6.
Fẹ́ràn Ọlọ́run, fẹ́ ọmọnìkéjì rẹ
Máttéù 22:37–40
Láti ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àwọn yíyàn rere, Ọlọ́run fúnni ní àwọn òfin. Òun ṣe èyí nítorí Òun ní ìfẹ́ yín. Àti pé èrèdí dídárajùlọ láti gbọ́ran sí àwọn òfin Ọlọ́run ni nítorí ẹ ní ìfẹ́ Rẹ̀. Ìfẹ́ wà ní oókan àwọn òfin Ọlọ́run.
Àwọn Òtítọ́ Ayérayé
Ọlọ́run fẹ́ràn yín. Òun ni Baba yín. Ìfẹ́ pípé Rẹ̀ lè mí síi yín láti fẹràn Rẹ̀. Nígbàtí ìfẹ́ yín fún Baba Ọ̀run bá jẹ́ ipá pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí ayé yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpinnu yíò di ìrọ̀rùn síi.
Àwọn òfin méjì nlá gbogbo ni láti fẹ́ràn Ọlọ́run àti láti Fẹ́ràn Ọlọ́run. Ta sì ni ọmọnìkéjì rẹ? Gbogbo ènìyàn! Gbogbo ohun míràn tí a kọ́ni nínú àwọn ìwé mímọ́ àti nípasẹ̀ àwọn wòlíì ni a sopọ̀ mọ́ àwọn òfin méjì wọ̀nyí.
Gbogbo ènìyàn ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin yín—pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ni, àwọn ènìyàn tí wọ́n yàtọ̀ sí yín tàbí tí wọn kò faramọ́ yín. Baba Ọ̀run nfẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ fẹ́ràn ara wọn. Nígbàtí ẹ bá nsin àwọn ọmọ Rẹ̀, ẹ̀ nsin Ín.
Àwọn ìfipè
Ẹ fi ìfẹ́ hàn fún Ọlọ́run nípa pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Fún àpẹrẹ, nípa pípa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́ ní mímọ́, pẹ̀lú mímúrasílẹ̀ lóòótọ́ fún àti ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, ẹ nfihan Ọlọ́run pé ẹ̀ nfẹ́ láti ya ọjọ́ kan sí mímọ́ ní ọ̀sẹ̀ kan sí I. Bí ẹ ti ngbàwẹ̀ tí ẹ sì nsan idamẹwa àti ọrẹ, ẹ̀ nfihan Ọlọ́run pé iṣẹ́ Rẹ̀ ṣe pàtàkì síi yín ju àwọn ohun ayé lọ. Nígbàtí ẹ bá lo àwọn orúkọ Ọlọ́run àti Krístì pẹ̀lú ọ̀wọ̀, láì ṣe ọ̀nà lásán tàbí yẹpẹrẹ, ẹ nfihan pé ẹ moore fún gbogbo ohun tí Wọ́n ti ṣe fún yín.
Ẹ tọ́jú gbogbo ènìyàn bí ọmọ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́bí ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì, ẹ lè darí gan ní títọ́jú àwọn ènìyàn gbogbo ẹ̀yà, ẹ̀sìn, àti eyikeyi àwọn ẹgbẹ́ míràn pẹ̀lú ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀—nípàtàkì nígbàmíràn àwọn ẹni tí a palára nípa àwọn ọ̀rọ̀ pípanilára àti ìṣe. Nawọ́ jáde sí àwọn tí wọ́n lè ní ìmọ̀ dídánìkanwà, ìpatì, tàbí àìní-ìrànlọ́wọ́. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Baba Ọ̀run nípasẹ̀ yín. Ẹ ṣe àbápín àwọn ìbùkún tí Ó ti fún yín pẹ̀lú wọn , kí ẹ sì pè wọ́n láti tẹ̀lé Jésù Krístì.
Ẹ mu dájú pé èdè yín fi ìfẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn hàn—bóyá ẹ̀ nsọ̀rọ̀ ní araẹni tàbí lórí-afẹ́fẹ́. Sọ àwọn ohun tí ó ngbéniga—kò sí ohunkankan tí ó lè yani-nípa, panilára, tàbí dunni àní bí ẹ̀fẹ̀ kan. Ọ̀rọ yín lè jẹ́ alágbára. Ẹ jẹ́ kí wọ́n di alágbára fún rere.
Ẹ fi ìfẹ́ hàn sí ẹbí yín. Níní ìfẹ́ gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run nbẹ̀rẹ̀ ní ilé. E sa ipá yín láti mú kí ilé yín jẹ́ ibití gbogbo ènìyàn ti lè ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olùgbàlà.
Àwọn ìlérí ìbùkún
Ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Ọlọ́run yíò jìnlẹ̀ bí ẹ ṣe ndi ìfẹ́ yín hàn nípa gbígbọ́ran sí àwọn òfìn Rẹ̀ àti pípa àwọn májẹ̀mú yín mọ́ pẹ̀lú Rẹ̀.
Ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn yíò jinlẹ̀ bí ẹ ṣe nfi ìfẹ́ yín hàn nípasẹ̀ ìsìn bíiti Krístì. Ẹ yíò rí ayọ̀ ní mímú kí ayé jẹ́ ibi ìfẹni síi.
Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn
Báwo ni èmi ó ṣe ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run? Ìfẹ́ Baba Ọ̀run wà ní àrọ́wọ́tó nígbàgbogbo. Ẹ sọ̀rọ̀ sí I léraléra nínú àdúrà. Ẹ ṣe àbápín àwọn ìmọ̀lára yín pẹ̀lú Rẹ̀, kí ẹ sì fọkansí àwọn ìwọnilọ́kàn láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ẹ ka àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nínú àwọn ìwé mímọ́. Ẹ ronú nípa gbogbo èyí tí Ó ti ṣe fún yín. Ẹ lo àkokò ní àwọn ibi àti àwọn ṣíṣe níbití Ẹ̀mí Rẹ̀ wà.
Njẹ́ Olúwa nretí mi láti ní ìfẹ́ gbogbo ènìyàn, àní àwọn tí wọ́n ṣe buburú sí mi? Olúwa nretí yín láti ní ìfẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí wọ́n nṣe àìdáa sí yín. Bbíotilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé ẹ níláti dúró nínú ipò tí ó nmú yín ní ìpalára ẹ̀dùn ọkàn, ti ara, tàbí ti ẹ̀mí. Ẹ gbé ààlà ìlera kalẹ̀ láti pa ara yín mọ́ láìléwu. Bí a bá jẹ́ yíyọlẹ́nu tàbí lò nílòkulò, tàbí ẹ mọ̀ pé èyí nṣẹlẹ̀ sí ẹlòmíràn, sọ̀rọ̀ sí àgbàlagbà tí ó nṣòótọ́.
Nígbàwo àti báwo ni mo fi níláti mọ àwọn ọmọ ẹ̀yà òdìkejì? Ọ̀nà dídárajùlọ láti mọ àwọn ẹlòmíràn ni nípasẹ̀ ìbàṣọ̀rẹ́ òtítọ́. Nígbàtí ẹ bá wà ní ọ̀dọ́, ẹ gbé ìbáṣọ̀rẹ́ rere ró pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn. Nínú àwọn ọ̀làjú kan, àwọn ọ̀dọ́ mọ àwọn ọmọ ẹ̀yà òdìkejì nípa àwọn ìṣe ṣíṣe ẹgbẹ́ dídára. Fún ìdàgbàsokè ẹ̀dùn ọkàn àti ààbò ti ẹ̀mí, ẹ sún àwọn ṣíṣe ìṣe ọ̀kan-sí-ọ̀kan síwájú títí ẹ ó fi dàgbà—ìlànà ọjọ́ orí mẹ́rìndínlógún. Ẹ dámọ̀ràn pẹ̀lú ẹbí àti olórí yín. Ẹ fi àwọn ìbáṣepọ̀ gangan pamọ́ fún ìgbàtí ẹ ó dàgbà si. Ẹ lo àkokò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ràn yín lọ́wọ́ láti pa àwọn ìfarajì yín sí Jésù Krístì.
Kíni mo lè ṣe bí ilé mi kò bá jẹ́ ibi ìfẹ́? Olùgbàlà yín mọ ipò yín, Ó sì ní ìfẹ́ yín. Ẹ ní sùúrù, ẹ tẹ̀síwájú láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí ẹ sì jẹ́ àpẹrẹ rere sí ẹbí yín. Àwọn ìṣe ìrọ̀rùn ti ìfẹ́ lè mú ìyàtọ̀ nlá wá. Bákannáà ẹ lè gbé ìbáṣepọ̀ ró ní àárín ẹbí Wọ́ọ̀dù yín. Ẹ múrasílẹ̀ nísisìyí láti gbé ẹbí ti ara yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì. Ẹ rántí: Jésù Krístì ni okun yín!
Wo Ìsàíàh 58:3–11 (àwọn èrèdí ààwẹ̀); 58:13–14 (àwọn ìbùkún ti bíbu-ọlá fún Ọjọ́ Ìsinmi); Málákì 3:8–10 (àwọn ìbùkún sían idamẹwa); Lúkù 6:27–28 (ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín); 10:25–37 (tani aladugbo mi?); Jòhánnù 3:16–17 (Ọlọ́run fẹ́ràn wa, nítorínáà ó rán Ọmọ Rẹ̀); 14:15 (à npa àwọn òfin mọ́ nítorí a fẹ́ràn Ọlọ́run); 1 Jòhánnù 4:19 (a fẹ́ràn Ọlọ́run nítorí Ó fẹ́ràn wa); Mòsíàh 2:17 (nígbàtí a bá sin àwọn ẹlòmíràn, a nsin Ọlọ́run).
Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì
-
Ṣé ẹ̀ ntẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Ìjọ Jésù Krístì nínú ìwà ìkọ̀kọ̀ àti gbangba yín pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹbí yín àti àwọn míràn?
-
Njẹ́ ẹ jẹ́ olùsan idamẹwa-kíkún?