa ọmọ náà. … Mo kọ̀ jálẹ̀.”
Títọ́jú àwọn Wọnnì nínú Àìní
Ó tẹ̀síwájú: “Mo ti gba ìfẹ́ púpọ̀ gan àti àtìlẹhìn láti ọ̀dọ̀ ẹbí wọ́ọ̀dù wa. Ó ti jẹ́ ìbonimọ́lẹ̀. Bíṣọ́ọ̀pù àti ààrẹ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin [mi] ti lọ sókè wọ́n sì kọjá láti fi ìfẹ́ àti àtìlẹhìn wọn hàn. … Mo ti rí ọwọ́ Ọlọ́run … tí ó ntọ́ mi àti ẹbí mi sọ́nà. … Wọ́ọ̀dù kan bíi ti tèmi ni ẹbí tí gbogbo ènìyàn nílò, nípàtàkì [fún] ọ̀dọ́mọbìnrin kan ní ipò mi.”
Òun àti ẹbí rẹ̀, àti ẹbí wọ́ọ̀dù rẹ̀, fi pẹ̀lú ìfẹ́ ki ọmọdékùnrin náà káàbọ̀ ní Oṣù Kejì.
Ààrẹ Russell M. Nelson wípé, “Àmì pàtàkì ti Ìjọ òtítọ́ àti alààyè yíò jẹ́ ìṣèto … ìtiraka láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí olúkúlùkù àwọn ọmọ Ọlọ́run nígbàgbogbo … [ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú ìfẹ́ni-inúrere] sí ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí Òun ti ṣe.”
Ṣíṣèrànwọ́ àwọn Yíyàn Òdodo
Nígbàtí obìnrin àdánìkanwà kan bá mọ̀ pé òun nretí ọmọ àìròtẹ́lẹ̀ kan, àníyàn ìlera, rúdurùdu ti ẹ̀mí, ìdójútì, ìdàmú owó, àwọn ìbèèrè ti ẹ̀kọ́, àìnírètí ìgbeyàwó, àti ìbànújẹ́ ti àlá ti kò ṣẹ lè, ní àkokò ìrora kan àti ìbẹ̀rù, darí elerò obìnrin láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ ti yíò mú ìrora àti àbámọ̀ jíjìnlẹ̀ wá.
Fún ẹnikẹ́ni tí ó nfetísílẹ̀ tí ó ti ní ìrírí ìrora àti àbámọ̀ jíjinlẹ̀ kúrò ní níní tàbí kópa nínú ìṣẹ́yún, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ránti: Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò lè yí ti àtẹhìnwá padà, Ọlọ́run lè wo àtẹ̀hìnwá sàn. Ìdáríjì lè wá nípasẹ̀ ìyanu ti oore-ọ̀fẹ́ ètùtù Rẹ̀ bí a ti nyí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn ìrònúpìwàdà àti ìrẹ̀lẹ̀.
Àwọn ọ̀rọ̀ méjì ni à nlẹ̀pọ̀ nígbàkugbà sí ipò mímọ́ ti ìbí ayé ikú: ayé àti yíyàn. Ayé jẹ́ apákan iyebíye jùlọ ti ètò pípé Baba wa, àti pé nípa àṣẹ Rẹ̀ à nṣìkẹ́ ìyè à sì ndá ààbò bo ìyè; a sì nyàn ìtẹ̀síwájú ti ìyè bí a ti bíni nígbàkan. Bákannáà a nṣìkẹ́ ẹ̀bùn ìwà agbára òmìnira—ní ṣíṣerànwọ́ láti fún àwọn yíyàn òdodo lókun bí a ti pàṣẹ nípasẹ̀ Ọlọ́run tí ó nmú ìdùnnú ayérayé wá.
Nígbàtí obìnrin kan àti ọkùnrin kan bá wà nínú irú àkokò ẹlẹgẹ́ kan, tí wọ́n dojúkọ yíyàn líle, àwọn ọ̀rọ̀ wa, ọwọ́ wa, ọkàn wa—níti ẹ̀mí, níti ẹ̀dùn ọkàn, àti níti owó—lè bùkún wọn láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olùgbàlà àti, bí Ààrẹ Henry B. Eyring ti sọ, mú híhàn kedere àtúnṣe sí ojú ti ẹ̀mí wọn látinú “ohun tí wọ́n rò pé wọ́n rí” sí “ohun tí wọn kò tíì lè rí síbẹ̀.”
Ẹ̀kọ́ Ìgbésí Ayé Ikú
Ààrẹ Dallin H. Oaks wípé: “Ìhùwàsí wa sí ìṣẹ́yún kò dá lé ìmọ̀ tí a fihàn nípa ìgbàtí ìgbé ayé ikú bẹ̀rẹ̀. … Ó ndi àtúnṣe nípa ìmọ̀ wa pé … gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀mí Ọlọ́run gbọ́dọ̀ wá sí ilẹ̀ ayé fún èrèdí ológo, àti pé ìdánimọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ ṣíwájú ìbí yíò sì tẹ̀síwájú fún gbogbo ayé àìlópin tó nbọ̀.”
Ọ̀rọ̀ Olúwa nípa àìbí, ohùn tí a fúnni nípasẹ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, kò tíì jẹ́ onírurú rí ó sì ntún àwọn ọ̀rọ̀ náà sọ nípa àwọn wòlíì ní gbogbo àwọn ọjọ́, ó nfúnni ní ìmọ́ kedere tọ̀run sí ohun tí Olúwa ti bèèrè lọ́wọ́ wa.
“Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn gbàgbọ́ nínú ìwà mímọ́ ayé ẹ̀dá. Nítorínáà, Ìjọ tako ṣíṣẹ́ oyún fún araẹni tàbí ìrọ̀rùn àwùjọ, ó sì gba àwọn ọmọ Ìjọ ní àmọ̀ràn láti kọ̀ ọ́, má ṣe ṣeé, gbìyànjú, sanwó fun, tàbí ṣe ètò fún irú ìṣẹ́yún bẹ́ẹ̀.
“[Olúwa] fi ààyè gba àwọn àyọkúrò tó ṣeéṣe … nígbàtí:
-
Oyún bá wá látinú ìfipa-bánilò tàbí ìbálòpọ̀ ẹbí, tàbí
-
Amòye olùwòsàn pinnu pé ìyè tàbí ìlera ìyá wà nínú ewu líle, tàbí
-
Amòye olùwòsàn pinnu pé ọlẹ̀ inú ní àbùkú olóró tí kò ní jẹ́ kí ọmọ náà yè kọ́já ìbí.”
Àjọ Ààrẹ Ìkínní tẹ̀síwájú: “Ìṣẹ́yún jẹ́ ọ̀ràn lílè jùlọ. [Àní nínú àwọn ipò tó ṣọ̀wọ́n wọ̀nyí] ó níláti jẹ́ yíyẹ̀wò lẹ́hìn tí àwọn ẹni tó kàn bá ti gba ìmúdánilójú nípasẹ̀ àdúrà” tí wọ́n si bá àwọn míràn dámọ̀ràn.
Ọgbọ̀n ọdún sẹ́hìn, àwọn wòlíì Olúwa ṣe àtẹ̀jáde ìkéde sí àgbáyé. Ó pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:
“A … kéde pé Ọlọ́run ti pàṣẹ pé agbára mímọ́ ti ìṣẹ̀dá ni a gbọ́dọ̀ mú ṣiṣẹ́ ní àárín ọkùnrin àti obìnrin nìkan, tí a ṣe ìgbeyàwó fún lábẹ́ òfin bíi ọkọ àti aya.
“A kéde ọ̀nà èyí tí a ti nda ìgbé ayé-ikú sílẹ̀ láti jẹ́ yíyàn tọ̀run. A tẹnumọ́ ìwà-mímọ́ ìgbésí-ayé àti pàtàkì rẹ̀ nínú ètò ayérayé Ọlọ́run.”
Ṣíṣìkẹ́ àti dídá ààbò bo ìgbésí-ayé tí a kò tíì bí kìí ṣe ipò òṣèlú kan. Ó jẹ́ òfin ìwà kan láti ọwọ́ Olúwa nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀.
