àwọn ọ̀dọ́
8. Àwọn ìlànà àti májẹ̀mú tẹ́mpìlì nfún yín ní ààyè títóbijù sí àwọn ìbùkún Ọlọ́run.


Jésù Krístì joko Ó sì nkọ́ àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀

8.

Àwọn ìlànà àti májẹ̀mú tẹ́mpìlì nfún yín ní ààyè títóbijù sí àwọn ìbùkún Ọlọ́run.

Ẹ̀kọ́ ati àwọn Májẹ̀mú 95:8

Àwọn kan lára ìbùkún Baba Ọ̀run jẹ́ mímọ́ gan, Ó ti pàṣẹ fún wa láti gbé, ibi mímọ́ pàtàkì sẹgbẹ níbití a ti lè gbà wọ́n: tẹ́mpìlì. Nínú tẹ́mpìlì, ilé Olúwa, ẹ lè gba àwọn ìlànà gígajùlọ Rẹ̀—ẹ̀bùn tẹ́mpìlì àti èdìdi—àti láti gba àwọn ìlérí títóbijù Rẹ̀.

Àwọn Òtítọ́ Ayérayé

Ẹ̀bùn tẹ́mpìlì ni ẹ̀bùn ti ìmọ̀ àti agbára kan. Nínú àwọn ìlànà ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, ẹ gbé orúkọ Olùgbàlà lé ara yín síi ní kíkún. Májẹ̀mú yín láti gbọ́ran sí Ọlọ́run, ìrúbọ láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, gbé ìhìnrere Jésù Krístì, gbọ́ràn sí òfin ìmáradúró, àti ìyàsọ́tọ̀—tàbí ìyàsímímọ́—ayè yín àti gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti fún yín sí Ìjọ Rẹ̀. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlérí yín. Àwọn ìlérí Ọlọ́run láti bùkún yín pẹ̀lú ìmọ̀ títóbijù, ààbò, àti ààyè sí agbára Rẹ̀. Bákannáà Ó ṣe àwọn ìlérí láti fún yín ní ìyè ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀. Bí ara ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, ẹ gba ànfàní mímọ́ ti wíwọ ẹ̀wù oyè àlùfáà mímọ́. Ẹ̀wù ni àmì kan nípa Jésù Krístì àti ìrántí kan nípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì yín

Èdìdi tẹ́mpìlì nda tọkọtaya àti ẹbí pọ̀ fún àìlópin. Nínú ìlànà èdìdi tẹ́mpìlì, ẹ̀yin àti tọkọtaya yín yíò dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run àti pẹ̀lú ara yín. Ẹ ó ṣe ìlérí láti jẹ́ olóòtítọ́ tán pátápátá sí Ọlọ́run àti sí ara wa, láti ní ìfẹ́ àti láti sin ara wa, àti láti ṣiṣẹ́ papọ̀ láti pa àwọn òfin Ọlọ́run. Èyí ni ìlérí yín. Ọlọ́run ṣe àwọn ìlérí pé ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú lọ́kọláyà yín àti pẹ̀lú àwọn ọmọ yín lè wà títíláé. Bákannáà Ó ṣe àwọn ìlérí pé ẹ lè gba ògo gígajùlọ pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ìjọba Sẹ̀lẹ́stíà bí ẹ ṣe npa àwọn májẹ̀mú yín mọ́. Ìbùkún yí ni à npè ní ìgbéga.

Àwọn ìfipè

Ẹ ní ìkaniyẹ tẹ́mpìlì kan nígbàgbogbo. Pàdé pẹ̀lú ọmọ bìṣọ́príkì kan láti gba ọ̀kan. Òun yíò bèèrè àwọn ìbèèrè lọ́wọ́ yín nípa bí ẹ̀yin ṣe ngbé òṣùwọ̀n Olúwa fún wíwọ ilé mímọ́ Rẹ̀. Àtúnyẹ̀wò àwọn ìbèèrè wọ̀nyí léraléra. (Ẹ lè rí wọn nínú àlẹ̀mọ́ sí atọ́nà yí.) Àní bí ẹ gbé jìnnà kúrò ní tẹ́mpìlì, ẹ jẹ́ kí ìkaniyẹ tẹ́mpìlì yín jẹ́ àmì ìfẹ́ yín fún Olúwa àti ìfarajì yín láti gbé o`ṣùwọ̀n Rẹ̀.

Ẹ lọ sí tẹ́mpìlì léraléra bí ẹ ti lè ṣe. Pẹ̀lú ìkaniyẹ tẹ́mpìlì yín, ẹ lè wọnú ilé Olúwa tí a sì ṣe ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ fún àwọn babanlá yín, kí wọ́n lè gba àwọn ìbùkún tí a ti fún yín. Ẹ gba ìfà gbogbo ànfàní láti wà nínú tẹ́mpìlì. Ẹ Wá Olúwa nínú ilé mímọ́ Rẹ̀. Ẹ wá A nínú àwọn ìlànà, àmì, àti Ẹ̀mí tí ẹ̀ nní ìmọ̀lára rẹ̀. Ẹ ó rí I.

Múrasílẹ̀ láti dá àwọn májẹ̀mú nínú ilé Olúwa. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà dídárajùlọ láti ṣe èyí ni láti pa májẹ̀mú ti ìrìbọmi yín mọ́. Ẹ mu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlépa títọ́nisọ́nà láti gba àwọn ìlànà tẹ́mpìlì àti láti jẹ́ olùpamọ́ májẹ̀mú ayé-pípẹ́. Ẹ bẹ̀rẹ̀ nísisìyí láti gbé àwọn òfin tí ẹ ṣe ìlérí láti gbọ́ràn sí nínú tẹ́mpìlì: ìgbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run, ìrúbọ, ìhìnrere Jésù Krístì, ìmáradúró, àti yíyàsọ́tọ̀. Ẹbí yín, bísọ́ọ̀pù, àti àwọn aṣaájú Ìjọ míràn lè ràn yín lọ́wọ́.

