Ètùtù Jésù Krístì Npèsè Ìgbàlà Ìgbẹ̀hìn
Bí a ti nyí sí Jésù Krístì, Olùgbàlà ayé, Ó ngbà wá là kúrò nínú àwọn ìjì ayé nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀.
Ètùtù Jésù Krístì npèsè ìgbàlà ìgbẹ̀hìn gíga kúrò nínú àwọn àdánwò tí à ndojúkọ nínú ayé yí. Ààrẹ Russell M. Nelson yàn mí láti ya Tẹ́mpìlì Casper Wyoming sí mímọ́ ní òpin ọdún tó kọjá. Ó jẹ́ ìrírí ìjìnlẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn, àti ti-ẹ̀mí. Ó mú ojúṣe tí àwọn tẹ́mpìlì ti nkópa ní gbígba àwọn ọmọ Ọlọ́run là nípasẹ̀ Ètùtù Olùgbàlà hàn kedere.
Àwọn èèkàn ní ẹ̀kùn Tẹ́mpìlì Casper Wyoming pẹ̀lú apákan ìtọ́pa ọ̀nà tí àwọn olùlànà Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn lò ní ààrín 1847 àti 1868. Ní mímúrasílẹ̀ fún ìyàsímímọ́ tẹ́mpìlì náà, mo ṣe àtúnkà àwọn ìwé-ìtàn ti ìtọ́pa lẹgbẹ Odò Platte nítòsí Casper àti títẹ̀síwájú sí Ìlú Salt Lake. Ìtọ̀pa náà ti jẹ́ ọ̀nà-lílà fún ọgọgọ́ọ̀rún ti ẹgbẹgbẹ̀ẹ̀rún ti àwọn àṣíkiri ìwọ̀-oòrùn. Kókó àtẹnumọ́ mi ni àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún ọgọ́ta àwọn olùlànà Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí wọ́n rin ìrìnàjò ìtọ́pa náà.
Púpọ̀jù lára àwọn olùlànà wa wá nípasẹ̀ ọkọ̀-akẹ̀rù, ṣùgbọ́n bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ni wọ́n sọdá nínú ẹgbẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí mẹ́wàá. Mẹ́jọ lára ẹgbẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí wọ̀nyí ṣe ìrìn àràbarà náà pẹ̀lú ìyege tó lápẹrẹ àti ikú díẹ̀. Kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí ẹgbẹ́ Willie àti Martin ti 1856 ni a yọkúrò.
Mo ṣe àyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ ti kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí ẹgbẹ́ Willie àti Martin látinú àkokò tí àwọn ipò ojú-ọjọ́ búburú bẹ̀rẹ̀. Mo ní ìfura tímọ́tímọ́ nípa àwọn ìpènijà tí wọ́n dojúkọ ní sísọdá Odò Omi-dídùn, Martin’s Cove, Rocky Ridge, àti Àpàta Creek Hollow.
Ní àárín àwọn ìjì, láti ọwọ́ Albin Veselka
Èmi kò tíì wà nínú Tẹ́mpìlì Casper ṣíwájú sí ìyàsímímọ́ náà. Nígbàtí mo wọnú ọ̀dẹ̀dẹ̀, ìfojúsí mi yí sí kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí àtilẹ̀bá kíkùn kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Ní ààrin àwọn Ìjì. Kíkùn náà kìí ṣe kedere láti fi àwọn àjálù tí ó ti ṣẹlẹ̀ hàn. Bí mo ti wò ó, mo lérò pé, “Kíkún yí tọ́; púpọ̀ jùlọ àwọn olùlànà kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí kò ní ìrírí àwọn àjálù.” Èmi kò lè ṣèrànwọ́ ní níní ìmọ̀lára pé èyí jẹ́ ìgbésí ayé káríayé. Nígbàmíràn a wà ní àárín àwọn ìjì àti nígbàmíràn ní àárín àwọn ìkukù àti ríràn oòrùn
Ẹnu-ọ̀nà Tọ̀run, láti ọwọ́ Jim Wilcox
Nígbàtí mo yí sí kíkùn àtilẹ̀bá lórí ògiri míràn, tí akọlé rẹ̀ jẹ́ Ẹnu-ọ̀nà ti Ọ̀run, Mo damọ̀ pé kíkùn rírẹwà ìgbà-ẹ̀rùǹ ti ohun tí à npè ní “Ilẹ̀kùn Èṣù,” pẹ̀lú Odò omi-Dídùn rírọlẹ̀ àti mímọ́ tí ó nṣàn nínú rẹ̀, tí ó gbé ẹwà ìdásílẹ̀ Olúwa kalẹ̀, kìí kàn ṣe àwọn ìpènijà tí àwọn olùlànà dojúkọ ní àkokò òtútù búburújù.
Nígbàtí mo wo iwájú, lẹ́hìn tábìlì, mo sì rí ẹwà kíkùn ti Olùgbàlà. Èyí lọ́gán ni ó fi àwọn ìmọ̀lára bíbonimọ́lẹ̀ ìmoore síi. Nínú ayé ti ẹwà nlá, bákannáà ni àwọn ìpènija títóbí wà. Bí a ti nyí sí Jésù Krístì, Olùgbàlà ayé, Ó ngbà wá là kúrò nínú àwọn ìjì ayé nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ètò Baba.
Fún mi, ọ̀dẹ̀dẹ̀ náà jẹ́ ìmúrasílẹ̀ pípé fún àwọn yàrá ìlànà tẹ́mpìlì tí ó fi àyè gbà wá láti gba àwọn ìlànà ìgbéga, dá àwọn májẹ̀mú mímọ́, kí a sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní kíkún kí a sì ní ìrírí àwọn ìbùkún Ètùtù Olùgbàlà. Ètò ìdùnnú Baba ni ó dálé ètùtù ìgbàlà Olùgbàlà.
Ìrírí olùlànà npèsè àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn pẹ̀lú àṣà ìwé-ìtàn àìláfiwé àti àpapọ̀ ìjogún ti-ẹ̀mí alágbára. Fún àwọn kan, ṣíṣíkiri náà ti gba ọdún púpọ̀ ní ṣíṣe lẹ́hìn fífi tipátipá lé wọn kúrò ní méjèèjì Missouri àti Nauvoo. Fún àwọn míràn, ó ti bẹ̀rẹ̀ lẹ́hìn tí Ààrẹ Brigham Young kéde ètò kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí, èyí tí a gbèrò láti mú àṣíkiri jẹ́ wíwà níkáwọ́. Kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí náà jẹ́ òye púpọ̀ ju ti àwọn kẹ̀kẹ́-akẹrù àti ràkúnmí.
Òjíṣẹ́ ìhìnrere kan ní England, Millen Atwood, wípé nígbàtí a bá kéde ètò kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí, “Ó sá bí ìná jíjó nínú pápá gbígbẹ, àti ọkàn òtòṣì àwọn Ènìyàn Mímọ́ tó kún fún ayọ̀ àti ìnúdídùn.” Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti “gbàdúrà wọ́n sì gbàwẹ̀ ní ọjọ́ sí ọjọ́, àti alẹ́ sí alẹ́, kí wọ́n lè ní ànfàní ti dídàpọ̀ pẹ̀lú arákùnrin àti arábìnrin wọn ní orí òkè [náà].”
Púpọ̀jù kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní ìrírí ìṣóro ṣùgbọ́n wọ́n yẹra fún kókó àbájáde àwọn ìṣẹ̀lẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí méjì, ẹgbẹ́ Willie àti ẹgbẹ́ Martin, ní ìrírí ebi, híhàn sí ojú ọjọ́ dídì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ikú.
Púpọ̀ lára àwọn arìnrìn àjò lọ láti Liverpool, England, ní Oṣù Karun ti 1856 lórí àwọn ọkọ̀-ojú omi méjì. Wọ́n dé ibi ìwọṣọ kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí ní Ìlú Iowa ní Oṣù Kẹfà àti Ìkéje. Pẹ̀lú àwọn ìkìlọ̀, ẹgbẹ́ méjèèjì kúrò lọ sí Àfonífojì Salt Lake pípẹ́ jù ní àkokò náà.
