Àwọn Àkókò Ìmúpadà Ohun Gbogbo
(Ìṣe 3:21)
“Ìròhìn rere” to jẹ́ pàtàkì àti ológo jùlọ ni ọ̀rọ̀ náà pé Olúwa Jésù Krístì ti mú ìhìnrere àti Ìjọ Rẹ̀ padàbọ̀sípò ní awọn ọjọ́ ìkẹhìn.
Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn ni a dásílẹ̀ ní ọdún máàrúndínlọ́gọ́wàá sẹ́hìn lónìí, ní Ọjọ́ Kẹfà, Oṣù Kẹrin 1830.
Àpéjọpọ̀ kékeré kan ti àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ọ̀rẹ́ kórajọ fún àkókò pàtàkì àti aláyọ̀ náà. Ìtújáde nlá ti Ẹ̀mí bùkún gbogbo awọn tí wọ́n wà níbẹ̀ bí ìlànà oúnjẹ Olúwa ti di pípinfúnni, tí ẹbùn Ẹmí Mímọ́ di fífúnni, àwọn ìfòróróyàn oyè-àlùfáà di ṣíṣe, àwọn òtítọ́ ìhìnrere Jésù Krístì di wíwàásù.
Ní ṣíṣe àtúngbékalẹ̀ ìjọ Rẹ̀, nípa ìfihàn Olúwa yan Joseph Smith ẹni ọjọ́ orí ọdún mẹ́rìnlélógún bíi olórí rẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé: “aríran, olùtúmọ̀, wòlíì, àpóstélì Jésù Krístì, alàgbà ìjọ nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run Baba, àti oore ọ̀fẹ́ Olúwa rẹ Jésù Krístì.”
Mo fi ìtara gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ ti Ẹmí Mímọ́ bí a ti ngbèrò pàtàkì àti ipa tó nlọ lọ́wọ́ ti ìṣẹ̀lẹ̀ kanṣoṣo yìí ninu ìtàn àgbáyé.
Ìran Ìkínní
Ìṣètò Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn lábẹ́ àṣẹ jẹ́ àkópọ̀ àwọn ìrírí ìyanu ọ̀kọ̀ọ̀kan. Àkọ́kọ́ àwọn ìrírí wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ ní ọdún mẹ́wàá ṣaájú ní New York.
Ní ìgbà ìrúwé 1820, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Joseph Smith lọ sínú àwọn igi ní ẹ̀bá ilé rẹ̀ láti gbàdúrà. Ó ní àwọn ìbéèrè nípa ìgbàlà ẹ̀mí rẹ̀, ó sì pòùngbẹ “láti mọ èwo nínú gbogbo [àwọn ìjọ] ló tọ́, pé kí [òun] le mọ èyí tí yíó darapọ̀ mọ́.” Jósẹ́fù ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run yíó dáhùn àdúrà òun yíò sì darí rẹ̀.
Jọ̀wọ́ kíyèsíi pé Jósẹ́fù kò gbàdúrà lásán láti kàn mọ ohun tí ó tọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gbàdúrà láti mọ ohun tí ó tọ́ kí òun le ṣe ohun tí ó tọ́. Jósẹ́fù bèèrè nínú ìgbàgbọ́ ó sì pinnu láti gbé ìgbésẹ̀ ní ìbámu sí àwọn ìdáhùn tí ó gbà.
“Ní [ìdáhùn] sí àdúrà [tòótọ́] rẹ̀, Ọlọ́run Bàbá àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, farahàn sí Jósẹ́fù wọ́n sì ṣe ìfìlọ́lẹ̀ ’ìmúpadà ohun gbogbo’ (Ìṣe Àwọn Àpóstélì 3:21) bí a ṣe sọtẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Nínú ìran yí, ó kọ́ pé lẹ́hìn ikú àwọn ojúlówó Àpóstélì, Ìjọ Krístì ti Májẹ̀mú Titun sọnù kúrò ní ilẹ̀ ayé.” Joseph Smith yíó jẹ́ ohun èlò ní mímú ẹ̀kọ́, àṣẹ, àti àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà Ìjọ àtijọ́ ti Olùgbàlà padà.
