Ìwọ Ni Krístì náà
Máttéù 16:16
A fẹ́ kí àwọn ọmọ wa gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, kí wọ́n jẹ́ ti Jésù Krístì àti ìjọ Rẹ̀ nípasẹ̀ májẹ̀mú, kí wọn sì gbìyànjú láti dàbí Jésù Krístì.
Nígbàtí ọmọkùnrin wa wà ní ìpele kẹrin, kíláàsì rẹ̀ gbé ìjọba kan kalẹ̀ níbití àwọn ojúgbà rẹ̀ ti yan Élì láti sìn bí adájọ́ kíláàsì. Lọ́jọ́ kan adájọ́ ìjókòó kan láti Àgbègbè Kejì Utah ṣe àbẹ̀wò, ó gbé àwọn ẹ̀wù àṣẹ iṣẹ́ rẹ̀ wọ Élì, lẹ́hìnnáà ó sì ṣe ìbúra ọ́fíìsi fún kíláàsì wọn. Èyí ru ìfẹ́ ọkàn ọ̀dọ́ rẹ̀, fún ìwúrí ní kíkẹ́kọ̀ọ́ òfin àti Olùfúnnilófin fúnra Rẹ̀, Jésù Kristi.
Lẹ́hìn àwọn ọdún ti ìgbìyànjú aláápọn, Eli gba ìfìwépè kan fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn yíyàn gíga jùlọ rẹ̀ fún ilé-ìwé òfin. Ó sọ pé, “Màmá, ìbéèrè mẹ́wàá ni wọ́n bi mí. Ìbéèrè tí ó kẹ́hìn ni pé, ‘Níbo ni o ti gba kọ́mpàsì ìwà rẹ?’ Mo sọ pé jákèjádò ìtàn-àkọọ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn ti gba àwọn ètò ti ìwà nípa títọpa ìgbésí ayé wọn láti inú àwọn àpẹrẹ-àṣà. Àpẹrẹ-àṣà ti ìwà rere tí mo nlàkàkà láti fi tọpa ìgbésí ayé mi jẹ́ ti Jésù Kristi. Mo sọ pé tí gbogbo ènìyàn bá tẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Krístì nínú Ìwàásù lórí Òkè, àgbáyé yóò jẹ́ ibi dídára, tó ní àlàáfíà díẹ̀ síi.” Lẹ́hìnnáà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà parí, ó sì ronú nínú ara rẹ̀, “Ibí ni àwọn àlá èwe mi lọ. Kò sẹ́ni onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ayé tó fẹ́ gbọ́ nípa Jésù Kristi.”
Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́hìnnáà, wọ́n gba Élì wọlé pẹ̀lú ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́. Ṣáájú fífaramọọ, a ṣàbẹ̀wò sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà. Ilé-ìwé òfin náà dàbí ilé nlá kan àti pé a ṣètò rẹ̀ sí orí òkè kan tí o nbojúwo adágún rírẹwà kan. Lọ́nà tí ó lámì, bí a ṣe nkọjá níbi yàrá ìkàwé nlá àti àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ rírẹwà tayọ náà, a rí lára àwọn àsíá àti òkúta gbígbẹ́ sára àwọn nkan láti inú Ìwàásù Lórí Òkè.
Ìwàásù lórí òkè jẹ́ ọ̀rọ̀ àsọyé tó yẹ fún àfiyèsí jùlọ tí a kò tíì sọ rí, ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ìkọ́ni Rẹ̀. Kò sí ìwàásù míràn tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye ìwà Jesu Kristi dáradára, àwọn ìhùwàsí àtọ̀runwá Rẹ̀, àti ìpinnu ìgbẹ̀hìn wa láti dàbi Rẹ̀.
Jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn Jésù Kristi ní gbogbo ìgbésí ayé wa bẹ̀rẹ̀ ní ilé wa—àti nínú Alákọbẹ̀rẹ̀ ní kùtùkùtù bí oṣù méjìdínlógún ọjọ́ orí. A fẹ́ kí àwọn ọmọ wa gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, kí wọ́n jẹ́ ti Jésù Krístì àti ìjọ Rẹ̀ nípasẹ̀ májẹ̀mú, kí wọn sì gbìyànjú láti dà bí Jésù Krístì.
Gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì
Ní àkọ́kọ́, gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì.
Lẹ́hìn ìwàásù ti Àkàrà Ìyè, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn [Olúwa náà] ni” ó ṣòro fún láti gba àwọn ìkọ́ni àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀, wọ́n “sì padà sẹ́hìn, wọn kò sì rìn pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. Lẹ́hìnnáà Jésù yíjú sí àwọn Méjìlá náà o sì bèèrè ìbéèrè ìbani-nínú jẹ́ pé: “Ẹ̀yin náà yóò ha lọ bí?”
