9.
Ẹ di alábùkúnfún nípa àwọn kọ́kọ́rọ́ àti àṣẹ oyè àlùfáà
Máttéù 16:18–19
Nígbàtí Jésù kọ́ Pétérù nípa àṣẹ oyè àlùfáà, Ó sọ̀rọ̀nípa àwọn kọ́kọ́rọ́. Àwọn kọ́kọ́rọ́ ni à nlò láti ṣí àti láti la àwọn nkan. Àwọn kọ́kọ́rọ́ lè ṣí agbára, ẹ̀bùn, àti àwọn ìbùkún Ọlọ́run nínú ayé yín.
Àwọn Òtítọ́ Ayérayé
Gbogbo àwọn kọ́kọ́rọ́ àti àṣẹ oyè àlùfáà nwá nípasẹ̀ Jésù Krístì. Gbogbo olùdimú oyè àlùfáà lè wo àṣẹ rẹ̀ padà sí I. Olùgbàlà npinnu ẹni tí yíò gba àṣẹ yí àti ẹni tí yíò gba oyè àlùfáà. A ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìmọ̀ pípé Rẹ̀.
Jésù Krístì ti mú oyè àlùfáà Rẹ̀ padàbọ̀sípò ní ọjọ́ wa. Ó ndarí bí a ó ṣe lò oyè àlùfáà. Ádámù, Mósè, Pétérù, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì míràn nínú gbogbo àkọọ́lẹ̀-ìtàn gba àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà. Ní ọjọ́ wa, Jósẹ́fù Smith gba àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà láti ọwọ́ Jòhánnù Onítẹ̀bọmi, Pétérù, Mósè, Élíásì, Èlíjàh, àti àwọn míràn. Àwọn ọmọ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpòstélì Méjìlá di gbogbo kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà mú ní ilẹ̀ ayé ní òní. Àwọn aṣaájú oyè àlùfáà ìbílẹ̀ àti iyejú àwọn ààrẹ bákannáà di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà mú fún àwọn ìpè wọn. Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà ní ó nṣe àkóso iṣẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n npàṣẹ wọ́n sì nró àwọn ọkùnrin àti obìnrin lágbára láti ṣèrànwọ́n nínú iṣẹ́ náà.
Àṣẹ oyè àlùfáà nbùkún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí a ti mú oyè àlùfáà padàbọ̀sípò, ẹ lè gba àwọn ìlànà kí ẹ sì dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ lè ṣe ìṣe ní orúkọ Ọlọ́run nígbàtí ẹ bá gba ìyànnisíṣẹ́ tàbí ìpè láti ọwọ́ ẹnìkan pẹ̀lú àṣẹ.
Àwọn ìfipè
Ẹ tẹ́wọ́gba àwọn ìpè Ìjọ kí ẹ sì sìn pẹ̀lú òtítọ́. Nígbàtí ẹ bá gba ìpè Ìjọ kan, a ó yà yín sọ́tọ̀ pẹ̀lú àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti sìn nínú ojúṣe náà. Bákannáà ẹ lè gba ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún iṣẹ́ ìsìn yín. Bí ẹ ti nsìn, ẹ̀ nṣojú Jésù Krístì. Ẹ fún Un ní dídárajùlọ yín.
Ẹ ṣe ìmúdúró àwọn ẹnití Ọlọ́run ti pè láti sìn Láti ṣe ìmúdúró túmọ̀sí jù nínawọ́ yín nìkan nígbàtí a bá ka orúkọ kan nínú ìpàdé Ìjọ kan. Ó túmọ̀sí láti tìlẹ́hìn àti láti ṣèrànwọ́. Ẹ wá àwọn ọ̀nà láti fihàn pé ẹṣe ìmúdúró àwọn ènìyàn tí Jésù Krístì ti pè láti sìn nínú Ìjọ Rẹ̀.