Ààrẹ Brigham Young kọ́kọ́ ní ìfura ipò ewu ti àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí ní Ọjọ́ Kẹ́rin Oṣù Kẹwa, 1856. Ní ọjọ́ kejì ó dúró níwájú àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Ilú Salt Lake ó sì wípé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí, … wọ́n sì gbọ́dọ̀ di mímú wá sí ìhín; a gbọ́dọ̀ rán ìrànwọ́ sí wọn … ṣíwájú kí òtútù tó bẹ̀rẹ̀.”
Ó ni kí àwọn bíṣọ́ọ̀pù ó pèsè ọgọ́ta ọ̀gbà ìbáàkà, kẹ̀kẹ́ akẹrù méjìlá, àti tóònù méjìlá ìyẹ̀fun ó sì kéde, “Ẹ lọ kí ẹ sì mú àwọn ènìyàn wọnnì tí wọ́n wà lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ wá nísisìyí.”
Àpapọ̀ iye àwọn olùlànà nínú àwọn ẹgbẹ́ kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí Willie àti Martin jẹ́ bíi ẹgbẹ́ẹ̀rún ó lé ọgọ́ọ̀rún. Àwọn igba lára àwọn Ènìyàn Mímọ́ iyebíye wọ̀nyí kú lẹ́gbẹ ọ̀nà náà. Láìsí pé ìgbàlà tètè wá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi ìbá ti ṣègbé.
Àwọn ìjì òtútù bẹ̀rẹ̀ ní bíi ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́hìn tí àwọn olùgbànisílẹ̀ àkọ́kọ́ fi Ilú Salt Lake sílẹ̀. Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ ìjọ ti ẹgbẹ́ Willie àti Martin júwe àwọn ìpènijà apanirun lẹ́hìn tí àwọn ìjì bẹ̀rẹ̀. Àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí bákannáà fi ayọ̀ hàn nígbàtí àwọn olùgbanisílẹ̀ dé.
Ní jíjúwe dídé ìran, Mary Hurren wípé, “Omijé nṣàn sílẹ̀ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ àwọn ènìyàn, àwọn ọmọ sì jó fún ayọ̀. Ní àìpẹ́ bí àwọn ènìyàn náà ti lè ṣàkóso àwọn ìmọ̀lára wọn, wọ́n kúnlẹ̀ nínú yìnyín wọ́n sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run.”
Ọjọ́ kejì lẹ́hìn náà, ẹgbẹ́ Willie níláti rin ìrìnàjò lọ síbi tó ṣòro jùlọ lára ìtọ̀pa náà, tó nlọ lórí Rocky Ridge, nínú ìjì dídì kan. Ìkẹhìn lára wọn kò dé àgọ́ títí di aago marun ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì. Àwọn ènìyàn mẹ́tàlá kú a sì sin wọ́n sínú ibòji ìwọ́pọ̀ kan.
Ní Ọjọ́ Kéje Oṣù Kọkànlá, ẹgbẹ́ Willie nsúnmọ́ Àfonífojì Salt Lake, ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ náà àwọn ikú mẹ́ta ṣì wà. Ọjọ́ kejì lẹ́hìn náà, ẹgbẹ́ Willie dé Salt Lake nígbẹ̀hìn, níbití wọ́n ti ní ìkíní yíyanilẹ́nu tí a sì kí wọn káàbọ̀ sínú ilé àwọn Ènìyàn Mímọ́.
Ní ọjọ́ kannáà, ẹgbẹ́ Martin ṣì jẹ́ ọgọ́rún mẹ́ta ó lé marundinlọgbọn máìlì sẹ́hìn lórí ìrìn náà, ní títẹ̀síwájú láti jìyà kúrò nínú òtútù àti àìsí oúnjẹ tó tó. Ọjọ́ díẹ̀ ṣíwájú, wọ́n ti sọdá Odò omi-Dídùn láti débi ohun tí a npè ní Martin’s Cove, níbití wọ́n ti nírètí láti rí ààbò kúrò nínú àwọn èròjà. Ọ̀kan lára àwọn olùlànà wípé, “Ó jẹ́ odò sísọdá tó búburújùlọ nípa ìrìnàjò náà.” Díẹ̀ lára àwọn olùgbanisílẹ̀—bíiti baba-baba-baba mi, David Patten Kimball, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, lẹgbẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀dọ́, “George W. Grant, Allen Huntington, Stephen Taylor, and Ira Nebeker—lo àwọn wákàtí nínú omi dídì,” pẹ̀lú ìrannilọ́wọ́ akọni ẹgbẹ́ náà tí wọ́n nsọdá omi-Dídùn.
