Ètò Àánú Náà
Olúwa jẹ́ aláanú àti pé ètò ìgbàlà ti Baba wa Ọ̀run jẹ́ ètò àánú nítòótọ́.
Ìfipè Kan ti Wòlíì
Ni ọdún tó kọjá níbi ìpàdé àpapọ̀ Oṣù Kẹrin, ní kété lẹ́hìn ìròhìn ayọ̀ pé Ìjọ ti gba Tẹ́mpìlì Kirtland, Ààrẹ Russell M. Nelson pe wá láti ṣe àṣàrò àdúrà ìyàsímímọ́ ti Tẹ́mpìlì Kirtland náà, ti a kọsílẹ̀ nínú ìpín mọ́kàndínàádọ́ọ̀fà ti Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú Àdúrà ìyàsímímọ́ náà, ni Ààrẹ Nelson sọ pé, “ó jẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa bí tẹ́mpìlì ti nfi agbára fún ẹ̀yin àti èmi níti-ẹ̀mí láti kojú àwọn ìpènijà ìgbésí ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí.”
Ó dámi lójú pé ṣíṣe àṣàrò yín nípa ìpín ọgọ́ọ̀rúnlémẹ́ẹ̀sán mú àwọn ìwòye wá tí ó nbùkún yín. Ní àṣálẹ́ yìí, mo pín díẹ̀ nínú àwọn ohun tí mo kọ́ bí mo ti ntẹ̀lé ìfipè wòlíì wa, Ipa ọ̀nà tó nfúnni ní àláfíà sísàlẹ̀ èyítí àṣàrò mi dárí ránmi létí pé Olúwa jẹ́ aláanú àti pé ètò ìgbàlà ti Baba wa Ọ̀run jẹ́ ètò àánú nítòótọ́.
Àwọn Àṣẹṣẹ̀pè Ìránṣẹ́ Ìhìnrere Nsìn nínú Tẹ́mpìlì
Bi ẹ lè ti mọ̀, “àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere àṣẹ̀ṣẹ̀pè ni a ngbà níyànjú láti gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì bí ó bá ti tètè ṣeéṣe tó àti láti lọ sí tẹ́mpìlì léralerá bi àwọn ipò wọn bá ti gbà.” Bí wọ́n bá ti gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, bákannáà wọ́n “le sìn bíi òṣìṣẹ́ ìlànà kí wọn ó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìsìn ìhìnrere.”
Àkókò nínú tẹ́mpìlì ṣaájú wíwọ Ibi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìránṣẹ́ Ìhìnrere le jẹ́ ìbùkún yíyanilẹ́nu fún àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere titun bí wọ́n ti nkẹ́kọ̀ọ́ síi nípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì ṣaájú pípín àwọn ìbùkún ti àwọn májẹ̀mú náà pẹ̀lú aráyé.
Ṣùgbọ́n nínú ṣíṣe àṣàrò ìpín ọgọ́ọ̀rúnlémẹ́ẹ̀sán, mo kọ́ pé, nínú tẹ́mpìlì, Ọlọ́run nró àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere titun—ní tòótọ́, gbogbo wa—lágbára ní ọ̀nà àfikún, mímọ́ kan. Nínú àdúrà ìyàsímímọ́ náà, tí a fúnni nípa ìfihàn, Jósẹ́fù gbàdúrà pé “nígbàtí àwọn ìránṣẹ́ rẹ yíó bá jáde kúrò nínú ilé rẹ … láti jẹ́ ẹ̀rí nípa orúkọ rẹ,” kí “ọkàn” ti “gbogbo ènìyàn”— ti “àwọn ẹni nlá ilẹ̀ ayé” àti “gbogbo àwọn tálákà, àwọn aláìní, àti awọn [náà] ti a pọ́n lójú … lè di mímú rọ̀.” Ó gbàdúrà pé ki “àwọn ẹ̀tanú le sá kúrò níwájú òtítọ́, àti kí àwọn ènìyàn rẹ le rí ojúrere lójú gbogbo èníyàn; pé kí gbogbo òpin ilẹ̀ ayé le mọ̀ pé àwa, ìránṣẹ́ rẹ, ti gbọ́ ohùn rẹ, àti pé ìwọ ti rán wa.”
