àwọn ọ̀dọ́
Ọ̀rọ̀ láti ọwọ́ Àjọ Ààrẹ Ìkínní


Ọ̀rọ̀ láti ọwọ́ Àjọ Ààrẹ Ìkínní

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n,

A ní ìfẹ́ yín, a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín. Ẹ wà ní àárín àwọn àṣàyàn ẹ̀mí ti Baba Ọ̀run lódodo, tí a rán wá sí ilẹ̀ ayé ní àkokò yí láti ṣe àwọn ohun pàtàkì.

Ẹ jẹ́ alágbára jù ẹ sì lókun síi ju bí ẹ ti lè damọ̀. Àti pé nígbàtí ẹ bá gbẹ́kẹ̀lé Olùgbàlà, àní okun yín ndàgbà síi. Jésù Krístì ni “okun awọn ọdọ́.”

Atọ́nà yí yíò ràn yín lọ́wọ́ láti kọ́ ìpìlẹ̀ líle fún ṣíṣe àwọn yíyàn láti dúró lórí ipa-ọ̀nà tí ó ndarí lọ sí ìyè ayérayé. Yíò ràn yín lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ láti dá àwọn májẹ̀mú mímọ́ nínú tẹ́mpìlì, múrasílẹ̀ láti sìn ní míṣọ̀n, àti láti rí ayọ̀ nínú títẹ̀lé Jésù Krístì ní gbogbo ayé yín. Ẹ ní ibi pàtàkì kan nínú Ìjọ Rẹ̀. Jésù Krístì yíò ràn yín lọ́wọ́ láti mú èrèdí Rẹ̀ fún yín Ṣẹ.

A mọ̀ pé Ọlọ́run wà láàyè. Ó jẹ́ àdúrà wa pé ẹ̀yin yíò dúró gbọingbọin lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú—ipa ọ̀nà dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́. Èyí ni ipa ọ̀nà tí ó ndarí lọ sí Baba yín ní Ọ̀run. Bí ẹti nṣe é, ẹ̀yin yíò jẹ́ ipá kan fún rere, ní pípín ìhìnrere aláyọ̀, kíkó àwọn ọmọ Ọlọ́run jọ, àti mímúra ayé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti Olùgbàlà. Ẹ rántí: Jésù Krístì ni okun yín!

Àjọ Ààrẹ Ìkínní Náà