Jósẹ́fù fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé: “Mo rí àwọn Ẹni Nlá méjì, àwọn ẹnití ìmọ́lẹ̀ àti ògo wọn ju gbogbo àpèjúwe, wọ́n ndúró ní òkè orí mi nínú afẹ́fẹ́. Ọ̀kàn lára wọn sọ̀rọ̀ sí mi, ó pè mí ní orúkọ ó nawọ́ sí ẹnìkejì, ó wípé—Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ ti Rẹ̀!”
Nípasẹ̀ ìran yìí àti àwọn ìrírí dídárajù tí ó tẹ̀lé, Joseph Smith wá ní òye pé Ọlọ́run àti Jésù Krístì mọ òun bí ẹnìkan, wọ́n ṣe àníyàn nípa ìgbàlà ayérayé rẹ̀, wọ́n sì ní iṣẹ́ fún un láti ṣe. Ó kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì bákannáà nípa àwọn ìṣe, ìwà, àti àwọn ìjẹ́-pípé ti Ọlọ́run-Olórí—àti pé Baba àti Ọmọ jẹ́ Ẹ̀dá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n sì yàtọ̀. Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run gan-an nínú ẹ̀mí àti nínú ẹran ara.
Joseph Smith kéde pé Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì jẹ́ àwọn ẹ̀dá àfojúrí. Ó wí pé, “Baba ní àgọ́ ara ti ẹran ara àti egungun tí ó ṣeé dìmú bíi ti ènìyàn; Ọmọ bákannáà; ṣùgbọ́n Ẹmí Mímọ́ kò ní àgọ́ ara ti ẹran ara àti egungun, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ẹni-nlá ti Ẹmí.”
Mo jẹ́rìí pé ìbẹ̀wò Baba ati Ọmọ sí Joseph Smith ni ìṣẹ̀lẹ̀ bíbẹ̀rẹ̀ nínú pàtàkì “ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo tí a ti sọ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì mímọ́ lati ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀.”
Ìwé Ti Mọ́mọ́nì
Èkejì ninu ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìrírí ìyanu tó darí sí àgbékalẹ̀ lábẹ́ òfin ti Ìjọ Olùgbàlà tí a mú padà bọ̀sípò ni ìyírọ̀padà àti jíjáde wá ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì.
“Joseph Smith ni a fún ní ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run láti ṣe ìyírọ̀padà-èdè àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan: Ìwé ti Mọ́mọ́nì— Ẹ̀rí Míràn ti Jésù Krístì. Àtẹ̀kọ mímọ́ yí ní àkọsílẹ̀ kan nínú nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ araẹni ti Jésù Krístì ní ààrin àwọn ènìyàn ní Ìwọ-oòrùn Ìpín Àyíká Ayé làìpẹ́ lẹ́hìn Àjíìnde Rẹ̀. [Ìwé ti Mọ́mọ́nì] kọ́ni nípa èrèdí ìgbésí ayé ó sì ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Krístì, èyí tí ó jẹ́ ààrin gbùngbun sí èrèdí náà. Bíi ojúgbà ìwé mímọ́ kan sí Bíbélì, Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ẹ̀rí pé gbogbo ènìyàn ẹlẹ́ran-ara jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ti olùfẹ́ni Bàbá Ọ̀run, pé Òun ní ètò tọ̀run kan fún ìgbé ayé wa, àti pé Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, nsọ̀rọ̀ loni bákannáà bí ti ìgbà àtijọ́.”
Bíi ọmọ ìjọ ti Ìjọ Olùgbàlà tí a mú padàbọ̀sípò, “A gbàgbọ́ pé Bíbélì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣe ìyírọ̀padà rẹ̀ ní pípé; a gbàgbọ́ bákannáà pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì, ó fi ẹsẹ̀ jíjẹ́ òtítọ́ Bíbélì múlẹ̀, ó sì ṣe ìmúpadàbọ̀sípò àwọn òtítọ́ kedere àti iyebíye tí ó sọnù láti inú Bíbélì.