Èyí jẹ́ ìlérí rírẹwà fún àṣẹ̀ṣẹ̀pè ìránṣẹ́ ìhìnrere kan—láti jẹ́ kí àwọn ẹ̀tanú “sálọ kúrò níwájú òtítọ́,” láti “rí ojúrere ní ojú gbogbo ènìyàn,” àti láti ríi pé aráyé mọ̀ pé Olúwa ló rán wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa dájúdájú nílò àwọn ìbùkún kannáà. Yíó ti jẹ́ ìbùkún tó láti rìi kí àwọn ọkàn di rírọ̀ bí a ti nní ìbáṣe pẹ̀lú àwọn aládùúgbò àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀. Àdúrà ìyàsímímọ́ náà kò ṣàlàyé ní pàtó bí àkókò wa nínú tẹ́mpìlì yíó ṣe rọ ọkàn awọn ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n ó dámi lójú pé ó jẹ́ síso pọ̀ pẹ̀lú bí àkókò nínú ilé Olúwa ti mú àwọn ọ̀kàn tiwa rọ̀ nípa fífi wa lé ààrin Jésù Krístì àti àánú Rẹ̀.
Olúwa Dáhùn Ẹ̀bẹ̀ Joseph Smith fún Àánú
Bí mo ti ṣe àṣàrò àdúrà ìyàsímímọ́ Kirtland, mo ríi bákannáà pé Jósẹ́fù bẹ̀bẹ̀ lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kansíi fún àánú—fún àwọn ọmọ Ìjọ, fún àwọn ọ̀tá Ìjọ, fún àwọn olórí orílẹ̀-èdè náà, fún àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé. Àti, ni ti araẹni gidi, ó bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa láti ránti òun àti láti ṣàánú fún àyànfẹ́ rẹ̀ Emma àti àwọn ọmọ wọn.
Báwo ni ìmọ̀lára Jósẹ́fù gbọ́dọ̀ ti rí nígbàtí, ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́hìnwá, ni òwúrọ̀ ọjọ́ Àjínde, Ọjọ́ Kẹ́ta Oṣù Kẹrin, 1836, nínú Tẹ́mpìlì Kirtland, Olùgbàlà farahàn sí òun àti Oliver Cowdery àti pé, bí a ti kọsílẹ̀ ní ìpín àádọ́ọ̀fà ti Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú, ó wí pé, “Mo ti tẹ́wọ́gba ilé yìí, orúkọ mi yíó sì wà ní ìhín; èmi yíó sì fi ara mi hàn sí àwọn ènìyàn mi nínú àánu nínú ilé yìí.” Ìlérí àánú yìí gbọ́dọ̀ ti ní ìtumọ̀ pàtàkì sí Jósẹ́fù. Àti pé bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni ní Oṣù Kẹrin to kọjá, ìlérí yìí bákannáà “wúlò fún gbogbo tẹ́mpìlì tí a ti yàsímímọ́ lonìí.”
Rírí Àánú nínú Ilé Olúwa
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà ló wà nínú èyítí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa le rí àánu nínú ilé Olúwa. Èyí ti jẹ́ òtítọ́ láti ìgbà tí Olúwa ti kọ́kọ́ pàṣẹ fún Isráẹ́lì láti kọ́ àgọ́ kan àti láti fi “ìtẹ́ àánu” sí ààrin gbùngbùn rẹ̀. Nínú tẹ́mpìlì, a nrí àánú nínú àwọn májẹ̀mú tí a ndá. Àwọn májẹ̀mú wọnnì, ní àfikún sí májẹ̀mú ti ìrìbọmi, so wá pọ̀ sí Baba àti Ọmọ ó sì nfún wa ní àyè púpọ̀ síi sí ohun ti Ààrẹ Nelson ti kọ́ni pé ó jẹ́ “irú ìfẹ́ àti àánú pàtàkì kan ti a pè ní hessed” ní èdè Hébérù.
A nrí àánú nínú ànfààní láti jẹ́ fífi èdìdi dì pẹ̀lú àwọn ẹbí wa fún ayérayé. A wá nní òye bákannáà pẹ̀lú ṣíṣe kedere púpọ̀ síi pé Ìṣẹ̀dá, Ìṣubú, ẹbọ ètùtù Olùgbàlà, àti agbára wa láti wọlé lẹ́ẹ̀kansíi sí ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run—nítòótọ́, gbogbo abala ti ètò ìgbàlà—jẹ́ ìfarahàn ti àánú. Ní tòótọ́, a lè sọ pé ètò ìgbàlà jẹ́ ètò ìdùnnú ní pàtó nítorípé ó jẹ́ ètò àánú.”
Wíwá Ìdáríjì Nṣí Ìlẹ̀kún sí Ẹ̀mí Mímọ́.
