àwọn ọ̀dọ́
3. Ẹ lè ṣèrànwọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ Ọlọ́run


Jésù Krístì nṣe ìbójútó àti ìtọ́jú fún àwọn àgùtàn Rẹ̀.

3.

Ẹ lè ṣèrànwọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ Ọlọ́run

Mósè1:39

Baba Ọ̀run ní ìfẹ́ gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀. Ó nfẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìdùnnú a`ti ayọ̀, padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, kí a sì jèrè ìyè ayérayé. Èyí ni à npè ní iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga Rẹ̀, Ó sì npè yín láti ṣèrànwọ́!

Àwọn Òtítọ́ Ayérayé

Iṣẹ́ àti ògo Ọlọ́run ní láti mú àìkú àti ìyè ayérayé yín wá sí ìmúṣẹ. Àìkú ni láti gbé títíláé pẹ̀lú ara àjínde Ìyè ayérayé, tàbí ìgbéga, ni láti dà bíiti Ọlọ́run kí a sì gbé pẹ̀lú Rẹ̀ ní ayérayé bí àwọn ẹbí. Gbogbo èyí ṣeéṣe nítorí Jésù Krístì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀. Ẹ lè gbẹ́kẹ̀lé E.

Ẹ lè ṣèrànwọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ Ọlọ́run nípa wíwá sí ọ̀dọ̀ Krístì àti ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe ọ̀kannáà. Ìgbàkugbà tí ẹ bá ṣe ohunkan láti ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti tẹ̀lé Jésù Krístì, ẹ nṣèrànwọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ Ọlọ́run.

Àwọn ìfipè

Gbígbé ìhìnrere Ẹ gbé ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì ró. Ronúpìwàdà lójojúmọ́. Ẹ gba àwọn ìlànà oyè àlùfáà Ọlọ́run kí ẹ sì pa àwọn májẹ̀mú yín mọ́. Ẹ ṣe àwòṣe náà fún ìyókù ayé yín.

Títọ́jú àwọn wọnnì nínú àìní. Ẹ wá àwọn ọ̀nà láti sìn àti láti ṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn, pẹ̀lú ẹbí yín, ọ̀rẹ́ yín, àti ìletò yín. Ọ̀nà títóbi kan láti ran àwọn ènìyàn nínú àìní lọ́wọ́ ni láti gbọ́ran sí òfin ààwẹ̀ àtiláti fi ọrẹ ààwẹ̀ fúnni.

Pípe gbogbo-ènìyàn láti gba ìhìnrere. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe yín fi ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì hàn. Ẹ ṣetán láti sọ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ yín nípa ìrètí àti ìdùnnú tí ẹ ní ìmọ̀lára rẹ̀ bí ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ Fún awọn ọ̀dọ́mọkùnrin, sísin míṣọ̀n ìgbà-kíkún ni ojúṣe oyè àlùfáà kan. Fún awọn ọ̀dọ́mọbìnrin, ó jẹ́ ànfàní alágbára; ẹ gbàdúrà láti mọ̀ bóyá Olúwa yíò fẹ́ kí ẹ sìn. Ẹ múrasílẹ̀ láti pín ìhìnrere ní gbogbo ayé yín.

Da ẹbí pọ̀ fún àìlópin nípa ṣíṣe àkọọ́lẹ̀ ìtàn ẹbí àti iṣẹ́ tẹ́mpìlì. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àwọn babanlá yín. Ẹ wáàdí ẹni tí ónílò àwọn ìlànà tẹ́mpìlì. Ẹ lọsí tẹ́mpìlì léraléra bí ẹ ti lè ṣe láti ṣe ìrìbọmi kí ẹ sì ṣe ìfẹsẹ̀múlẹ̀ fún wọn. Bí ẹ bá nílò ìrànlọ́wọ́, ẹ lọ sí FamilySearch.org.

Jésù Krístì nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn Amẹ́ríka

Àwọn ìlérí ìbùkún

Ẹ yíò ní ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Ọ̀run kò retí yín láti ṣe iṣẹ́ yí fúnrara yín. Ó wà pẹ̀lú yín. Nígbàtí ẹ bá fi ìrẹ̀lẹ̀ fi àkokò àti ọkàn yín fúnni, Òun yíò ṣe àwọn ohun àrà nípasẹ̀ yín. Jésù Krístì ni okun yín!

Ẹ ó kún fún ayọ̀. Iṣẹ́ Ọlọ́run ni iṣẹ́ aláyọ̀! Bí ẹ ṣe nkópa nínú rẹ̀, ẹ lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ tí Ó nní ìmọ̀lára. Ẹ rò ayọ̀ tí ẹ yíò pín pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti àwọn ọmọ Rẹ̀ tí ẹ̀ nṣèrànwọ́ láti mú wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀!

Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn

Njẹ́ Ọlọ́run nlò mí nínú iṣẹ́ Rẹ̀ lódodo? Bẹ́ẹ̀ni! Àwọn ọ̀nà púpọ̀ wà láti ṣèrànwọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ náà. Ó dàbí ẹnipé àwọn ènìyàn míràn jẹ́ onítálẹ́ntì jù tàbí oníṣẹ́, ṣùgbọ́n Baba yín Ọ̀run nrí ìlèṣe yín. Ó ti fún yín ní àwọn ẹ̀bùn tí ẹ lè lò láti sìn àti láti kó àwọn ọmọ Rẹ̀ jọ. Ó dára bí àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí bá yàtọ̀ kúrò nínú ohun tí àwọn ènìyàn míràn bá ní. Ní tòótọ́, èyí ni ìdí tí àwọn ẹ̀bùn yín fi jẹ́ oníyelórí. A nílò yín!

Wo Máttéù 10:39 (bí ẹ bá sọ ayé yín nù nínú ìsìn Olùgbàlà, ẹ yíò rí i); 1 àwọn ará Kọ́ríntì 12:14–27 (gbogbo ọmọ ìjọ ni a nílò nínú ara Krístì); àwọn ará Fílíppì 1:6 (ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run nṣiṣẹ́ nínú yín); Jákọ́bù 5:72 (Olúwa ọgbà àjàrà nṣiṣẹ́ pẹ̀lú yín); Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 18:15–16 (ayọ̀ yín yíò pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ẹ múwá sí ọ̀dọ̀ Krístì); 64:33–34 (iṣẹ́ títóbi nwá látinú àwọn ohun kékeré àti jẹ́jẹ́); Mósè 1:6 (“Èmi ní iṣẹ́ kan fún yín”); 6:31–34 (Ọlọ́run nmú àwọn tí Ó pè yege, àní bí wọ́n bá ní ìmọ̀lára àìtó).

Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì

  • Ṣe ẹ ní ẹ̀rí kan nípa Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì?