Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìfẹ́ Aláìlẹ́gbẹ́—Àmì Kan ti Jíjẹ́ Ọmọ-Ẹ̀hìn Tòótọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2025


11:29

Ìfẹ́ Aláìlẹ́gbẹ́—Àmì Kan ti Jíjẹ́ Ọmọ-Ẹ̀hìn Tòótọ́

Òpin àjò gan an ti jíjẹ́ ọmọ-lẹ̀hìn jẹ́ ìtumọ̀ tààrà sí láti dàbí Jésù Krístì ti jẹ́.

Ààrẹ Russell M. Nelson láìpẹ́ pè wá láti “mú kí jíjẹ́ ọmọ-lẹ̀hìn wa jẹ́ ààyò wa jùlọ.” Ìpè alágbára yi ti rú mi sókè láti ní àròjinlẹ̀ araẹni nípa jíjẹ́ ọmọ-lẹ́hìn Jésù Krístì fúnra à mi .

Jíjẹ́ Ọmọ-lẹ́hìn Jẹ́ Amọ̀ọ́mọ̀-ṣe

Ọmọ-lẹ́hìn jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn tàbi akẹ́kọ ti òmíran. Àwọn ọmọ-lẹ́hìn jẹ́ “àwọn olùkọ́ṣẹ́” tí wọ́n fi ìgbésí ayé wọn fọkànsìn láti dàbí olùkọ́ wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, jíjẹ́ ọmọ-lẹ́hìn Jésù Kristi túmọ̀ sí ju gbígbàgbọ́ nínú àwọn ìkọ́ni àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀ lọ. Ó tilẹ̀ túmọ̀ sí ju jíjẹ́wọ́ àtọ̀runwá Rẹ̀ àti títẹ́wọ́gbà Á gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà àti Olùràpadà wa—gẹ́gẹ́bí kókó pàtàkì bí ó ti jẹ́.

Ààrẹ Dallin H. Oaks ṣàlàyé pé: “Títẹ̀lé Kristi kì í ṣe àṣà lásán tàbí ìṣe ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó jẹ́ ìfaramọ́ tí ó nlọsíwájú àti ọ̀nà ìgbésí-ayé tí ó yẹ kí ó ṣe amọ̀nà wa nígbogbo ìgbà àti ní gbogbo ibi.” Jíjẹ́ ọmọ-lẹ́hìn jẹ́ ìrìnàjò tí a nmọ̀ọ́mọ̀ ṣe láti di yíyípadà nípasẹ̀ ẹbọ ètùtù ti Olúwa àti agbára ìlèṣe Rẹ̀. Ibi dídé òtítọ́ ti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn jẹ́ ìtumọ̀ tààrà sí dídà bíiti Jésù Kristi—àní títí dé àmì tí a ti gba “àwòrán Rẹ̀ ní ìwò [wa].”

Láti jẹ́ ọmọlẹ́hìn Olúwa, a gbọ́dọ̀ mọ̀ọ́mọ̀ fara wé ìrònú àti ìṣe Rẹ̀ lójoojúmọ́—fún àpẹẹrẹ, ìgbọràn Rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀, àti sùúrù Rẹ̀. Bí a ṣe àkópọ̀ àwọn ìhùwàsí wọ̀nyí díẹ̀díẹ̀ sínú ìdánimọ̀ ti arawa, a ó di “alábápín nínú ìwà-ẹ̀dá ìwà ọ̀run [Rẹ̀].” Àfarawé ìwà Olùgbàlà yìí wà ní oókan-ọkàn ti jíjọ́sìn Rẹ̀. Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Nelson ṣe kọ́ni, “Ọ̀wọ̀ fún Jésù ni a fi hàn dáradára nípa àfarawé wa nípa Jésù.”

Àmì ti Jíjẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn Tòótọ́

Nínú gbogbo àwọn ìhùwásí àtọ̀runwá ti Jésù Kristi tí a ní láti farawé, ọ̀kan ni ó hàn jùlọ tí ó sì fi gbogbo àwọn ìrísí míràn hàn. Ìhùwàsí náà ni ìfẹ́ mímọ́ Rẹ̀, tàbi ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ Rẹ̀. Àwọn méjèèjì wòlíì Mọmọnì àti Àpọ́sítélì Páùlù rán wa létí pé láìsí ìfẹ́, “[a] kò jẹ́ nkànkan.” Tàbí, gẹ́gẹ́bí a ti fihan Wòlíì Joseph Smith, láìsí “ìfẹ́, [a] kò le ṣe ohunkóhun.”