Mo ní ìmoore fún ìlérí rírẹwà nínú ìpin àádọ́fà pé Olúwa yíó fi Ara-Rẹ̀ hàn nínú àánu nínú àwọn Tẹ́mpìlì Rẹ̀. Mo ní ìmoore bákannáà fún ohun tí ó fihàn nípa bí Olúwa yíó ti fi Ara-Rẹ̀ hàn nínú àánú nígbàkugbà tí àwa, bíi Jósẹ́fù, bá bẹ̀bẹ̀ fún àánú.
Ẹ̀bẹ̀ Joseph Smith fùn àánú ní ìpín mọ́kàndínlàádọ́fà kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún àánú mú ìfihàn wá. Nínú Igbó Ṣúúrú Mímọ́, ọ̀dọ́mọdé Joseph gbàdúrà kìí ṣe láti mọ Ìjọ èyí tí ó jẹ́ òtítọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó sọ bákannáà pé òun “kígbe sí Olúwa fún àánú, nítorí kò sí ẹlòmíràn tí mo le tọ̀ lọ láti gba àánú.” Bákannáà dídámọ̀ rẹ̀ pé òun nílò àánú ti Olúwa nìkan le pèsè ìrànlọ́wọ́ láti ṣí àwọn fèrèsé ọ̀run sílẹ̀. Ọdún mẹ́ta lẹ́hìnnáà, angẹ́lì Mórónì farahàn ní títẹ̀lé ohun tí Jósẹ́fù pè ní “àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ òun sí Ọlọ́run Alágbára Jùlọ fún ìdáríjì gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àìmọkan mi.”
Irú àpẹrẹ yí ti ìfihàn títẹ̀lé ẹ̀bẹ̀ fún àánú jẹ́ eyítí ó wọ́pọ̀ nínú àwọn ìwé mímọ́. Énósì gbọ́ ohùn Olúwa lẹ́hìn gbígbàdúrà fún ìdáríjì nìkan. Ìyípadà ọkàn ti baba Ọba Lámónì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà pé: “Èmi ó fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sílẹ̀ láti mọ̀ yín.” A lè má jẹ́ bíbùkún pẹ̀lú àwọn ìrírí àrà ọ̀tọ̀ kannáà, ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ntiraka nígbà míràn láti ní ìmọ̀lára àwọn ìdáhùn sí àdúrà, wíwá àánú Olúwa jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà alágbára jùlọ láti ní ìmọ̀lára ẹ̀rí ti Ẹmí Mímọ́.
Ríronújinlẹ̀ lórí Àánú Ọlọ́run Nṣí Ìlẹ̀kùn sí Ẹ̀rí kan nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì
Ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ kan tí ó jọra ni a kọ́ni dáradára nínú Mórónì 10:3–5. A máa nfi ìgbà gbogbo ṣe ìkékúrú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí láti kọ́ni pé, nípasẹ̀ àdúrà àtọkànwá, a le kọ́ bóyá Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́. Ṣùgbọ́n ìkékúrú yìí le ṣe àìnáání ipa pàtàkì ti àánú. Ẹ fetísí bí Mórónì ti bẹ̀rẹ̀ ìgbani-níyànjú rẹ̀: “Èmi yíò rọ̀ yín pé nígbàtí ẹ̀yin bá kà àwọn ohun wọ̀nyí, … pé ẹyin ó rántí bí Olúwa tí jẹ́ aláànú tó sí àwọn ọmọ ènìyàn, láti igbà ìṣẹ̀dá Ádámù àní títí dé ìgbà tí ẹ̀yin yíò gba àwọn ohun wọ̀nyí, kí ẹ sì rò ó jinlẹ̀ nínú ọkàn yín.”
Mórónì rọ̀ wa kìí ṣe láti ka àwọn ohun wọ̀nyí nìkan—àwọn àkọsílẹ̀ tí òun ti fẹ́ fi èdìdi dì—ṣùgbọ́n bákannáà láti rònú jinlẹ̀ nínú ọkàn wa ohun tí Ìwé ti Mọ́mọ́nì fihàn nípa “bí Olúwa ti jẹ́ aláànú sí àwọn ọmọ ènìyàn sí.” Ríronú jinlẹ̀ lórí àánú Olúwa ni ó nmúra wa sílẹ̀ láti “béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Baba Ayérayé, ní orukọ Krístí, bí àwọn ohun wọ̀nyí kò bá í ṣe òtítọ́.”