Nígbàtí ìṣẹ̀lẹ̀ yí gba ọ̀pọ̀ ìfojúsí, bí mo ti nkẹkọ síi nípa àwọn olùgbanisílẹ̀, mo damọ̀ pé gbogbo wọn ni wọ́n ntẹ̀lé wòlíì tí wọ̀n sì nṣe àwọn ojúṣe líle ní gbígba àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí wọ́n ní ìdààmú. Gbogbo àwọn olùgbànisílẹ̀ ni akọni, bí ti àwọn aṣíkiri.
Ní kíkọ́ ìtàn wọn, mo mọ iyì àwọn ìbáṣepọ̀ iyebíye àti ìran ayérayé pípẹ́ ní àárín àwọn aṣíkiri. John àti Maria Linford àti àwọn ọmọkùnrin wọn mẹ́ta jẹ́ ọmọ ti ẹgbẹ́ Willie. John kú ní wákàtí díẹ̀ ṣíwájú kí àwọn olùgbanisílẹ̀ àkọ́kọ́ tó dé. Ó ti wí fún Maria pé inú òun dùn pé wọ́n ti rin ìrìnàjò náà. “Èmi kò ní wà láyé láti dé Salt Lake,” ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin náà yíò débẹ̀, àti pé èmi kò kábámọ̀ gbogbo ohun tí a ti là kọjá bí àwọn ọmọkùnrin wa bá le dàgbà tí wọ́n sí ṣe ìtọ́jú àwọn ẹbí tiwọn ní Síónì.”
Ààrẹ James E. Faust pèsè àkópọ̀ oníyanu yí: “Nínú ìtiraka ti akọni kẹ̀kẹ́ àfọwọ́yí àwọn olùlànà, a kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ nlá. Gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ kọjá nínú iná olùyọ́po, àti pé àìṣe-pàtàkì àti àìjẹ̀-pàtàkì nínú ayé wa lè yọ́ kúrò bíi ti ìdàrọ kí ó sì mú ìgbàgbọ́ wa mọ́lẹ̀, múlẹ̀, àti níní agbára. Ó dàbí ìwọ̀n kíkún ti ìrora, ìkorò, àti nígbàkugbà ìrora-ọkàn fún gbogbo ènìyàn, pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n nfi ìtara wá láti ṣe ohun tótọ́ àti láti jẹ́ olótítọ́. Síbẹ̀ èyí ni ara ìwẹ̀nùmọ́ láti di olùbárìn pẹ̀lú Ọlọ́run.”
Nínú Ètùtù àti Àjínde àtúnṣe-àìlópin Rẹ̀, Olùgbàlà já “ìdè ikú, ní jíjèrè ìṣẹ́gun lórí ikú” fún gbogbo ènìyàn. Fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀, “ó ti gbé àìṣedéédé wọn àti ìrékọjá wọn rù, ó sì ti rà wọ́n padà, ó sì ti tẹ àwọn ìbèèrè àìsègbè lọ́rùn.”
Láìsí Ètùtù, a kò lè gba ara wa là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nígbàtí ẹ̀ṣẹ̀ lè ṣe ojúṣe pàtàkì kan nínú àwọn àdánwò wa, ìgbésí ayé àwọn ìpọ́njú ni ó rújú nípa àwọn àṣìṣe, ìpinnu burúkú, àwọn ìṣe ibi láti ọwọ́ àwọn ẹlòmíràn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun tí ó kọjá ìṣàkóso wa.
Wàásù Ìhìnrere Mi kọ́ni: “Bí a ti ngbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, Òun lè ràn wá lọ́wọ́ láti farada àwọn ìdánwò, àìsàn, àti ìrora wa. A lè kún fún ayọ̀, àláfíà àti ìtùnú. Gbogbo ohun tí kò dára nípa ìgbésí-ayé ni a lè mú yẹ nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.”
