Àwọn Ẹ̀bùn Nlá ti Ayéraye : Ètùtù Jésù Krístì, Àjínde, Ìmúpadàbọ̀sípò
A nrí àláfíà, dídà, àti jíjẹ́ ti nínú Ọdún Àjínde nínú Jésù Krístì—èyí tí ó jẹ́ nní ìforìtì òdodo àti aláyọ̀, dídunnú àti títíláé.
Àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, kílásì òwúrọ̀ kùtùkùtù ti àkọ́sórí àwọn ọ̀rọ̀ bíbélì wa. Níti àdánidá mo ní ìfàsí àwọn ẹsẹ kúkurú. Èyí pẹ̀lú John 11:35—ẹsẹ tó kúrújùlọ nínú ìwé-mímọ́, àwọn ọ̀rọ̀ méjì péré—“Jésù sọkún.”
Fún mi báyìí, pé Jésù sọkún nínú ìkorò àti ayọ̀ jẹ́ ẹ̀rí nípa òdodo ìyanilẹ́nu: Ọmọ àtọ̀runwá Ọlọ́run wá níti ara sínú ayé ikú ó sì kẹkọ gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara láti wà pẹ̀lú àti láti bùkún wa nígbàgbogbo.
Nígbàtí a bá kígbe síta nínú ọ̀fọ̀ tàbí ayọ̀, Jésù Krístì ní ìmọ̀ ní pípé. Òun lè wà ní àrọ́wọ́tó ní àwọn àkokò nígbàtí a bá nílò àwọn ẹ̀bùn nlá ayérayé: Ètùtù Jésù Krístì, Àjínde, ìmúpadàbọ̀sípò.
Mary àti Martha sọkún fún arákùnrin wọn Lazarus, ẹni tí ó kú. Pẹ̀lú ìyọ́nú, Jésù sọkún. Ó jí Lásárù dìde wá sí ìyè.
Jésù kíyèsí Jésúsálẹ́mù ní ìrọ̀lẹ́ Ìrékọjá. Ó sọkún, ní àìlè kó àwọn ènìyàn Rẹ̀ jọ bí ẹdìyẹ kan yíò fi kó òròmọdìyẹ rẹ̀ jọ. Ní òní Ètùtù Rẹ̀ nfún wa ní ìrètí nígbàtí a bá ní ìkorò fún ohun tí ìbá ti wà.
Olúwa ọgbà àjàrà nsọkún bí Ó ti nbèèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀, èyí tí ó lè jẹ́ tiwa bí oníṣẹ́ ìránṣẹ́ arákùnrin àti arábìnrin, “Kíni èmi ìbá ṣe síi fún ọgbà àjàrà mi?”
Mary dúró ní ibi bojì bí aládánù. Jésù fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bèèrè, “Kílódé tí ẹ̀ nsọkún??” Ó mọ̀ pé “ẹkún le pẹ́ di alẹ́ kan, ṣùgbọ́n ayọ̀ nbọ̀ ní òwúrọ̀.” Àjínde nmú òwúrọ́ wá fún gbogbo ènìyàn.
Nínú àwọn ilẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, bí àwọn èrò olótítọ́ ti ndìde sí I, ayọ̀ Jésù kún. Ó nsọkún.
“Ó sì gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ó sì súre fún wọn, ó sì gbàdúrà sí Bàbá fún wọn.
“Nígbàtí ó sì ti ṣe èyí tán ó tún sọkún.”
Èyí ni ọdún Àjínde nínú Jésù Krístì: Ó dáhùn àwọn ìpòngbẹ ọkàn wa àti àwọn ìbèèrè ẹ̀mí wa. Ó nu omijé wa kúrò, àyàfi àwọn omijé ayọ̀ wa.
Nígbàtí omijé wa bá nṣàn, à nṣe gáfárà nígbàmíràn, ìdójútì. Ṣùgbọ́n mímọ̀ pé Jésù Krístì ní ìmọ̀ ìrora àti ayọ̀ ayé lè fún wa ní okun kọjá ti ara wa bi a ti nyíká nínú ìkorò àti adùn.
Ní Gúsù Amẹ́ríkà, baba kan nrin. Ìfọ̀wọkàn nínú ayé rẹ̀, ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀, ti kú. “Èmi yíò fi ohunkóhun fúnni láti ríi lẹ́ẹ̀kansi,” ó nké ní apá mi. Mo sọkún pẹ̀lú.
