Àṣẹ Àtọ̀runwá, Àwọn Ọ̀dọ́mọkùnrin Gíga Jùlọ
Ẹ̀rí mi ni pé àwọn tó di Oyè-Àlùfáà Áárónì mú, pẹ̀lú agbára rẹ̀, àwọn ìlànà, àti ojúṣe, máa nbùkún gbogbo wa.
Ẹ ṣeun, Alàgbà Andersen, fún ìfihàn àgbàyanu ti agbára oyè-àlùfáà àti ti agbára Ètùtù ti Olùgbàlà.
Ní òwúrọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi kan ní oṣù kínní yí, bí mo ṣe jókòó ní ìpàdé oúnjẹ Olúwa, díẹ̀ síi ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin méjìlá ni a ṣèmúdúró fún láti lọsíwájú nínú Oyè-Àlùfáà ti Áárónì. Mo rò pé àgbáyé nyípadà lábẹ́ àwọn ẹsẹ̀ wa.
O jọ mí lójú pé ní gbogbo ayé, àkókò agbègbè sí àkókò agbègbè, nínú àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa bí èyíinì, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn díákónì, àwọn olùkọ́, àti àwọn àlùfáà—bí ọ̀rẹ́ Ààrẹ Holland ní òwúrọ̀ yí, Easton—a ṣe ìmúdúró fún wọn láti fàmìòróró yàn sí àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ oyè-àlùfáà fún gbogbo ìgbé-ayé ní títànká gígùn àti ibú ìpéjọ Ìsráẹ́lì.
Oṣù Kínní kọ̀ọ̀kan, a ngbé ọwọ́ lé orí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ọgọ́ọ̀rún ẹgbẹ̀rún, ní síso wọ́n pọ̀ nípasẹ̀ ìlànà sí ìlà ìmọ́lẹ̀ ti àṣẹ tí nnà sẹ́hìn nípasẹ̀ àkókò Ìmúpadàbọ̀sípò sí Joseph àti Oliver, sí Jòhánnù Onítẹ̀bọmi, àti sí Jésù Krístì.
Nísisìyí, tiwa kìí ṣe ìjọ tí ó ṣe àfihàn púpọ̀ nígbàgbogbo. Nihin, a ṣe abẹ́ gbólóhùn.
Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, ní rírí àrá tó nyí ti àwọn olórí oyè-àlùfáà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn tí ó tàn káàkiri ayé, ó ṣemí ní kàyéfì—nínú “ìjọ ayọ̀” ni ọ̀nà kan—bí kò bá níláti pariwo láti orí òrùlé. “Lónìí,” ni mo rò pé, “ó yẹ kí kàkàkí àti símbálì olóhùn gooro wà àti iná ìbọn aláyẹyẹ. Àwọn àfihàn ìtòlẹ́sẹ yẹ kí ó wà!”
Mímọ agbára Ọlọ́run fún ohun tí ó jẹ́ ní tòótọ́, mo rí i bí àwòṣe ayé yìí ti njẹ́ dídàrú bí àṣẹ ìwà-bí-Ọlọ́run ti bo ilẹ̀ ayé.
Àwọn ìfàmì òróró yàn wọ̀nyí ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọ̀nyí sínú ìgbé ayé iṣẹ́-ìsìn bí wọ́n yíò ṣe wá jáde tí a sì jù wọ́n sínú àwọn ààyè níbití wíwà wọn àti àdúrà àti oyè àlùfáà Ọlọ́run tí wọ́n dì mú yíò ti jẹ pàtàkì jíjinlẹ̀.
Ìhùwàpadà ẹ̀wọ̀n ìdarí yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ángẹ́lì ìránṣẹ́ kan tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Jòhánnù Onítẹ̀bọmi olujinde farahàn Joseph àti Oliver, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí wọn, ó sì wí pé, “Ní orí yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi, ní orúkọ Mèssíà ni mo fi Oyè-Àlùfáà Áárónì fún un yín, èyí tí ó di kọ́kọ́rọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì mú, àti ti ìhìnrere ìrònúpìwàdà, àti ti ìrìbọmi nípa rírì bọmi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 13:1).
Jòhánnù pe àṣẹ yí ní “Oyè-àlùfáà Aárónì,” ní ìtìlẹhìn arákùnrin àti ojúgbà oyè-àlùfáà ti Mósè. Ní ayé àtijọ́, àwọn tó di oyè-àlùfáà Áárónì mú yìí ní láti kọ́ni àti láti ṣèrànwọ́ pẹ̀lú àwọn ìlànà—àwọn ìlànà tí ó dojúkọ jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn sórí Mèssáì ọjọ́ iwájú, Olúwa Jésù Krístì (wo Deuterónómì 33:10).
