àwọn ọ̀dọ́
11. Òtítọ́ yíò sọ yín di òmìnira


Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní àwọn ìgbà àtijọ́ nkàwé látinú ìwé kan

Ẹ Ṣe Àpejẹ Lórí Ọ̀rọ̀ náà?, láti ọwọ́ Liz Lemon Swindle Nípasẹ̀ ti Havenlight

11.

Òtítọ́ yíò sọ yín di òmìnira

Jòhánnù 14:15

Baba yín Ọ̀run ni Ọlọ́run òtítọ́. Ó jẹ́ olùmọ̀-gbogbo. Gbogbo òtítọ́ nwá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ó sì ndarí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ẹ fihàn pé ẹ mọyì òtítọ́ bí ẹ ṣe nwá ìkọ́ni, gbé pẹ̀lú ìṣòtítọ́, kí ẹ sì dúró pẹ̀lú ìgboyà fún ohun tí ẹ mọ̀ pé ó tọ́—àní bí ẹ bá níláti dánìkan dúró.

Àwọn Òtítọ́ Ayérayé

Baba Ọ̀run nfẹ́ kí àwọn ọmọbìnrin àti ọmọbìnrin máa kọ́ ẹ̀kọ́ Rẹ̀ nígbàgbogbo. Ẹ ní méjèèjì àwọn èrèdí ti ara àti níti ẹ̀mí láti wá àti láti kọ́ ẹ̀kọ́. Ẹ̀kọ́ kìí ṣe nípa gbígba owó nìkan. Ó jẹ́ ara ìlépa yín láti dàbíi Baba Ọ̀run síi.

Gbígbé pẹ̀lú ìṣòtítọ́ túmọ̀ sí pé ẹ ní ìfẹ́ ohun tí ó tọ́ ní ojú Ọlọ́run—púpọ̀ ju bí ẹ ti ní ìfẹ́ ìtùnú, òkìkí, tàbí ìrọ̀rùn araẹni. Ó túmọ̀ kí a kàn ṣe ohun tí ó tọ́ nítorí tí ó tọ́.

Ẹ ní ohunkan iyebíye láti pín. Ìhìnrere Jésù Krístì ndi àwọn ìdáhùn sí ìbèèrè ayé. Òun ni ọ̀nà sí àláfíà àti ìdùnnú. Ẹ kò lè mọ gbogbo ohun, ṣùgbọ́n ẹ mọ̀ tó láti ní ìfẹ́ aladugbo, pín àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́ pẹ̀lú wọn, kí ẹ sì pè wọ́n láti kọ́ ẹ̀kọ́ síi.

Àwọn ìfipè

Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ nígbàgbogbo. Ẹ wo àwọn ànfàní láti mú inú àti iṣẹ́ yín gbòòrò. Àwọn ànfàní wọ̀nyí lè pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àṣẹ ní ilé ìwé tàbí idanilẹkọ ìkọ́ṣẹ́, bákannáà bí ìkọ́ni àìláṣẹ látinú orísun tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé. Ẹ fi Olúwa sínú ìtiraka yín, Òun ó sì tọ́ yín sọ́nà.

Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti ẹ̀mí. Bí ẹ ti nkọ́ nípa ayé ní àyíká yín, bákannáà ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Olùgbàlà, ẹnití o´ dá ayé sílẹ̀. Ẹ ṣe àṣàrò ayé àti ìkọ́ni Rẹ̀. Ẹ mú idanilẹkọ ìhìnrere, ile ẹ̀kọ́ ìhìnrere, àti ara àṣàrò ìhìnrere araẹni ti ìkọ́ni ayé-pípẹ́ yín. Ó lè múra yín sílẹ̀ láti sìn ní míṣọ̀n àti láti pín ìhìnrere ní gbogbo ayé yín.

Ẹ gbé pẹ̀lú ìṣòtítọ́. Ẹ máṣe jalè, parọ́, yannijẹ, tàbí tànjẹ ní ọ̀nà eyikeyi—ní ilé ìwé, níbi iṣẹ́, orí afẹ́fẹ́, níbigbogbo. Jẹ́ ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì olóòótọ́ kannáà ní gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀.

