Ṣe àwọn yíyàn tí ó ní ìmísí
Nínú Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, ẹ yíò rí àwọn Ìkọ́ni ti Jésù Krístì àti àwọn wòlíì Rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn òtítọ́ wọ̀nyí bí atọ́nà yín, ẹ lè ṣe àwọn yíyàn tí ó ní ìmísí tí yíò bùkún yín nísisìyí àti ní gbogbo ayé àìlópin.
Ẹ̀yin jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ ẹ̀mí Ọlọ́run. Ètò nlá ìdùnnú Rẹ̀ nmu ṣeéṣe fún yín láti dàgbà níti ẹ̀mí àti láti gbèrú ìlèṣe àtọ̀runwá yín. Ó rán Jésù Krístì láti jẹ́ Olùgbàlà yín.
Baba yín ní Ọ̀run ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín. Ó ti fún yín ní àwọn ìbùkún nla, pẹ̀lu ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere àti àwọn ìlànà mímọ́ àti àwọn májẹ̀mú tí ó so yín pọ̀ mọ́ Ọ tí ó sì mú agbára Rẹ̀ wá sínú ayé yín. Pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí ni àfikún ayọ̀ àti ojúṣe nwá. Ó mọ̀ pé ẹ lè ṣe ìyàtọ̀ nínú ayé, èyí sì bèèrè fún, ní ọ̀pọlọ̀pọ̀ ọ̀ràn, jíjẹ́ yíyàtọ̀ kúrò nínú ayé. Ẹ wá ìtọ́nisọ́nà Baba Ọ̀run yín bí ẹ ṣe nṣe àwọn yíyàn. Òun yíò bùkún yín pẹ̀lú ìmísí nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
Jésù Krístì ni ọ̀nà sí ayọ̀ ayérayé. Bí ẹ ṣe nlo òmìnira yín láti yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì, ẹ wà lórí ipa ọ̀nà tí ó ndarí sí ìdùnnú ayérayé. Ẹ mú Jésù Krístì jẹ́ òṣùwọ̀n yín, ìpìnlẹ̀ àpàtà-líle yín. Ẹ gbé ìgbé ayé yín ró lórí àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, kí ẹ sì wọn àwọn yíyàn yín nípasẹ̀ wọn. Àwọn májẹ̀mú tí ẹ dá ní ìrìbọmi, ní ìgbà oúnjẹ Olúwa, àti nínú tẹ́mpìlì ni àwọn búlọ́kì ìgbéró ìpìlẹ̀ gbọingbọin yín nínú Krístì. Ẹ ṣì nkojú àwọn ìlàkàkà àti àdánwò, ṣùgbọ́n Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà yíò ràn yín lọ́wọ́ nínú gbogbo wọn.
Èrèdí ti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ kìí ṣe láti fún yín ní “bẹ́ẹ̀nì” tàbí “rárá” kan nípa gbogbo ṣíṣeéṣe yíyàn tí ẹ̀ ndojúkọ. Dípò bẹ́ẹ̀, Olúwa npè yín láti gbé ìgbé ayé ní ọ̀nà kan gígajù àti mímọ́jù—ìgbé ayé tí ó dá lórí àwọn òtítọ́ ayérayé àti ìlérí àwọn ìbùkún Olúwa. Èyí ni ọ̀nà Rẹ̀. Atọ́nà yí yíò kọ́ yín nípa ọ̀nà Rẹ̀. Ó ṣe àwọn àlàyé àwọn òtítọ́ tí Ó ti fihàn. Ẹ mú àwọn òtítọ́ wọ̀nyí jẹ́ atọ́nà yín fún ṣíṣe àwọn yíyàn—àwọn yíyàn títóbi, bíiti dídá àwọn májẹ̀mú nínú tẹ́mpìlì àti sísìn ní míṣọ̀n kan, bákanńà bí àwọn yíyàn ojojúmọ́, bíiti títọ́jú àwọn ènìyàn tàbí bí ẹ ó ṣe lo àkokò yín.
Nígbàtí àwọn ẹlòmíràn lè ràn yín lọ́wọ́, ìdàgbà ti ẹ̀mí yí jẹ́ ti araẹni. Eyí ni ojúṣe yín. Ẹ ṣe dídárajùlọ yín láti gbèrú ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, kí ẹ pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ kí ẹ sì bu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú yín, kí ẹ sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti súnmọ́ Olùgbàlà típẹ́típẹ́.
Wo Mòsíàh 4:29–30 (àwọn ọ̀nà sí ẹ̀ṣẹ̀ kò lónkà, nítorínáà a gbọ́dọ̀ wo arawa); Hẹ́lámánì 5:12 (gbé ìpìlẹ̀ yín ró lórí Krístì); Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 45:57 (ẹ mú Ẹ̀mí Mímọ́ fún atọ́nà yín); 25:13 (ẹ rọ̀ mọ́ àwọn májẹ̀mú yín).
Bí a ti ṣètò atọ́nà yí
Àkọlé kọ̀ọ̀kan ní àwọn ìpín mẹ̀ta:
-
Àwọn òtítọ́ ayérayé, tàbí ẹ̀kọ́ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì
-
Àwọn ìfipè láti ṣe ìṣe lórí àwọn òtítọ́ wọnnì
-
Àwọn ìlérí ìbùkún tí Olúwa fi fún àwọn wọnnì tí wọ́n ngbé nípa àwọn ìkọ́ni Rẹ̀