àwọn ọ̀dọ́
10. Ara yín jẹ́ mímọ́


Baba àti ìyá àti ọmọ-ọwọ kan

Ẹ̀bí Nwo Ìmọ́lẹ̀ Níwájú, láti ọwọ́ Lovetta Reyes Cairo. Nípasẹ̀ ti Havenlight

10.

Ara yín jẹ́ mímọ́

1 Kọ́ríntì 6:18–20

Ara yín jẹ́ ẹ̀bùn oníyanu kan láti ọ̀dọ̀ Baba yín Ọ̀run. Níní ara kan nfún yín ní a`lékún agbára láti lo o`mìnira yín láti yàn ní àárín títọ́ àti àṣìṣe. Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì lè ràn yín lọ́wọ́ láti rí ara yín látinú ìrírí Ọlọ́run. Àti pé èyí nmú ìyàtọ̀ nlá wá nínú àwọn yíyàn yín nípa ohun láti ṣe pẹ̀lú ara yín àti bí ẹ ó ṣe tọ́jú rẹ̀.

A`wọn Òtítọ́ Ayérayé

Ara yín wà ní àwòrán Ọlọ́run—ológo jùlọ, Ẹni ọlọ́lá ní gbogbo ayé. Àwọn ìwé mímọ́ fi ara wa wé tẹ́mpìlì mímọ́, ibi tí Ẹ̀mí lè gbé. Bẹ́ẹ̀ni, ara yín kò pé nísisìyí. Ṣùgbọ́n àwọn ìrírí tí ẹ̀ nní pẹ̀lú ara yín lè ràn yín lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ láti gbá ara pípé kan, tó jínde, ológo ní ọjọ́ kan.

Ẹ̀mí yín ni a ṣe papọ̀ nípa ara àti ẹ̀mí yín. Fún èrèdí yí, ìlera ti ara àti ìlera ti ẹ̀mí súnmọ́ra típẹ́típẹ́. Olùgbàlà fi Ọ̀rọ̀ ti Ọgbọ́n hàn láti kọ́ àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ti títọ́jú ara yín àti láti ṣèlérí àwọn ìbùkún ti ara àti ti ẹ̀mí,

Àwọn ìmọ̀lára ìbálòpọ̀ jẹ́ pàtàkì ara ètò Ọlọ́run láti dá ìgbeyàwó dídùn a`ti ẹbí ayérayé sílẹ̀. Àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀—wọ́n jẹ́ mímọ́. Nítorípé àwọn ìmọ̀lára ìbálòpọ̀ jẹ́ mímọ́ tí ó sì lágbára, Ọlọ́run ti fún yín ní òfin ìmáradúró Rẹ̀ láti múra yín sílẹ̀ láti lò àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí bí Ó ti nfẹ́. Òfin ìmáradúró wí pé Ọlọ́run nfàṣẹ sí ìṣe ìbálòpọ̀ nìkan ní àárín ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ṣe ìgbeyàwó. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn patì tàbí pàápàá fi òfin Ọlọ́run ṣẹ̀sín, ṣùgbọ́n Olúwa npè wá láti jẹ́ ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ kí a sì gbé o`ṣùwọn gígajù.

Àwọn ìfipè

Ẹ tọ́jú ara yín—àti ara àwọn ẹlòmíràn—pẹ̀lú ọ̀wọ̀. Bí ẹ ti nṣe àwọn ìpinnu nípa aṣọ, ẹ̀yà-irun, àti ìrísí, ẹ bèèrè lọ́wọ́ ara yín, “Njẹ́ èmi nbu-ọlá fún ara mi bí ẹ̀bùn mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run?” Baba Ọ̀run nfẹ́ kí a rí ara wa fún ẹni tí a jẹ́ lódodo: kìí ṣe àwọn ara rírí ṣùgbọ́n àwọn àyànfẹ́ ọmọ Rẹ̀ pẹ̀lú àyànmọ́ tọ̀run. Ẹ yẹra fún àwọn ẹ̀yà tí ó ntẹnumọ́ tàbí nmú ìfojúsí kí kò tọ́ wá sí ara rírí yín dípò ẹni tí ẹ jẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run pẹ̀lú ọjọ́ ọ̀la ayérayé. Ẹ jẹ́ kí ìwà mímọ́ àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run tọ́ àwọn yíyàn wa sọ́nà. Ẹ wá àmọ̀ràn látinú ẹbí yín.