Oyè-àlùfáà Di Mímúpadàbọ̀sípò
Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kọ́ni pé ojúlówó Ìjọ tí a gbékalẹ̀ láti ọwọ́ Olùgbàlà, pẹ̀lu àṣẹ, ẹ̀kọ́, ati awọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà àtọ̀runwa, ni sọnù kúrò lórí ilẹ̀ ayé tẹ́lẹ̀. Bíi apákan ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo ni àwọn ọjọ́ ìkẹhìn tí a ti sọtẹ́lẹ̀, àwọn wòlíì ati awọn àpóstélì ìgbàanì fúnra arawọn fi àṣ̣ẹ oyè-àlùfáà sí orí Joseph Smith wọ́n sì fún un ní awọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà. Èyí ni ìkẹta nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìrírí ìyanu náà tó darí sí àgbékalẹ̀ lábẹ́ òfin ti Ìjọ Olùgbàlà tí a múpadàbọ̀sípò.
Àṣẹ oyè-àlùfáà ngba àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láàyè láti “ṣe aṣojú [Òun] kí wọn ó sì ṣe àwọn nkan ni orúkọ Rẹ̀.” “Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà jẹ́ àṣẹ láti darí ìlò oyè-àlùfáà, ní ìtìlẹ́hìn awọn ọmọ Ọlọ́run.”
Lábẹ́ ìdárí ti Baba àti Ọmọ, Jòhánnù onírìbọmi tó ti jíìnde mú àṣẹ láti ṣe ìrìbọmi nípa rírini-sínú omi padàbọ̀sípò, ní 1829, fún ìmúkúrò awọn ẹ̀ṣẹ̀. Ní ọdún kannáà, mẹ́ta nínú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá àkọ́kọ́—Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù—mú jíjẹ́ àpọ́stélì àti kọ́kọ́rọ́ àṣẹ oyèàlùfáà padàbọ̀sípò.
Ọdún mẹ́fà lẹ́hìn àgbékalẹ̀ Ìjọ náà, nínú Tẹ́mpìlì Kirtland, Mósè, Èlíásì, àti Èlíjàh fún Jósẹ́fù ní àfikún àṣẹ tí ó ṣe dandan lati yọrí iṣẹ́ Ọlọ́run ní awọn ọjọ́ ìkẹhìn.
Mósè fún un ní awọn kọ́kọ́rọ́ ti kíkó Isráẹ́lì jọ.
Èlíásì fún un ní iṣẹ́ ìríjú ti ìhìnrere Ábráhámù, èyí tí ìmúpadàbọ̀sípò májẹ̀mú ti Ábráhámù wà nínú rẹ̀.
Èlíjà fún un ní àwọn kọ́kọ́rọ́ agbára fífi èdìdi dì, ní pípèsè àṣẹ tó fi ààyè gba àwọn ìlànà tó bá jẹ́ ṣíṣe ní orí ilẹ̀ ayé láti wúlò ní ayérayé, bí irú síso àwọn ẹbí papọ̀ nínú àwọn ìbáṣepọ̀ ayérayé ti yíó tayọ ikú.
Ìjọ Jésù Krístì di Gbígbékalẹ̀
Bí Joseph Smith ti ṣe ìyírọ̀padà Ìwé Ti Mọ́mọ́nì, ó gba àwọn ìfihàn tí ó tọ́ka sí pé Ìjọ Jésù Krístì yíó tún di gbígbékalẹ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Jósẹ́fù pé kó má gbé Ìjọ náà kalẹ̀ ní kíákíá. Dípò bẹ́ẹ̀, “nípa ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfihàn” Olúwa fi hàn sí Jósẹ́fù “ọjọ́ gan-an tí [òun] yíó tẹ̀síwájú láti ṣe àgbékalẹ̀ Ìjọ Rẹ̀ [lẹ́ẹ̀kansíi,] lórí ilẹ̀ ayé.”