Ìwé Númérì sọ̀rọ̀ ní pàtó fún àwọn tó di oyè àlùfáà Áárónì mú ní àwọn iṣẹ́ tí ó nbójútó àwọn ohun èlò àwọn ìlànà. “Kí o sì yan Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ … àti iṣẹ́ wọn ni … tábìlì … àti àwọn ohun èlò ibi mímọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀” (Númérì 3:10, 31).
Ìlànà Májẹ̀mú Láéláé ti ẹran ìrúbọ ni ó dí mímúṣẹ àti rírọ́pò nípasẹ̀ ìgbé ayé Olùgbàlà àti Ètùtù. Òfin àtijọ́ náà ni a rọ́pò pẹ̀lú ìlànà tí a pè nísisìyí ní sakramenti ti Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.
Lónìí Olúwa fi sí ìkáwọ́ àwọn olùgbé oyè-àlùfáà Áárónì ti òde òní láti ṣe púpọ̀ gan-an àwọn ohun kannáà tí wọ́n ṣe nígbà àtijọ́: láti kọ́ni àti láti ṣe àbójútó àwọn ìlànà—gbogbo rẹ̀ láti ránwa létí Ètùtù Rẹ̀.
Nígbàtí àwọn díákónì, àwọn olùkọ́, àti àwọn àlùfáà ṣèrànwọ́ pẹ̀lú oúnjẹ Olúwa, wọ́n gba àwọn ìbùkún rẹ̀ gẹ́gẹ́bí gbogbo ènìyàn míràn: nípa pípa májẹ̀mú tí wọ́n ṣe mọ́ bí wọ́n ṣe nṣe alabapin nínú búrẹ́dì àti omi. Ṣùgbọ́n nípa ṣíṣe àwọn ojúṣe mímọ́ wọ̀nyí, wọ́n tún kẹ́kọ̀ọ́ síi nípa àwọn ojúṣe oyè-àlùfáà wọn.
Oyè-Àlùfáà Árónì ni a pè ní oyè-àlùfáà ìmúrasílẹ̀ lápá kan nítorí pé àwọn ìlànà rẹ̀ jẹ́ kí wọ́n ní ìrírí ìwọ̀n àti ayọ̀ wíwà nínú iṣẹ́ ìsìn Olúwa, ní mímúra wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn oyè-àlùfáà ọjọ́ iwájú, nígbàtí wọ́n lè pè wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ ní àwọn ọ̀nà tí a kò rí tẹ́lẹ̀—pẹ̀lú pípe àwọn ìbùkún onímìísí ní àwọn àkókò tí ìrètí àti àlá, àti àní ìyè àti ikú, rọra dúró ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.
Irú àwọn ìfojúsọ́nà tó ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀ nílò ìmúrasílẹ̀ tó jinlẹ̀.
Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú náà ṣàlàyé pé àwọn díákónì àti àwọn olùkọ́ “ní láti kìlọ̀, sọ àsọyé, gbani níyànjú, àti kọ́ni, kí wọ́n sì pe gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ Krístì” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:59). Ní àfikún sí àwọn ànfàní wọ̀nyí, àwọn àlùfáà ní láti “wàásù … kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:50).
Ó dára, gbogbo ohun tí ó dún bíi ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n ní ayé òdodo, àwọn nkan wọ̀nyí nṣẹlẹ nípa ti ìwà-ẹ̀dá ní gbogbo àgbáyé.
Bíṣọ́pù kan kọ́ àjọ ààrẹ iyejú àwọn díákónì titun rẹ̀ ní àwọn ojúṣe wọ̀nyí. Nígbànáà ọ̀dọ́ àjọ ààrẹ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa ohun tí èyí lè jọ nínú iyejú àti wọ́ọ̀dù wọn. Wọ́n pinnu pé wọ́n ní láti ṣàbẹ̀wò sí àwọn àgbàlagbà ọmọ ẹgbẹ́ wọ́ọ̀dù láti rí àwọn ohun tí wọ́n nílò àti lẹ́hìnnáà lọ ṣe bẹ́ẹ̀.
Lára àwọn tí wọ́n nsìn ni Alan, oní pálapàla kan, tó sábà máa nṣàìmọ́, tó sì tún máa nkórìíra àwọn aládùúgbò rẹ̀ nígbà míràn. Ìyàwó Alan, Wanda, ti di ọmọ ìjọ, ṣùgbọ́n Alan kòì di ọmọ ìjọ, gẹ́gẹ́bí a ti sọ, iṣẹ́ kékeré kan.
Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn díákónì lọ láti ṣiṣẹ́, láì fojú sí ẹ̀gàn rẹ̀, nígbàtí wọ́n kó òjò dídì tí wọ́n sì nkólẹ̀ jáde. Ó nira láti korira àwọn díákónì, Alan sì bẹ̀rẹ̀ síí gbádùn àkókò rẹ̀ pẹ̀lú wọn. Nígbà kan wọ́n pè é wá sí ilé ìjọsìn.
“Èmi kò fẹ́ràn ilé ìjọsìn,” ni ó dáhùn.
“Ó dára, o fẹ́ràn wa,” ni wọ́n sọ. “Nítorínáà wá pẹ̀lú wa. O kan lè wá sí ìpàdé iyejú nìkan bí o bá fẹ́.”
Àti pẹ̀lú ìfọwọ́sí bíṣọ́pù, ó wá—ó sì túnbọ̀ nwá.
Àwọn díákónì náà di olùkọ́, bí wọ́n sì ṣe nsìn ín, ó kọ́ wọn bí wọ́n ṣe nṣiṣẹ́ lórí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti bí wọ́n ṣe nkọ́ nkan. Nígbàtí áwọn olùkọ́ náà fi máa di àlùfáà, Alan npè wọ́n ní “àwọn ọmọkùnrin mi.”
Wọ́n ti nmúra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìhìnrere báyìí wọ́n sì bèèrè bóyá wọ́n lè fi ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ìsìn ìhìnrere kọ́ ọ. Ó búra pé òun kìí yíò gbọ́ tàbí gbàgbọ́, ṣùgbọ́n, bẹ́ẹ̀ni, wọ́n lè ṣe àdáṣe ní ilé rẹ̀.
Nígbànáà Alan ṣàìsàn. Ó sì ti di rírọ̀.
Lọ́jọ́ kan, nínú ìpàdé iyejú, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n gbàdúrà fún òun láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, nítorí náà wọ́n ṣe é. ṣùgbọ́n lẹ́hìnnáà wọ́n tẹ̀le lọ sílé wọ́n sì sọ gbogbo tábà rẹ̀ nù.
Bí ìlera rẹ̀ kíkùnà ṣe fi Alan sí ilé-ìwòsàn àti ilé-iṣẹ́ ìsọdọ̀tun, “àwọn ọmọkùnrin” rẹ̀ nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún un, ní dídákẹ́jẹ́ nífífi àwọn agbára oyè-àlùfáà àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn hàn (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn májẹ̀mú 121:41).
Iṣẹ́ ìyanu náà ntẹ̀síwájú nígbàtí Alan gbà láti ṣe ìrìbọmi—ṣùgbọ́n ó kọjá lọ kí ó tó ṣẹlẹ̀. Nípa ìbéèrè rẹ̀, àwọn díákónì rẹ̀ tí wọ́n di àlùfáà jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ àti olùbánisọ̀rọ̀ níbi ìsìnkú rẹ̀, níbi tí wọ́n—ní ìbámu—kìlọ̀, sọ àsọyé, gbani níyànjú, kọ́ni, tí wọ́n sì pè gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ Krístì.
Àti lẹ́hìnnáà, nínú tẹ́mpìlì, ó jẹ́ ọ̀kan lára “àwọn ọmọkùnrin Alan” tí ó ṣe ìrìbọmi tí ààrẹ àwọn díákónì ìgbà àtijọ́ náà sì ṣojú fún Alan.
Gbogbo ohun tí Jòhánnù Onítẹ̀bomi sọ pé kí wọ́n ṣe, ni wọ́n ṣe. Wọ́n ṣe ohun tí àwọn díákónì, àwọn olùkọ́, àti àwọn àlùfáà ṣe ní gbogbo Ìjọ yìí àti ní gbogbo ayé.
Ọ̀kan nínú àwọn ohun tí a paláṣẹ fún olùdìmú oyè-àlùfáà Aárónì láti ṣewà pẹ̀lú ìlànà oúnjẹ Olúwa.
Ní ọdún tó kọjá mo pàdé bíṣọ́pù onimisi kan àti ìyàwó àgbàyanu rẹ̀. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sátidé láìpẹ́, wọ́n nwakọ̀ lọ sí ibi ìrìbọmi ọmọkùnrin wọn àti pé wọ́n ti jìyà ìbànújẹ́ àti àdánù òjijì ti ọmọbìnrin wọn olólùfẹ́ ọmọ ọdún méjì, Tess.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù wọn péjọ fún ìpàdé oúnjẹ Olúwa pẹ̀lú ikaanu, ní jíjẹra wọn níyà nítorí ìpàdánù ọmọdébìrin kékeré pípé yìí. Kò sẹ́ni tí ó nírètí pé ẹbí bíṣọ́pù yíò wà ní ilé ìjọsìn ní òwúrọ̀ náà, ṣùgbọ́n ìṣẹ́jú bíi mélòó kan kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, ẹbí bíṣọ́pù náà wọlé ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí ààyè wọn.
