Ọ̀wọ̀ fún àwọn Ohun Mímọ́
Ọ̀wọ̀ fún ohun mímọ́ nmú ìmoore òdodo jáde, mú ìdùnnú òtítọ́ gbòòrò, ndárí iyenú wa sí ìfihàn, ó sì nmú ayọ̀ títóbijù wá sínú ayé wa.
Nínú ìwé Eksódù, a rin ìrìnàjò pẹ̀lú àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Horeb bí ó ti yípadà sẹgbẹ kúrò nínú àwọn ojúṣe ojojúmọ́ rẹ̀—ohunkan tí gbogbo wa níláti ní ìfẹ́ láti ṣe—láti rí igbó jíjó tí kò di píparun. Bí ó ti débẹ̀, “Ọlọ́run pè é jáde ní àárín igbó, ó sì wípé, Mósè, Mósè. Ó sì wípé, Nihin ni mo wà. [Ọlọ́run] wípé, … bọ́ bàtà ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ kúro ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ilẹ̀ tí ìwọ wà ni ilẹ̀ mímọ́ ni.” Nínú ọ̀wọ̀ títóbi, ìrẹ̀lẹ̀, àti ìyàlẹ́nu , Mósè bọ́ bàtà rẹ̀ ó si múra ara rẹ̀ sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àti láti ní ìrírí mímọ́ níwájú Rẹ̀.
Òke mímọ́ náà ẹ̀fífánì ni ìrírí kan tí ó kún fún ìyanu-ìmísí ọ̀wọ̀, tí ó so Mósè pọ̀ mọ́ ìdánimọ̀ àtọ̀runwá rẹ̀ lótítọ́, tí ó sì jẹ́, kókó èròjà kan nípa ìyípadà kúrò ní onírẹ̀lẹ̀ olùṣọ́-àgùtàn sí wòlíì alágbára, tí ó ndarí rẹ̀ láti rin ní ipa ọ̀nà titun nínú ayé. Bákannáà, ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa lè yí jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn wa padà sí àwòṣe gígajù níti ẹ̀mí nípa mímú ìwàrere ti ọ̀wọ̀ jẹ́ apákan mímọ́ ìhùwàsí ti ẹ̀mí wa.
Ọ̀rọ̀ náà ọ̀wọ̀ ni a lè tọpasẹ̀ dé ọ̀rọ̀-ìṣe Látin revereri, èyí tí ó túmọ̀ sí “dúró nínú ọ̀wọ̀ ti.” Nínú ọgbọ́n ìhìnrere, ìtumọ̀ yí dàpọ̀ mọ́ ìmọ̀lára tàbí ìwà ìjìnlẹ̀ ọ̀wọ̀, ìfẹ́, àti ìmoore. Irú ìfihàn bẹ́ẹ̀ fún ohun mímọ́ nípasẹ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn àti ìfọkànsìn tó jinlẹ̀ sí Ọlọ́run àti Jésù Krístì láti mú àníkún ayọ̀ jáde nínú ọkàn wọn.
Ọ̀wọ̀ fún àwọn ohun mímọ́ ni ìṣípayá títóbijùlọ ti ẹ̀mí pàtàkì dídára; ó jẹ́ àbájáde ti ìsopọ̀ wa sí ìwàmímọ́ ti ó sì nfi ìfẹ́ wa fún àti ìsúnmọ́tòsí Baba wa Ọ̀run àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Bákannáà ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìrírí tó ga jùlọ ti ẹ̀mí. Irú ìwà rere bẹ́ẹ̀ ndarí èrò wa, ọkàn, àti ìgbésí ayé síwájú Ọba kan. Nítòótọ́, ọ̀wọ̀ kìí íṣe èrò ti ẹ̀mí nìkan; ó jẹ́ àkójá rẹ̀—ìpìnlẹ̀ lórí èyí tí a kọ́ ẹ̀mí lé, ní dídá ìsopọ̀ araẹni sílẹ̀ sí tọ̀run, bí a ti kọ́ni nípasẹ̀ àwọn ọmọdé nígbàtí wọ́n bá nkọrin: “Nígbàtí mo bá lọ́wọ́, mo mọ̀ nínú ọkàn mi pé / Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì wà nítòsí.”
Bí àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì, a pè wá láti mú ẹ̀bùn ọ̀wọ̀ dàgbà nínú ayé wa ní èrò láti ṣí arawa sí ìdàpọ̀ jíjìnlẹ̀ si pẹ̀lú Ọlọ́run àti Ọmọ Rẹ̀ Jésù Krístì, lẹgbẹ fífún ìhùwàsí ti ẹ̀mí wa lókun ní ìgbàkannáà. Tí a bá ní púpọ̀ àwọn ìmọ̀lára irú bẹ́ẹ̀ nínú ọkàn wa, láìṣiyèméjì ayọ̀ títóbijù àti ìdùnnú yíò wà nínú ayé wa, a ó sì ní ìdínkù ààyè fún ìkorò àti ìbànújẹ́. A gbọ́dọ̀ rántí pé fífi ọ̀wọ̀ fún àwọn ohun mímọ́ fi ìtumọ̀ sí púpọ̀ ohun tí à nṣe lójojúmọ́ ó sì nfún ìmọ̀lára ìmoore wa ní okun—ìmísí iyanu, ọ̀wọ̀, àti ìfẹ́ fún àwọn ohun gígajù àti mímọ́jù.
Ní àìdára, à ngbé nínú ayé níbití fífi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ohun mímọ́ ti di àìwọ́pọ̀ gan an. Nítòótọ́, ayé máa nṣe àjọyọ̀ ohun àìní-ọ̀wọ̀, bí eyikeyi àtúnwò ìròhìn tábúlọ́ìdì, ètò amóhùnmáwòrán, tàbí ìjẹ́rí ayélujára. Àìsí ọ̀wọ̀ fún àwọn ohun mímọ́ nmú àlékún àìkàsí nínú ìwà àti àìbìkítà nínú ìṣe jáde, èyí tí ó lè ṣe àjìjà kánmọ́kánmọ́ ìran kan lọ sí itàra kí ó sì ta ìran tí ó nbọ̀ sínú òṣì.
Àìní ọ̀wọ̀ pẹ̀lú lè darí wa lọ kúrò nínú isopọ̀ tí àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run pèsè kí ó sì dín ọgbọ́n ìjiyìn wa níwájú Ọba kan kù. Ní àbáyọ, a nní ewu títọ́jú nípa ìtùnú ara wa nìkan; títẹ́ àwọn ìpebi tí a kò lè ṣákóso lọ́run; àti nígbẹ̀hìn kí a dé ibi àìmọ́ ti títàbùkù àwọn ohun mímọ́, àní Ọlọ́run, àti ní àbájáde ìwà-ẹ̀dá tọ̀run wa bí àwọn ọmọ Baba Ọ̀run. Àìní ọ̀wọ̀ sí àwọn ohun mímọ́ nmú ìmọ̀ ọ̀tá tẹ̀síwájú nípa dídàmú àwọn ọ̀nà ìfura ti ìfihàn wa, èyí tí ó ṣe pàtàkì fún yíyè ti ẹ̀mí wa ní ọjọ́ wa.
Ìtumọ̀ àti pàtàkì ọ̀wọ̀ fún ohun tí ó jẹ́ mímọ́ ni a làsílẹ̀ dáadáa ní gbogbo àwọn ìwé mímọ́. Àpẹrẹ kan nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú yíò dàbí ẹnipé à nfihàn pé ọ̀wọ̀ sí Baba Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀ Jésù Krístì ni ìwàrere pàtàkì kan fún àwọn wọnnì tí wọ́n dé ìjọba sẹ̀lẹ́stíà.
