Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Ẹ Padà sí Ọ̀dọ̀ Mi … Kí Èmi Ó Lè Wò Yín Sàn”
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


11:2

“Ẹ Padà sí Ọ̀dọ̀ Mi … Kí Èmi Ó Lè Wò Yín Sàn”

Ayọ̀ yíyọ̀ wà ní ọ̀run lórí àwọn tí wọ́n padà wá. Kò tí ì pẹ́jù fún yín láti padà wá.

A gbé ní ilé kan rí tí ó ní àwọn igi dáradára ní àyíká rẹ. Ní ẹ̀bá ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ni igi wílò tó rẹwà kan wà. Ní òru ìbànújẹ́ kan ìjì líle nlá kan fẹ́, wílò náà sì wó lulẹ̀. Ó nà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn gbòngbò rẹ̀ ní fífà sóde ó sì jẹ́ ìran tó gba ìrònú.

Mo ti ṣetán láti lo ẹ̀rọ rẹ́girẹ́gi kí n sì gé igi nà fún ìdáná nígbàtí aládùúgbò wa sáre wá láti dámi dúró. Ó bá mi wí fún ṣíṣe àròpin lórí igi náà ó sì rọ̀ wá pẹ̀lú àtẹnumọ́ láti máṣe ju igi náà nù. Lẹ́hìnnáà ó tọ́ka sí gbòngbò kan tí ó ṣì wà nínú ilẹ̀ ó sì wí pé bí a bá gbé igi náà sókè, tí a gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀, tí a sì tọ́jú rẹ̀, pé àwọn gbòngbò náà yíó mú un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi.

Igi wílò to ṣubú.
Gbòngbò igi ẹyọkan tó ṣẹ́kù nínú ilẹ̀.

Èmi kò gbàgbọ́ mo sì ṣiyèméjì bí igi kan, tó hàn tóbẹ́ẹ̀ pé ó ti ṣubú tó sì wà nínù ìyọnu, ti lè ṣeéṣe kí ó yè kí ó sì padà sáyé. Mo ròó pé bí ó bá tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà lẹ́ẹ̀kansíi, dájúdájú kò le ye ìjì tó máa tẹ̀lé. Ṣùgbọ́n ní mímọ̀ pé aládùúgbò wa gbàgbọ́ pé igi náà ṣì ní ọjọ́ ọ̀la, a lọ pẹ̀lú ètò náà.

Igi to wà ní ìhòhò.
Àwọn àmì dídàgbà lára igi náà.

Àti abájáde náà? Lẹ́hìn àkókò díẹ̀, a rí àwọn àmì ìyè bí igi náà ti bẹ̀rẹ̀ sí fi gbòngbò múlẹ̀. Báyìí, ní ọdún méjìlá lẹ́hìnwá, igi náà lágbára ó sì kún fún ìyè pẹ̀lú àwọn gbòngbò líle àti pé, lẹ́ẹ̀kansíi ó nfikún ẹwà àdúgbò náà.

Igi to lágbára to sì jípépé.

Bí mo ti npàdé àwọn Ènìyàn Mímọ́ káàkiri àgbáyé, a nránmilétí nípa igi wílò yí àti bí ìrètí ti wà àní nígbàtí ó dàbí pé gbogbo rẹ̀ ti sọnù. Àwọn kan ti fìgbà kan rí ní àwọn ẹ̀rí nípa ìhìnrere tí ó le to si lágbára bíi wílò náà. Lẹ́hìnnáà, fún àwọn ìdí ti araẹni àrà ọ̀tọ̀, àwọn ẹ̀rí wọnnì di alálágbára, ní didári sí sísọ ìgbàgbọ́ nù. Àwọn míràn so rọ̀ pẹ̀lú àwọn gbòngbò tó kéré jùlọ ní wíwọlé sínú ilẹ̀ ìhìnrere.

Síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo nní ìmísí nípasẹ̀ àwọn ìtàn púpọ̀ àwọn tí wọ́n ti yàn láti sọ jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn wọn dọ̀tun kí wọn ó sì padà wá sí Ìjọ ilé wọn. Dípò dída ìgbàgbọ́ wọn àti ohun tí wọ́n gbàgbọ́ nù bíi igi ìdáná tí kò wúlò, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n ti dáhùn sí àwọn ìṣílétí ti ẹ̀mí àti àwọn ìpè ìfẹ́ni láti padà wá

Mo wà níbi ìpàdé àpapọ̀ ti èèkàn kan ni Korea níbití ọmọ ìjọ tó npadàbọ̀ kan ti ṣe àbápín pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn arákùnrin fún ṣíṣetán wọn láti gba àìní-ìgbàgbọ́ àti àìlera mi, fún bíbẹ̀míwò, àti fún àwọn ọmọ ìjọ ti wọ́n nfi ìgbà gbogbo jẹ́ aláanú sí mi tóbẹ́ẹ̀. Mo ṣì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ní àyíká mi tí wọn kò ṣe déédé. Ó panilẹ̀rìn-ín, ṣùgbọ́n wọ́n máa nsọ fún ara wọn láti padà sínú Ìjọ láti gba ìgbàgbọ́ wọn padà. Mo rò pé bóyá gbogbo wọn npòngbẹ fún ìgbàgbọ́.”

Sí àwọn tí wọ́n npòngbẹ fún ìgbàgbọ́, a pè yín láti padà wá. Mo ṣèlérí pé ìgbàgbọ́ yín le di fífún lókun bí ẹ ti njọ́sìn lẹ́ẹ̀kansíi pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́.

Ìránṣẹ́ ìhìnrere tẹ́lẹ̀rí kan láti Áfríkà kọ̀wé sí àgbà olùdarí Ìjọ kan, ní bíbẹ̀bẹ̀ àti wíwá ìdáríjì fún pé ó ṣẹ̀ òun nípasẹ̀ àwọn ìkọ́ni rẹ̀, èyítí ó darí òun láti fi Ìjọ sílẹ̀. Ó fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Pẹ̀lú ìbànújẹ́, pé níní ìbínú mi ní ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́hìn ti mú mi fi ara gbá àyọrísí tó wúwo gidi. Mo sọ ohun púpọ̀ gan-an nù—púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ ju bí mo ti rò rí. Mo ní ìtìjú tó jinlẹ̀ nípa ìjàmbá ti ó ṣeéṣe pé mo ti fa bí ọ̀rọ̀ ti nlọ, ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ inú mi dùn pé mo ti rí ọ̀nà mi padà.”

Sí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ ohun tí ẹ ti sọnù, a pè yín láti padà wá kí ẹ lè tọ́ èso aláyọ̀ ti ìhìnrere wò lẹ́ẹ̀kansíi.

Arábìnrin kan ni United States ti lọ kúrò nínú Ìjọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ìtàn pípadà wá rẹ̀ ní àwọn ẹ̀kọ́ alágbára nínú fún àwọn òbí àti àwọn ọmọlẹ́bí tí wọ́n ndààmú lórí àwọn olùfẹ́ wọn tí wọ́n lọ kúrò. Ó kọ pé:

“Mo le ṣe àtòkọ àkàìníye àwọn èrèdí fún lílọ mi kúrò nínú Ìjọ, nínú ìhìnrere, àti ní ọ̀nà kan, lọ́dọ̀ ẹbí mi. Ṣùgbọ́n wọn kò kúkú fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nkan. Èmi kò ṣe ìpinnu títóbi kan láti fi Ìjọ sílẹ̀—bóyá mo ṣe bíi ẹgbẹ̀rún kan yíyàn, Ṣùgbọ́n ohun kan tí mo fi ìgbà gbogbo mọ̀ ni pé àwọn òbí mi ṣe ìpinnu títóbi kan, wọ́n sì dúró sórí rẹ̀. Wọ́n pinnu láti fẹ́ràn mi.

“Kò ṣeéṣe fúnmi láti mọ iye omijé ti wọ́n ti ta sílẹ̀, iye àwọn òru àìsí-oorun, tàbí iye àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀bẹ̀ bíbẹ̀ nínú àdúrà àtọkànwá tí wọ́n ti sọ ní ìgbẹnusọ mi. Wọn kò pè mí jáde lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi; dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n pè jáde sími nínú jíjẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ mi. Wọn kò jẹ́kí nní ìmọ̀lára kíkọ̀sílẹ̀ nínú ile wọn àti ni ibi àwọn ìpéjọpọ̀ ẹbí; èyíkeyìí awọn ìmọ̀lára wọnnì jẹ́ ṣíṣe tèmi. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n tẹ̀síwájú láti máa gbàmí-mọ́ra. Wọ́n gbọ́dọ̀ ti ríi pé ìmọ́lẹ̀ mi ndínkù bí àkókò ti nlọ. Ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé ẹnití mo jẹ́ nígbànáà sẹ́hìn kàn jẹ́ òjìji ẹnití èmi ṣì máa jẹ́ síbẹ̀.

“Gẹ́gẹ́bí ipa ọ̀nà mi kúrò nínú Ìjọ ti díjú, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀nà mi padà. Ṣùgbọ́n ohun kan tí kò le nípa pípadà wá ni ìmọ̀lára pípadà sílé nibití mo ti jẹ́ ara wọn.”

Ọ̀rọ̀ mi lónìí jẹ́ sí gbogbo àwọn tí wọ́n ti figbàkanrí ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí ṣùgbọ́n tí wọ́n nbéèrè bóyá ọ̀nà wà láti padà tàbí àyè kan fún yín nínú Ìjọ Jésù Krístì tí a mú padà bọ̀ sípò. Bákannáà ó jẹ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó kàn rọra ndúró tàbí tí a ndánwò láti lọ kúrò.

Ọ̀rọ̀ yí kìí ṣe ìpèníjà kan, àti pe kìí ṣe ìdálẹ́bi. Ó jẹ́ ìfipè kan, tí a nàwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́-inú tòótọ́ láti kíi yín káàbọ̀ padà sí ilé yín ti ẹ̀mí.

Mo ti gbàdúrà pé ẹ ó le ní ìmọ́lára ìjẹ́rìí ti Ẹmí Mímọ́ bí ẹ ti ngbọ́ ìfipè ìfẹ́ni yìí nisisìnyí àti ìlérí nlá láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.

“Njẹ́ ẹ̀yin kì yíó ha padà sí ọ̀dọ̀ mi nísisìyí, kí ẹ sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì yí ọkàn padà, kí èmi ó lè wò yin sàn?”

Ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ndáhùn sí ìfipè Olùgbàlà nípa pípadà sí jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn àti àwọn ohun ṣíṣe Ìjọ, wọ́n nfi jẹ́ẹ́jẹ́ àti pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ lépa ìwòsàn náà tí Jésù ṣ̣èlérí. Àti pé ní àtakò sí àwọn ọ̀rọ̀ tó máa nlọ kiri nígbà-míran, àkọsílẹ̀ iye àwọn ọ̀dọ́ wa nyàn láti dúró gbọnin àti láti mú ìgbàgbọ́ wọn dàgbà nínú Jésù Krístì.

Nígbàtí díẹ̀ lára àwọn èròlẹ́hìn Jésù ni Kapernáúmù rí àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ pé ó le tí wọ́n sì yàn láti kúrò, Ó yí sí àwọn Àpóstélì Rẹ̀ Ó sì béèrè pé, “Njẹ́ ẹ̀yin náà yíó lọ bí?”

Èyí ni ìbéèrè tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa níláti dáhùn bí a ti nkojú àwọn àkókò ti dídánwò ọ̀kọ̀ọ̀kan wa. Ìdáhùn Pétérù sí Jésù kò ní àkókò ó sì jẹ́ àdún-tún-dún: “Sí ọ̀dọ̀ tani awa yíó lọ? Ìwọ ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè ayérayé.”

Nítorínáà bí ẹ ti ngbèrò ìfipè Olùgbàlà láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, kínni ohun tí ẹ lè kọ́ láti inú ìtàn igi wílò náà?

  1. Ìrìnajò padà kìí fi ìgbà gbogbo rọrùn tàbi tunilára, ṣùgbọ́n ó máa nyẹ fún un. Nígbàtí a gbé igi wílò wa padà sókè, gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ di gígé kúrò. Kò rẹwà rárá. Àwa náà lè ní ìmọ̀lára àìlágbára bí a ti nda àwọn ọ̀ná àtijọ́ nù ti a sì já ìgbéraga kùrò. Fífi ojú ìgbàgbọ́ yín sùn sórí Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀—igi àti àwọn gbòngbò náà—yíó fún yín ní ìrètí àti ìgboyà láti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ náà padà.