Ìjọ náà jẹ́ gbígbékalẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan tó tọ́ lẹ́hìn ìmúpadàbọ̀sípò oyè-àlùfáà àti títẹ̀jáde Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Àwọn ẹ̀dà àkọ́kọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì di wíwà ní àrọ́wọ́tó ní Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n Oṣù Kẹta, 1830, Ìjọ sì di gbígbékalẹ̀ lábẹ́ àṣẹ ni Ọjọ́ Kẹfà Oṣù Kẹrin.
“Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ Ìjọ Májẹ̀mú Titun ti Krístì tí a múpadàbọ̀sípò. Ìjọ yí ni ó mú dúró nínú ìgbé ayé pípé ti òkúta pàtàkì igun-ile, Jésù Krístì, àti nínú Ètùtù Àìlópin àti Àjíìnde Rẹ̀ gan-an. Jésù Krístì ti pe àwọn Àpọ́stélì lẹ́ẹ̀kansi ó sì ti fún wọn ní àṣẹ oyèàlùfáà. Ó pe gbogbo wa láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀, láti gba Ẹ̀mí Mímọ́, àwọn ìlànà ìgbàlà, àti láti jèrè ayọ pípẹ́.”
Ìgbà Iṣẹ́ Ìríjú ti Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn Àkókò
Ìfarahàn Baba àti Ọmọ sí Joseph Smith, ìyírọ̀padà àti jíjáde wa Ìwé ti Mọ́mọ́nì, àti ìmupadàbọ̀sípò àṣẹ àti awọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà jẹ́ awọn ohun bíbèèrè fún dandan sí àgbéáde kalẹ̀ Ìjọ ti Olúwa tí a mú padà sípò ní ọdún marundín-nígba sẹ́hìn lónìí.
Nínú Májẹ̀mú Láéláé, wòlíì Dáníẹ́lì túmọ̀ àlá kan nípa okúta kan tí a ó gé jáde láti ara òkè kan láìsí àwọn ọwọ́ tí yíó sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé. Ọdún kan lẹ́hìn àgbékalẹ̀ Ìjọ náà, Olúwa sọ fún Joseph Smith pé awọn kọ́kọ́rọ́ ijọba Ọlọ́run ni a ti “fi fún ènìyàn lẹ́ẹ̀kansi ní orí ilẹ̀ ayé” àti pé “ìhìnrere [ti Jésù Krístì yíó] yí jáde sí awọn ìkangun ilẹ̀ ayé, bí okúta náà tí a gé jáde láti ara òkè láìsí àwọn ọwọ́.”
Mo jẹ́rìí pé: Olúwa nmú àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ. Ìjọ ti Olùgbàlà tí a múpadàbọ̀sípò ni a ti gbékalẹ̀ jákèjádò àgbáyé ó sì jẹ́ ohun èlò nípa èyítí Ọlọ́run yíò “kó àwọn ohun gbogbo jọ ní ọ̀kan nínú Krístì, méjèèjì èyí tí ó wà ní ọ̀run, àti èyí tí ó wà ní ilẹ̀ ayé; àní nínú rẹ̀” .
Iṣẹ́ ti Olúwa ní ọjọ́-ìkẹhìn “jẹ́ iṣẹ́ tí ó tì dùnmọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run nínú ní gbogbo ìgbà; ó jẹ́ àkórí lórí èyí tí àwọn wòlíì, àwọn àlùfáà àti àwọn ọba ti gbé pẹ̀lú adùn àrà ọ̀tọ̀; wọ́n ti fojúsọ́nà pẹ̀lú ìrètí aláyọ̀ sí ọjọ́ náà nínú èyí tí a ngbé; àti ní gbígbóná pẹ̀lú àwọn ìrètí tọ̀run àti aláyọ̀ tí wọ́n ti kọrin tí wọ́n sì ti kọ̀wé tí wọ́n sì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa yìí.”
