“Súnmọ́ ọ̀dọ̀ Mi”
Jésù Krístì fẹ́ran ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Ó fún wa ní ànfàní láti sún mọ́ Ọ.
Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, ó jẹ́ ayọ̀ fún mi láti wà pẹ̀lú yin nínú ìpàdé àpapọ̀ ti Ìjọ ti Jésù Krístì tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn yí. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀. A kórajọ nínú àwọn ilé àti ibùgbé káàkiri gbogbo ayé ní orúkọ Rẹ̀.
A ngba orúkọ Rẹ̀ lé orí ara wa bí a ti nwọlé sínú ìjọba Rẹ̀ nípa májẹ̀mú. Òun ni olùjínde àti ológo Ọmọ Ọlọ́run. A jẹ́ ènìyàn kíkú, tí ó wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Síbẹ̀, nínú ìfẹ́ Rẹ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, Olùgbàlà npè wá láti súnmọ́ Òun.
Níbí ni àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀: “Sún mọ́ mi Èmi yíó sì sún mọ́ Ọ; wá mi lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀ ìwọ yíó sì rí mi; bèèrè, àti ìwọ yíó rí gbà; kànkù, a ó sì ṣí fún ọ.”
Àwọn ìgbà wà tí à nní ìmọ̀lára sísúnmọ́ Olùgbàlà Jésù Krístì. Àti pé síbẹ̀, nígbàmíràn nínú àwọn àdánwò ayé ikú, a lè ní ìmọ̀lára jíjìnnà kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀ kí a sì fẹ́ ní ìdánilójú pé Òun mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn wa ó sì fẹ́ràn wa bí olúkúlùkù.
Ìfipè Olùgbàlà pẹ̀lú ọ̀nà tí a fi nní ìdánilójú náà. Ẹ sún mọ́ Ọ nípa fífi ìgbàgbogbo rántí Rẹ̀. Ẹ wá A pẹ̀lú aápọn nípasẹ̀ àṣàrò ìwé mímọ́. Ẹ bèèrè nínú àdúrà àtọkànwá sí Baba Ọ̀run láti ní ìmọ̀lára sísúnmọ́ Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀.
Ọ̀nà ìrọ̀rùn kan láti ronú nípa rẹ̀ wà. Ó jẹ́ ohun tí ẹ yíò ṣe bí ẹ̀yin bá yapa kúrò fún àkokò kan kúrò ní ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan. Ẹ ó rí ọ̀nà kan láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn, ẹ ó ṣìkẹ́ eyikeyi ọ̀rọ̀ tí ẹ bá gbà láti ọ̀dọ̀ wọn, ẹ ó sì ṣe gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Bí èyí ti nṣẹlẹ̀ síi, bí ó ti pẹ́ tó, ni ìsopọ̀ jíjinlẹ̀ ti ìfẹ́ni yíò gba okun sí, ẹ ó sì rí arayín ní sísúnmọ́ ara yín síi títíláé. Bí àkokò púpọ̀ bá ti kọjá láìsí ìṣìkẹ́ ìbárasọ̀rọ̀ àti ànfàní láti ran arawa lọ́wọ́, ìsopọ̀ yíò di àìlágbára.
Jésù Krístì fẹ́ran ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Ó fún wa ní ànfàní láti sún mọ́ Ọ. Bí olùfẹ́ni ọ̀rẹ́ kan, ẹ yíò ṣe é dáadáa ní irú ọ̀nà kannáà, nípa sísọ̀rọ̀ nínú àdúrà sí Baba Ọ̀run ní orúkọ Jésù Krístì, fífetísílẹ̀ fún ìṣìkẹ́ ìtọ́nisọ́nà láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, àti sísin àwọn ẹlòmíràn fún Un pẹ̀lú ìtújúká. Láìpẹ́ ẹ yíò ní ìmọ̀lára ìbùkún ti sísún mọ́ Ọ si.