Tẹ́mpìlì Tegucigalpa Honduras

Àwọn ìlérí ìbùkún

Ẹ lè dàbíiti Jésù Krístì síi. Òun yíò ràn yín lọ́wọ́ láti di ọmọlẹ́hìn títóbijù òdodo. Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì àti àwọn májẹ̀mú yíò kọ́ yín bí ẹ ó ṣe wọ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kí ẹ sì gba ìyè ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀.

Ẹ ó d ríró pẹ̀lú agbára Ọlọ́run. Àwọn májẹ̀mú Tẹ́mpìlì wá pẹ̀lú ìlérí pé agbára àti ògo Ọlọ́run yíò wà lórí yín. Àwọn ángẹ́lì Rẹ̀ yíò ṣe ìṣọ́ lórí yín.

Àkokò nínú tẹ́mpìlì yíò so yín mọ́ Jésù Krístì àti Ẹ̀mí Mímọ́ típẹ́típẹ́. Ẹ yíò ní ìmọ̀lára àlàáfíà àti ìsinmi Ọlọ́run. Ẹ yíò gbọ́ ohùn Rẹ̀ pẹ̀lú híhànjù kedere. Àwọn ọ̀run yíò ṣí síi yín, ẹ yíò sì ní òye dídára sí àwọn ọ̀nà Rẹ̀. Ẹ yíò ní okun títóbijù láti kojú àwọn ìpènijà yín nítorí ọkàn yín sopọ̀ mọ́ Tirẹ̀.

Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn

Nígbàwo ni mo lè gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì? Ìpinnu láti gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì yín jẹ́ ti araẹni; ẹ ṣe ìpinnu yí pẹ̀lú àdúrà. Ẹ dámọ̀ràn pẹ̀lú ẹbí àti àwọn aṣaájú yín. Láti gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, ẹ nílò láti jẹ́ bíi ọmọ ọdún méjìdínlógún tí kò sí ní ilé ìwé gíga mọ́ tàbí ilé ìwé sẹ́kọ́ndìrì. Ẹ ó gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì ṣíwájú sísìn ní míṣọ̀n kan tàbí jíjẹ́ fífi èdìdi dì, ṣùgbọ́n ẹ kò níláti dúró fún eyikeyi lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣíwájú gbígba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì. Ẹ kàn nílò ìfẹ́ inú àti ìmúrasílẹ̀ láti dá àti láti pa àfikún àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Baba yín Ọ̀run. Bíṣọ́ọ̀pù tàbí ààrẹ ẹ̀ka yín lè ràn yín lọ́wọ́ láti mọ̀ bí ẹ bá ti múrasílẹ̀. Ẹ máṣe rí ẹ̀bùn tẹ́mpìlì bí iṣẹ́ lórí ìfàmìsí ayérayé kan. Wò ó bí ara ìrìnàjò ẹlẹ́wà àti ológo ayérayé yín láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì àti láti gba àwọn ìbùkún títóbijùlọ ti ẹ̀mí Ọlọ́run.

Kínìdí tí mo fi nílò ìkaniyẹ tẹ́mpìlì kan láti wọ inú tẹ́mpìlì? Tẹ́mpìlì ni ilé Olúwa, Òun sì tì gbé àwọn òṣùwọ̀n kalẹ̀ fún wíwọnú rẹ̀. Àwọn ìlànà àti májẹ̀mú tẹ́mpìlì jẹ́ mímọ́ gan tí wọ́n fi bèèrè fún ìmúrasílẹ̀ pàtàkì ti ẹ̀mí. Ìfọ̀rọ̀wànilẹ́nuwò ìkaniyẹ tẹ́mpìlì ní ó jẹ́ láti mu dájú pé ẹ ti múrasílẹ̀ níti ẹ̀mí fún àwọn ànfàní gígajù ti àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì. Baba Ọ̀run npe gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ láti múrasílẹ̀ láti ṣe àwọn ìlérí pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ilé mímọ́ Rẹ̀.

Njẹ́ èmi nílò láti jẹ́ pípé láti dá àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì? Kò sí ẹni pípé. Ọlọ́run ní kí ẹ jẹ́ olóòótọ́ kí ẹ sì ní ìfẹ́ láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni ohun tí ó nfún yín ní agbára láti di pípé nípasẹ̀ Jésù Krístì. Òun ni okun yín.

Wo Ìsàíàh 2:2–3 (Ọlọ́run nkọ́ wa ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀ nínú tẹ́mpìlì); Máttéù 11:28–30 (ẹ gbé àjàgà Olùgbàlà lé orí yín); 1 Néfì 14:14 (agbára Ọlọ́run wà lórí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀); Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 97:15–16 (Wíwà ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ògo Rẹ̀ wà ní inú ilé Rẹ̀); 109:22 (nínú tẹ́mpìlì a` ndi ríró pẹ̀lú agbára Ọlọ́run); 131:1–4; 132:4–6, 15–20 (láti gba ìyè ayérayé, ọkùnrin àti obìnrin kan gbọ́dọ̀ jẹ́ fífi èdìdi dì fún àìlópin nípasẹ̀ májẹ̀mú titun àti ayérayé); Ábráhámù 1:2 (Ábráhámù nfẹ́ láti jẹ́ ọmọlẹ́hìn olódodo títóbijù kí a sì gba ìmọ̀ títóbijù).

Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì

  • Ṣé ẹ ká ara yín yẹ láti wọnú ilé Olúwa àti láti kópa nínú àwọn ìlànà tẹ́mpìlì?