àwọn ọ̀dọ́
12. Jésù Krístì nmú ayọ̀ wá


Jósẹ́fù àti Màríà pẹ̀lú ọmọ-ọwọ́ Jésù

12.

Jésù Krístì nmú ayọ̀ wá

Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 101:36

Baba yín Ọ̀run jẹ́ aláyọ̀. Ó nfẹ́ kí ẹ̀yin, ọmọ Rẹ̀, láti níọ̀pọ̀ ayọ̀ bí ó ti ṣeéṣe. Èyí ni ìdí tí Òun fi múra ètò ìdùnnú sílẹ̀. Ó rán Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, láti jẹ́ Olùgbàlà yín àti láti kọ́ ìhìnrere Rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà ìhìnrere túmọ̀sí “ìròhìn rere,” àti pé ìròhìn rere ni pé nítorí Jésù Krístì, ẹ lè ní ìdùnnú nínú ayé yí àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ fún àìlópin.

Òtítọ́ Ayérayé

Ẹ ní ìgbìrò láti ní ìdùnnú àti ayọ̀. Èyí ni èrèdí ti ayé yín. Ó jẹ́ èrèdí ètò ìdùnnú ti Baba Ọ̀run. Èyí kò túmọ̀sí pé ẹ kò ní banújẹ́ láé tàbí ní àwọn àkokò líle. Ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí pé Olùgbàlà lè ràn yín lọ́wọ́ láti la àwọn àkokò líle já a`ti láti rí ayọ̀.

Ayọ̀ kìí wá látinú àwọn ipò yín; ó nwá látinú títẹ̀lé Jésù Krístì. Ẹ lè ní ọjọ́ búburú kan, ọ̀sẹ̀ búburú kan, tàbí ọdún búburú kan. Ṣùgbọ́n ayọ̀ kìí ṣe àìsí ìkorò nínú ayé yín; ó jẹ́ wíwà Krístì nínú ayé yín.

Ayọ̀ Olùgbàlà tóbijù ó sì jẹ́ pípẹ́ ju ohunkóhun míràn lọ. Sátánì yíò dán yín wò láti wá ìgbádùn àti ìtẹ́lọ́rùn nínú àwọn ọ̀nà ìmọ̀taraẹni-nìkan tàbí látinú gbígbádùn ayé. Ohunkóhun tí ó lòdì sí Jésù Krístì àti àwọn òfin Rẹ̀ kò lè mú yín jẹ́ òtítọ́, ayọ̀ àti ìdùnnú pípẹ́. Ẹ rántí pé àwọn ohun ti ilẹ̀ ayé yí jẹ́ ránpẹ́. Ìhìnrere Jésù Krístì fi ayọ̀ àti ìdùnnú tí ó jinlẹ̀ fúnni, mímọ́, àti ayérayé.

Àwọn ìfipè

Ẹ yan ayọ̀. Bíótilẹ̀jẹ́pé ó jẹ́ òtítọ́ pé kò sí ìbànújẹ́ àti ìnira nínú ayé yí, Baba Ọ̀run bákannáà ti kún ayé pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ẹlẹ́wà, dídára. Ẹ wá wọn jáde. Ẹ gbìyànjú láti kíyèsí àwọn èrèdí láti yayọ̀ lójojúmọ́—àní bóyá wọ́n kọ wọ́n sílẹ̀. Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ olùfẹ́ni Baba ní Ọ̀run.

Ẹ mú ayọ̀ àti ìdùnnú wá fún a`wọn ẹlòmíràn. Jésù Krístì rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ nínú mímú ayọ̀ wá fún wa. Ẹ lè tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ nípa wíwá ayọ̀ àti ìdùnnú ní sísin àwọn ẹlòmíràn. Ẹ ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́. Ẹ fúnni ní oríyìn àtinúwá. Ẹ gba ẹnìkan tí ó nlàkàkà ní ìyànjú. Bí ẹ bá ní ìmọ̀lára rí bí ẹnipé ẹ nílò ayọ̀ síi nínú ayé yín, ẹ gbìyànjú láti mú ayọ̀ wá fún ẹlòmíràn.

Ẹ jẹ́ aláyọ̀ nínú jíjọ́sìn Olúwa. Nígbàtí ẹ bá lọ sí ilé ìjọsìn, ẹ kọjúsí ayọ̀ tí Jésù Krístì fún yín, kí ẹ sì yìn I´n fún èyí! Ẹ sa ipá yín láti dásí ẹ̀mí aláyọ̀ nínú àwọn ìpàdé Ìjọ. Ẹ mú orin mímọ́ jẹ́ ara ìjọ́sìn yín ní ilé àti ní ìjọ.