Pétérù dáhùn:
“Olúwa, sọ̀dọ̀ tani àwa yíò lọ? Ìwọ ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè ayérayé.
“… A gbàgbọ́ ó sì dá wa lójú wípé ìwọ ni Krístì, ọmọ Ọlọ́run alààyè.”
Bí Pétérù ṣe ṣàfihàn, ìgbàgbọ́ ni “láti ní ìgbàgbọ́ nínú ẹnìkan tàbí láti gba ohun kan bíi òótọ́.” Àti pé fún ìgbàgbọ́ wa láti darí sí ìgbàlà, ó gbọ́dọ̀ wà ní ìdojúkọ nínú Olúwa Jésù Krístì. A nlo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì nígbàtí a bá ní ìdánilójú pé Ó wà, òye kan nípa ìwà tòótọ́ àti àdánidá Rẹ̀, àti ìmọ̀ pé a ngbìyànjú láti gbé ní ìbámu sí ìfẹ́ Rẹ̀.
Àyànfẹ́ wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, kéde pé, “Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì jẹ́ ìpìlẹ̀ gbogbo ìgbàgbọ́ àti àwọn ọ̀nà sí agbára tọ̀run.”
Báwo la ṣe lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti fún ìgbàgbọ́ wọn nínú Jésù Krístì lókun kí wọ́n sì ní àyè sí agbára àtọ̀runwá Rẹ̀? A kò nílò láti wò síwájú ju sí Olùgbàlà wa Fúnrarẹ̀.
“[Olúwa] sọ fún àwọn ènìyàn náà, wípé:
“Ẹ wóó, Èmi ni Jésù Krístì. …
“Ẹ dìde kí ẹ sì jáde wá. …
“… Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì jáde lọ, nwọ́n sì fi ọwọ́ wọn sí ìhà rẹ̀, nwọ́n sì ní ìmọ̀ ọwọ́ ìṣó náà li ọwọ́ rẹ̀ àti lí ẹsẹ̀ rẹ̀; èyí sì ni wọ́n ṣe, tí wọ́n jáde lọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan … nwọ́n sì ri pẹ̀lú ojú wọn nwọ́n sì ní ìmọ̀lára pẹ̀lú ọwọ́ wọn, nwọ́n sì mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú nwọ́n sì jẹ́ ẹ̀rí, pé Òun ni.”
Mo pè yín láti ronú jinlẹ̀ ohun tí èyí le jọ nínú ìgbésí-ayé àwọn ọ̀dọ́mọdé. Njẹ́ wọ́n gbọ́ àwọn ẹ̀rí nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀? Njẹ́ wọ́n rí àwọn àwòrán bíbọ̀wọ̀, jíjọsìn ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti jijẹ́ Ọlọ́run Rẹ̀? Njẹ́ wọ́n ní ìmọ̀lára kí wọ́n sì mọ Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó njẹ́ri nípa jíjẹ́ òtítọ́ àti ti ọ̀run Rẹ̀? Njẹ́ wọ́n mọ nípa ọ̀rọ̀ àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀?
Jẹ́ ara ti Jésù Krístì àti Ìjọ Rẹ̀
Èkejì, jẹ́ ara ti Jésù Krístì àti Ìjọ Rẹ̀.
Àwọn ènìyàn Ọba Bẹ́ńjámínì ní ìrírí ìyípadà ńlá ti ọkàn àti nípa májẹ̀mú wọ́n ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí májẹ̀mú tí wọ́n dá pẹ̀lú Ọlọ́run àti Jésù Kristi, a “pè wọ́n ní ọmọ Kristi, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.” Bí ọmọ ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a ní ojúṣe ti májẹ̀mú láti kọ́ ìjọba Rẹ̀ kí a sì múra sílẹ̀ fún bíbọ̀ Rẹ̀.
Báwo ni a ṣe lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti dá àti láti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́? Nínú ìwé ìléwọ́ Wá, Tẹ̀lé Mi wa, Ní àfikún A àti B, a rí àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ìbánisọ̀rọ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ tí yíò fi agbára fún àwọn ẹbí àti ìtìlẹ́hìn àwọn olùkọ́ àti àwọn aṣáájú nínú iṣẹ́ ìríjú mímọ́ wọn láti múra àwọn ọmọ sílẹ̀ fún ìgbé ayé ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú Ọlọ́run.
Dà bíi Jésù Krístì
Ẹ̀kẹta, dà bíi Jésù Krístì.
Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Olùgbàlà gba àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ pè níyànjú láti tẹ̀ lé àpẹrẹ Òun ní tímọ́tímọ́ bí ó ti ṣeéṣe: “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹyin jẹ́? Lootọ ni mo wí fún yín, àní gẹ́gẹ́bí èmí ti rí.”
