àwọn ọ̀dọ́
4. Jésù Krístì yíò ràn yín lọ́wọ́


Jésù Krístì

4.

Jésù Krístì yíò ràn yín lọ́wọ́

Orin Dáfídì 147:3

Jésù Krístì ni okun wa! Ó ti ṣe ohun gbogbo tí ó ṣeéṣe fún yín láti ní ayọ̀ nínú ayé yí àti títíláé. Nípa yíyàn Án àti ìhìnrere Rẹ̀, ẹ nyan ìdùnnú àti ayọ̀ ayérayé.

Àní nígbàtí ẹ̀ ngbìyànjú láti ṣe dídárajùlọ yín láti ṣe àwọn yíyàn rere, nígbàmíràn ẹ ó ṣe àwọn àṣìṣe. Ẹ yíò ṣe àwọn ohun tí ẹ kò tíì ṣe. Gbogbo ènìyàn nṣeé. Nígbàtí èyí nṣẹlẹ̀, ó rọrùn láti ní ìmọ̀lára ìjákulẹ̀ tàbí ní ìyàlẹ́nu bí ẹ ó bá dára tó. Ṣùgbọ́n ìròhìn ìyanilẹ́nu—rere, ìròhìn onírètí wà! Nítorí Ọlọ́run ní ìfẹ́ yín, Ó rán Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ẹnití ó gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín lé orí Ararẹ̀ kí ẹ lè ronúpìwàdà, gba ìdáríjì, kí ẹ sì tẹramọ́ níní ìlọsíwájú.

Àwọn Òtítọ́ Ayérayé

Jésù Krístì yíò fún yín lókun. Òun yíò ràn yín lọ́wọ́ láti yí ìfẹ́ inú yín padà, àwọn èrò yín, àti àwọn ìṣe yín. Nígbàtí ẹ ní ìdàmú, ẹ̀rù, tàbí lílàkàkà ní ọ̀nà eyikeyi, Òun yíò tù yín nínú. Òun yíò ràn yín lọ́wọ́ nínú gbogbo ìgbìrò ayé yín. Ẹ lè gbẹ́kẹ̀lé E.

Ìronúpìwàdà kìí ṣe ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀; ó jẹ́ ọ̀nà tí Olùgbàlà fi fún wa ní òmìnira kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Láti ronúpìwàdà túmọ̀ sí láti yípadà―láti yà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó túmọ̀ sí láti dára si kí à sì gba ìdáríjì. Irú ìyípadà yí kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ àkokò-kan; ó jẹ́ ìlànà tí ó nlọ lọ́wọ́.

Àwọn ìfipè

Ẹ fi Krístì ṣe ìdojúkọ ìgbé ayé yín. Ẹ wá ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ẹ̀ nṣe.

Ẹ ronúpìwàdà. Ẹ yípadà sí Olúwa pẹ̀lú ìfẹ́ inú láti dára síi. Nígbàtí ẹ bá ṣe ohun àṣìṣe kan, pẹ̀lú ìṣòtítọ́ ti ẹ gbà á níwájú Ọlọ́run àti, bí a ti nílò, sí bíṣọ́ọ̀pù yín àti ẹnikẹ́ni tí ẹ lè ti palára. Ẹ ṣe dídárajùlọ yín láti mú àwọn ohun tọ́.

Ẹ yọ̀ nínú ẹ̀bùn láti ṣe dídárajù àti di dídárajù. Àní nígbàtí kò rọrùn tí ó sì ngba ìgbà pípẹ́ ju bí ẹ ti fẹ́, ẹ máṣe dáwọ́dúró ní gbígbìyànjú láé. Ẹ tẹramọ́ ṣíṣe iṣẹ́ àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa. Òun yíò ràn yín lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbésẹ̀ ojú ọ̀nà náà.

Jésù joko níbi kànga pẹ̀lú obìnrin Samáríà

Àwọn ìlérí ìbùkún

Baba Ọ̀run yíò dáríjì yíò sì wò yín sàn bí ẹ bá ronúpìwàdà. Òun yíò rọ́pò ẹ̀bi yín pẹ̀lú àlàáfíà àti ayọ̀. Òun kì yíò rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́. Jésù Krístì ni okun yín, àti pẹ̀lú okun Rẹ̀, ìfẹ́ inú yín láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ yíò pọ̀ si.

Òun yíò yí ọkàn yín àti ìgbésí ayé yín padà. Ní díẹ̀ díẹ̀, ẹ ó dàgbà ẹ ó sì dà bíi Tirẹ̀ síi.

Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn

Báwo ni èmi ó ṣe mọ̀ bí Ọlọ́run ti dáríjì mí? Ọlọ́run ṣe ìlérí pé Òun yíò dáríji àwọn tí ó ronúpìwàdà. Nígbàtí ẹ bá ní ìmọ̀lára ìtùnú láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí, ẹ lè mọ̀ pé agbára ìràpadà ti Olùgbàlà nṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé yín.

Nígbàwo ni èmi ó nílò ìrànlọ́wọ́ ti bíṣọ́ọ̀pù láti ronúpìwàdà? Bíṣọ́ọ̀pù yín di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà mú ó sì ní àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí láti ràn yín lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà. Ẹ lè wá ìrànlọ́wọ́ àti àmọ̀ràn rẹ̀ ní ìgbàkugbà. Bí ẹ bá ṣe àwọn àṣìṣe líle, bí irú rírú òfin ìmáradúró, pàdé pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù yín. Òun kò ní dá a yín lẹ́bi. Ó jẹ́ aṣojú Jésù Krístì yíò sì ràn yín lọ́wọ́ láti mọ̀ bí ẹ ó ti ronúpìwàdà ní kíkún àti láti gba ìwòsàn Olùgbàlà àti agbára ìfúnnilókun.

Èmi ngbìyànjú láti ronúpìwàdà, ṣùgbọ́n mo ntẹramọ́ ṣíṣe irú àṣìṣe kannáà. Kíni mo ní láti ṣe? Máṣe sọ ìrètí nù. Ẹ yípadà sí Krístì, kí ẹ sì fi ìgbàgbọ́ yín sínú Rẹ̀. Ore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ tó. Gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansi. Ẹ kò dánìkan wà nínú ìtiraka wa láti ní ìlọsíwájú. Jésù Krístì nwà pẹ̀lú yín nígbàgbogbo.

Wo Énọ́sì 1:6 (a lè gbá ẹ̀bi kúrò); Mòsíàh 4:3 (nípa Ẹ̀mí Mímọ́, Ọlọ́run njẹ́ kí ẹ mọ̀ pé a dáríjì yín); 26:30 (Olùgbàlà ndáríjì léraléra bí a ti nronúpìwàdà); Étérì 12:27 (oore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlàlè mú àwọn ohun àìlera di alágbára); Mórónì 6:8 (àwọn tí ó ronúpìwàdà ni a dáríjì); 10:32 (di pípé nínú Krístì); Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 1:32 (Olúwa ndáríji àwọn tí ó ronúpìwàdà); 58:42–43 (ìrònúpìwàdà pẹ̀lú jíjẹ́wọ́ àti pípa ẹ̀ṣẹ̀ tì).

Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì

  • Ṣé ẹ ní ẹ̀rí Ètùtù Jésù Krístì àti ojúṣe Rẹ̀ bí Olùgbàlà àti Olùràpadà yín?

  • Njẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ líle kan wà nínú ayé yín tí ẹ nílò láti ṣàtúnṣe pẹ̀lú àwọn aláṣẹ oyèàlùfáà bí apákan ìrònúpìwàdà yín?