àwọn ènìyàn nkúnlẹ̀ ṣíwájú àjínde Krístì

Àwọn ìlérí ìbùkún

Ẹ̀kọ́ nmú okun yín láti sin Olúwa pọ̀ si, pẹ̀lú jíjẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere. Ó nró yín lágbára láti bùkún àwọn ẹlòmíràn, nípàtàkì ẹbí yín. Bí ẹ ti nkọ́ ẹ̀kọ́ si, bẹ́ẹ̀ ni ẹ lè ṣèrànwọ́ láti gbé ìjọba Ọlọ́run ró àti láti ní ipa rere fún ayé.

Òtítọ́ nmú àlàáfíà àti ọ̀wọ̀-araẹni. Nígbàtí àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe yín bá wà ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́, ẹ nfihàn pé ẹ lè di gbígbẹ́kẹ̀lé nípasẹ̀ àwọn ènìyàn míràn àti nípasẹ̀ Olúwa.

Nígbàtí ẹ bá dúró fún àwọn Ìkọ́ni ti Jésù Krístì, Ó dúró pẹ̀lú yín. Jésù Krístì ni okun wa! Àwọn ẹlòmíràn lèmá tilẹ̀ faramọ́ ìgbàgbọ́ yí, ṣùgbọ́n ìgboyà yín àti ìṣòdodo yíò ní àkíyèsí. Bóyá tàbí àwọn ẹlòmíràn kò tẹ̀lé àpẹrẹ yín, ẹ̀rí yín, ìgbẹ́kẹ̀lé, àti ìgbàgbọ́ nínú Krístì yíò dàgbà.

Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn

Ṣé ó jẹ́ àṣìṣe láti ní àwọn ìbèèrè nípa Ìjọ? Báwo ni mo fi lè rí àwọn ìdáhùn? Níní àwọn ìbèèrè kìí ṣe àmì àìlera tàbí àìní ìgbàgbọ́. Nítòótọ́, bíbééré àwọn ìbèèrè lè ṣèrànwọ́ láti gbé ìgbàgbọ́ ró. Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere bẹ̀rẹ̀ nígbàtí Joseph Smith ọmọ ọdún mẹ́rìnlá bèèrè àwọn ìbèèrè pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ẹ wá àwọn ìdáhùn nínú àwọn ìwé mímọ́, nínú àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Ọlọ́run, láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣaájú yín àti àwọn ọmọ ẹbí olóòtítọ́, àti láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Fúnrarẹ̀. Bí àwọn ìdáhùn kò bá wá lọ́gán, ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ ó kọ́ ẹ̀kọ́ ìlà lórí ìlà. Tẹramọ́ gbígbé nípa ohun tí ẹ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, kí ẹ sì tẹramọ́ wíwá òtítọ́.

Báwo ni mo ṣe lè dúró fún ohun tí ó tọ́ láìsí ṣíṣẹ àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ yíyàtọ̀? Ẹ bẹ̀rẹ̀ nípa mímu dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe yín ní ìmísí nípa ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀. A kò ní láti ṣe pípín ìhìnrere nínú ẹ̀mí ìjà ṣùgbọ́n sànjù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú híhàn kedere, ìwàtútù, àti inúrere. Ẹ lè jẹ́ olùfẹ́ni sí àwọn ẹlòmíràn àní bí ẹ kò bá ní ìfaramọ́ pẹ̀lú ìwò wọn. Ẹ jẹ́ àpẹrẹ rere ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì nípa ọ̀nà tí ẹ fi ngbé.

Wo Máttéù 5:14–16 (ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín tàn); Jòhánnù 14:6 (Jésù ni òtítọ́); 1 Pétérù 3:15 (ẹ ṣetán nígbàgbogbo láti pín ìrètí yín nínú Krístì); Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:77–80 (àwọn ohun tí Olúwa nfẹ́ kí a ṣe láti kọ́ ẹ̀kọ́); 88:118 (ẹ wá ọgbọ́n látinú àwọn ìwé dídárajùlọ); 93:36 (ògo Ọlọ́run ni òye); 124:15 (ìṣòtítọ́ túmọ̀ sí fífẹ́ ohun tí ó tọ́); 130:18 (òye wa yíò dìde pẹ̀lú wa nígbàtí a bá jínde).

Àwọn Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì

  • Ṣé ẹ̀ ntiraka láti jẹ́ olotitọ nínú ohun gbogbo tí ẹ̀ nṣe?

  • Ṣé ẹ nṣàtìlẹhìn tàbí gbé àwọn ìkọ́ni, ìṣe, tàbí ẹ̀kọ́ tó lòdì sí àwọn ti Ìjọ Jésù Krísti ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kọ̀ọ̀kan wọnnì ga.