Ìgbẹ́kẹ̀lé ní Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run
Bí a ti nfi taratara wá láti ní ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́ àti tí ìwà-ọ̀run kún ilé ayé wa, ìgbẹ́kẹ̀lé wa ní dídé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run yíò pọ̀si.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo fi ìmoore hàn láti sọ̀rọ̀ síi yín ní òní nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò pàtàkì yí. Ojú mi ntẹ̀síwájú ní dídàgbà si. Ẹ ṣeun fún òye yín bí mo ti ngbé ọ̀rọ̀ mi kalẹ̀.
À ngbé ní ọjọ́ ipa nlá nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Inú mi kún fún ayọ̀ bí mo ti rí ìlọsíwájú ní àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè.
Nípàtàkì mo ní ìmísí nípasẹ̀ àwọn ọ̀dọ́ wa. Wọ́n nfi iṣẹ́-ìsìn fúnni ní ọ̀pọ̀ yanturu. Wọ́n nwá àwọn babanla wọn wọ́n sì nṣe àwọn ìlànà nínú tẹ́mpìlì. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti obìnrin wa nfi ìwé ṣọwọ́ fún iṣẹ́-ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere ní àkọsílẹ̀ púpọ̀. Ìran tí ó ndìde ndide sókè bí akọni àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì.
Láìpẹ́ mo pàdé ọmọ-ọmọ-ọmọbìnrin titun kan. Nígbàtí mo ro àwọn ipènijà tí òun yíò ní ìrírí nínú ayé rẹ̀, mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ gidi láti ràn án lọ́wọ́ láti gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jésù Krístì ga. Gbígbé ihìnrere Rẹ̀ ṣe pàtàkì fún ìdùnnú ọjọ́-ọ̀là rẹ̀.
Òun, bíiti ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yíò dojúkọ àwọn ìpènijà. Gbogbo wa yíò ní ìrírí àìsàn, ìjákulẹ̀, àdánwò, àti àdánù. Àwọn ìpènijà wọ̀nyí lè gbá ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni dànù. Bákannáà, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì ní ààyè sí oríṣiríṣi irú ìgbẹ́kẹ̀lé.
Nígbàtí a bá dá tí a sì pa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé tí a bí nípa ti Ẹ̀mí. Olúwa wí fún Wòlíì Joseph Smith pé kí ìgbẹ́kẹ̀lé wa lè “lágbára si ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Ẹ ro ìtùnú ti níní ìgbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
Nígbàtí mò nsọ̀rọ̀ níní ìgbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, mò ntọ́ka sí níní ìgbẹ́kẹ̀lé ní dídé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bayi nisisìyí! Mò ntọ́ka sí gbígbàdúrà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé pé Baba Ọ̀run ngbọ́ wa, pé Ó ní ìmọ̀ àwọn àìní wa ju bí a ti ṣe lọ. Mo ntọ́ka sí níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ó fẹ́ràn wa ju bí a ti lè ní òye lọ, pé Ó nrán àwọn ángẹ́lì láti wà pẹ̀lú wa àti pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn. Èmi ntọ́ka sí níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ó nfẹ́ láti ràn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti dé ibi ìlèṣe gígajùlọ wa.
Nísisìyí, báwo ni a ó ṣe jèrè irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀? Olúwa dáhùn àwọn ìbèèrè yí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Jẹ́ kí … inú rẹ kún fún ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ sí ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn, … kí ìwà ọ̀run ó sì ṣe èrò ọkàn rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ láì dáwọ́ dúró; nígbànáà ni ìfi ọkàn tán rẹ yíò ní agbára síi ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
Níbẹ̀ ni kókó ọ̀rọ̀ náà! Ní àwọn ọ̀rọ̀ ti Olúwa, ìfẹ́ àìlẹgbẹ́ àti ìwà ọ̀run nṣí ọ̀nà sí níní ìgbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, a lè ṣe èyí! Ìgbẹ́kẹ̀lé wa nítòótọ́ lè lágbára síi ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bayi nísisìyí!
Ẹ jẹ́ kí a yẹ méjèèjì ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ àti ìwà ọ̀run wò.
Ìkínní, ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́. Ọdún méjì sẹ́hìn, mo pè wá, gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì, láti jẹ́ olùlàjà. Mo tun ohun tí mo wí nígbànáà sọ pé: “Ìbínú kìí pàrọwà síni láé. Ìkanra kìí gbé ẹnikẹ́ni ga. Ìjà kò lè darí sí ojúùtú ìmísí láé.”
Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ tòótọ́ sí gbogbo ènìyàn ni àmì pàtàkì àwọn olùlàjà! Ó ṣe kókó kí a ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ nínú ìwàásù wa, méjèèjì ní gbangba àti ìkọ̀kọ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn kan lára yín tí wọ́n gba àmọ̀ràn mi tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ sọ́kàn. Ṣùgbọ́n a ṣì lè ṣe dáradára síi.
Ìkanra ìsisìyí ní ìsọ̀rọ̀ gbangba àti lórí ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ nkọni lóminú. Àwọn ọ̀rọ̀ ikorira jẹ́ ohun-ìjà olóró. Ìjà ndènà Ẹ̀mí Mímọ́ kúrò ní jíjẹ́ ojúgba léraléra wa.