Bíṣọ́pù lọ sókè ó sì rìn kọjá ìjókòó déédé rẹ̀ laarin àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ó sì jókòó dípò laarin àwọn àlùfáà rẹ̀ ní tábìlì oúnjẹ Olúwa.
Ní alẹ́ ìbànújẹ́ àti àìsùn náà kí á tó wa òye àti àlàáfíà, ó ti gba ìtẹ̀mọ́ran alágbára kan nípa ohun tí ẹbí rẹ̀ nílò jùlọ—àti ohun tí ẹ̀ka rẹ̀ nílò jùlọ. Ó jẹ́ láti gbọ́ ohùn bíṣọ́ọ̀bù wọn, Ààrẹ Oyè-Àlùfáà Áráónì wọn, baba wọn tó nṣọ̀fọ̀, kéde àwọn ìlérí májẹ̀mú oúnjẹ Olúwa.
Nítorínáà, nígbàtí àkókò tó, ó kúnlẹ̀ pẹ̀lú àwọn àlùfáà náà ó sì bá Baba Rẹ̀ sọ̀rọ̀. Pẹ̀lú àwọn ọ̀nà ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó sọ díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lágbára jùlọ tí a kò gba ẹnikẹ́ni láàyè láti sọ rárá ní ìgbé ayé yí.
Àwọn ọ̀rọ̀ ti àbájáde ayérayé.
Àwọn ọ̀rọ̀ ìlànà.
Àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú.
Ìtọ́nisọ́nà tí ó so wá pọ̀ mọ́ àwọn èrèdí ìgbésí-ayé yìí gan-an—àti sí àwọn àbájáde títayọ ọlọ́lá jùlọ ètò tí Baba Ọ̀run fún wa.
Njẹ́ ẹ lè fojú inú wo ohun tí ìjọ gbọ́ nínú ilé ìjọsìn náà—ohun tí wọ́n gbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí a ngbọ́ ní gbogbo Ọjọ́ Ìsinmi ní ilé ìjọsìn wa?
“Áà Ọlọ́run, Baba Ayérayé, àwa bẽrè lọ́dọ̀ rẹ ní orúkọ Ọmọ rẹ, Jésù Krístì, láti súre àti láti yà àkàrà yĩ sí mímọ́ sí ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹnití ó ní ìpín nínú rẹ̀, kí wọ́n lè jẹ ní ìrántí ti ara Ọmọ rẹ, àti kí wọ̀n jẹ̃rí sí ọ, Áà Ọlọ́run, Baba Ayéráyè, pé wọ́n fẹ́ láti gbà orúkọ ọmọ rẹ sí orí wọn, àti láti rántí rẹ̀ nígbàgbogbó àti láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ èyítí ó ti fi fun wọn; kí wọn lè ni Ẹ̀mi rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn nígbàgbogbo. Àmín” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77).
Àti nìgbánáà: “Áà Olọ́run, Baba Ayérayé, àwa bẽrè lọ́dọ̀ rẹ ní orúkọ Ọmọ rẹ, Jésù Krístì, láti súre àti láti yà [omi] yĩ sí mímọ́ sí ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹnití ó mu nínú rẹ̀, pé kí wọ́n lè ṣe é ní ìrántí ti ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ, èyítí a ta sílẹ̀ fún wọn; pé kí wọ́n lè jẹ̃rí sí ọ, Áà Ọlọ́run, Baba Ayérayé, pé wọ́n nrántí rẹ̀ nígbàgbogbo, pé kí wọn lè ní Ẹ̀mi rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn. Àmín” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:79).
Baba àti ìyá rere yìí jẹ́rìí pé ìlérí náà ti di mímúṣẹ. Wọ́n ṣe, ní tòótọ́, sí ìtùnú ayérayé wọn, “wọ́n ní Ẹ̀mí rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn.”
Mo fi ẹ̀mí ìmoore hàn títíláé pé àwọn olùdìmú Oyè-Àlùfáà Áárónì, pẹ̀lú agbára rẹ̀, àwọn ìlànà, àti ojúṣe, máa nbùkún gbogbo wa nípasẹ̀ àwọn kọ́kọ́rọ́ ti “iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì gan-an, àti ti ìhìnrere ìrònúpìwàdà, àti ti ìrìbọmi nípa rírì bọmi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 13:1). Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.