Bí ìjọ kan à ntiraka láti di Baba àti Ọmọ mú nínú ohun mímọ́ jùlọ àti ọ̀wọ̀ ní gbogbo ìṣe, pẹ̀lú bí a ti nfi àwọn àwòrán Wọn hàn. Ìtọ́nisọ́nà Ẹ̀mí Mímọ́ ni kókó ẹ̀yà ní ṣíṣe ìpinnu bí àwọn àwòrán wọ̀nyí yíò ṣe fi ìwà-ẹ̀dá mímọ́, ìwà, àti ìhùwàsí ti ọ̀run hàn nípa Baba àti Ọmọ. À nṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gidi láti yẹra fún fífi àwọn èròjà tí ó lè dààmú kúrò ní ìdojúkọ wa lórí Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, àti àwọn ìkọ́ni Wọn, pẹ̀lú bí a ṣe nlo àwọn ohun èlò tó ní ìlọ̀síwájú tí a fúnni nípa ẹ̀rọ ìgbàlódé, bí irú òye àtọwọ̀dọ̀wọ̀ (OA) láti mú àkóónú àti àwọn àwòrán jáde.
Ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ yí kannáà ni à nlò sí orísun eyikeyi ìwífúnni tí ó wà ní àrọ́wọ́tó nípasẹ̀ àṣẹ àwọn ọ̀nà ìbárasọ̀rọ̀ ti Ìjọ. Gbogbo ẹ̀kọ́, ìwé, àfọwọ́yí, àti ọ̀rọ̀ ni a fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gbèrú tí a si fi àṣẹ sí lábẹ́ ìdarí Ẹ̀mí láti múdájú pé a ṣe ìmúdúró ìwàrere mímọ́, iye, àti òṣùwọ̀n ìhìnrere Jésù Krístì. Nínú ọ̀rọ̀ àìpẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà ti Ìjọ, Alàgbà David A. Bednar kọ́ni pé, “Láti yíká nínú ẹ̀ka ìkorítà ti ẹ̀mí àti ẹ̀rọ ìgbàlódé, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn níláti fi ìrẹ̀lẹ̀ àti pẹ̀lú àdúrà (1) ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere tí ó lè tọ́ lílò wọn sọ́nà nípa òye àtọwọ́dọ́wọ́ àti (2) ìtiraka òdodo fún ojúgbà Ẹ̀mí Mímọ́ àti ẹ̀bùn ti ẹmí ìfihàn.”
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, bí fáfá ti ẹ̀rọ̀ ìgbàlódé òdé-òní ti dà, kò lè ṣèdásílẹ̀ ìyanu, ọ̀wọ̀, àti ìyàlẹ́nu lásán tí a rí nínú irú ọ̀wọ̀ tí ó jáde látinú ipa Ẹ̀mí Mímọ́. Bí àwọn ọmọẹ̀hìn Krístì, a nílò láti ṣe pẹ̀lẹ́ kí a máṣe mú ìsopọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti Ọmọ Rẹ̀ ṣe àláìlera nípa lílo OA-àkóónú àti àwọn àwòrán tí a mú jáde láìtọ́. A níláti rántí pé gbígbáralé ẹ̀rọ̀ ìgbàlódé ti òde-òní “apá ẹran ara” ni àìtó àti àìní ọ̀wọ̀ kan tí a fi rọ́pò ìmísí, ìgbéga, àti ẹ̀rí tí a lè gbà nípasẹ̀ àgbára Ẹ̀mí Mímọ́ nìkan. Bí Néfì ti kéde: “A Olúwa, èmi ti gbẹ́kẹ̀lé ọ, èmi yíò sì gbẹ́kẹ̀lé ọ títí láé. Èmi kì yíò fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sí apá ẹran ara.”
