2.
Ọlọ́run nfẹ́ láti báa yín sọ̀rọ̀.
Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere bẹ̀rẹ̀ nígbàtí ọ̀dọ́mọdé tí a pè ní Jósẹ́fù Smith gbàdúrà, Baba Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, sì dá a lóhùn. Ọlọ́run tẹ̀síwájú ní títọ́ Ìjọ Rẹ̀ sọ́nà nípasẹ̀ àwọn wòlíì alààyè. Bákannáà Ó nfẹ́ láti báa yín sọ̀rọ̀, ọmọ Rẹ̀, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Kíkọ́ láti ṣe ìdámọ̀ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe nsọ̀rọ̀ sí yín ni ọ̀kan làra àwọn iṣẹ́ oníyelórí jùlọ tí ẹ lè jèrè.
Àwọn Òtítọ́ Ayérayé
Ẹ̀mí ndarí yín sí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. Èyí ni ojúṣe pàtàkì ti Ẹ̀mí Mímọ́. Òun bákannáà yíò mísí yín láti ronúpìwàdà àti láti tẹ̀lé Jésù Krístì kí ẹ lè gba àwọn ìbùkún ti Ètùtù Rẹ̀. Bí ẹ ṣe nronúpìwàdà, Ẹ̀mí nwẹ̀ yín mọ́ ó sì nràn yín lọ́wọ́ láti yí padà.
Ẹ̀mí Mímọ́ nsọ̀rọ̀ sí inú àti ọkàn yín. Àwọn ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí lè wá sí inú yín ní àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà—nípa àwọn èrò ìmísí, ìkìlọ̀, òye kedere, àti àwọn ìrántí ti ẹ̀mí. Ẹ̀mí Mímọ́ lè sọ̀rọ̀ sí ọkàn yín nípa gbígbé àwọ̀n ìmọ̀lára yín ga bíiti ìtùnú, ìgbẹ́kẹ̀lé, àlàáfíà, ìfẹ́, ayọ̀, ìrẹ̀lẹ̀, ìmoore, àti sùúrù.
Àwọn ìfipè
“Gba Ẹ̀mí Mímọ́.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a sọ nígbàtí a bá fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ bí ọmọ Ìjọ Krístì. Báwo ni ẹ ṣe gba Ẹ̀mí Mímọ́? Nípa gbígbọ́ran sí àwọn Ìkọ́ni ti Jésù Krístì. Òun ni okun yín. Títẹ́lé E npe Ẹ̀mí Mímọ́ wá sínú ayé yín.
Ẹ wá Baba Ọ̀run nínú àdúrà yín. Ẹ tú ọkàn yín jáde sí I. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún ìyanu tí Ó ti fi fún yín. Ẹ pín ayọ̀, ìdàmú, àti ìbèèrè yín pẹ̀lú Rẹ̀. Ẹ dúró jẹ́ kí ẹ sì fetísílẹ̀ fún àwọn ìdáhùn Rẹ̀, èyí tí ó lè wá bí ìmọ̀lára àlàáfíà, èrò nínú yín, tàbí ìwọ̀lọ́kàn láti ṣe ohunkan.
Ẹ gbọ́ ohùn Ọlọ́run nínú àwọn ìwé mímọ́. Àwọn ìwé mímọ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí yín! Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ látinú wọn lójojúmọ́ láti rí ohùn Rẹ̀ kí ẹ sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀. Bí ẹ ti nkàá, ẹ ronújinlẹ̀ ohun tí Ó lè máa kọ́ yín, kí ẹ sì kọ àwọn ìwọ̀lọ́kàn tí ó wá sílẹ̀. Ẹ mu ṣe ìhùwà ojojúmọ́ láti ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́—nípàtàkì Ìwé ti Mọ́mọ́nì—ní gbogbo ayé yín.
Ẹ ṣe ìṣe lórí ìwọ̀lọ́kàn ti ẹ̀mí tí ẹ gbà. Bí ẹ bá ní èrò tàbí ìwọ̀lọ́kàn láti ṣe ohun rere kan tí yíò bùkún ẹnìkan, ṣe é! Gbogbo ohun rere nwá làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ẹ fi hàn Baba yín Ọ̀run pé Òun lè gbẹ́kẹ̀lé yín láti tẹ̀lé àwọn ìwọ̀lọ́kàn láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Àwọn Ìlérí Ìbùkún
Ẹ̀mí Mímọ́ yíò tù nínú yíò sì tọ́ yín sọ́nà. Òun ni a mọ̀ bí Olùtùnú. Òun yíò tì yín lẹ́hìn ní àwọn àkokò àdánwò! Òun yíò ràn yín lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ẹ ó sọ tàbí ṣe. Pẹ̀lú ipá Rẹ̀, ẹ lè sọ ìyàtọ̀ ní àárín ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ àti ohun tí ó jẹ́ irọ́. Ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti rí rerenínú àwọn ẹlòmírán àti nínú arayín. Bákannáà Ẹ̀mí lè kìlọ̀ fún yín nípa ewu. Òun yíò ṣe atọ́nà yín síwájú Jésù Krístì àti kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
Ẹ lè gba àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí. Àwọn ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn wà tí Ọlọ́run nfi fún àwọn ọmọ Rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí Rẹ̀. Àwọn kan mẹ́nubàá nínú àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú ìfihàn, gbígbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, kíkọ́ni, níní òye, àti ọgbọ́n. Ẹ gbàdúrà láti bèèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run nípa àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí tí Òun ti fi fún yín, bí ẹ ṣe lè gbèrú wọn, àti bí Òun ṣe fẹ́ kí ẹ lò wọ́n láti bùkún àwọn ẹlòmíràn.
Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn
Kínìdí tí àwọn ènìyàn míràn ṣe ní àwọn ìrírí ti ẹ̀mí títóbijù bí èmi ti ṣe? Kìí ṣe gbogbo àwọn ìrírí ti ẹ̀mí jẹ́ ìyanilẹ́nu tàbí wíwúnilórí. Ní ọ̀pọ̀ ígbà, Ọlọ́run nbá wa sọ̀rọ̀ nípa àwọn èrò sí inú wa tàbí ìmọ̀lára jẹ́jẹ́ sí ọkàn wa. Ìwọ̀nyí ni ìkùnsínilétí píparọ́rọ́ ti ohùn jẹ́jẹ́, kékeré. Ẹ lè máa ní ìmọ̀lára ti Ẹ̀mí tí ẹ kò sì ní ìdámọ̀ rẹ̀ síbẹ̀. Ẹ tẹramọ́ gbígbàdúrà. Ẹ tẹramọ́ ṣíṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Pẹ̀lú àkokò àti ìgbáradì, ẹ yíò kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe ìdámọ̀ Ẹ̀mí nínú onírúurú àwọn ọ̀nà.
Wo 1 Àwọn Ọba 19:11–12 (Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nínú ohùn kẹ́lẹ́, kékeré); Jòhánnù 15:26 (Ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀rí Krístì); Mórónì 10:3–5 (mọ òtítọ́ nípa Ẹ̀mí); Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 11:12–13 (Ẹ̀mí ndarí láti ṣe rere); 45:57 (gba Ẹ̀mí bí atọ́nà rẹ); 46:8–26 (àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí).
Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì
-
Ṣe ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àti ẹ̀rí kan nípa Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé; Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì; àti Ẹ̀mí Mímọ́?