Báwo ni a ṣe lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọdé tí a ti rìbọmi tí a sì ti fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ láti mú ojúṣe májẹ̀mú wọn ṣẹ láti kó ara wọn àti àwọn míràn jọ sọ́dọ̀ Jésù Krístì? Jíjẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn ìgbésí ayé nílò wa láti “jẹ́ … olùṣe ọ̀rọ̀ náà, tí kìí ṣe àwọn olùgbọ́ nìkan.”
Nígbàtí a bá nnawọ́ ìkésíni sí àwọn ọmọ-ẹ́hìn Olúwa tí ó kéré jùlọ, jọ̀wọ́ lo gbogbo àǹfààní láti darí wọn, ṣamọ̀nà wọn, rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí Ọ̀nà. Dámọ̀ràn pẹ̀lú àwọn ọmọ kéékèèké ṣíṣeyebíye wọ̀nyí bí wọ́n ṣe nmúra sílẹ̀ láti kọ́ni, jẹ́rìí, gbàdúrà, tàbí sìn kí wọ́n lè ní ìgboyà kí wọ́n sì ní ìrírí ayọ̀ ní mímú àwọn ojúṣe wọn ṣẹ. Wá àwọn ọ̀nà onímìísí láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ pé èyí ni ìjọ wọn àti pé wọn ní ipa pàtàkì láti kó nínú mímúrasílẹ̀ fún ìpàdàbọ̀ Olùgbàlà.
Bí Jésù Krístì ṣe di ìfojúsùn àwọn ìgbésí ayé wa, ohun tí a fẹ́, àti bí a ti fẹ́ ẹ, yóò di títúnṣe láéláé. Ìyípadà nyí ohun gbogbo padà! Ó nyí ìwà ẹ̀dá wa padà “pé a kò ní ìtẹ̀sí mọ́ láti ṣe búburú, bí kò ṣe láti máa ṣe rere nígbà gbogbo.” Ó nṣe àyípadà bí a ti nlo àkókò wa, àwọn ohun èlò wa; ohun tí a nkà, tí a nwò, ti a nfetí sí, àti ti a npín. Àní ó nṣe àyípadà bí a ṣe ndáhùn nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ti ó yàtọ̀, ètò ẹ̀kọ́, iṣẹ́-lórí ayélujára.
A nílò láti fi Ìmọ́lẹ̀ Jésù Krístì sí gbogbo àwọn igun ìgbésí ayé wa. Bí a kò bá jẹ́rìí sí òtítọ́ ìwà-ọlọ́run rẹ̀ ṣáájú ayé-ikú, iṣẹ́ àtọ̀runwá rẹ̀, àti túbú-fífọ́ ti àjínde Rẹ̀ nínú ilé wa àti nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan gbogbo ìpàdé Ìjọ yi, nígbànáà àwọn ọ̀rọ̀ wa ti ìfẹ́, iṣẹ́ ìsìn, òtítọ́, ìrẹ̀lẹ̀, ìmoore, àti àánú kò lè di nkankan ju ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ ti gbígbé ìgbésí-ayé àníyàn lọ. Láìsí Jésù Krístì kò sí agbára láti yípadà, kò sí èrò láti lépa sí, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìlàjà ti àwọn làálàá ìgbésí-ayé. Tí a bá jẹ́ aláìronú nínú jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì wa, ó lè di ìjàmbá fún àwọn ọmọ wa.
Nígbàtí a bá sọ fún àwọn ọmọ wa pé a fẹ́ràn wọn, njẹ́ à nsọ fún wọn bákannáà pé Baba wọn Ọ̀run àti Olùgbàlà Jésù Krístì fẹ́ràn wọn? Ìfẹ́ wa lè ṣe ìtùnú àti ìwúrí, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tiwọn lè sọ di mímọ́, gbéga, àti wòsàn.
Jésù yi kò gbọ́dọ̀ jẹ́ Jésù àròsọ, tàbí Jésù rírọrùn, tàbi Jésù tí kò ní ara, tàbí Jésù àirónútẹ́lẹ̀, tàbí Jésù tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n Jésù ológo, olódùmarè, tó jínde, tí a gbéga, lẹ́mi ìsìn, lágbára Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Ọlọ́run, tí ó lágbára láti gbàlà. Àti pé bí ọmọ kékeré kan ní Philippines ti fi ọ̀rànyàn jẹ́rìí fún mi lọ́jọ́ kan, “A yẹ fún gbígbàlà!” Ní orúkọ Rẹ̀ tó lọ́wọ̀ tó sì jẹ́ mímọ́ “ẹnití Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù [nlá náà],” Jésù Kristi, àmín.