Nínú àkókò títóbijùlọ ati ìkẹhìn ti gbogbo iṣẹ ìríjú ìhìnrere yìí, “ìdàpọ̀ odidi àti pátápátá àti pípé, àti síso papọ̀ ti àwọn àkókò iṣẹ ìríjú, ati awọn kọ́kọ́rọ́, ati awọn agbára, ati awọn ògo níláti ṣẹlẹ̀, kí ó sì jẹ́ fífihàn láti awọn ọjọ́ Ádámù àní títí di àkókò yí. Kìí sì í ṣe èyí nìkan, ṣùgbọ́n àwọn ohun wọnní èyí tí ìbá májẹ̀ fífihàn láé láti ìpìlẹ̀sẹ̀ ayé … yíó jẹ́ fífihàn … nínú èyí, ìgbà iṣẹ́ ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò.”
Wòlíì Jósẹ́fù ṣàlàyé síwájú pé, “Gbogbo àwọn ìlànà àti ojúṣe ti ó ti jẹ̀ bíbèèrè rí láé nipasẹ̀ Oyè-àlùfáà, lábẹ́ ìdarí ati awọn aṣẹ Alágbára Jùlọ nínú èyíkéyi àwọn àkókò iṣẹ ìríjú, ni gbogbo rẹ̀ yíó jẹ́ níní ní àkókò iṣẹ ìríjú ti ìkẹhìn … ní mímú ìmúpadàbọ̀sípò tí a ti sọ nípa rẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn Wòlíì Mímọ́ wá sí ìmúṣẹ.”
Àwọn Ìlérí àti Ẹrí
Mo ti gbìyànjú láti ṣe ìkékúrú àwọn èròjà “ìròhìn dídára” tó jẹ́ pàtàkì àti ológo jùlọ tí ẹnikẹ́ni níbikíbi ní àgbáyé le gbà—ọ̀rọ̀ náà pé Olúwa Jésù Krístì ti mú ìhìnrere àti Ìjọ Rẹ̀ padàsípò ní awọn ọjọ́ ìkẹhìn.
Mo pe gbogbo enìyàn láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa kí wọn ó sì dán ọ̀rọ̀ yí wò. Mo jẹ́rìí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan “tí ó bá fi tàdúrà-tàdúrà ṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ímúpadàbọ̀sípò náà àti ìṣe nínú ìgbàgbọ́ yíò di alábùkúnfún [nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́] láti jèrè ẹ̀rí ti arawọn nípa jíjẹ́ ti ọ̀run rẹ̀ àti nípa èrò rẹ̀ láti pèsè ayé sílẹ̀ fún ilérí Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.” Bí ẹ ti nfi ìtara gbàdúrà pẹ̀lú ìrètí láti rí gbà àti láti gbé ìgbésẹ̀ lórí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ọ̀dọ́mọdé Joseph Smith ti ṣe, agbára yín láti mọ̀ kí ẹ sì dáhùn sí ẹ̀rí àtọ̀runwá náà yíó pọ̀ síi.
Mo jẹri pé Ọlọ́run, Baba Ayérayé, ni Baba wa. Mo jẹ́rìí mo sì ṣe ẹlẹ́rìí pé Jésù Krístì ni Àyànfẹ́ Ọmọ ti Baba àti Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo Rẹ̀ nínú ẹran ara. Òun ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa.
Mo sì fi tayọ̀tayọ̀ jẹ́ríì pé Baba àti Ọmọ farahàn sí ọ̀dọ́mọkùnrin Joseph Smith, nipa báyi ó bẹ̀rẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì ní awọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ìwé ti Mọ́rmọ́nì ni ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì ó sì ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú. Àṣẹ oyè-àlùfáà láti ṣojú fún Olùgbàlà kí a sì ṣe nkan ní orúkọ Rẹ̀ ni a tún rí ní orí ilẹ̀ ayé lẹ́ẹ̀kansíi. Àti pé Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni Ìjọ Májẹ̀mú Titun ti Krístì tí a múpadàbọ̀sípò. Mo jẹ́ ẹ̀rí mi tó dájú pé gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́ ní orúkọ mímọ́ Olúwa Jésù Krístì, Àmín.