àwọn ọ̀dọ́
5. Ẹ rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run


Jésù Krístì nṣe olùṣọ́-àgùtàn ti àwọn ọ̀gbà àgùtàn

Èmi kì yio Ṣe Aláìní, láti ọwọ Yongsung Kim Nípasẹ̀ ti Havenlight

5.

Ẹ rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run

Gàlátíà 5:25

Ẹ̀ nṣe àwọn yíyàn dídárájù nígbàtí ẹ bá lè rí àwọn nkan kedere. Èyí ni ìdí tí ìmọ́lẹ̀ fi ṣe pàtàkì; ìmọ́lẹ̀ nmu rọrùn láti rí ipa-ọ̀nà títọ́. Baba Ọ̀run ti fún yín ní ààyè sí orísun ìmọ́lẹ̀ ti ọ̀run—ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́—láti ràn yín lọ́wọ́ láti rí ohun tí ó dara àti búburú, títọ́ àti àṣìṣe kedere.

Àwọn Òtítọ́ Ayérayé

Ṣùgbọ́n wọ́n lè ní Ẹmí Mímọ́ gẹ́gẹ́bí ojúgbà lemọ́lemọ́ kan. Nígbàtí a bá fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ bí ọmọ Ìjọ, a pè yín láti “gba Ẹ̀mí Mímọ́.” Ànfàní láti ní Ẹ̀mí bí ojúgbà lemọ́lemọ́ yín ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run títóbijùlọ sí yín.

Ṣíṣe àwọn yíyàn rere nmú okun yín dára si láti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí. Rere púpọ̀ àti àwọn ohun dídára wà nínú ayé yí. Gẹ́gẹ́bí ara yín ṣe ní ipa nípa ohun tí ẹ̀ njẹ tí ẹsì nmu, inú yín àti ẹ̀mí ni ó ní ipa jíjinlẹ̀ nípa ohun tí ẹ nkà, wò, àti fétísílẹ̀ sí.

Àwọn ìfipè

Ẹ wá àkokò fún Olúwa lójojúmọ́. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Rẹ̀. Ẹ rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo Ẹ Gbàdúrà sí Baba Yín Ọ̀run. Ẹ ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè. Lẹ́hìnnáà ẹ tiraka láti gbé nípa ohun tí ẹ kọ́.

Ẹ wá èyí tí ó ngbéniga, nmísí síni, tí ó sì npe Ẹ̀mí. Bí ẹ ṣe nṣe àwọn yíyàn nípa ohun tí ẹ ó wò, kà, fétísílẹ̀sí, tàbí kópa nínú, ronú nípa bí ó ṣe nmú yín ní ìmọ̀lára. Njẹ́ èyí pe àwọn èrò rere? Kúrò ní dídúró sí ohunkankan tí ó nṣẹ̀sín àwọn ohun mímọ́ tàbí ó jẹ́ àìmọ́. Ẹ máṣe kópa nínú ohunkóhun tí ó nbo ìdájọ́ tàbí fífura yín sí ẹ̀mí mọ́lẹ̀, bí irú ìjà, ọtí, àti egbòògi pípanilára. Ẹ ní ìgboyà láti yí fídíò tàbí eré kúrò, rìn jáde nínú múfì tàbí ijó, yí orin yín pada, tàbí yí kúrò nínú ohunkóhun tí kò wà lemọ́lemọ́ pẹ̀lú Ẹ̀mí.

Ẹ lo ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ láti gbéga. Ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ lè jẹ́ ohun èlò ìbárasọ̀rọ̀ alágbára. Bí ẹ bá lò ó, ẹ dojúkọ ìmọ́lẹ̀, ìgbàgbọ́, àti òtítọ́. Ẹ máṣe fi ayé yín wé ohun tí ó dàbí àwọn ẹlòmíràn nní ìrírí rẹ̀. Ẹ rántí pé yíyẹ yín nwá látinú jíjẹ́ ọmọ àwọn òbí tọ̀run, kìí ṣe látinú ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ.

Ẹ wá àwọn ìrírí ìbáṣepọ̀ dídára àti dídájú, pípẹ́. Ẹ ṣe pẹ̀lẹ́ kí ìlò ohun ìgbàlódé àti ìbákẹ́gbẹ́ máṣe rọ́pò lílo àkokò ti araẹni pẹ̀lú ẹbí àti ọ̀rẹ́. Ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ àti àwọn ohun ìgbàlóde míràn lè gba púpọ̀ lára àkokò yín láìsí fúnni ní ọ̀pọ̀ oye ní ìpadàbọ̀. Ẹ mú àkokò kúrò nínú ayé ayélujára kí ẹ sì sopọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní ayé tòótọ́.