Sísọ̀rọ̀ Síta Síi
Ẹ̀là ọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ààrẹ J. Reuben Clark Jr., ẹni tí ó sìn nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, júwe dídára àwọn ọ̀dọ́ wa ní òní: “Àwọn ọ̀dọ́ Ìjọ npebi fún àwọn ohun Ẹ̀mí; wọ́n sì ní ìtara láti kọ́ ìhìnrere, wọ́n sì nfẹ́ ẹ ní tààrà, àìládàlù. Wọ́n nfẹ́ láti mọ̀ nípa … àwọn ìgbàgbọ́ wa; wọ́n fẹ́ láti jèrè àwọn ẹ̀rí ti òtítọ́ [náà]. Wọ́n jẹ́ … àwọn òlùbèèrè, tí wọ́n nwa òtítọ́.” Ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ léraléra síi pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti àánú sí àwọn ọ̀dọ̀ wa nínú ilé, àti nínú àwọn ìpàdé Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ àti Iyejú àwọn Alàgbà, nípa òfin ìparaẹnimọ́ ti Olúwa, ìwà-mímọ́ ti ìgbésí ayé, àti ìtọ́jú àwọn tí a kò tíì bí àti ìyá wọn.
Arábìnrin ọ̀wọ́n kan kọ̀wé sí mi nípa ìrírí kan tí ó ní ní àwọn díkédì sẹ́hìn: “Gẹ́gẹ́bí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún … , mo rí ara mi nínú oyún pẹ̀lú àìní tàbí àtìlẹhìn díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́kùnrin mi. Ojú tì mí mo sì dánìkanwà [ṣùgbọ́n èmi] kò yẹ [ṣíṣẹ́yún] wò rí. … Mo [ní] àwọn olùfẹ́ni ẹbí mi àti bíṣọ́ọ̀pù, ẹnití mò npadé déédé fún ìtọ́nisọ́nà. … Mo yí sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Mo ṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ … mo sì gbàdúrà [mo sì] rí okun nínú Olùgbàlà mi àti ètò ìrònúpìwàdà. … Mo gba ìdáhùn kan [sí àwọn àdúrà mi] tí èmi kò lè sẹ́. … Ó jẹ́ ìbanilọ́kànjẹ́, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé èmi yíò gbé ọmọbìnrin mi lọ fún àgbàtọ́. … Mo gbàdúrà fún ìgboyà [mo sì] ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olùgbàlà kedere gidi nípa ìrònúpìwàdà, mo mọ̀ pé Ọlọ́run … ndáhùn àwọn àdúrà ó sì nfún wa lókun.”
Olùfẹ́ni tọkọtaya kan gba ọmọdébìnrin iyebíye wọn tọ́ wọ́n sì kọ́ ní ìhìnrere. Ó ti ṣe ìgbeyàwó nisisìyí pẹ̀lú ẹbí rirẹwà kan ti ara rẹ̀.
Nígbàmíràn, ìṣòro àti ìrora jíjinlẹ̀ àìnírètí lè bá ààbò ìgbésí ayé rìn.
Láìpẹ́ tọkọtaya ọ̀dọ́ kan tí Kathy àti èmi fẹ́ràn kọ̀wé sí mi nípa iyebiyé ọmọ wọn tí wọ́n nretí.
Baba náà kọ̀wé: “[Nígbàtí ìyàwó mi wà ní] ọ̀sẹ̀ kẹwa oyún a ri pé ọmọ ìyanu wa wà ní ipò ìran ti trísómì mọ́kànlélógún tí a mọ̀ ní ibi-gbogbo sí àìsàn àìlera. A ní ìmọ̀lára ìtẹ̀mọ́lẹ̀ … láti ààyè ìwòsàn láti yẹ ìfòpinsí wò. Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́hìnnáà a ri pé … ọmọ wa tí a kò tíì bí … yíò nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ abẹ ọkàn ní ọdún àkọ́kọ́ ayé rẹ. Nínú gbogbo ètò yí bí a ti ngbàdúrà taratara fún ìrànlọ́wọ́ tọ̀run, … a ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí ti ó nfún wa ní ìtùnú. A gba ìfihàn a sì ní òye pé ọmọbìnrin wa jẹ́ ọmọ olùtayọ ti Baba Ọ̀run ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀ gan láti wà nínú ẹbí wa àti láti wá sí ilẹ̀-ayé.”
Ìyá ọmọ yí kọ̀wé pé: “[A] ní ìdẹ́rùbà, ìdàmú, lódodo a sì di rúdurùdu tán pátápátá nípa ìròhìn náà. … Nígbàtí mo wà nínú oyún ọ̀sẹ̀ mẹ́rìnlá, a ri pé ọmọ wa ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìlera àwọn àrùn ọkàn, ọ̀kan tí ó lè jẹ́ ìpani líle. A rí àwọn àìlónkà dókítà àti ọ̀jọ̀gbọ́n láti ọ̀sẹ̀ kẹwa sí méjìdínlógún oyún. … Ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpinnu láti pàdé wa, wọ́n máa nbèèrè bí a bá fẹ́ láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú oyún tàbí kí a fòpinsi . … Olùgbàlà wo ọkàn mi sàn ó sì fún mi ní ọgbọ́n ti àláfíà àti ìdùnnú nípa ọmọbìnrin wa. … [Baba Ọ̀run] ti fihàn mi nígbàkan àti nígbàkan síi pé Òun ní ètò pípé fún mi [mo sì] gbẹ́kẹ̀lé E.”
Wọ́n fi inúdídùn kí ọmọbìnrin wọn káàbọ̀ ní ọ̀sẹ̀ kan gééré sẹ́hìn ní òní. Ó wà nínú tiwọn wọ́n sì jẹ́ tirẹ̀ títíláé.
Ìgbàgbọ́ àìmikàn àti ìgboya alámì ni àmì pàtàkì ti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì.
Àpẹrẹ Ìgbàgbọ́ Alámì Kan
Ní àwọn ọdún náà, mo ti ní ànfàní láti pàdé pẹ̀lú àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti fi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ wá láti padà sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú àti sí oyè-àlùfáà àti àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́hìn tí wọ́n ti pàdánù jíjẹ́ ọmọ ìjọ.
Ní ìgbà kan, ó yẹ kí nṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún ọkùnrin kan ní ìtìlẹhìn Àjọ Ààrẹ Ìkínní fún ìmúpadàbọ̀sípò oyè-àlùfáà àti àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì rẹ̀.
Lẹ́hìn ìgbéyàwó rẹ̀ nínú tẹ́mpìlì mímọ́, àti lẹ́hìn níní àwọn ọmọ ìyanu mẹ́ta, ọkùnrin yí ṣe àìṣòdodo sí ìyàwó rẹ̀ àti àwọn májẹmú mímọ́. Obìnrin àdánìkanwa lóyún ó sì fẹ́ ṣe ìṣẹ́yún.
Ẹni mímọ́ ìyàwó ọkọ náà bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú obìnrin náà lati bi ọmọ náà ó sì ṣe ìlérí pé òun yìò tọ́ ọmọ náà nígbatí a bá bíi pẹ̀lú àwọn ọmọ ti ara òun.
Obìnrin àdánìkanwà náà pẹ̀lú èrò faramọ kí ó máṣe ṣẹ́ oyún náà.
Ó ti di ọdún mẹwa bayi. Obìnrin onírẹ̀lẹ̀ náà joko ní iwájú mi ó fẹ́ràn ọmọdékùnrin náà bí ti ara rẹ̀ ó sì wí fún mi nípa ìtiraka ọkọ rẹ̀ láti ṣe àtúnṣe àti láti fẹ́ràn àti láti tọ́jú rẹ àti ẹbí náà. Baba náà sọkún bí ó ti nsọ̀rọ̀.
Báwo ni obìnrin akọni Ọlọ́run yí ṣe lè gba ọmọ náà bíi ti ara rẹ̀ èyí tí ó lè jẹ́ ìrántí ojojúmọ́ ti àìṣododo ọkọ rẹ̀? Báwo? Nítorí ó rí okun nípasẹ̀ Jésù Krístì ó sì gbàgbọ́ nínú jíjẹ́ mímọ́ ìyè, ìwà mímọ́ ti ìyè. Ó mọ̀ pé ọmọ tí a kò tíì bí náà jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, aláìmọ̀kan àti aláìléèrí.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìfẹ́ dídínkù fún àwọn ọmọ àìtíìbí káríayé jẹ́ àníyàn burúkú kan. Ọlọ́run nṣìkẹ́ ìgbésí ayé. Ó jẹ́ iṣẹ́ Rẹ̀ àti ògo Rẹ̀ láti mú àìkú àti ìyè ayérayé wá fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn ti Jésù Krístì, a nṣìkẹ́ ìgbésí ayé. “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn mi, tí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.” Njẹ́ kí a pín ìfẹ́ wa àní ní lọ́pọ̀lọpọ̀ síi pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n nílò wa pẹ̀lú ìtara. Mo fi ìfẹ́ mi hàn fún yín àti ìfẹ́ Baba wa Ọ̀run fún àwọn ọmọ Rẹ̀ tí ó nbọ̀ ní ilẹ̀ ayé. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.