Bí a ti nronu jinlẹ̀ lórí Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a lè béèrè pé: Njẹ́ ó jẹ́ òtítọ́ gan-an, bí Álmà ti kọ́ni, pé ètò àánú Ọlọ́run fi dáni lójú pé gbogbo ènìyàn ti ó ti gbé rí ní ilẹ̀ ayé yìí ni a ó jí dìde àti pé a ó mú wọn padàbọ̀sípò sí àgọ́ ara pípé wọn? Njẹ́ òtítọ́ ni Ámúlẹ́kì sọ—Njẹ́ àánú Olùgbàlà le tẹ́ gbogbo àwọn ìbéèrè òtítọ́ kíkorò ti àìṣègbè lọ́rùn bíbẹ́ẹ̀kọ́ ìbá jẹ́ dandan fúnwa láti san àti dípò bẹ́ẹ̀ ˆ[ká wa mọ́] nínú apá ààbò”?
Njẹ́ òtítọ́ ni, bí Álmà ti jẹ́rìí, pé Krístì jìyà kìí ṣe fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nìkan ṣùgbọ́n fún “àwọn ìrora àti àwọn ìpọ́njú wa” kí Òun le “mọ … bí yíó ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú ní ìbámu sí àwọn àìlera wọn”? Njẹ́ Olúwa jẹ́ aláanú tóbẹ́ẹ̀ nítòótọ́, bí Ọba Bẹ́njámínì ti kọ́ni, pé bíi ẹ̀bùn ọ̀fẹ́, Ó ṣe ètùtù “fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wọnnì … tí wọ́n ti kú láì mọ ìfẹ́ Ọlọ́run nípa wọn, tàbí tí wọ́n ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nínú àìmọ̀kan”?
Njẹ́ òtítọ́ ni, bí Léhì ti sọ, pé “Ádámù ṣubú kí ènìyàn le wà; àti pé ènìyàn wà, kí wọn ó le ní ayọ̀”? Àti pé ṣe ó jẹ́ òtítọ́ gan-an, bí Ábínádì ti jẹ́rìí, ní ṣíṣe àyọsọ Isáíàh, pé Jésù Krístì ni a “pa lára fún àwọn ìrékọjá wa, a ṣá a lọ́gbẹ́ fún àwọn àìṣedéédé wa, ìbáwí àláfíà wa nbẹ lára rẹ̀; àti nípa ìnà rẹ̀ ni a mú wa lárada”?
Ní àkótán, Njẹ́ ètò ti Baba bí a ti kọ́ni nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ aláanú báyìí nítòótọ́? Mo jẹ́ ẹ̀rí pé bẹ́ẹ̀ ni àti pé àwọn ìkọ́ni àánú tó nfúnni ní àláfíà àti ìrètí tó wà nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́.
Síbẹ̀, mo wòye pé àwọn kan lè máa tiraka, láìka ìwé kíkà àti àwọn àdúrà ìgbàgbọ́ yín sí, láti mọ ìlérí Mórónì pé Baba Ọ̀run “yíò fi òtítọ́ rẹ̀ hàn sí yín, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ̀.” Mo mọ ìtiraka yìí nítorípé mo mọ̀ ọ́ lára, ní ọdún púpọ̀ sẹ́hìn, nígbàtí àwọn kíkà àkọ́kọ́ mi ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì kò mú ìdáhùn ojú-ẹsẹ̀ àti kedere wá sí àwọn àdúrà mi.
Bí o bá ntiraka, njẹ́ kí npè ọ́ láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn Mórónì láti ronújinlẹ̀ lórí àwọn ọ̀nà púpọ̀ tí Ìwé ti Mọ́mọ́nì fi nkọ́ni “bí Olúwa ti jẹ́ aláànú tó [si] àwọn ọmọ ènìyàn”? Dá lórí ìrírí mi, mo nírètí pé, nígbàtí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, àláfíà ti Ẹ̀mí Mímọ́ le wọnú ọkàn yín ẹ̀yin sì le mọ̀, gbàgbọ́, kí ẹ sì ní ìmọ̀lára pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti ètò àánú ti ó nkọ́ni jẹ́ òtítọ́.
Mo fi ìmoore mi hàn fún ètò nlá Baba nípa àánú àti fún ṣíṣetán Olùgbàlà láti gbé e jáde. Mo mọ̀ pé yíó fi Ara-Rẹ̀ hàn nínú àánú nínú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ Rẹ̀ àti ní gbogbo apákan ìgbésí ayé wa bi a bá wá A. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.