Ní ọ̀dọ́ mi, mo ní ìrírí ayọ̀ ti wíwá láti súnmọ́ Olùgbàlà si—áti ti wíwá Rẹ̀ láti súnmọ́ mi si—nípasẹ̀ àwọn ìṣe ìrọ̀rùn ti ìgbọràn sí àwọn òfin. Nígbàtí mo wà ní ọ̀dọ́, oúnjẹ Olúwa ni a nfúnni ní ìgbà ìpàdé ìrọ̀lẹ́ kan. Mo ṣì lè rántí alẹ́ kan pàtó, ó ju ọdún marundinlọ́gọ́rin sẹ́hìn, nígbàtí ìlẹ̀ ṣókùnkùn tí ó sì tutù níta. Mo rántí ìmọ̀ ìmọ́lẹ̀ àti ìyárí bí mo ti damọ̀ pé mo ti pa òfin náà mọ́ láti kórajọ pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ láti ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, ní dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run láti rántí Ọmọ Rẹ̀ nígbàgbogbo àti láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.
Ní ìparí ìpàdé ní alẹ́ náà, a kọ orin “Bá mi Gbé, ’ní Ìrọ̀lẹ́ yí,” pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ mánigbàgbé “Ah Olùgbàlà, dúró lálẹ́ yí pẹ̀lú mi.”
Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mú ọgbọ́n ìbonimọ́lẹ̀ kan nípa Ẹ̀mí wá sọ́dọ̀ mi, àní bí ọ̀dọ́mọ̀kùnrin kan. Mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olùgbàlà àti sísúnmọ́ ní ìrọ̀lẹ́ náà nípasẹ̀ ìtùnú ti Ẹ̀mí Mímọ́.
Àwọn ọdún lẹ́hìnnáà mo fẹ́ láti tún irú ìmọ̀lára ìfẹ́ Olùgbàlà àti sísúnmọ́ tí mo ní ìmọ̀lára sí Olúwa rújáde ní ìgbà ìpàdé oúnjẹ Olúwa náà ní ọ̀dọ́ mi. Nítorínáà mo pa òfin ìrọ̀rùn míràn mọ́: mo ṣe ìwákiri àwọn ìwé mímọ́.
Nínú ìwé ti Lúkù, mo kà nípa ọjọ́ kẹ́ta lẹ́hìn ìkànmọ́-àgbélèbú àti ìsìnkú, nígbàtí àwọn olóótọ́ àwọn ìránṣẹ́ ti wá, nínú ìfẹ́ fún Olùgbàlà, láti fi àmì òróró yan ara Rẹ̀. Nígbàtí wọ́n de, wọ́n ri tí a ti yí òkúta kúrò nínú túbú wọ́n sì rí wípé ara Rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́.
Àwọn àngẹ́lì méjì dúró ní tòsí wọ́n sì bèèrè ìdí tí wọ́n fi ń bẹ̀rù:
“È é ṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láárín àwọn òkú?
“Kò sí níhín, ṣùgbọ́n ó jíìnde: rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Gálílì,
“Wípé, Ọmọ-ènìyàn ni a ó fi lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélèbú, ní ijọ́ kẹ́ta yíó sì tún dìde.”
Ní ìrọ̀lẹ́ náà ní àṣálẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn méjì rìn láti Jérúsálẹ́mú ní ọ̀nà sí Émmáúsì, Olúwa olùjínde sì farahàn sí wọn ó sì rìn pẹ̀lú wọn.
Ìwé ti Lúkù gbà wá láàyè láti rìn pẹ̀lú wọn ní ìrọ̀lẹ́ náà:
“Ó sì ṣe, nígbàtí wọ́n nbá ara wọn sọ, tí wọ́n sì nbá ara wọn jíròrò, Jésù tìkararẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì bá wọn rìn lọ.
“Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú kí wọ́n kí ó máṣe lè mọ̀ọ́.
“Ó sì bi wọ́n pé, Ọ̀rọ̀ kíni ẹ̀yin nbá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti nrìn? Wọ́n sì fajúro?