Gẹ́gẹ́bí ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì, a níláti darí ọ̀nà bí àwọn olùlàjà. Bí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ṣe ndi ara ìwà-ẹ̀dá wa, a ó sọ ìrò láti rẹ àwọn ẹlòmíràn sílẹ̀ nù. A ó dáwọ́dúró dídájọ́ àwọn ẹlòmíràn. A ó ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ fún àwọn wọnnì láti gbogbo ilẹ̀ ayé. Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ sí gbogbo ènìyàn ṣe pàtàkì sí ìlọsíwájú wa. Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni ìpìnlẹ̀ ìwà tọ̀run.
Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run láti kún inú ọkàn wa pẹ̀lú ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́—nípàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọ́n ṣòro láti fẹ́ràn—nítorí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ni ẹ̀bùn kan láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn tòótọ́ Jésù Krístì. Olùgbàlà ni Ọba Àláfíà. A níláti jẹ́ ohun èlò Rẹ̀ fún àláfíà.
Nísisìyí, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ ìwà ọ̀run. Olúwa wí fún wa láti ṣìkẹ́ àwọn èrò wa láìsimi pẹ̀lú ìwà ọ̀run. Ẹ ronú ìgbéga tí ẹ ó gbà sí èrò dídára eyikeyi nígbàtí ẹ bá mú u gbòòro pẹ̀lú ìwà ọ̀run. Ìwà ọ̀run nmú ohun gbogbo dára si àti dunni nínú síi! Ní ọ̀nà míràn, ẹ ronú ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ nígbàtí ẹ bá fi ìwà ọ̀run kún èrò àìmọ́, èrò burúkú, tàbí èrò ìrẹ̀wẹ̀sì. Ìwà ọ̀run yíò lé àwọn èrò wọnnì lọ. Ìwà ọ̀run yíò sọ yín di òmìnira kúrò nínú àwọn èrò àníyàn, oníwàhálà.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí ayé ti ndàgbà síi nínú ibi, a nílò láti dàgbà púpọ̀ síi ní mímọ́. Àwọn èrò, ọ̀rọ̀, àti ìṣe wa nílò láti jẹ́ ìwà ọ̀run àìkùnà tí ó sì kún fún ìfẹ́ mímọ́ ti Jẹ́sù Krístì sí gbogbo ènìyàn. Ànfàní nlá níwájú wa ni láti di ènìyàn tí Ọlọ́run nílò wa láti jẹ́.
Ìjọsìn déédé nínú ilé Olúwa nmú okun wa pọ̀sì fún ìwà ọ̀run àti ifẹ́-àìlẹ́gbẹ́ pẹ̀lú. Bayi, àkokò nínú tẹ́mpìlì nmú ìgbẹ́kẹ̀lé wa níwájú Olúwa pọ̀si. Àkokò púpọ̀ nínú tẹ́mpìlì yíò ràn wá lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. A kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí bíbọ̀ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo mọ pé Olúwa nṣí mi létí láti rọ̀ wá láti ṣetán fún “ọjọ́ nlá àti bíbanilẹ́rù náà.”
Bí a ti nfi ìtara wá láti ní ìfẹ́-àìlẹ́gbẹ́ àti tí ìwà-ọ̀run nkún ilé ayé wa, ìgbẹ́kẹ̀lé wa ní dídé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run yíò pọ̀si. Mo pè yín láti mọ̀ọ́mọ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti dàgbà nínú ìgbẹ́kẹ̀lé yín ní ọ̀dọ̀ Olúwa. Nígbànáà, bí a ti nlọ sọ́dọ̀ Baba wa Ọ̀run pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ si, a ó kún inú wa pẹ̀lú ayọ̀ púpọ̀ síi, àti pé ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì yíò pọ̀ si. A ó bẹ̀rẹ̀ láti ní ìrírí agbára ti ẹ̀mí tí ó kọjá ìrètí títóbi jùlọ wa.
A fi ìmoore hàn sí Olúwa fún yíyára ní kíkọ́-tẹ́mpìlì ní àwọn àìpẹ́ ọdún. Lábẹ́ ìdarí Rẹ̀, ní òní a kéde àwọn ètò láti kọ́ tẹ́mpìlì kan ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ibí wọ̀nyí:
-
Reynosa, Mexico
-
Chorrillos, Peru
-
Rivera, Uruguay
-
Campo Grande, Brazil
-
Porto, Portugal
-
Uyo, Nigeria
-
San Jose del Monte, Philippines
-
Nouméa, New Caledonia
-
Liverpool, Australia
-
Caldwell, Idaho
-
Flagstaff, Arizona
-
Rapid City, South Dakota
-
Greenville, South Carolina
-
Norfolk, Virginia
-
Spanish Fork, Utah
Mo jẹri pé Jésù Krístì, Olùràpadà Ísráẹ́lì, ndarí Ìjọ Rẹ̀, yí. Ó nmúra láti wá lẹ́ẹ̀kansi. Njẹ́ kí àwa bákannáà múra láti gbà Á. Fún èyí ni mo gbàdúrà ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.