Ẹ mú àwọn ìyànnisíṣẹ́ láti ọwọ́ àwọn aṣaájú ṣẹ—pẹ̀lú inú iyejú yín tàbí àjọ ààrẹ kíláàsì. Wọ́n ní àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, èyí tí wọ́n yàn sí yín fún ìyannisíṣẹ́ náà. A lè yàn yín sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ẹnìkan, kí àwọn ènìyan káàbọ̀ bí wọ́n ṣe ndé sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa, tàbí ṣèrànwọ́ pẹ̀lú ìṣe ṣíṣe kan. Eyikeyi tí ìyànisíṣẹ́ jẹ́, ẹ ri bí ànfàní láti jẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì kí ẹ sì sin àwọn ọmọ Ọlọ́run.
Àwọn ìlérí ìbùkún
Ẹ lè gbẹ́kẹ̀lé pé àwọn ìlànà náà tí ẹ ti gbà ni a fàṣẹsí nípasẹ̀ Jésù Krístì. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó nmú kí Ìjọ Jésù Krístì jẹ́ àìláfiwé. Nínú àwọn ìlànà oyè àlùfáà, agbára Ọlọ́run ni a fihàn.
Joseph Smith jẹ́ ohun-èlò ní ọwọ́ Olúwa. Bí ẹ ti nsin Olúwa pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ àti ní abẹ́ ìdarí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ tí wọ́n di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà mú, Òun yíò ràn yín lọ́wọ́ láti mọ bí ẹ ó ti sin àwọn ẹlòmíràn nínú iṣẹ́ Rẹ̀. Jésù Krístì ni okun wa! Iṣẹ́ ìsìn yín yíò ràn yín lọ́wọ́ láti súnmọ́ Ọ síi yíò sì mú ayọ̀ wá fún yín.
Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn
Tani ó di kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà mú nínú wọ́ọ̀dù mi? Bíṣọ́ọ̀pù àti àwọn ààrẹ ti alàgbà, olùkọ́ni, àti àwọn iyejú díákónì tí wọ́n di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà mú. Èyí túmọ̀sí pé Olúwa ti yàn wọ́n láti darí bí a ó ti lò oyè àlùfáà láti sìn àti láti bùkún gbogbo ènìyàn nínú wọ́ọ̀dù náà.
Báwo ni àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà ṣe nbùkún mi? Àwọn ìlànà bíiti ìrìbọmi àti oúnjẹ Olúwa nípa àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà. Nígbàtí ẹ bá gba ìpè nínú Ijọ, a ó yà yín sọ́tọ̀ lábẹ́ ìdarí ẹnìkan tí ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ mú. Èyí nbùkún yín pẹ̀lú àṣẹ láti sìn nínú ìpè náà. Àwọn aṣaájú Ìjọ àti olùkọ́́ni tí wọ́n nsìn yín bákannáà ó gba àṣẹ nípa àwọn kọ́kọ́rọ́.
Báwo ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin ṣe nsìn pẹ̀lú àṣẹ oyè àlùfáà? Àwọn ọkùnrin yíyẹ ní a fi oyè àlùfáà lé lórí tí asì yàn sí àwọn ipò oyè àlùfáà bíi díákónì, olùkọ́ni, àlùfáà, àti alàgbà. Méjèèjì àwọn obìnrin àti ọkùnrin tí a yà sọ́tọ̀ láti sìn nínú ìpè gba àṣẹ oyè àlùfáà tí a yàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti mú ìpè náà ṣẹ. Ọ̀kannáà jẹ́ òtítọ́ fún àwọn obìnrin àti ọkùnrin tí wọ́n gba ìyànisíṣẹ́ kan láti ọwọ́ aṣaájú Ìjọ.
Wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 35:24–27 (Ìjọ ni à ndarí nípa àwọn kọ́kọ́rọ́ tí Olúwa ti fúnni); 107:18–20 (àwọn kọ́kọ́rọ́ Oyè Àlùfáà Melkísédékì àti Oyè Àlùfáà Áárónì); 110:11–16 (Mósè, Élíásì, àti Élíjàh mú àwọn kọ́kọ́rọ́ padàbọ̀sípò).
Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì
-
Ṣe ẹ ṣe ìmúdúró Ààrẹ ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti bí ẹnìkanṣoṣo lórí ilẹ̀ ayé tí a fún láṣẹ láti lo gbogbo kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà?
-
Ṣe o ṣe ìmúdúró àwọn ọmọ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn?
-
Ṣe o ṣe ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò àti àwọn olórí ìbílẹ̀ Ìjọ?