Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Bíi Ọmọ Kékeré
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


15:9

Bíi Ọmọ Kékeré

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ọmọ ọwọ́ àti àwọn ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́ jẹ́ àwòrán ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n nṣe rere ní orí ilẹ̀ ayé ní gbogbo agbára àti ẹwà rẹ̀.

Jésù bẹ̀rẹ̀ ọdún tó gbẹ̀hìn nínú ayé ikú Rẹ̀ nipa títẹramọ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn Apóstélì Rẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀ yíó bá gbẹ̀hìn Rẹ̀, púpọ̀ síi níláti jẹ́ titú sínú ọkàn àwọn ènìyàn lásán méjìlá náà tí wọ́n ti mọ̀ Ọ́ fún kò tíì tó oṣù mẹ́rìnlélógún tán.

Ní ọjọ́ kan Jésù ṣe ẹlẹ́rìí aríyànjiyàn kan ní ààrin wọn ó sì béèrè lẹ́hìnnáà pé, “Kínni ohun náà tí ẹ̀yin njà sí ni ààrin ara yín?” Ó hàn pé ojú tì wọ́n, wọn “kò sọ̀rọ̀,” ni àkọsílẹ̀ náà wí. Sùgbọ́n ẹni gígajùlọ nínú gbogbo àwọn olùkọ́ni yí wòye ìrònú ọkàn wọn ó sì rí ìtìjú àkọ́kọ́ ti ìgbéraga araẹni níbẹ̀. Nítorínáà Ó “pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, …

“Ó sì wipe, Lóotọ́ ni mo wí fún un yín, Bíkòṣepé ẹ̀yin bá ní ìyípadà ọkàn, tí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yío wọ ìjọba ọ̀run.

”Nítorínáà ẹnikẹ́ni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bíi ọmọ kékeré yìí, òun kannáà ni ó tóbi jùlọ ní ìjọba ọ̀run.”

Ó níláti jẹ́ àkíyèsíi pé àní ṣaáju ìbí Krístì, ìwàásù ìdágbére ti Ọba Bẹ́njámínì ní ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yí nínú lórí ìrẹ̀lẹ̀ ti ọmọ kékeré. Ó wí pé, “Ènìyàn nípa ti ara jẹ́ ọ̀tá sí Ọlọ́run, … yíò sì wà bẹ́ẹ̀, láé àti títí láé, bíkòṣepé … òun di ènìyàn mímọ́ nípasẹ̀ ètùtù ti Krístì Olúwa, tí ó sì dàbí ọmọdé, títẹ ara rẹ̀ ba, … nírẹ̀lẹ̀, … kíkún fún ìfẹ́, … àní bí ọmọdé tií [jọ̀wọ́ ara] fún baba rẹ̀.”

Nísisìnyí, ní àfojúrí àwọn òye níní kan wà tí a kìí gbani níyànjú rẹ̀. Ní ọdún karundínlọ́gbọ̀n sẹ́hìn, ọmọ-ọmọ mi, ọmọdékùnrin ẹni ọdún mẹ́ta nígbànáà gé arábìnrin rẹ̀ ẹni ọdún márun jẹ, ni apá. Ọkọ-ọmọ-mi, ni ṣíṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ náà ní alẹ́ ọjọ́ náà, ṣagbára láti kọ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní gbogbo ẹ̀kọ́ lórí àláfíà tí ó le ronú nípa rẹ, ní píparí pé bóyá ọmọkùnrin kékeré náà kò tilẹ̀ mọ bí gígénijẹ ní apá ti máa nrí lára. Ọ̀rọ̀ àìrònújinlẹ̀ baba náà ṣiṣẹ́ dáradára fún bíi ìṣẹ́jú kan, bóyá ìṣẹ́jú kan àti ààbọ̀, títí di ìgbà tí igbe kan tí ó fẹ́rẹ̀ yọ fèrèsé wá láti inú yàrá àwọn ọmọdé níbití ọmọ-ọmọ mi obìnrin ti rọra pè jáde pé, “Ó ṣeé nísisìyí.”

Nígbànáà kínni ohun náà tí ó yẹ ká rí nínú àwọn ìwà rere fásítì kékeré ti ìgbé ayé? Kínni ohun náà ti ó mú Krístì Fúnrarẹ̀ wá ní omijé nínú ìran tó ṣe ẹlẹgẹ́ jùlọ nínú gbogbo Ìwé ti Mọ́mọ́nì? Kínni ohun ti Jésù nkọ́ni nígbàtí Ó pe iná ọ̀run àti àwọn ángẹ́lì olùṣọ́ sọ̀kalẹ̀ láti yí àwọn ọmọdé wọnnì ká, ní pípàṣẹ fún àwọn àgbà láti “wo àwọn ọmọdé [wọn]”?

A kò mọ ohun tó fa gbogbo rẹ̀, ṣùgbọ́n mo níláti rò ó pé ó ní nkan ṣe pẹ̀lú àìlábàwọ́n àti àìmọ̀kan wọn, ìrẹ̀lẹ̀ àbínibí wọn, àti ohun tí ó mú wá sí ìgbésí ayé wa.

Èéṣe tí àwọn ọjọ́ àìnírètí wa fi jẹ́ jíjúwe láti ẹnu ẹnìkan bíi “asán ti àwọn asán”? Kínníṣe tí “àwọn èrò orí asán àti ìgbéraga awọn ọmọ ènìyàn” ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe àpẹrẹ ilé nlá àti gbígbòòrò, tí ó kú ní ti ẹ̀mí tóbẹ́ẹ̀ nínú ìran Léhì? Àti àwọn ará Sórámù, ẹgbẹ́ náà ti ó gbàdúrà pẹ̀lú sísìn-araẹni tóbẹ́ẹ̀? Nípa wọn ni Álmà wí pé, “Áà Ọlọ́run, wọn [ngbàdúrà] sí ọ́ pẹ̀lú ẹnu wọn, nígbàtí wọ́n rú sókè … pẹ̀lú àwọn ohun asán ayé.”

Ní ìdàkejì, njẹ́ ohunkóhun kan wà tí ó jẹ́ dídùn jù, àìléèrí jù, tàbí nírẹ̀lẹ̀ ju ọmọdé kan níbi àdúrà lọ? Ó dàbí pé ọ̀run wà nínú yàrá náà. Ọlọ́run àti Krístì jẹ́ òtítọ́ tóbẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n fún àwọn míràn ìrírí náà le dàbí àròsọ síi.

Bí Alàgbà Richard L. Evans ti ṣe àyọsọ rẹ̀ ní bíi ọgọ́ta ọdún sẹ́hìn: “Púpọ̀ nínú wa jẹ́wọ́ pé a jẹ́ Krístíẹ́nì, síbẹ̀ a … kò gbà Á pẹ̀lú ìrònú. … A nbọ̀wọ̀ fún Un, ṣùgbọ́n a kò tẹ̀lé E. … A nṣe àyọsọ àwọn ọ̀rọ̀ sísọ Rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbé nípasẹ̀ wọn.” “A mọyì Rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò sìn Ín.”

Ìgbésí ayé ìbá ti yàtọ̀ tó bí aráyé bá gbé Jésù tayọ ìpele ṣíṣe ìbúra asán láti ìgbà sí ìgbà.

Ṣùgbọ́n àwọn ọmọdé fẹ́ràn Rẹ̀ ní tòótọ́, àti pé ìfẹ́ náà le jẹ́ gbígbé kọjá sínú àwọn ìbáṣepọ̀ míràn nínú pápá ìṣeré ìgbésí ayé. Bíi ìlànà kan, àní ní ìgbà èwe wọn jùlọ, àwọn ọmọdé máa nfẹ́ràn pẹ̀lú ìrọ̀rùn, máa ndáríjì lójú ẹsẹ̀, ẹ̀rín wọn sì máa nwuni tóbẹ́ẹ̀ àní tí ọkàn tó tutù jùlọ, le yọ́.

Ó dára, àtòkọ náà tẹ̀síwájú. Àìlábàwọ́n? Ìgbẹ́kẹ̀lé? Ìgboyà? Ìwà?

Wá pẹ̀lú mi láti wo ìrẹ̀lẹ̀ níwájú Ọlọ́run tó jẹ́ fífihàn nípasẹ̀ ọ̀dọ́ ọ̀rẹ́ mi kan.