Minerva Teichert, Krístì nínú Ẹ̀wù Pupa kan

Àwọn ìlérí ìbùkún

Ẹ lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ àní nígbàtí ìgbé ayé bá le. Ẹ lè ní ìyàlẹ́nu bí èyí ti ṣeéṣe, ṣùgbọ́n ó jẹ́ òtítọ́. Ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì, agbára ìwòsàn Rẹ̀, àti pé àwọn ìlérí ayérayé Rẹ̀ lè fún yín ní ayọ̀ léraléra. Ayọ̀ Rẹ̀ borí ìkorò ó sì mú àlàáfíà tí ó kọjá òye gbogbo wá.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ ndúró dè yín nínú ìjọba Sẹ̀lẹ́stíà Ọlọ́run. Jésù Krístì borí gbogbo a`wọn ohun tí ó lè pa yín mọ́ kúrò ní gbígba ayọ̀ ayérayé. Bí ẹ ṣe ngbẹ́kẹ̀lé E tí ẹ sì ntẹ̀lé E, ayọ̀ yí yíò jẹ́ tiyín.

Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn

Bí ìhìnrere bá jẹ́ aláyọ̀, kínìdí tí èmi fi ní ìmọ̀lára ìbànújẹ́ gidi? Níní ìmọ̀lára ìbànújẹ́ kìí ṣe àmì kan pé ẹ kìí gbé ìhìnrere. Gbogbo ayé àwọn ènìyàn wà pẹ̀lú ìpọ́njú, àdánwò, àti ìkorò. Títẹ̀lé Jésù Krístì kìí yí èyí padà, ṣùgbọ́n ó so yín mọ́ Olùgbàlà ẹnití ó lè tù yín nínú kí ó sì ràn yín lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ àti ìdùnnú.

Kínìdí tí ìjìyà púpọ̀ fi wà nínú ayé? Àwọn kan lára ìjìyà nínú ayé nwá nítorí àwọn ènìyàn nlo agbára òmìnira wọn láti ṣe àwọn yíyàn àṣìṣe. Èyí lè fa ìjìyà fún arawọn àti fún àwọn ènìyàn míràn. Ní àwọn ọ̀ràn míràn, ìjìyà kìí ṣe ẹ̀bí ẹnikẹ́ni—ó kàn jẹ́ àbájáde gbígbé nínú ayé àìpé. Eyikeyi tí ìdí jẹ́, ó jẹ́ ìrora ọkàn láti rí ẹnìkan tó jìyà, nípàtàkì ẹnìkan tí ẹ ní ìfẹ́. Ẹ ní ìdájú pé Ọlọ́run bákannáà ní ìbànújẹ́ nígbàtí ẹ bá jìyà. Ó fi ààyè gba àwọn àdánwò ti ayé ikú láti ràn yín lọ́wọ́ láti dàgbà àti láti múrasílẹ̀ fún ayọ̀ ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀, ṣùgbọ́n Ò kò fi yín sílẹ̀ láti dánìkan jìyà. Ó rán Jésù Krístì wá láti gbé ìrora yín lé orí Ararẹ̀ kí Òun lè ràn yín lọ́wọ́. Jésù Krístì ni okun yín! Ó sì pè yín, bí ọ̀kan lára àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀, láti ṣe ohun tí ẹ lè ṣe láti ṣèrànwọ́ ríran ìjìyà àwọn ẹlòmíràn.

Wo Orin Dáfídì 16:11 (ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀); 95:1 (ẹ kọrin sí Olúwa); Jòhánnù 16:33 (ẹ tújúká; Jésù Krístì ṣẹ́gun ayé); àwọn ará Galátíà 5:22 (èso ti Ẹ̀mí ni ayọ̀); àwọn ará Hébérù 12:2 (Jésù foríti ìjìyà Rẹ̀ nítorí ayọ̀ gbígba àwọn ọmọ Ọlọ́run là); 2 Néfì 2:25 (Ọlọ́run nfẹ́ kí ẹ ní ayọ̀); Álmà26:15–16 (ṣíṣe iṣẹ́ Ọlọ́run ndarí sí ayọ̀); Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 18:15–16 (bí ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó nígbàtí ẹ bá ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì).

Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì

  • Ṣé ẹ ní ẹ̀rí Ètùtù Jésù Krístì àti ojúṣe Rẹ̀ bí Olùgbàlà àti Olùràpadà yín?