àwọn ọ̀dọ́
1. Ètò Ọlọ́run wà fún yín


Krístì nrìn nínú pápá kan

1.

Ètò Ọlọ́run wà fún yín

Álmà 22:13

Ṣíwájú kí ẹ tó wá sí ilẹ̀ ayé, ẹ gbé pẹ̀lú àwọn òbí tọ̀run yín. Ẹ jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ wọn. Ní ọ̀run, ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ètò fún ẹbí Rẹ̀. Ẹ gba ètò rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀ nítorí yíò ràn yín lọ́wọ́ láti dàgbà àti láti ní ìlọsíwájú láti dàbí Ọlọ́run síi nípa gbígba ara rírí kan, tí ó jẹ́ apákan ẹbí ti ayé, àti níní ìririí ìgbé ayé lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn kan lára àwọn ìrírí wọ̀nyí yíò nira. Baba wa mọ èyí, nítorínáà bí apákan èto Rẹ̀, Ó rán Olùgbàlà kan, Jésù Krístì, láti ràn yín lọ́wọ́. A pe èyí ní ètò ìgbàlà tàbí ètò ìdùnnú.

Àwọn Òtítọ́ Ayérayé

Baba Ọ̀run ni olùpilẹ̀ṣẹ̀ ètò náà. Òun ni Baba ẹ̀mí yín, Ó sì ní ìfẹ́ yín. Ó fẹ́ láti fún yín ní ìbùkún Rẹ̀ títóbijùlọ—ìyè ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀. Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, Ó nfẹ́ kí ẹ dàbí Tirẹ̀ síi kí ẹ sì gbé ìgbé aláyọ̀, ológo tí Òun ngbé. Ó ní gbogbo agbára Ó sì mọ ohun gbogbo. Ẹ lè gbẹ́kẹ̀lé E. Àní nígbàtí ìgbé ayé bá le.

Jésù Krístì mú kí ètò náà ṣeéṣe. Ṣíwájú kí a tó dá ayé, Baba Ọ̀run yàn Án láti jẹ́ Olùgbàlà. Jésù Krístì nìkan ni ẹnìkan tí ó lè mú yín padà wá sí ọ̀dọ̀ Baba yín ní Ọ̀run. Èyí ni ìdí tí a fi yàn láti tẹ̀lé E. Gbogbo nkan dá lórí yíyàn náà!

Ìgbeyàwó àti ẹbí ṣe pàtàkì sí ètò Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ apákan ẹbí Ọlọ́run, àti pé gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀ wá sí ayé nípasẹ̀ ìyá àti baba kan. Ọlọ́run nfẹ́ kí àwọn ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin Rẹ̀ ní ìlọsíwájú papọ̀ sí jíjẹ́ pípé ayérayé. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin kọ̀ọ̀kan ndásí ìgbeyàwó ìfẹ́ni, ìdápọ̀ kan dọ́gbadọ́gbà. Ìgbé ayé ẹbí ní ìhín lórí ilẹ̀ ayé—àní pẹ̀lú gbogbo àwọn àìpé rẹ̀—lè mú ayọ̀ títóbi wá. Ó jẹ́ láti ṣèrànwọ́ láti múra yín sílẹ̀ fún ìyè ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run.

Àwọn ìfipè

Ẹ teramọ́ ìrísí ayérayé. Nígbàkugbà tí ẹ bá kojú àwọn àdánwò, ìdánwò, ìjákulẹ̀, tàbí àwọn yíyàn tó nira, ẹ rán ara yín létí nípa ètò Ọlọ́run. Wo bí àwọn òtítọ́ Ayérayé tí ẹ mọ̀ nípa ètò Rẹ̀ lè ràn yín lọ́wọ́ láti wo àwọn ìpènijà yín ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ẹ wá ọwọ́ Ọlọ́run nínú ayé yín. Ẹ kíyèsí àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run fi nbùkún yín. Ó lè jẹ́ ìṣe inúrere kan láti ọ̀dọ̀ ẹnikan, àkokò àlàáfíà, tàbí ìdáhùn sí àdúrà kan.