  2. Ó gba ọ̀pọ̀ ọdún fún wílò wa láti gba okun àti ẹwà rẹ̀ tẹ́lẹ̀ padà. Báyìí ó tilẹ̀ lágbarajù ó sì rẹwà síi ju ti ìṣaájú lọ. Ẹ ní sùúrù bí ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí yín ti ndàgbà bákanáà. Nínú èyí ni àìbinú sí àwọn ọ̀rọ̀ àìnírònú bíi “Níbo lo ti wà ni gbogbo ọdún wọ̀nyí?”

  3. Wílò náà ìbá má yè láé láìsí àníyàn àti ìtọ́jú léraléra Ẹ ó tọ́jú ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí yín bí ẹ ti nṣe àpèjẹ ní ibi tábìlì oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí ẹ sì njọ́sìn nínú ilé Olúwa.

  4. Gẹ́gẹ́ bí wílò náà ti nílò oòrùn fún àwọn ẹ̀ka áti ewé rẹ̀ láti tún dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rí yín yíó dagbà bí ẹ ti nní ìfura sí àwọn ìmọ̀lára àti ẹ̀rí ti Ẹ̀mí. Ẹ kọ́ láti ọ̀dọ̀ Ámúlẹ́kì, ẹnití ó ṣe àpèjúwe àkókò rẹ̀ bíi aṣáko ọmọ ìjọ nípa sísọ pé, “a pè mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà èmi kò sì gbọ́.”

  5. Aládùúgbò mi mọ ohun tí wílò náà le dà lẹ́ẹ̀kansíi. Bákannáà Olúwa mọ agbára ìleṣe àtọ̀runwá yín àti ohun ti ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí yín le dà. Òun kì yío jáwọ́ lọ́rọ̀ yín láéláé. Nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì, gbogbo ohun tó ti bàjẹ́ lè di wíwòsàn.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ayọ̀ yíyọ̀ wà ní ọ̀run lórí àwọn wọnnì tí wọ́n padà wá. A nílò yín, a sì fẹ́ràn yín. Mo jẹ́ri pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà wa àti pé Ó nbùkún gbogbo àwọn tí wọ́n bá padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà àti ayọ̀ gígajù. Àwọn apá àánú Rẹ̀ kò ká ṣùgbọ́n wọ́n ṣí sílẹ̀ wọ́n sì nà sí yín. Kò tí ì pẹ́jù fún yín láti padà wá. Pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́ nínú ọkàn wa, a kíi yín káàbọ̀ sílé. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Èyí jẹ́ òun ṣì ni ilé mísàn fún Mísàn Washington Spokane Àwọn àwòrán igi wílò náà ni a yà láti ọwọ́ ìyàwó mi, Jacqui.

  2. 3 Néfì 9:13. Ẹ kíyèsíi pé ìfipè láti ronúpìwàdà jẹ́ àmúlò sí gbogbo wa. Wo 1 Jòhánnù 1:8 (“Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa tan ara wa jẹ,”) àti ìfipè ti Ààrẹ Russell M. Nelson láti ronúpìwàdà lójoojúmọ́: “Ipa Agbára Ti-ẹ̀mí,” Làìhónà, Osù Karun 2022, 98–99.

  3. Wo Quentin L. Cook, “Dídojúkọ Ayé àti àwọn Ìpèníjà Ìgbàgbọ́” (ìsìn àkanṣe káríayé fún àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ọ̀dọ́ àgbà, 14 Oṣù Kọkànlá, 2023), Ibi Ìkàwé Ìhìnrere: “Fún ìwífúnni yín, àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ọ̀dọ́ àgbà kò jẹ́ aṣáko tàbí máa fi Ìjọ sílẹ̀ ní àwọn iye gíga ju ti àtẹ̀hìnwá bí èyí tí wọ́n npín kiri. Iye àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere tí a pè láti sìn ti pọ̀ síi gidigidi. Iye kíkópa nínú Ìjọ fún àwọn ìran tó ndìde ṣe àfihàn títẹ̀síwájú láti máa lọ sókè. Pẹ̀lú-pẹ̀lù, iye àwọn ọ̀dọ́ àgbà tó nwà ní ínstítútì ti nlé síi bákannáà.”

    Bákannáà wo D. Todd Christofferson àti Clark G. Gilbert, “Fídíò: Alàgbà Christofferson Challenges Narrative, Wí pé Ẹ̀mí Nṣiṣẹ́ nínú àwọn Ọ̀dọ́,” Ìròhìn Ìjọ, 13 Oṣù Kejìlá, 2024, newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

  4. Jòhánnù 6:67.

  5. Jòhánnù 6:68.

  6. Wo Álmà 5:28.

  7. Wo Dieter F. Uchtdorf, “Tọ́jú Àwọn Gbòngbò, Àwọn Ẹ̀ka Yío sì Dàgbà,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2024, 102. “Jésù Krísti àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ ni gbòngbò ẹ̀rí wa. Gbogbo àwọn nkan míràn jẹ́ àwọn ẹ̀ka. Nígbàtí ó bá kan títọ́jú àwọn ẹ̀rí wa nípa Jésù Krístì, ó nyàmílẹ́nu bí a bá nfi ìgbà míràn ṣe àṣìṣe àwọn ẹ̀ka fún àwọn gbòngbò. … Ẹ tọ́jú àwọn gbòngbò, àwọn ẹ̀ka yío sì dàgbà.”

  8. Wo Álmà 32:41.

  9. Wo Russell M. Nelson, “Ronú Sẹ̀lẹ́stíà,” Lìàhónà, Oṣù Kọkànlá 2023, 119: “Lílo àkokò síi nínú tẹ́mpìlì nmú ìgbàgbọ́ dàgbà. Iṣẹ́ ìsìn àti ìjọ́sìn yín nínú tẹ́mpìlì yío sì ràn yín lọ́wọ́ láti ronú sẹ̀lẹ́stíà.”

    Wo Russell M. Nelson, “Ẹ Yọ̀ nínú Ẹ̀bùn àwọn Kọ́kọ́rọ́ Oyè-àlùfáà,” Làìhónà, Oṣù Karun 2024, 122: “Èyí ni ìlérí mi. Kò sí ohun tí yíò ràn yín lọ́wọ́ síi láti ṣe ìdìmú ṣinṣin sí ọ̀pá irin ju jíjọ́sìn nínú tẹ́mpìlì déédé bí ipò yín bá ti gbà. Kò sí ohun tí yíò ṣe ìgbélárugẹ ẹ̀rí yín nípa Olúwa Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ tàbí ràn yín lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ ètò títóbi jùlọ Ọlọ́run síi.”

  10. Wo Álmà 32:28.

  11. Álmà 10:6.

  12. Wo Patrick Kearon, “Èrò-Inú Ọlọ́run Ni láti Mú Yín Wá Sílé,” Làìhónà, Oṣù Karun 2024, 87. “Ọlọ́run nlépa yín láìṣàárẹ̀.”

  13. Wo Jeffrey R. Holland, “Àwọn Ohun tó Fọ́ láti TúnṣeLàìhónà, Oṣù Karun 2006, 69–71.

  14. Wo Lúkù 15:11–32; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:13.

  15. Wo Jòhánnù 15:9.

  16. Wo Álmà 5:33.

  17. Wo Russell M. Nelson, “Jésù Krístì Olúwa Yíò Padà Wá,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2024, 122: “Kò jẹ́ yíyá jù tàbí pípẹ́ jù fún yín láti di olùfọkànsìn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì. Nígbànáà ẹ ó ní ìrírí àwọn ìbùkún Ètùtù Rẹ̀ ní kíkún.”

    Bákannáà wo Russell M. Nelson, “Agbára Ipa Ti Ẹ̀mí,” 99: “Bí ẹ bá nímọ̀lára pé ẹ ti ṣìnà kúrò ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú jìnnà gan-an tàbí gígùn gan-an tí ẹ kò sì ní ọ̀nà láti padà, èyí kìí ṣe òtítọ́ rárá.”