Jésù Krístì ndarí agbo àgùtàn lórí pápá koríko

Àwọn ìlérí ìbùkún

Ẹ lè ní Ẹ̀mí pẹ̀lú yín nígbàgbogbo. Ìlérí yí ni ara májẹ̀mú tí ẹ dá ní gbogbo ìgbá tí ẹ bá ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa. Ẹ̀mí yíò jẹ́ ẹ̀rí sí yín nípa Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. Òun yíò tùnínú, ṣe atọ́nà, kìlọ̀, àti wẹ̀ yín mọ́. Òun yíò ràn yín lọ́wọ́ láti dá òtítọ́ mọ̀ àti láti rí rere nínú ayé.

Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn

Báwo ni ẹ ṣe lè mọ̀ bí mo bá ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́? Kíkọ́ láti ní ìfura Ẹ̀mí ngba àkokò, ìgbáradì, àti sùúrù. Ó nsọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹ máṣe fojúfo àwọn ohun ìrọ̀rùn—ìmọ̀lára ti àlàáfíà tí ẹ̀ ngbà ní gbígbọ́ ẹ̀rí ẹnìkan tàbí ìmọ̀lára àìbalẹ̀-ọkàn tí ẹ̀ nní lẹ́hìn ṣíṣe yíyàn àṣìṣe. Ẹ wá àwọn ìwé mímọ́ kiri fún àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Ẹ̀mí fi nbánisọ̀rọ̀, ẹ gbàdúrà nípa rẹ̀, kí ẹ sì pa wíwá àwọn ànfàní láti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí.

Kíni ìwà èérí? Kínìdí tí mo níláti yẹra fún un? Ìwà èérí ni rírọ́pò kan, nínú àwọn àwòrán tàbí ọ̀rọ̀, tí a ṣe láti mú ìmọ̀lára ìbálòpọ̀ dide. Ìwà èérí nwá ní àwọn ọ̀nà púpọ̀, pẹ̀lú àwọn fídíò, àwòrán, ìwé, eré, àti orin. Bákannáà ó lè jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán tí a fi ránṣẹ́ ní àárín àwọn ọ̀rẹ́. Ìwà èérí ntọ́jú àwọn ohun tí ó jẹ́ mímọ́—àwọn ara wa àti ìmọ̀lára ìbálòpọ̀—pẹ̀lú àìní ọ̀wọ̀. Ẹ lè bá ìwà èérí pàdé láìrò ó. Bóyá ẹ mọ̀ọ́mọ̀ bá ìwà èérí pàdé tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, ẹ yípadà lọ́gán. Bákannáà ẹ lè fẹ́ láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òbí kan tàbí àgbàlagbà míràn tó ṣe gbẹ́kẹ̀lé. Mímọ̀ọ́mọ̀ wo ìwà èérí jẹ́ ìwà-ẹ̀ṣẹ̀ ó sì pa okun yín lára láti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí. Ó nmú àìlera bá ìkóraẹni-níjánu yín ó sì nyí ọ̀nà tí ẹ fi rí ara yín àti ẹlòmíràn po. Jésù Krístì ní agbára láti ràn yín lọ́wọ́ láti kọ ìwà èérí kí a sì ronúpìwàdà. Ẹ yípadà sí I kí ẹ sì yípadà kúrò nínú òkùnkùn. Bíṣọ́ọ̀pù yín lè ràn yín lọ́wọ́ láti gba okun àti ìdáríjì nípasẹ̀ Olùgbàlà. Jésù Krístì ni okun wa!

Wo Orin Dáfídì 119:105 (ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dàbí ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà wa); Ámósì 5:14 (wá rere); àwọn ará Galátíà 5:22–23 (èso Ẹ̀mí); Mórónì 7:18–19 (ìmọ́lẹ̀ Krístì); Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 6:23 (Olúwa nsọ̀rọ̀ àlàáfíà); 20:77, 79 (àwọn àdúrà oúnjẹ Olúwa).

Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì

  • Olúwa ti wípé gbogbo àwọn ohun ni a níláti “ṣe nínú ìwẹ̀nùmọ́” níwájú Rẹ̀ (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 42:41). Ṣé ẹ̀ ntiraka fún ìwà mímọ́ nínú àwọn èrò àti ìwà yín?