Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Olóotọ́ sí Ìgbàgbọ́ Tí Àwọn Òbí Wa Ti Ṣìkẹ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


11:0

Olóotọ́ sí Ìgbàgbọ́ Tí Àwọn Òbí Wa Ti Ṣìkẹ́

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ kí ẹ sì gba okun láti inú ìgbàgbọ́ àti àwọn ẹ̀rí ti àwọn wọ́nnì tí wọ́n wá ṣaáju yín.

Nígbàtí mo nṣe ìbẹ̀wò sí Tẹ́mpìlì Nashville Tennessee fún àyẹ̀wò tẹ́mpìlì, mo ní ànfààní láti ṣe ìrìn-kọjá bíi ara iṣẹ́ yíyàn yí, ní ṣíṣe àyẹ̀wò ilé Olúwa rírẹwà yí. Mo ni ìtẹ̀mọ́ra pàtàkì pẹ̀lú àwòrán kíkùn ti Màríà Wanlass ti a pè ni Tẹ̀ Síwájú tí a fi kọ́ ògiri ní ọ́fíìsì ìyá ijọ.

Èyí ni ìtàn tó wà lẹ́hìn àwòrán kíkùn náà:

Ní Missouri ní 1862 Màríà Wanlass ẹni ọdún mẹ́rìnlá ṣèlérí fún ìyá rẹ̀ kékeré tó nkú lọ pé òun yíó ríi pé aláàbọ̀ ara baba òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ tí wọ́n kéré síi ni gbogbo wọn yíó dé Àfonífojì Salt Lake Nlá náà Màríà wa ọkọ̀ màlúù ó sì nfún wàrà àwọn abo màlúù ti wọ́n nfa ọkọ̀-akẹ́rù nínú èyítí baba rẹ̀ wà ní orí ibùsùn, ó sí ṣe ìtọ́jú àwọn àbúrò rẹ̀. Lẹ́hìn ìrìnàjò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ó nbọ́ ẹbí náà nipa wíwá àwọn ewéko, àwọn òdòdó, ati àwọn bẹ́rì tí wọ́n jẹ́ jíjẹ. Amọ̀nà rẹ̀ kanṣoṣo ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti ó ti gbà láti tẹramọ́ rírin ìrìnàjò náà sí ìhà ilà oòrùn ‘títí tí àwọn ìkùùku yio fi di àwọn òkè.’

Wọ́n dé Àfonífojì Utah ni Oṣù Kẹsan, lẹ́hìn tí wọ́n ti rin ìrìnàjò ní gbogbo ìgbà ìrúwé àti ẹ̀ẹ̀rùn. Baba rẹ̀ kú láìpẹ́ lẹ́hìn tí ẹbí náà tẹ̀dó ni Agbègbè Utah, nibití Màríà ti ṣègbéyàwó lẹ́hìnnáà tí ó sì tọ́ ẹbí ti [ara] rẹ̀.”

Èyí jẹ́ ìtàn ìyanu nípa ìgbàgbọ́ ati okun ọ̀dọ́mọbìnrin ẹni ọdún mẹ́rìnlá kan tí ó le ran ẹnìkọ́ọ́kan wa lọ́wọ́ lónìí láti “ṣáà tẹ̀síwájú.”

“Ṣáà Tẹ̀síwájú,” tàbi ní títúmọ̀ si èdè abínibí mi Dutch, Gewoon Doorgaan—bákannáà jẹ́ àṣà dídá ti ìyá àti baba mi ni gbogbo ọjọ́ ayé wọn.

Àwọn òbí àti àwọn àna mi ni àwọn olùlànà nínú ẹbí wa. Wọ́n ti la “àwọn ilẹ̀ títẹ́jú” tiwọn kọjá gẹ́gẹ́bí gbogbo àwọn tí wọ́n nwá sí inú Ìjọ, agbo ti Olúwa, lójojúmọ́. Àwọn ìtàn wọn ní kékeré íṣe pẹ̀lú màlúù àti àwọn ọkọ̀-akẹ̀rù ṣùgbọ́n ó ní irù ayọrísí kannáà sí àwọn ìran ọjọ́ iwájú.

Wọ́n gba ìhìnrere mọ́ra wọ́n sì jẹ́ rírìbọmi ni awọn ọdún ọ̀dọ́ àgbà wọn. Àwọn òbí mi méjèèjì ni wọ́n ní ìgbà èwe tó nira. Baba mi dàgbà ní erékùsù ti Java Indonesia. Ní igbà Ogun Àgbáyé Kejì, a fi ipa pín in níyà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀ a si rì í mọ inú àgọ́ èrò kan, nibití ó ti jìyà àwọn ìṣoro tí kò ṣeé sọ ni ọjọ́ orí ọmọdé.

Ìyá mi ni a tọ́ dàgbà ní ilé tí ìgbéyàwó ti dàrú àti pé òun bákannáà jìyà ebi àti àwọn ìṣòro Ogun Àgbáyé Kejì. Ní àwọn ìgbà míràn àní ó máa nílati jásí jíjẹ àwọn bọ́ọ̀bù túlíìpù. Nítorí àwọn ìgbésẹ̀ baba rẹ̀, àti níkẹhìn ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ kúrò lọ́dọ́ ìyá rẹ̀, ó máa nṣòro fún nígbà míràn láti rí Baba Ọ̀run bíi Baba olùfẹ́ni.

Àwọn òbí mi pàde níbi ìpéjọpọ̀ ìdárayá kan ti Ìjọ àti pé láìpẹ́ lẹ́hìn ìgbà náà wọ́n pinnu láti ṣe ìgbéyàwó wọ́n sì di fífi èdìdi dì ni Tẹ́mpìlì Bern Switzerland. Bí wọ́n ti ndúró ní ibùdó ọkọ̀ ojú irin, lẹ́hìn tí wọ́n ti ná gbogbo àfipamọ́ kékeré wọn fún ìrìnàjò sí tẹ́mpìlì náà, wọ́n ronú bí àwọn o ti tọ́jú ara wọn ṣùgbọ́n wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé gbogbo rẹ̀ yíó dára. Ó sì rí bẹ́ẹ̀!

Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tọ́ ẹbí wọn látinú ìrẹ̀lẹ̀ gidi, ibùgbé oní yàrá atijọ́ kan ní oókan ti Amsterdam. Lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti fífọ àwọn aṣọ wọn pẹ̀lú ọwọ́, wọ́n ní owó ní ìpamọ́ tí ó tó láti ra ẹ̀rọ ìfọṣọ kan. Ó kù díẹ̀ kí wọ́n rà á, bíṣọ́pù bẹ̀ wọ́n wò, ní bíbèèrè fún ìdáwó láti kọ́ ilé ìpàdé kan ní Amsterdam. Wọ́n pinnu láti fi gbogbo owó tí wọ́n ti fi pamọ́ fún ẹ̀rọ ìfọṣọ náà sílẹ̀ wọ́n sì tẹ̀síwájú láti máa fi ọwọ́ fọ aṣọ wọn.

Bíi ẹbí a la àwọn ìṣoro díẹ̀ kọjá gẹ́gẹ́ bíi ti èyíkéyìí ẹbí míràn. Ìwọ̀nyí kàn ti mú wa lágbára síi ó sì mú ìgbàgbọ́ wa nínú Olúwa Jésù Krístì jinlẹ̀ síi, gẹ́gẹ́bíi ìgbà tí Álmà nsọ ìtàn rẹ̀ fún ọmọ rẹ̀ Hẹ́lámánì, níbití ó ti sọ fún un pé a ti ṣe àtìlẹ́hìn fún òun nínú àwọn àdánwò àti ìdààmú ní onírurú nítorípé ó ti fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sí inú Olúwa Jésù Krístì.

Báwo ni àwọn èníyàn méjì tí wọ́n ní ìrírí àwọn àdánwò púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ ní ìgbà ọ̀dọ́ wọn ṣe di òbí dídára jùlọ tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè ní ìfẹ́ fún? Ìdáhùn náà rọrùn: wọ́n gba ìhìnrere náà mọ́ra ní kíkún wọ́n sì gbé nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú wọn títí di ọjọ́ yìí gan-an!

Lẹ́hìn ìgbéyàwó tó ti ju ọdún marunlelọ́gọ́ta lọ, ìyá mi, ẹnití ó jìyà àrùn Gbígbàgbé nkan, kọjá lọ ninu Oṣù Kejì. Baba mi, ní ọjọ́ orí kejìléláàdọ́ọ̀wá tí ó sì ngbé nílé, bẹ̀ ẹ́ wo léraléra bí ó ti lè ṣe tó títi tí ó fi kọjá lọ. Ní ìgbà kan sẹ́hìn ó mẹ́nubà a fún àwọn àbúrò mi pé àwọn ìrírí bíbanilẹ́rù náà nínú àgọ́ ní Indonesia nígba Ogun Àgbáyé Kejì ti múra òun sílẹ̀ láti fi sùúrù tọ́jú ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún bí ó ti ní àìlera tí ó sì nburú síi nínú àìsàn náà, àti bákannàà fún ọjọ́ burúkú náà tí òun níláti fi í sílẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn láti tọ́jú tí òun kò sì le wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ́. Àkọlé wọn títi di ìsisìnyí ni pé “Ṣáa Tẹ̀síwájú,” ní níní ìrètí pípé nínú Krístì láti jẹ́ gbígbé sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn àti lati gbé pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ògo títí láé.

Ìgbàgbọ́ àti àwọn ẹ̀rí wọn jẹ́ okun fún àwọn ìran ti wọ́n ti wá lẹ́hìn wọn.

Ni abúlé ibití ìyàwó mi ti dàgbà, àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ẹnití ó nlọ sí ilé ìjọsìn dàradàra, tẹ̀wọ́gba ìhìnrere tí a múpadàbọ̀sipò bíi ọ̀dọ́ tọkọtaya pẹ̀lu ìyàwó mi bíi ọmọbìnrin wọn ọmọ ọdún méjì ti ó sì jẹ́ ọmọ kanṣoṣo ní ìgbà náà. Ìpinnu wọn láti di ọmọ ijọ́ ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní ipa nlá lórí ayé wọn bi wọ́n ti di pípatì láti ọ̀dọ̀ àwọn ara abúle àti ẹbí wọn. Ó gba ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ìwé kíkọ ìfẹ́ni sí àwọn mọ̀lẹ́bí, àti iṣẹ́-ìsìn sí agbègbè náà kí wọ́n ó tó di títẹ́wọ́gbà níkẹhín.

Ní àkókò kan nígbàtí baba ìyáwó mi nsìn bíi bíṣọ́pù, wọ́n parọ́ mọ́ ọ nipa ohun kan wọ́n sì yọ ọ́ kúrò lójú ẹsẹ̀. Ó ká ìyá ìyàwó mi lára tóbẹ́ẹ̀ tí ó bèèrè lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀ pé ṣé kí àwọn ó tẹ̀síwájú láti máa lọ ilé ìjọsìn. Ó dáhùn pé ní tòótọ́ àwọn ó tẹ̀síwájú láti máa lọ ilé ìjọsìn níwọ̀nbí èyí kìí tií ṣe ìjọ àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí jẹ́ ìjọ ti Jésù Krístì

Ó gba àkókò díẹ̀ kí òtítọ́ to farahàn tí àforíjì si di títọrọ. Ohun tí ìbá ti di fífọ́ ojúàmì wọn kan fikún okun ati ìdánilójú wọn.

Kíníṣe tí àwọn kan lára wa máa nṣe àìkàsí ìgbàgbọ́ àti àwọn ẹ̀rí ti àwọn òbí wa tí wọ́n ti dúró nínú òtítọ́ la gbogbo ìṣoro wọn já? Njẹ́ a rò pé wọn kò ní òye kedere nipa àwọn nkan bí? A kò tàn wọ́n wọn kò sí jẹ́ títànjẹ! Wọ́n kàn ti ní àwọn ìrírí púpọ̀ju pẹ̀lú Ẹ̀mí wọ́n sì le sọ pẹ̀lú Wòlíì Jósẹ́fù pé, “Mo mọ̀ ọ́, … èmi kò sì lè sẹ́ ẹ.”

Ẹ̀yin kò hà fẹ́ràn orin nípa ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hẹ́lámánì, ti a rí nínú Ìwé Orin àwọn Ọmọdé bí?

A ti bíwa, bíi Néfì àtijọ́,

Fún àwọn òbí dídára ti wọ́n fẹ̀ràn Olúwa,

A ti kọ́ wa, ó sì yé wa,

Pé a gbọ́dọ̀ ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ.

Àni nígbàtí èyí le má rí bẹ́ẹ̀, bi ìyá mi ti ní ìrírí rẹ̀ bíi ọmọdé, ẹ̀yin lè di ọ̀kan nínú àwọn “òbí dídára ti wọ́n fẹ̀ràn Olúwa” kí ẹ sì pèsè àpẹrẹ òdodo fún àwọn ẹlòmíràn.