Olùgbàlà fúnra rẹ̀ fi ìfẹ́ hàn gẹ́gẹ́bí àmì tàbí àmì èyítí a ó fi dá àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ tòótọ́ mọ̀ nígbàtí Ó kéde pé:

“Òfin titun kan ni mo fi fún yín, Pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́bí èmi ti fẹ́ràn yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín bákannáà.

“Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn mi, bí ẹ bá ní ìfẹ́ sí ara yín.”

Ìfẹ́ jẹ́ ìmọ̀ràn ọlọ́rọ̀ tí ó le nira láti ṣàlàyé ṣùgbọn ní ìrọ̀rùn ó ní òye nípasẹ̀ gbogbo àwọn tí a fọwọ́kàn nípa rẹ̀. Wàásù Ìhìnrere Mi kọ́ni pé “ìfẹ́, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́, ndarí sí ìṣe.” Nítòótọ́, ìfẹ́ ni a le ṣe àpèjúwe bíi “ìfẹ́ ninu ìṣe.” Àpèjúwe yì pèsè ìjìnlẹ̀ òye ńláǹlà sí àkópọ̀ gbólóhùn ti ìgbé ayé Olùgbàlà—Ó “nlọ káàkiri ní ṣíṣe rere.”

Gẹ́gẹ́bí ọmọlẹ́hìn Jésù Kristi, a gbọ́dọ̀ wá láti farawé ọ̀nà tí Ọ̀gá wa ṣe fi ìfẹ́ mímọ́ Rẹ̀ hàn fún àwọn ẹlòmíràn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olùgbàlà nfi ìfẹ́ hàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, èmi yíò fẹ́ láti pe àkíyèsí sí àwọn àwòṣe pàtàkì mẹ́ta ti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ Rẹ̀ tí a ti rí nínú àwọn ọmọ-lẹ́hìn Rẹ̀ tòótọ́.

Ìfẹ́ Jẹ́ Fífi Ìyọ́nú Hàn

Àkọ́kọ́, Olùgbàlà fi ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ hàn nípa jíjẹ́ oníyọ̀ọ́nú. Nígbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ láàrín àwọn ará Néfì gẹ́gẹ́bí a ti kọ ọ́ sínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Olúwa pe àwọn ènìyàn náà láti padà sí ilé kí wọn sì ronú lórí àwọn ohun tí Ó ti kọ́ni kí wọ́n sì múrasílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ Rẹ̀ ní ọjọ́ kejì. Àwọn àkọsílẹ̀ lẹ́hìnnáà sọ pé:

“Wọ́n nsọkún, wọ́n sì tẹjú mọ́ Ọ bí ẹnipé wọ́n yíò ní kí ó dúró pẹ̀lú wọn díẹ̀ sí i.

“Ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsíi, inú mi kún fún ìyọ́nú sí yín.”

Ìyọ́nú jẹ́ ara ti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ tí ó nwá láti dín ìjìyà kù. Ní kíkún fún ìyọ́nú, Olúwa wo àwọn aláìsàn àti àwọn olùpọ́njú nínú àwọn ènìyàn náà sàn. Lẹ́hìnnáà, ó súre fún àwọn ọmọ wọn nígbà tí àwọn ángẹ́lì sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run tí wọ́n sì yí wọn ká. Ó ṣe àwọn ìṣe jẹ́jẹ́, ìfẹ́ni, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan mìràn síi, nítorí pé “àánú ṣe É.”

Nígbàtí mò nsìn gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere ní Gúsù Amẹ́ríkà, èmi náà jẹ ànfààní látinú ìyọ́nú ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n kan. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan nígbàtí mo nwakọ̀ lọ sí ilé ààrẹ míṣọ̀n wa, ọ̀dọ́kùnrin kan tó gun kẹ̀kẹ́ yíjú lójijì níwájú ọkọ̀ mi. Ó ṣẹlẹ̀ ní kíákíá tí Èmi kò le yàgò fún ìjàmbá náà. Ní àjálù, ọ̀dọ́mọkùnrin yi kú nípasẹ̀ ìkọlù náà. Inú mi bàjẹ́ nítorí ẹ̀mí rẹ̀ tí ó pàdánù. Nínú ìjayà àti ìpayà bí òtítọ́ ẹ̀rù ti ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ̀lẹ̀ ṣe kọlu mi, wọ́n mú mi lọ sẹ́wọ̀n wọ́n sì tì mí mọ́lé. Emi ko ni irú ìmọ̀lára púpọ̀ ti ìbẹ̀rù àti dídáwà bẹ́ẹ̀ rí. Ìbànújẹ́ bá mi mo sì nbẹ̀rù pé wọ́n máa fi mí sẹ́wọ̀n fún ìyókù ìgbésí ayé mi.

Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ẹlẹgbẹ́ kan, Alàgbà Brian Kochever, gbọ́ nípa ìjàmbá náà àánú sì ṣeé. Ó wá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ó sì bẹ àwọn ọlọ́pàá pé kí wọ́n jẹ́kí òun máa gbé lọ́dọ̀ mi nínú àhámọ́ náà kí nmá bàa dá wà. Lọ́nà ìyanu, wọ́n gbà. Títí di òní yìí, mo mọrírì ìmoore jíjinlẹ̀ fún ìṣe ìfẹ́ bíi ti Kristi tí ọmọlẹ́hìn yìí ṣe, èyí tó mú kí ọkàn mi balẹ̀, tó tù mí lára, tó sì tù mí nínú lákòókò wàhálà tó ga jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Ìyọ́nú ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ rẹ̀ jẹ́ àmì kan tí ó sọ nípa jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn rẹ̀. Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Nelson ṣe ṣàkíyèsí, “Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó rọrùn jùlọ láti dá ọmọlẹ́hìn tòótọ́ ti Jésù Krístì mọ̀ ni bí ẹni náà ṣe nfi ìyọ́nú bá àwọn ẹlòmíràn lò.”

Ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ jẹ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn Àìnì tí a Kò-sọ

Àpẹrẹ míràn ti bí Olùgbàlà ṣe nfi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn ni nípasẹ̀ ṣíṣe àkíyèsí àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn àìní àisọ ti àwọn míràn. Sí ọkùnrin náà tí ó ti yarọ fún ọdún méjìdínlógójì tí kò sí ẹnití yíò ràn án lọ́wọ́, Olúwa gbé e sókè ó sì gbà á níyànjú láti máa gbé ní òdodo. Fún obìnrin tí a mú nínú panṣágà, Ó fúnni ní ìrètí àti ìtùnú dípò ìdálẹ́bi . Fún ọkùnrin alárùn-ẹ̀gbà tí a sọ̀kalẹ̀ láti orí òrùlé, Olúwa fúnni ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, kìí ṣe ìwòsàn ara nìkan.

Nígbàtí wọ́n pè mí láti sìn gẹ́gẹ́bí bíṣọ́ọ̀pù, àwọn ọmọ wa mẹ́fà ṣe àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa ní ìpèníjà fún aya mi, Cristin, ẹnití ó ní láti dá ṣe àbójútó wọn nígbàtí mo jókòó lórí ìdúró. Gẹ́gẹ́bí ẹ ṣe lè fojú inú wò ó, àwọn ọmọ wa kì í sábà ní ọ̀wọ̀. Nígbàtí wọ́n ṣàkíyèsí ipò rẹ̀, àwọn ọmọ ìjọ méjì ní wọ́ọ̀dù wa, John àti Debbie Benich, bẹ̀rẹ̀ sí jókòó pẹ̀lú rẹ̀ ní ọjọ́ Ìsinmi kọ̀ọ̀kan láti ṣèrànwọ́. Inúrere wọn tẹ̀síwájú fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n sì di alágbàtọ́ òbí-àgbà fún ìdílé wa. Bíi ti Olúwa, àwọn ọmọ ẹ̀hìn wọ̀nyí ti kíyèsí àìní tí a kò sọ wọ́n sì ṣe àfihàn ìfẹ́—àmì híhàn gidi kan ti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn wọn.

Ìfẹ́ Aláìlẹ́gbẹ́ Ni Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Ní Ipa Ọ̀nà Májẹ̀mú

Nígbẹ̀hìn, ìfẹ́ pípé ti Olùgbàlà ní ìdojúkọ lórí ìlèṣe gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run láti mú agbára a`tọ̀run wa ṣẹ kí a lè “ṣe a`bápín ìgbàlà rẹ̀, àti agbára ìràpadà rẹ̀.” Bí a ṣe ndàbí Olùkọ́ni wa síi, ìfẹ́ ọkàn wa láti ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lọ́wọ́ ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú yíò pọ̀ sí i níti ìwà-ẹ̀dá.