“Ọ̀kan nínú wọn, tí à npè ní Klẹ́ópà, sì dáhùn ó wí fún un pé, Àlejo ṣá ní ìwọ ní Jérúsálẹ́mù, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣe níbẹ̀ ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí?”
Wọ́n sọ fun Un nípa ìbànújẹ́ wọn wípé Jésù ti kú nígbà tí wọ́n gbẹ́kẹ̀le pé yí Ó jẹ́ Olùràpadà Ìsráẹ́lì.
Ìfẹni gbọ́dọ̀ ti wà nínú ohùn Olúwa olùjínde bí Ó ṣe bá àwọn ọmọ ẹ̀hìn méjì oníròbìnújẹ́ àti tí wọ́n nkẹ́dùn wọ̀nyí sọ̀rọ̀:
Bí mo ti tẹ̀síwájú láti kàwé, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá tí ó mú ọkàn mi ní ìyárí, gẹ́gẹ́bí mo ti ní ìmọ̀lára nígbàtí mo jẹ́ ọmọdékùnrin:
“Wọ́n sì súnmọ́ ìletò, níbi tí wọ́n nlọ, àti ó sì ṣe bí ẹnipé yíó lọ́ sí ìwajú.
“Ṣùgbọ́n wọ́n sì rọ̀ ọ́, wípé, Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán. Ó sì wọlé lọ ó bá wọn dúró.”
Olùgbàlà gbà ìpè ní alẹ́ náà láti wọ ilé àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀. Ó jókó ti oúnjẹ pẹ̀lú wọn. Ó mú búrẹ́dì, ó súre sí i, ó bù ú, ó sì fifún wọn. A ṣí ojú wọn, wọ́n sì dáa mọ̀. Nígbànáà Ó parẹ́ mọ́ wọn lójú.
Luku ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìmọ̀-inú fún wa nípa àwọn ọmọ ẹ̀hìn alábùkún nnì: “Wọ́n sì wí fún ara wọn, ọkàn wa kò há à gbiná nínú wa, nígbàtí ó nbá wa sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà, àti nígbàtí ó ntúmọ̀ àwọn ìwé mímọ́ fún wa?”
Lẹ́hìnnáà àwọn ọmọ-ẹ̀hìn méjì sá padà sí Jérúsálẹ́mù láti sọ fún àwọn Àpóstélì mọ́kànlá náà nípa ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Bí wọ́n ti npín ìrírí wọn, Olùgbàlà farahàn.
Ó dìde ní àárín wọn ó sì “wí fún wọn pé, Àlàáfíà fún yín.” Ó ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ láti ṣètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ Bàbá Rẹ̀ àti láti já àwọn ìdè ikú.
“Ó sọ fún wọn pé, Bẹ́ẹ̀ni a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, kí Krístì kí ó jìyà, àti kí ó sì jíìnde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú:
“Àti kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní orúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀ ède gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ.
“Ẹ̀nyìn sì ni ẹlẹ́rí nkan wọ́nyí.”