Njẹ́ a ní ìmọ́lára pé èyí jẹ́ òtítọ́ pátápátá nígbàtí a bá nkọ ọ́ bí? Njẹ́ ẹ ní ìmọ̀lára pé ẹ jẹ́ “bíi ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hẹ́lámánì” àti pé ẹ̀yin “yíó jẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere ti Olúwa láti mú òtítọ́ rẹ̀ wá fún aráyé bí”? Mo ti ní ìmọ̀lára rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò bí mo ti nkọ orin yìí ni oríṣiríṣi ìṣètò Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ àti ìpéjọpọ̀ míràn ti àwọn ọ̀dọ́.

Tàbí kínni a nní ìmọ̀lára rẹ̀ nígbàtí a bá nkọ orin isìn “Òtítọ́ sí Ìgbàgbọ́ náà”?

Njẹ́ àwọn ọ̀dọ́ Síónì yíó kọsẹ̀

Ní dídáàbò bo òtítọ́, àti títọ́?

Nígbàtí ọ̀tá bá kọjú ìjà,

Njẹ́ a ó lọ́ra tàbí pa ìjà náà ti bí? Rárá!

Òtítọ́ sí Ìgbàgbọ́ Tí àwọn Òbí wa Ti Ṣìkẹ́.

Sí àwọn wọnní nínú ìran tí ó ńdìde níbikíbi ti ẹ wà àti nínú ipòkípò tí ẹ le rí ara yín, ẹ jọ̀wọ́ ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ kí ẹ sì gba okun láti inú ìgbàgbọ́ àti àwọn ẹ̀rí ti àwọn wọ́nnì tí wọ́n wá ṣaáju yín. Yíó ràn yín lọ́wọ́ láti ní òye pé láti lè jèrè tábí mú ẹ̀rí dàgbà, àwọn ìrúbọ yíó níláti jẹ́ ṣíṣe àti pé “ìrúbọ nmú àwọn ìbùkún ọ̀run wá.”

Ní ríronú nípa ìrúbọ kan tí yíó bùkún ayé yín nítòótọ́, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe àgbéyẹ̀wò kí ẹ sì gbàdúrà nípa ìfipè wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, nígbàtí ó wí fún “gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yíyẹ, àti pípéye láti múrasílẹ̀ fún àti sin ní míṣọ̀n kan. Fún ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, iṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere jẹ́ ojúṣe òyè àlùfáà. …

Fún … ẹ̀yin arábìnrin ọ̀dọ́ àti tí ó péye, iṣẹ́ ìránṣẹ́ bákannáà jẹ́ ànfààní alágbára kan, ṣùgbọ́n bí ó bá wuni.”

Ẹ lè jẹ́ pípè bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere oníṣẹ́-ìsìn tábi olùkọ́ni. Irú àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere méjèèjì nlọ́wọ́ nínú ibiafẹ́dé irú kannáà ti mímú ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, olukúlùkù ní ọ́nà àrà ọ̀tọ̀ àti alágbára tiwọn.

Nínú irú iṣẹ́-ìsìn méjèèjì, ẹ ó fi hàn Olúwa pé ẹ fẹ́ràn Rẹ̀ àti pé ẹ fẹ́ láti mọ Òun dáradára síi. Ẹ rántí, “Nítorí báwo ni ènìyàn yíò ṣe mọ olúwa rẹ̀, èyítí kò tíì sìn, àti tí ó jẹ́ àjòjì sí i, tí ó sì jìnà sí ìrònú àti àwọn èrò ọkàn rẹ̀?”

Gbogbo wa, bóyá a jẹ́ ìran àkọ́kọ́ nínú ìhìnrere tàbí ìkarun, níláti bi ara wa léèrè irú àwọn ìtàn ìgbàgbọ́, okun, ati ìfarají ti sẹ̀lẹ́stíà wo ni èmi ó fi fún ìran to nbọ̀?

Ẹ jẹ́ki gbogbo wa ó tẹ̀síwájú nínú aápọn láti mọ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, dáradára sìi kí a sì fi Òun ṣe oókan ìgbésí ayé wa. Òun ni àpáta lórí èyítí a gbọ́dọ̀ kọ́lé sí tó bẹ́ẹ̀ pé nígbàtí àwọn àkokò bá di líle, a ó le dúró láìyẹsẹ̀.

Ẹ jẹ́kí a jẹ́ “olóotọ́ sí ìgbàgbọ́ tí àwọn òbí wa ti ṣìkẹ́, olóotọ́ sí òtítọ́ fún èyítí àwọn ajẹ́rìíkú ti parun, sí àṣẹ Ọlọ́run, ẹ̀mí, ọkàn, àti ọwọ́, bì onígbàgbọ́ àti olóotọ́ ni a ó dúró láé.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.