Fún àpẹrẹ, a lè ṣe ìgbéga àti ìbádọ́rẹ àwọn tí wọ́n nímọ̀lára pé a ṣẹ̀ sí tàbí pé a gbàgbé wọn, a lè ran àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sínú ìjọ wa lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìkíni káàbọ̀, tàbí kí a pe àwọn ọ̀rẹ́ láti jọ́sìn pẹ̀lú wa ní ìpàdé oúnjẹ Olúwa—bóyá nínú Ọdún Àjínde tí nbọ̀ yìí. Ọ̀nà àìlóǹkà ló wà láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ìgbìyànjú àti láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nínú ìlọsíwájú wọn bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ tí a sì fi pẹ̀lú àdúrà wá ìrànlọ́wọ́ ọ̀run láti ní ojú láti rí àti ọkàn láti ní ìmọ̀lára bí Jésù Kristi ti nrí àti ní ìmọ̀lára fún wọn.

Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú wọn lè gba ìrísí iṣẹ́ ìsìn aláìlẹ́gbẹ́ kan. Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, nígbà ìyannisísẹ́ mi lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Philippines, mo kọ́ nípa ìdílé Agamata. Wọ́n ṣe ìrìbọmi ní 2023, wọ́n sì fi ìtara gbé ọjọ́ kan kalẹ̀ tí wọ́n máa fi èdìdì dì gẹ́gẹ́bí ìdílé nínú Tẹ́mpìlì Urdaneta Philippines tó wà nítòsí. Ṣùgbọ́n, ní kété ṣáájú ọjọ́ ìpinnu yíyàn wọn, ọ̀pọ̀ ìjì líle kọlu ẹkùn náà. Arákùnrin Agamata, tó jẹ́ àgbẹ̀ onírẹsì, kò lè gbin irúgbìn rẹ̀ nígbà ìjì líle náà. Nígbàtí ìjì líle lọ níkẹhìn, ó ní láti tètè gbin ìrẹsì náà nígbàtí ilẹ̀ ti rẹró pẹ̀lú omi—àwọn ipò tó dára fún ọ̀gbìn. Ó ṣeni láàánú pé, wọ́n ní láti sún ìrìn àjò tẹ́mpìlì náà síwájú.

Àwọn Ìránṣẹ́ Ìhìnrere ṣe ìrànlọ́wọ́ gbíngbin ìrẹsì.
Àwọn Ìránṣẹ́ Ìhìnrere ngbin ìrẹsì.

Àwọn ọmọ ẹ̀hìn méjì, Alàgbà àti Arábìnrin Cauilan, pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere iṣẹ́ ìsìn mẹ́ta, gbọ́ nípa ìlàkàkà ìdílé Agamata wọ́n sì ṣèrànwọ́ láìfi àìní ìrírí iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣe. Ṣíṣe iṣẹ́ lábẹ́ oòrùn ríroro, wọ́n ṣe ìrànlọ́wọ́ láti gbin àwọn irúgbìn, ní gbígba Agamatas láàyè láti parí iṣẹ́-ṣíṣe wọn kí wọ́n sì lọ sí fífi èdìdi dì tẹ́mpìlì wọn bí a ti ṣètò. Alàgbà Cauilan ṣàkíyèsí pé ìwò ojú “[àwọn Agamatas] ràn bí a ṣe rí wọn tí wọ́n wọ aṣọ funfun nínú ilé Olúwa. Ayọ̀ tí a nímọ̀lára ní ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ẹnìkan náà jẹ́ ayọ̀ tí ó tayọ àfiwé!”

Ẹbí Agamata níta tẹ́mpìlì.

Àwọn Agamata ngbádùn àwọn ìbùkún ọlọ́rọ̀ ti fífi èdìdì dì gẹ́gẹ́bí ìdílé ayérayé nítorí pé àwọn ọmọ-lẹ́hìn ẹlẹgbẹ́ wọn díẹ̀ tí wọ́n kún fún ìfẹ́—àmì ti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn wọn—pinnu láti ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn lọ́wọ́ lẹgbẹ ipa ọ̀nà májẹ̀mú wọn.

Ẹ̀yin Arákùnrin àti Arábìnrin, jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn Jésù Kristi ni ọ̀nà kanṣoṣo tí a lè gbà ní ayọ̀ pípẹ́ títí. Ó jẹ́ ọ̀nà tí ó kún fún ìmọ̀ọ́mọ̀ àti ti èrò àwọn ìṣe ìfẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipa ọ̀nà jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn lè ṣòro kí ó sì peni-níjà, àti nígbà míì, a lè máa làkàkà kí a sì kùnà, a lè rí ìtùnú pé Ọlọ́run nrántí wa ó sì npòùngbẹ láti ràn wá lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà tí a bá gbìyànjú. Ìsàíàh rán wa létí pé “Ọlọ́run yíò di ọwọ́ [wa] mú, ní sísọ pé … , Má bẹ̀rù; èmi yíò ràn ọ́ lọ́wọ́.”

Pẹ̀lú ìdánilójú yìí láti ọ̀dọ̀ Bàbá wa tí nbẹ ní Ọ̀run ní ọkàn, mo fi taratara gbàdúrà pé kí a lè tẹ̀lé ìpè Ààrẹ Nelson láti fi jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn sí ipò ààyò wa. Ǹjẹ́ kí a “gbàdúrà sí Baba pẹ̀lú gbogbo agbára ọkàn” láti “kún fún ìfẹ́ yìí, èyítí ó ti fifún gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́hìn tòótọ́ ti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì; … pé nígbàtí ó bá farahàn àwa yíò dàbí rẹ̀” nítorípé a ó ru àmì jíjẹ́ ọmọ lẹ̀hìn tòótọ́, èyítí ó jẹ́ “ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ … ìfẹ́ mímọ́ ti Kristi.”

Mo jeri pé Jésù Krístì ni, Olùgbàlà ológo, Olùràpadà, Àlápẹrẹ, àti Ọ̀rẹ́ alààyè wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Jésù Krístì Olúwa Yíò Padàwá,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2024, 121.

  2. Wo Merriam-Webster.com Dictionary, “ọmọ-ẹ̀hìn.”

  3. Dallin H. Oaks, “Títẹ̀lé Krístì,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá. 2024, 23.

  4. Álmà 5:14; tún wo Álmà 5:19.

  5. Wo 2 Pétérù 1:4–8

  6. Russell M. Nelson, “Pípe Ní Ìsúnmọ́tòsí,” Ẹ́nsìgn, Oṣù kọkànlá. 1995, 87.

  7. Mórónì 7:46; tún wo 1 Àwọn Ará Kọ̀ríntì 13:3.

  8. Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 18:19; àfikún àlàyé.

  9. Jòhánnù 13:34–35; àfikún àlàyé.

  10. Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà Kan Sí Pípín Ìhìnrere Jésù Krístì (2023), 127.

  11. Ìṣe Àwọn Àpóstélì 10:38

  12. Wo 3 Néfì 17:3

  13. 3 Néfì 17:5–6.

  14. Wo Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Merriam-Webster.comìdè.”

  15. Wo 3 Néfì 21:1–7

  16. Máttéù 9:36; 14:14; Markù 1:41; 6:34.

  17. Àwọn ọlọ́pàá fi mí sẹ́wọ̀n gẹ́gẹ́ bí ara ìlànà àgbékalẹ̀ wọn fún jàmbá tó yọrí sí ikú. Wọ́n yà mí kúrò lọ́dọ̀ alábàákẹ́gbẹ́ mi nítorí pé èmi ni awakọ̀. Mo wà nínú túbú fún ọjọ́ méjì. Nígbà táwọn ọlọ́pàá nṣèwádìí, wọ́n wá rí i pé ọ̀dọ́kùnrin yìí ti mu ọtí lákoko ti ìjàǹbá náà ṣẹlẹ̀ ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lójijì ló yí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa sí iwájú ọkọ̀. Mo farahàn níwájú onídajọ́ kan fún ìgbọ́ran dééde, níbití ó ti pinnu pé kò sí ẹ̀rí àṣìṣe tàbí àìbìkítà ṣúgbọn dípò pé èyí jẹ́ ìrọ̀rùn àìláanú àti ìjàmbá nlá.

  18. Wo Máttéù 25:31–40, nípàtàkí ẹsẹ 36.

  19. Russell M. Nelson, “A Nílò Àwọn Onílàjà,” Làìhónà, Oṣù karun 2023, 98.

  20. Wo Jòhánnù 5:2–9, 14.

  21. Wo Jòhánnù 8:2–11

  22. Wo Markù 2:1-12

  23. Ómnì 1:26

  24. Wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 76:12.

  25. Wo 2 Néfì 26:24

  26. Ìbásọ̀rọ̀ ti ara ẹni pẹ̀lú Darwin Serrano Cauilan, Oṣù kejìlá. 1, 2024.

  27. Ìsàíàh 54:17

  28. Mórónì 7:48

  29. Mórónì 7:47