Gẹ́gẹ́bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀, gbogbo ọmọ Baba Ọ̀run tí wọ́n yàn láti wọ ẹnu ọ̀nà ìrìbọmi wà ní abẹ́ májẹ̀mú láti jẹ́ ẹlẹri nípa Olùgbàlà kí a sì ṣe ìtọ́jú fún àwọn aláìní ní gbogbo ìgbésí ayé ikú wa. Ìfarajìn yí ni a fi hàn kedere fún wa nípa wòlíì nlá Ìwé ti Mọ́mọ́nì Álmà ní àwọn sẹ́ntúrì sẹ́hìn níbi àwọn Omi ti Mọ́mọ́nì:
“Bí ẹ ti nfẹ́ láti wá sínú agbo Ọlọ́run, tí a sì pè wá ní ènìyàn rẹ̀, tí a sì múra tán láti ru àwọn ẹrù ọmọnìkejì wa, kí wọ́n lè fúyẹ́;
“Bẹ́ẹ̀ni, tí ẹ̀yin sì ṣetán láti ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tí nṣọ̀fọ̀; bẹ̃ni, àti láti tu àwọn tí ó fẹ́ ìtùnú nínú, àti láti dúró gẹ́gẹ́bí àwọn ẹlẹ́rĩ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo àti níbi gbogbo … , àní títí dé ojú ikú, kí a lè rà yín padà nípasẹ̀ Ọlọ́run, kí a sì … lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
Bí ẹ ti njẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ yíò ri pé Olúwa npa ilérí Rẹ̀ mọ́ láti jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú yín nínú iṣẹ́ ìsìn yín, ní mímú àwọn ẹrù yín fúyẹ́. Ẹ yíò wá láti mọ̀ Olùgbàlà, àti ní àkokò ẹ ó dàbíi Rẹ̀ ẹ ó sì “di pípé nínú rẹ̀.” Nípa ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ fún Olùgbàlà, ẹ ó ri pé ẹ̀ nsúnmọ́ Ọ́ síi.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín ni ó ní àwọn àyànfẹ́ tí wọ́n nṣáko kúrò ní ipa ọ̀nà iyè àìnípẹ̀kun. Ẹ má nronú ohun tí ẹ lè ṣe láti mú wọn padà. Ẹ lè gbẹ́kẹ̀lé Olúwa láti súnmọ́ wọn bí ẹ ṣe nsìn Í nínú ìgbàgbọ́.
Ẹ rántí ìlérí Olúwa sí Joseph Smith àti Sidney Rigdon nígbà tí wọ́n kò sí lọ́dọ̀ àwọn ìdílé wọn torí ìṣẹ́ Rẹ̀: “Ẹ̀ yin ọ̀rẹ́ mi Sidney àti Josefu, àwọn ìdílé yín wà dáradára, wọ́n wà ní ọwọ́ mi, Èmi yíó si ṣe pẹ̀lú wọn bí ó ṣe tọ́ sí mi; nítorí nínú mi ni gbogbo agbára wà.”
Bí ẹ ṣe ndi ọgbẹ́ àwọn wọnnì nínú àìní, agbára Olúwa yíò ṣe ìmúdúró yín. Àwọn apá Rẹ̀ wà ní níná sítà pẹ̀lú ti yín láti tìlẹ́hìn àti láti bùkún àwọn ọmọ ti Bàbá wa Ọ̀run.
Gbogbo ìránṣẹ́ májẹ̀mú ti Jésù Krístì yíò gba ìdarí Rẹ̀ bíi pé láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí bí wọ́n ti nbùkún tí wọ́n sì sin àwọn ẹlòmíràn fún Un. Nígbànáà wọn yíó ní ìmọ̀lára ti ìfẹ́ Rẹ̀ wọ́n ó sì rí ayọ̀ ti sísúnmọ́ Ọ síi.
Mo jẹ́ ẹlẹ́rí ti Àjínde ti Olúwa dájúdájú bí ẹnipé mo wa níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹhìn méjì nínú ilé náà ní ọ̀nà Ẹmmausì. Mo jẹri pé Ó wà láàyè.
Èyí ni Ìjọ òtítọ́ Rẹ̀—Ìjọ Jésù Krístì. Ní Ọ̀jọ́ Ìdájọ́, a ó, dúró níwájú Olùgbàlà, ní ojú ko ojú. Yíò jẹ́ àkokò ayọ nlá kan fún àwọn wọnnì, nínú ayé yí, tí wọ́n ti súnmọ́ Ọ nínú iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀ tí wọ́n sì lè fi ìtara gbìrò láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́.”
Mo jẹ́rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́bí i ẹlẹ́rí ti Olùgbàlà olùjínde àti Olúràpadà wa, ní orúkọ ti Jésù Krístì, àmín.