Easton Darrin Jolley

Ní 5Ọjọ́ karun Oṣù Kínní, 2025,—ọjọ́ mọ́kànléláàdọ́wá sẹ́hìn—Easton Darrin Jolley ni a fi Oyè Àlùfáà Áárónì fún ti a sì yàn án bíi díákónì nínu Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Easton ti fojúsọ̀nà láti pín àmì májẹ̀mu ti Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa fún ìgbà pípẹ́ tó bí ó ti lè rántí. Ṣùgbọ́n ànfààní mímọ́ yí wá pẹ̀lú ìbẹ̀rù dída inú rú pé òun yíó kùnà, pé òun yíó ṣubú, pé wọ́n ó fi òun ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kó ìtìjú bá ara òun àti ẹbí rẹ̀.

Easton ní àrún kan tó ṣọ̀wọ́n tó sì nbanijẹ́ gidi.

Ṣé ẹ ríi, Easton ní àrún kan tó ṣọ̀wọ́n tó sì nbanijẹ́ gidi, ó ní í ṣe pẹ̀lu àìlera egungun, iṣan àti oríkèé ara. Ó ti tẹ̀síwájú láti gba gbogbo ayé rẹ̀ bíi ọ̀dọ́ pẹ̀lú àwọn ìpèníjà púpọ̀ bí ó ti nba ìrètí àti àwọn àlá rẹ̀ fún ọjọ́ iwájú jẹ́. Láìpẹ́ òun yíó wà lórí àga aláfọwọ́yí títílọ. Ẹbí rẹ̀ kìí sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó ndúró dè é lẹ́hìn èyí.

Ní Ọjọ́ Ìsinmi tó tẹ̀lé yíyàn rẹ̀, Easton yíò pín oúnjẹ Olúwa fún ìgbà àkọ́kọ́. Ìwúrí rẹ̀ tí ó sì rọra mú dání ní àṣírí ni pé òun yíó gbé ara òun àti àwọn àmì mímọ́ wọ̀nyí lọ fún baba òun, ẹnití ó jẹ́ bíṣọ́pù ní wọ́ọ̀dù náà. Ni fífi ojú sọ́nà fún iṣẹ́ náà, ó ti bẹ̀bẹ̀ ó sì ti bèèrè ó sì sunkún ó sì bẹ̀bẹ̀, ní gbígba ìdánilójú pé kò sí ẹnikẹ́ni, ẹnikẹ́ni, tí yíò gbìyànjú láti ran òun lọ́wọ́. Fún àwọn ìdí púpọ̀, tó jẹ́ àṣírí sí òun funrarẹ̀, ó nílò láti dá nìkan ṣe èyí àti láìsí ìrànnilọ́wọ́.

Lẹ́hìn tí àlùfáà ti bu àkàrà náà tí ó sì súre sí i—àmì tó dúró fún bíbù ara ti Krístì—Easton, pẹ̀lú bíbu ara rẹ̀, ti ẹsẹ̀ sókè láti gba ọpọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn àtẹ̀gùn mẹ́ta wà láti ilẹ̀ ilé ìjọ́sìn náà sí ibi pèpéle ìdúró. Nítorínáà, lẹ́hìn gbígba ọpọ́n rẹ̀, ó nà sókè bí ó ti lè ga tó ó sì gbé e sí orí ibikan ní òkè ìgbọ́wọ́lé. Lẹ́hìnnáà, ní jíjókòó lórí ọ̀kan lára àwọn àtẹ̀gùn tó ga jù, pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì ó fa ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún sókè sí orí àtẹ̀gùn àkọ́kọ́. Lẹ́hìnnáà ó fa ẹsẹ̀ rẹ̀ òsì sí orí àtẹ̀gùn kannáà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ títí tí, pẹ̀lú ìnira, ó fi dé ibi Òkè Ẹvẹ́rẹ́stì alátẹ̀gùn mẹ́ta ti araẹni rẹ̀.