Níbi ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Puebla Mexico, omijé rin ojú arábìnrin ọ̀wọ́n kan. Àwọn ẹ̀yà rẹ̀ ndán nínú ìgbàgbọ́ àti ìrúbọ. Ó wípé, “Todos mis hijos estan aqui en el templo hoy”—“Gbogbo àwọn ọmọ mi wà nihin nínú tẹ́mpìlì ní òní.” Àwọn ìran tó kórajọ nínú ilé Olúwa nmú omijé ayọ̀ àti ìmoore wá.
Nínú ogun ìkà abẹ̀lé, àwọn ẹbí àti aladugbo ṣe àwọn ohun àìlèsọ sí ara wọn. Àwọn omijé kíkorò nfi ọ̀nà sílẹ̀ fún ìrètí. Ohùn rẹ̀ ngbọ̀n, obìnrin kan nínú ìletò kékeré kan wípé, “Aladugbo, ṣíwájú kí ntó lọ sí ibojì mi, mo fẹ́ kí ẹ mọ ibití tí ẹ ó ti rí àwọn ọmọ ẹbí yín tí wọ́n sọnù.”
Ìyàwó dídán kan àti ọkọ-ìyàwó dídára ni à nṣe èdìdi fún nínú ilé Olúwa. Obìnrin náà jẹ́ àádọ́rin ọdún, bí ti òun. Arẹwà ìyàwó kan, ó ti dúró ní yíyẹ fún ọjọ́ yí. Ó fi títìjú yí aṣọ ìgbéyàwó rẹ̀ ní ọ̀nà yí, lẹ́hìnnáà ní ọ̀nà náà. A sun omijé aláyọ̀. Àwọn ìlérí Ọlọ́run ni à múṣẹ. Àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ mú àwọn ìbùkún wá.
Nígbàtí à nkọ́ arábìnrin opó kan nílé, ọ̀dọ́ Boyd K. Packer kọ́ ẹ̀kọ́ rírọ́lẹ̀ kan. Ní títẹ̀lé èdèàìyedè kan pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, arábìnrin náà ti ṣe ìpè ọ̀rọ̀ ìgbẹ̀hìn pípanilára kan jáde. Ìjàmbá àìrò kan mu ayé ọkọ rẹ̀ lọ níjọ́ náà. “Fún àádọ́ta ọdún,” opó náà rin, “Mo ti gbé nínú ọ̀run àpáàdì ní mímọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹhìn rẹ̀ tí ó gbọ́ láti ẹnu mi ni àwọn ọ̀rọ̀ ìkọlù, ẹ̀tanú.”
Ọdún Àjínde nínú Jésù Krístì nṣèrànwọ́ láti tú wa ṣe, bálàjà, mú àwọn ìbáṣepọ̀ wa tọ́, ní àwọn ẹ̀gbẹ́ ìkelè méjèèjì. Jésù lè wo ìbìnújẹ́; Ó sì lè fàyè gba ìdáríjì. Òun lè fún wa àti àwọn ẹlòmíràn ní òmìnira kúrò nínú àwọn ohun tí àwa tàbí àwọn ti sọ tàbí ṣe bíbẹ́ẹ̀kọ́ tí ìbá ti so wá pọ̀ ní ìgbèkùn.
Ọdún Àjínde nínú Jésù Krístì njẹ́ kí a ní ìmọ̀lára ìfọwọ́sí ti Ọlọ́run. Ayé yí nwí fún wa pé a ti ga jù, kúrú jù, gbòòrò jù, há jù—àìgbọ́n, lẹ́wà, tàbí níti ẹ̀mí tó. Nípasẹ̀ ìyípadà ti ẹ̀mí nínú Jésù Krístì, a lè ní àbáyọ àìlera ní pípé.
Pẹ̀lú ayọ̀ ọdún Àjínde, à nkọrin, “A ti ṣẹ́gun ikú; ènìyàn ti ní òmìnira. Krístì ti gba ìṣẹ́gun.” Àjínde Krístì sọ wá di òmìnira kúrò nínú ikú, láti àkokò àìlágbára àti àwọn àìpé ti ara. Ètùtù Jésù Krístì pẹ̀lú nmú wa padàsípò níti ẹ̀mí. Ó ṣẹ̀jẹ̀ láti gbogbo ihò-ara, ó nsọkún ẹ̀jẹ̀ bí ó ti wà, láti pèsè ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìyapa. Ó tún wa dàpọ̀, ní odindi àti mímọ́, pẹ̀lú arawa àti Ọlọ́run Nínú àwọn ohun gbogbo, Jèsù Krístì mú ọ̀pọ̀ padàbọ̀sípò—kìí ṣe ohun tí ó wà nìkan ṣùgbọ́n ohun tí ó lè jẹ́ pẹ̀lú.