Ní àkokò Ọdún Àjínde yí, ìdojúkọ wa wà lórí Olùgbàlà àti ìrúbọ Ètùtù Rẹ̀. Ètùtù npèsè ìrètí àti ìmọ́lẹ̀ ní ìgbà kan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ó fi dàbí ó ṣókùnkùn tí ó sì burú. Ààrẹ Gordon B. Hinckley kéde, “Nígbàtí a bá yẹ gbogbo ìwé-ìtàn wò, … [kò sí] ohunkóhun tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu gidi, ọlọ́lá gidi, títóbi gidi bí ìṣe oore-ọ̀fẹ́ yí.”
Mo ṣe àbápín àwọn ìkaniyẹ mẹ́ta èyí tí mo rò pé ó jẹ́ kókó nípàtàkì fún ọjọ́ wa.
Àkọ́kọ́, kí a máṣe rẹ pàtàkì ṣíṣe ohun tí a lè ṣe láti gba àwọn ẹlòmíràn là kúrò nínú àwọn ìpènijà ti ẹ̀mí àti ti ara nípàtàkì sílẹ̀.
Ìkejì, fi pẹ̀lú ìmoore tẹ́wọ́gba Ètùtù Olùgbàlà. Gbogbo wa níláti làkàkà làti fi ayọ̀ àti ìdùnnú hàn àní bi a ti ndojúkọ àwọn ìpènijá ìgbésí ayé. Àfojúsùn wa níláti jẹ́ pé kí a gbé ìgbésí ayé ìrètí ní ẹ̀gbẹ́ mímọ́lẹ̀ òpópónà. Mo ti ṣe àkíyèsí bí ojúgbà iyebíye mi, Mary, ti ṣe èyí ní gbogbo ayé rẹ̀. Mo ti fi ìmoore hàn sí dídàn rẹ̀, dídé ìgbéga àní bí a ti ndojúkọ àwọn wàhálà ní gbogbo àwọn ọdún.
Àmọ̀ràn mi ìkẹ́ta ni láti gbé àkokò lemọ́lemọ́ sẹgbẹ láti gbèrò lótítọ́ nípa Ètùtù Olùgbàlà. Àwọn ọ̀nà púpọ̀ wà láti ṣe èyí nínú àkíyèsí ẹ̀sìn araẹni wa. Bákannáà, lílọ sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa àti ṣíṣe àbápín ti oúnjẹ Olúwa nípàtàkì ṣe kókó.
Pátákì bákannáà ni lílọ déédé sí tẹ́mpìlì níbití ó bá ti ṣeéṣe. Tẹ́mpìlì npèsè ìrántí ìtẹ̀síwájú kan nípa Ètùtù Olùgbàlà àti ohun tí ó borí. Àti, àní nípàtàkì síi, lílọ sí tẹ́mpìlì fi àyè gbà wá láti pèsè ìgbàlà ti ẹ̀mí fún àwọn olóògbé olùfẹ́ni wọnnì àti àwọn babanlá jíjìnnà síi.
Ààrẹ Russell M. Nelson, ní ìpàdé àpapọ̀ tó kọjá, tẹnumọ́ ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ yí ó sì fikùn pé, “Àwọn ìbùkún [Tẹ́mpìlì] … nṣèrànwọ́ láti múra àwọn ènìyàn tí yíò ṣèrànwọ́ láti múra ayé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa!”
A ko gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn ìrúbọ àti àpẹrẹ ti àwọn ìran ìṣíwájú, ṣùgbọ́n ìpọ́nni, ìmọyì, àti ìjọsìn wa níláti jẹ́ gbùngbun lórí Olùgbàlà aráyé àti ìrúbọ̀ ètùtù Rẹ̀. Mo jẹri pé kọ́kọ́rọ́ sí ètò ìdùnnú Baba ni Ètùtù tí a ṣe nípasẹ̀ Olùgbàlà, Jésù Krístì. Ó wà láàyè ó sì ndarí Ìjọ Rẹ̀. Ètùtù Jésù Krístì npèsè ìgbàlà ìgbẹ̀hìn kúrò nínú àwọn àdánwò tí à ndojúkọ nínú ayé yí. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.