Ẹ ṣe àwọn ohun tí yíò fún ara yín lókun, kìí ṣe àwọn ohun tí yíò palára tàbí bàá jẹ́. Ẹ gbádùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè pẹ̀lú ìmoore . Ẹ rántí pé ọtí, tábà, kọfí, tíì, àti àwọn òògùn olóró míràn àti egbòogi kìí ṣe fún ara yín tàbí ẹ̀mí yín. Àní àwọn egbòogi tí ó nṣèrànwọ́, bíi àwọn òògùn tí a júwe, lè jẹ́ pípanirun bí a kò bá lòó déédé.

Ẹ pa ìbálòpọ̀ àti àwọn ìmọ̀lára ìbálòpọ̀ mọ́ ní mímọ́. Wọn kò gbọdọ̀ mú kí ó jẹ́ ẹ̀kọ́ àpárá tàbí ìdánilárayá. Ní òde ìgbeyàwó ní àárín ọkùnrin àti obìnrin kan, ó jẹ́ àṣìṣe láti fọwọ́kan ibi-ìkọ̀kọ̀, apákan mímọ́ ti ara ẹlòmíràn, àní bí ó bá tilẹ̀ wọṣọ. Nínú àwọn yíyàn yín nípa ohun tí ẹ̀ nṣe, wò, ka, fetísílẹ̀ sí, ronú nípa, lẹ̀, tàbí tẹ̀kọ, ẹ yẹra fún ohunkóhun tí ó nmọ̀ọ́mọ̀ mú ìdìde àwọn ẹ̀dùn-ọkàn àdánù nínú àwọn ẹlòmíràn tàbí ara yín wá. Èyí pẹ̀lú ìwà èérí ní ọ̀nà eyikeyi. Bí ó bá ri pé àwọn ipò náà tàbí àwọn ìṣe ṣíṣe nmú àwọn àdánwò lílejù wá, yẹra fún wọn. Ẹ mọ̀ ohun tí àwọn ipò wọ̀nyí àti àwọn ṣíṣe jẹ́. Àti pé bí ẹ kò bá mọ̀ dájú, Ẹ̀mí náà, ẹbí yín, àti àwọn aṣaájú yín lè ràn yín lọ́wọ́ láti mọ̀. Ẹ fihan Baba yín ní Ọ̀run pé ẹ bu-ọlá àti ọ̀wọ̀ fún agbára mímọ́ láti dá ayé sílẹ̀.

Jésù Krístì nronú àti gbígbáralé orí ọ̀pá rẹ̀

Àwọn ìlérí ìbùkún

Ọ̀wọ̀ yín fún ara yín àti àwọn ẹlòmíràn yíò pọ̀si bí ẹ ti nbu-ọlá fún ara yín nípasẹ̀ ìwà yín, ìrísí, àti ìwọṣọ.

Olúwa ti ṣèlérí àwọn ìṣúra títóbi ti ìmọ̀ fún àwọn ẹni tí wọ́n pa Ọ̀rọ̀ ti Ọgbọ́n mọ́. Ara ìlera, lọfẹ kúrò nínú ìwà bánbákú, bákannáà nmú okun yín láti gba ìfihàn araẹni pọ̀ si, ronú kedere, kí ẹ sì sin Olúwa.

Gbígbé òfin ìmáradúró nmú ìfàṣẹsí Ọlọ́run àti agbára ti ẹ̀mí wá. Ó ndá ààbò bò yín àti ẹbí ọjọ́ ọ̀la yín. Nígbàtí ẹ bá ṣe ìgbeyàwó, òfin yí yíò mú ìfẹ́ títóbijù wá, ìgbẹ́kẹ̀lé, àti ìdàpọ̀ sí ìgbeyàwó yín. Gbígbọ́ran sí òfin yí yíò mu ṣeéṣe fún yín láti ní ìlọsíwájú níti ayérayé kí ẹ sì dàbíi ti Baba yín Ọ̀run. Ìgbẹ́kẹ̀lé yín yíò dàgbà bí ẹ ti ngbé bí ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì.

Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn

Kíni òṣùwọ̀n Olúwa lórí ìwọṣọ, títọ́jú, tàtúùù, àti àwọn ara yíya? Òṣùwọn Olúwa ni fún yín láti bú-ọlá fún jíjẹ́mímọ́ ara yín, àní nígbàtí èyí túmọ̀sí yíyàtọ̀ kúrò ní àwọn ènìyàn míràn. Ẹ jẹ́ kí òtítọ́ àti Ẹ̀mí yí jẹ́ atọ́nà yín bí ẹ ti nṣe àwọn ìpinnu—ní pàtàkì àwọn ìpinnu tí ó ní àbájáde pípẹ́ lórí ara yín. Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóòótọ́, kí ẹ sì wá àmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ẹbí àti àwọn aṣaájú yín.

Báwo ni mo ṣe lè borí àwọn àdánwò àti ìhùwà búburú? Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ní agbára láti ràn yín lọ́wọ́. Ẹ kún ìgbé ayé yín pẹ̀lú àwọn ohun tí ó npe agbára Wọn wá sínú ayé yín, bí irú àdúrà, àṣàrò ìwé mímọ́, àti iṣẹ́ ìsìn sí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ yípadà sí Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀, ẹ ó sì ri pé àwọn àìlera lè di akun. Ẹ wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ẹbí, aṣaájú, àti àwọn olóye olùdámọ̀rán tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé bí a ti nílò. Wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ láti gba àkóso ìgbé ayé yín padà. Ó lè gba àkokò, nítorínáà ẹ ní sùúrù, kí ẹ má sì ṣe sọ ìrètí nù.

Èmi nní ìfàmọ́ra sí àwọn ènìyàn irú ẹ̀yà-irúkannáà. Báwo ni àwọn òṣùwọ̀n wọ̀nyí ṣe wúlò sí mi? Ìmọ̀lára ìfàmọ́ra irú ẹ̀yà-irúkannáà kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀. Bí ẹ bá ní àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí tí ẹ kò sì lépa tàbí ṣe ìṣe lórí wọn, ẹ ngbé òfin mímọ́ ìmáradúró Baba Ọ̀run. Ẹ jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ Ọlọ́run àti ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì. Ẹ rántí pé Olùgbàlà ní òye ohun gbogbo tí ẹ̀ nní ìrírí. Nípasẹ̀ ìsopọ̀ májẹ̀mú yín pẹ̀lú Rẹ̀, ẹ ó rí okun láti gbọ́ran sí àwọn òfin Ọlọ́run kí ẹ sì gba àwọn ìlérí ìbùkún Rẹ̀. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé E àti ìhìnrere Rẹ̀.

A lò mí ní ìlòkulò, mo sì ní ìmọ̀lára ìtìjú. Ṣé mo ní ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀? Rárá. Jíjẹ́ olùpalára ìlòkulò eyikeyi tàbí àrífín kò mú yín jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. Olúgbàlà fẹ́ràn yín. Òun ni okun yín. Ó nfẹ́ láti ràn yín lọ́wọ́, wò yín sàn, kí ó sì fi àlàáfíà fún yín. Àwọn olùdámọ̀ràn olóye tí ó ṣe gbẹ́kẹ̀lé, àwọn ọmọ ẹbí yín, àti àwọn aṣaájú yín bákannáà lè ṣèrànwọ́.

Wo Gẹ́nọ́sísì 1:27 (a wà ní àwòrán Ọlọ́run); Jòhánnù14:18 (Olùgbàlà ṣèlérí ìtùnú); àwọn ará Fílíppì 4:7 (àlàáfíà Ọlọ́run kọjá lílóye); Mòsíàh 2:41 (àwọn ẹni tí ó pa òfin Ọlọ́run mọ́ di alábùkún níti ara àti níti ẹ̀mí blessed temporally and spiritually); Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:15 (ẹ̀mí àti ara jẹ́ ẹ̀mí); 89 (Ọ̀rọ̀ ti Ọgbọ́n); 121:45 (àwọn èrò rere ndarí sí ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ síi).

Àwọn Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì

  • Olúwa ti wípé gbogbo àwọn ohun ni a níláti “ṣe nínú ìwẹ̀nùmọ́” níwájú Rẹ̀ (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 42:41 Ṣé ò ntiraka fún ìwà mímọ́ nínú àwọn èrò àti ìwà rẹ?

  • Ṣé ò ngbọ́ran sí àṣẹ ìmáradúró?

  • Ṣé ẹ ní ìmọ̀ tí ẹ sì ngbọ́ran sí Ọ̀rọ̀ ti Ọgbọ́n?