Yàn láti tẹ̀lé ètò Ọlọ́run. Kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ohun tí Baba Ọ̀run nfẹ́ kí ẹ ṣe. Ẹ wá ìtọ́nisọ́nà Rẹ̀ bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́, ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè, ìkéde ẹbí, àti ìbùkún babanlá yín. Èyí yíò ràn yín lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ láti sin Olúwa, bí ìránṣẹ́ ìhìnrere kan ní gbogbo ayé yín. Ẹ mú kí iṣẹ́ ìsìn sí Olúwa, ìgbeyàwó ayérayé, àti títọ́ àwọn ọmọ jẹ́ ààyò gíga. Ẹ ṣe ipa yín láti ní ẹbí ìdùnnú kan nísisìyí nípa títẹ̀lé àwọn Ìkọ́ni ti Jésù Krístì.

Jésù Krístì nrìn nínú pápá koríko pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ tí ntàn kúrò lára rẹ̀

Àwọn ìlérí ìbùkún

Ẹ lè kojú àwọn àdánwò ìgbé ayé pẹ̀lú ìgboyà àti ìrètí nínú Krístì. Nítorí ẹ mọ̀ nípa ètò ayérayé Ọlọ́run, ẹ ní ohun èlò iyebíye tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ ní àwọn àkokò líle. Ẹ mọ̀ pé púpọ̀ wà sí ayé ju ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín ìbí àti ikú. Ẹ mọ ẹnití ẹ jẹ́ lódodo, ohun tí èrèdí yín jẹ́, àti ẹnití ẹ lè dà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà. Jésù Krístì ni okun yín!

Ẹ lè gba ìyè ayérayé bí ẹ ṣe ntẹ̀lé Jésù Krístì. Òun yíò fún yín ní agbára láti dàbíi Tirẹ̀ síi, padà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí yín ọ̀run, kí ẹ sì gbé nínú ayọ̀ pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ yín ní ayérayé. Gbígbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì.

Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn

Kínìdí tí ìgbé ayé fi nlè gan nígbàmíràn? Báwo ni mo fi lè rí okun? Àwọn ìrírí yín nínú ayé yí—àní ní àwọn ìgbà ínira jùlọ—lè jẹ́ fún rere yín. Wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ láti dàgbà àti láti ní ìlọsíwájú bí ẹ ṣe nyípadà sí Olùgbàlà. Kò sí ohunkankan tí ẹ̀ nlàkọjá tí Jésù Krístì kò ní òye nítorí ìrúbọ ètùtù Rẹ̀. Ó mọ̀ bí yíò ṣe ràn yín lọ́wọ́ déédé. Ẹ kọjúsí ìgbé ayé yín lórí Rẹ̀, àti pé Òun yíò gbé yín ga ju gbogbo iyèméjì àti ìbẹ̀rù.

Nígbàmíràn, èrò ìdùnnú nínú ẹbí àti ìgbeyàwó dàbí ní jíjìnnà réré gidi. Báwo ni mo fi lè rí ìgbẹ́kẹ̀lé? Eyikeyi ipò yín, ẹ máṣe sọ ìrètí nù lórí ètò Baba Ọ̀run. Òun kò ní sọ ìrètí nù lórí yín. Bí ẹ bá jẹ́ olóòótọ́ sí Olùgbàlà àti àwọn májẹ̀mú yín, ẹ̀yin ó rí àwọn ìdáhùn nínú àwọn Ìkọ́ni ti Jésù Krístì. Ó ní òye gbogbo ohun tí ẹ ní ìrírí. Nípasẹ̀ Rẹ̀, ẹ ó jèrè okun láti gbọ́ran sí àwọn òfin Ọlọ́run kí ẹ sì gba àwọn ìlérí ìbùkún Rẹ̀. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé E àti ìhìnrere Rẹ̀

Wo 2 Néfì 9:13 (báwo ni ètò ti Ọlọ́run wa ṣe tóbi!); Mòsíàh 2:41 (àwọn tí wọ́n bá pa àwọn òfin mọ́ lè gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ìdùnnú àìlópin); Álmà 12:28–34 (Ọlọ́run ṣe ètò ìràpadà di mímọ̀ sí àwọn ọmọ Rẹ̀); Ábráhámù 3:22–26 (Ètò Ọlọ́run wà pẹ̀lú rírán wa wá sí ilẹ̀ ayé, níbití a ti lè yàn fún arawa láti tẹ̀lé àwọn òfin Rẹ̀).

Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì

  • Ṣe ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àti ẹ̀rí kan nípa Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé; Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì; àti Ẹ̀mí Mímọ́?