Lẹ́hìnnáà ó gbé ara rẹ̀ sí ipò kan nípa èyítí òun le gùn sí ipò ìdúró. Ó mú ọ̀nà rẹ̀ padà sí ibi ọpọ́n náà. Lẹ̀hìn àwọn ìgbésẹ̀ díẹ̀ síi ó sì dúró níwájú bíṣọ́pù, baba rẹ̀, ẹnití, pẹ̀lú omijé kíkún ojú rẹ̀ tí ó sì nṣàn sọ̀kalẹ̀ wò ojú rẹ̀, o´ ní láti kó ara rẹ̀ níjánu ní dídìmọ́ ọmọ onígboyà àti onígbàgbọ́ pípé yí. Àti pé Easton, pẹ̀lu ìtura àti ẹ̀rín nlá tí ó bo ìwò ojú rẹ̀, ti lè sọ dáradára pé, “Èmi ti ṣe [baba mi] lógo mo sì ti parí iṣẹ́ náà tí [ó fún] mi láti ṣe.”

Ìgbàgbọ́, ìṣòtítọ́, àìlábàwọ́n, ìgbẹ́kẹ̀lé, bíbu ọlá fún, àti, ní ìparí, ìfẹ́ fún baba náà tí ó fẹ́ tóbẹ́ẹ̀ láti tẹ́ lọ́rùn. Ìwọ̀nyí àti àwọn àmúyẹ míràn bíi dọ́sìnnì kan ló nmú wa sọ bákannáà pé, “Ẹnikẹ́ni … tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí, òun kannáà ni ó tóbi jùlọ ní ìjọba ọ̀run.”

Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin àti ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ní òkè pátápátá àtòkọ àwọn àwòrán to rẹwà jùlọ ni mo mọ̀ tí àwọn ọmọ ọwọ́ àti àwọn ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹlẹrìí-ọkàn àti àìdíyelé bíi àwọn wọnnì tí a ti tọ́ka sí lonìí. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n jẹ́ àwòrán ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n nṣe rere ní orí ilẹ̀ ayé ní gbogbo agbára àti ẹwà rẹ̀.

Nínú ẹ̀mi yí kannáà ti ẹ̀rí, mo jẹ́ ẹ̀rí pé ní ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀, Joseph Smith rí ohun tó sọ pé òun rí ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ó sọ pé òun bá sọ̀rọ̀. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni mímọ́ Russell M. Nelson kan ni wòlíì àti aríran tí Ọlọ́run yàn tó sì fún ní ẹ̀bùn. Ní wíwá láti inú kíkàwé déédé ti gbogbo ọjọ́ ayé, mo jẹ́rìí pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ìwé to fúnni lérè jùlọ tí mo ti kà àti igun okúta ti ibùgbé kékeré mi nínú ìjọba kan tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibùgbé. Mo jẹ́rìí pé oyè-àlùfáà àti àdúrà nmú ìgbé ayé mi padàbọ̀sípò—oyè-àlùfáà ti Krístì àti àwọn àdúrà yín. Mo mọ gbogbo eyí pé ó jẹ́ òtítọ́ mo sì jẹ́ ẹ̀rí rẹ̀ ní orúkọ olóotọ́ àti onírẹ̀lẹ̀ jùlọ nínú gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run—Álfà àti Ómégà, Èmi Ni Nlá náà, ẹnití a kàn mọ́ àgbélèbú, ẹlẹ́rìí òdodo—àní Olúwa Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Márkù 9:33.

  2. Márkù 9:34.

  3. Wo Lúkù 9:47.

  4. Máttéù 18:2–4.

  5. Mòsíàh 3:19.

  6. 3 Néfì 17:23; bákannáà wo àwọn ẹsẹ 11–24.

  7. Oníwàásù 1:2.

  8. 1 Néfì 12:18.

  9. Álmà 31:27.

  10. James W. Clarke, ṣe àyọsọ nínú Richard L. Evans, nínú Ìròhìn Ìpàdé Àpapọ̀,Oṣù Kẹrin 1965, 136. Alàgbà Evans ṣe àkíyèsí pé àyọsọ yí wá láti inú ìwàásù orí rédíò tí a fúnni láti ọwọ́ Dr. James W. Clarke, èyítí a ṣe àyọsọ rẹ̀ láti ẹnu William H. Danforth.

  11. Clarke, nínú Richard L. Evans, nínú Ìròhìn Ìpàdé Àpapọ̀,Oṣù Kẹrin 1965, 136.

  12. Jòhánnù 17:4. Àkọsílẹ̀ ti araẹni tí a pín láti ọwọ́ Brian àti Charisa Jolley pẹ̀lú Jeffrey R. Holland, Oṣù Kínní 2025.

  13. Máttéù 18:4.

  14. Wo Ìfihàn 1:5.