Ìgbésí ayé Jésù àti ìmọ́lẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀. Nítorí Ọlọ́run Baba wa fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ orí àti ilẹ̀, a nrí ìfipè ìfẹ́ni Rẹ̀ láti wá àláfíà àti ayọ̀ rí nínú Rẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣà àti ọ̀làjú. Níbikíbi, nígbàkugbà, ẹnikẹ́ni tí a jẹ́, à npín ìdánimọ̀ àtọ̀runwá bí àwọn ọmọ ti Aṣẹ̀dá kannáà. Nínú irú ẹ̀mí kannáà, àwọn àtẹ̀lé Islam, Judaism, àti Krístẹ́nì npín ogun ẹ̀sìn nínú Baba Ábráhámù àti ìsopọ̀ májẹ̀mú nípasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nínú Égípítì àtijọ́.
Baba Ábráhámù wá sí Égípítì ó sì di alábùkúnfún
Joseph, tí a tà ní ẹrú sí Égípítì, mọ àlá Pharaoh tí ó fi ọ̀dún méje ọ̀pọ̀ tí ó tẹ̀lé ọdún méje ìyàn hàn. Joseph gba ẹbí rẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀ là. Joseph sọkún nígbàtí ó rí ètò títóbi jù Ọlọ́run, níbití gbogbo ohun ti ṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere fún àwọn wọnnì tí wọ́n pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́.
Mósè, tí a tọ́ ní Égípìtì nínu agbo-ilé Fáráò, gba ó sì mú àwọn kọ́kọ́rọ́ fún ìkójọ àwọn ọmọ Ọlọ́run padàbọ̀sípò lẹ́hìnwá.
Ní mímú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, Joseph, Mary, àti ọmọ jòjòló Krístì wá ààbò nínú Égípítì. Ní Cairo, olùfọkànsìn mùsùlùmí kan fi pẹ̀lú ọ̀wọ̀ wípé: “Kùránì kọ́ni pé Joseph, Mary, àti Jésù ọmọ-ọwọ́ rí ààbò àti ilé mímọ́ ní orílẹ̀-èdè mi. Ní orílẹ̀-èdè mi, Jésù bí ọmọ kékeré jẹ́ oúnjẹ, gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ Rẹ̀, sọ àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ Rẹ̀. Nihin ni orílẹ-èdè mi, a gbàgbọ́ pé àwọn igi ntẹ̀ba sílẹ̀ láti fún Òun àti ẹbí Rẹ̀ ní èso. Wíwà ní orílẹ̀-èdè mi Rẹ̀ bùkún àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wa.”
Ètò Ọlọ́run nípa ìwà àti agbára òmìnira ayé ikú fi ààyè gbà wá láti kẹkọ nípa ìrírí ara wa. Àwọn ẹ̀kọ́ ayé wa púpọjùlọ nwá látinú àwọn ohun tí a kò ní yàn láéláé. Nínú ìfẹ́, Jésù Krístì sọ̀kalẹ̀ ó sì gòkè kọjá àwọn ohun gbogbo. Ó yayọ̀ nínú àwọn okun àtọ̀runwá fún dídásílẹ̀ àti ìdùnnú, inúrere láìsí ìrètí fún èrè, ìgbàgbọ́ sí ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì. Ó sì sọkún nínú ìkorò àti ọ̀pọ̀ ìjìyà, ìwà ìkà, àìdára ti ènìyàn wa—tí yíyàn ènìyàn nmú wá nígbàkugbà—bí àwọn ọ̀run ti ṣe àti Ọlọ́run ti ọ̀run pẹ̀lú wọn.
Ọdún Àjínde orísun àkokò kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹ̀rí ti ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀mí àti pé ìdàpọ̀ ni ara méjèèjì ti àwòṣe àtọ̀runwá ti ètùtù, àjínde, àti ìmúpadàbọ̀sípò nípasẹ̀ Jésù Krístì. Ìdàpọ̀ mímọ́ àti alámì yí nwá kìí ṣe nípa ìjàmbá tàbí pẹ̀kírẹ̀kí. Ọjọ́-ìsinmi Ọ̀pẹ, Ọ̀sẹ̀ rere, àti pé ọdún Àjínde nṣe àjọyọ̀ Ètùtù àti Àjínde Krístì. Bí oní, ní gbogbo Ọjọ́ Kẹfà Oṣù Kẹ́rin à nṣe àjọyọ̀ ìdásílẹ̀ àti ìṣètò Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ìmúpadàbọ̀sípò yí ni èrèdí kan tí a fi kórajọ ní Ọjọ́-ìsinmi àkọ́kọ́ ní Oṣù Kẹ́rin kọ̀ọ̀kan nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò.