Nínú ìfihàn míràn, Wòlíì Joseph Smith ni a pàṣẹ fún pé àwọn tẹ́mpìlì tí a gbé dide sí Olúwa níláti jẹ́ ibi ọ̀wọ̀ sí I. Nínú gbogbo iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀, wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti tẹnumọ ìjọ́sìn wa gidigidi nínú ọ̀wọ̀ nínú tẹ́mpìlì mímọ́. Nínú ilé Olúwa à nkẹkọ nípa wíwọnú ọ̀dọ̀ mímọ́ Baba àti Ọmọ. Mo ti nfi ìgbagbogbo rí i nínú ikẹkọ àní àti ìmísí pé ọ̀kan lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí à nṣe ní wíwọnú tẹ́mpìlì àti mímúra arawa sílẹ̀ láti kópa nínú àwọn ìlànà mímọ́ tí ó wà ni láti bọ́ àwọn bàtà wa kí a sì yípadà sínú aṣọ funfun wa. Bíi ti Mósè, bí a bá jẹ́ alámọ̀ọ́mọ̀ ṣe, a lè damọ̀ pé bíbọ́ àwọn bàtà ti ayé kúrò ni bíbẹ̀rẹ̀ gbígbé ẹsẹ̀ wọnú ilẹ̀ mímọ́ àti dídi yíyípadà nínú àwọn ọ̀nà gígajù àti mímọ́jù.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, a kò nílò láti gùnkè lọ sí orí òkè kan, bíi Mósè ti ṣe, láti ṣe àwárí ọ̀wọ̀ fún àwọn ohun mímọ́ kí a sì yí jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn wa padà sínú ipò jíjìn jùlọ ti ẹ̀mí ìfọkànsìn. A lè rí i, fún àpẹrẹ, bí a ṣe ntiraka láti dá ààbò bo àyíká ilé wa kúrò nínú àwọn ipa ti ayé. Èyí ni a lè ṣe yọrí nípa gbígbàdúrà lódodo àti kárakára níwájú Baba wa Ọ̀run ní orúkọ Jésù Krístì àti wíwá láti mọ Olùgbàlà wa síi nípasẹ̀ fífi taratara wa ṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a rí nínú àwọn ìwé-mímọ́ àti nínú àwọn ìkọ́ni àwọn wòlíì wa. Ní afikún, irú ìyípadà ti ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ lè wá bí a ti nbu ọlá fún àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Olúwa nípa gbígbé nínú ìgbọ́ran sí àwọn òfin Rẹ. Àwọn ìtiraka wọ̀nyí lè mú ìdákẹ́rọ́rọ́ jẹ́jẹ́ àti ọ̀kan pàtó sí ọkàn wa. Níní ìdojúkọ lórí irú àwọn ìṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣèrànwọ́ láti yí ilé wa padà dájúdájú sínú àwọn ibi ààbò ti ẹ̀mí—ilé mímọ́ ti araẹni nípa ìgbàgbọ́ níbití Ẹ̀mí ngbé, bíi ti ìrírí òkè ti Mósè.
Bákannáà a lè ní ìrírí irú ìyípadà ti ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ bí a ti nfi òtítọ́ kópa nínú ìjọsìn ìsìn Ìjọ, pẹ̀lú yíyí ọkàn wa sí Olúwa nípasẹ̀ kíkọrin òdodo ti àwọn orin mímọ́ wa. Yíyí sẹgbẹ́—bíi ti Mósè—kúrò nínú àwọn ìdààmú ti ayé, nípàtàkì fóònù àgbéká wa tàbí ohunkóhun tí kò sí ní ìbámu pẹ̀lú àkokò mímọ́, nfún wa ní ìlèṣe láti yí ìfojúsí wa kíkún láti ṣe àbápín ti oúnjẹ Olúwa, pẹ̀lú iyenú wa àti ọkàn tí ó dojúkọ Olùgbàlà àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ lẹgbẹ pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú ti ara wa. Irú ìdojúkọ ti oúnjẹ Olúwa bẹ́ẹ̀ yíò mú àkokò àtúnṣe ọ̀wọ̀ ti ìdàpọ̀ wa pẹ̀lú Olùgbàlà tí yíò sì mú Sábbáótì jẹ́ ìdùnnú àti ìyípadà sí ayé wa jáde.
Nígbẹ̀hìn, a lè ní ìrírí ìyípadà ti ẹ̀mí yí nínú jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn wa bí a ṣe njọ́sìn déédé ní òkè ilé Olúwa—àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ wa—kí a sì tiraka láti gbé pẹ̀lú májẹ̀mú ìgbẹ́kẹ̀lé, nípàtàkì nígbàtí a bá kojú àwọn àdánwò ti ayé ikú.
Ìyàwó mi àti èmi ti ní ìrírí ti araẹni nípa àwọn àkokò mímọ́ òkè nínú ọ̀wọ̀ bi a ti ntiraka láti lo àwọn ẹ̀kọ́-ipìlẹ̀ wọ̀nyí nínú ayé wa, èyí tí ó mú iyípadà onítumọ̀ nínú jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn wá. Mo rántí pé ó dàbí àná tí à nrín nínú ìtẹ́ ìsìnkú ṣíwájú sísin ọmọ wa kejì, ẹni tí a bí láìtọ́jọ́ tí kò sì yè, nígbàtí ìyàwó mi ṣì npadasípò ní ilé ìwòsàn. Mo rántí gbígbàdúrà sí Ọlọ́run pẹ̀lú ìtara àti ọ̀wọ̀ nlá, ní bíbééré fún ìrànlọ́wọ́ láti faramọ́ àdánwò pípeni-níjà náà. Nínú àpẹrẹ náà, mo gba ìdánilójú híhàn kedere àti alágbára ti ẹ̀mí nínú ọkàn mi: ohungbogbo yíò dára nínú ayé wa bí ìyàwó mi àti èmi bá forítì, ní ṣíṣe ìdìmú lórí ayọ̀ tí ó nwá látinú gbígbé ìhìnrere Jésù Krístì. Ohun tí ó dàbí ìpènijà àìlèkojú, pẹ̀lú ìkorò ní ìgbànáà yí sínú ìrírí ọ̀wọ̀, mímọ́, olùborí tí ó ti ṣèrànwọ́ láti mú ìgbàgbọ́ wa dúró tí ó sì fún wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Olúwa àti àwọn ìlérí Rẹ̀ fún mi àti ẹbí mi.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, ọ̀wọ̀ fún ohun mímọ́ nmú ìmoore òdodo jáde, mú ìdùnnú òtítọ́ gbòòrò, ndárí iyenú wa sí ìfihàn, ó sì nmú ayọ̀ títóbijù wá sínú ayé wa. Ó fi ẹsẹ̀ wa sórí ilẹ̀ mímọ́ ó sì ngbé ọkàn wa ga sí Ọba kan.
Mo jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé bí a ti ntiraka láti fi irú ìwà-rere bẹ́ẹ̀ sínú àwọn ìgbésí ayé ojojúmọ̀ wa, a ó lè ṣe àníkún ìrẹ̀lẹ̀ wa, mú níní ìmọ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run wa fún wa gbòòrò, kí ó sì fún ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú àwọn ìlérí májẹ̀mú tí a dá pẹ̀lú Olúwa lókun si. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ti nrọ̀mọ́ ẹ̀bùn ọ̀wọ̀ fún àwọn ohun mímọ́ yí—bóyá nínú òkè ilé Olúwa, nínú ilé ìjọsìn, tàbí nínú ilé ti ara wa—a ó kún fún ìyalẹ́nu àtì ọ̀wọ̀ ọlọ́lá bí a ti nsopọ̀ mọ́ ìfẹ́ pípé ti Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. Mo fi pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jẹri àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní orúkọ mímọ́ ti Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, Jésù Krístì, àmín.