Ìmúpadàbọ̀sípò pẹ̀lú nwá bí olùjínde Jésù Krístì, Mósè, Elias, àti Elijah ti da àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà àti àṣẹ padà ní Tẹ́mpìlì Kirtland tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàsímímọ́ ní ọdún Àjínde Ọjọ́-ìsinmi, 1836. Nínú àgbékalẹ̀ náà ní ọjọ́ náà sí ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Jésù Krístì ni àṣẹ Ọlọ́run àti àwọn ìbùkún láti kó àwọn ọmọ Rẹ̀ jọ wà, múra àwọn ọmọ Rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, kí ó sì da àwọn ẹbí pọ̀ fún ayé àìlópin. Ìmúpadàbọ̀sípò ní ọjọ́ náà mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ nípa ṣíṣẹlẹ̀ ní ọdún Àjínde àti Ìrékọjá papọ̀.
Pẹ̀lú Tẹ́mpìlì Kirthland, láìpẹ́ mo bẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibi mímọ́ wò níbití Wòlíì Joseph àti àwọn míràn ti rí ìran Ọlọ́run Baba wa àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Wòlíì Joseph rí bí ọ̀run ṣe rí. Ní ọ̀run, Baba Ọ̀run, nípasẹ̀ Jésù Krístì, “gba gbogbo àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ là ” nínú ìjọba ológo. Àwọn àyọkúrò kanṣoṣo ni àwọn wọnnì tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ “sẹ́ Ọmọ lẹ́hìn tí Baba ti fi í hàn.”
Bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, Jésù kéde iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ láti bùkún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa pẹ̀lú gbogbo èyí tí à nfẹ́ láti gbà—ní gbogbo ìgba, gbogbo ilẹ̀, gbogbo ipò. Lẹ́hìn àwẹ̀ ogójì ọjọ́, Jésù lọ sínú sínágọ́gù ó sì kà pé, “Ẹ̀mí Olúwa nbẹ lára mi, nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mi láti wàásù ìhìnrere sí àwọn òtòṣì, ó ti rán mi láti wò àwọn ọkàn oníròbìnújẹ́ sàn, láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn tó wà nígbèkùn, àti ìríran fún àwọn afọ́jú, láti sọ àwọn tí a pa lára di ọ̀mìnira.”
Tálákà, oníròbìnújẹ́ ọkàn, onígbèkùn, afọ́jú, olùpalára—ìyẹn ni ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa.
Ìwé Ísáíàh tẹ̀síwájú nípa ìlérí ti ìrètí, ìràpadà, ìdánilójú ti-Mèssíà: “Yàn fún àwọn tí nṣọ̀fọ̀ fún Síónì, … fi ọ̀ṣọ́ fún wọn nípò eérú, òróró ayọ̀ nípò ọ̀fọ̀, aṣọ ìyìn nípò ẹ̀mí ìbànújẹ́.”
Báyìí, a kígbe síta, “Èmi ó yọ̀ gidigidi nínú Olúwa, ọkàn mi yíò yọ nínú Ọlọ́run mi; nítorí ó ti fi ẹ̀wù ìgbàlà wọ̀ mí, ó ti fi aṣọ òdodo bò mí.”
Ní àkokò ọdún Àjínde kọ̀ọ̀kan à nṣe àjọyọ̀, bí àmì odindi, àwọn ẹ̀bùn nlá ayérayé nípasẹ̀ Jésù Krístì: Ètùtù Rẹ̀; (àti ìlérí ti) Àjínde Rẹ̀ fún wa bí ọ̀rọ̀ gan, Ìmúpadàbọ̀sípò ti Ìjọ Rẹ̀ ọjọ́-ìkẹhìn pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà àti àṣẹ láti bùkún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run. A yọ̀ nínú àwọn ẹ̀wù ìgbàlà àti aṣọ òdodo. A kígbe, “Hòsánnà sí Ọlọ́run àti Ọ̀dọ́-àgùtàn!”
“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ́ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
Njẹ́ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa rí ètùtù, àjínde, àti ìmúpadàbọ̀sípò—àláfíà, dídà, àti wíwà-pẹ̀lú—èyí tí ó nní ìforítì òdodo àti aláyọ̀, inúdídùn àti títíláé nínú Jésù Krístì, ni mò gbàdúrà nínú orúkọ mímọ́ Rẹ̀, Jésù Krístì, àmín.