“Oṣù Karun 25–31. ‘Olúwa Gbé Olùdándè kàn Dìde’: Àwọn Onídàájọ́ 2–4; 6-8; 13–16,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Karun 25–31. ‘Olúwa Gbé Olùdándè kàn Dìder,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026
“Dájúdájú Èmi Yíò Tẹ̀lé Ọ”—Dèbórà Wòlíì Obìnrin, láti ọwọ́ Des Leavitt
Oṣù Karun 25–31: “Olúwa Gbé Olùdándè kàn Dìde”
Àwọn Onídàájọ́ 2–4; 6–8; 13–16
Gbogbo wa mọ bí ó ti rí láti ṣẹ̀, ní ìmọ̀lára búburú nípa rẹ̀, àti nígbànáà kí a ronúpìwàdà kí a sì pinnu láti yí àwọn ọ̀nà wa padà. Ṣùgbọ́n nígbàkugbà pẹ̀lú a ngbàgbé ṣíṣetán ìṣíwájú, àti, nígbàtí ìdánwò bá wá, à nrí ara wa ní dídá ẹ̀ṣẹ̀ kannáà. Àwòṣe yí hàn lemọ́lemọ́ nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́. Ní ipa nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti ìjọsìn ìṣe àwọn ará Kénáánì—àwọn tí ó yẹ kí a lé kúrò ní ilẹ̀ náà—àwọn ará Ísráẹ́lì já àwọn májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Olúwa wọ́n sì yípadà kúrò ní jíjọ́sìn Rẹ̀. Gẹ́gẹ́bí àbájáde, wọ́n sọ ààbò Rẹ̀ nù wọ́n sì ṣubú sínú ìgbèkùn. Àti pé síbẹ̀ ìgbà kọ̀ọ̀kan tí èyí bá ṣẹlẹ̀, Olúwa fún a`wọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀ ní ààyè láti ronúpìwàdà tí yíò sì gbé olùdándè kan dide, olórí ológun tí a npè ní “onídàájọ́.” Kìí ṣe gbogbo àwọn Onídàájọ́ ló jẹ́ olódodo, ṣùgbọ́n àwọn kan lára wọn lo ìgbàgbọ́ títóbi ní gbígba àwọn ọmọ Ísráẹ́lì sílẹ̀ àti mímú wọn padà sípò sí ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Olúwa. Àwọn ìtàn wọ̀nyí rán wa létí pé ohun èyíówù tí ó ti darí wa kúrò lọ́dọ̀ Jésù Krístì, Òun ni Olùràpadà Ísráẹ́lì Ó sì nfi ìgbàgbogbo gbà wá sílẹ̀ kí ó sì kí wa káàbọ̀ padà bí a ṣe npadàwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Fún àkópọ̀ ti ìwé àwọn Onídàájọ́, wo “Ìwé ti, Àwọn Onídàájọ́” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.
Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ
Àwọn Onídàájọ́ 2:1–19; 3:5–12
Olúwa ndáríjì léraléra bí mo ti nronúpìwàdà.
Ìwé Àwọn Onídàájọ́ lè jẹ́ méjèèjì ti ìkìlọ̀ àti ìgbani-níyànjú. Ẹ wá ìkìlọ̀ yí àti ìgbàni-níyànjú bí ẹ ti nka Àwọn Onídàájọ́ 2:1–19; 3:5–12. Báwo ni ẹ ṣe ní ìmọ̀lára pé ìkìlọ̀ náà àti ìgbàni-níyànjú wúlò sí yín?
Fún àpẹrẹ, bí Àwọn Onídàájọ́ 2:19 bá jẹ́ nípa yín àti àwọn ìdánwò yín sànju nípa àwọn ará Ísráẹ́lì àtijọ́, kínni ó lè sọ? Bí Àwọn Onídàájọ́ 3:9 bá jẹ́ nípa ohun tí Olúwa ti ṣe láti gbà yín sílẹ̀, kínni ó lè sọ?
Ẹ yẹ kíka ìbèèrè àti ìdáhùn ní ojú-ewé 9 ti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn. Báwo ni ẹ ṣe ní ìmọ̀lára pé èyí wúlò sí ìrírí àwọn ará Ísráẹ́lì nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́? Kínni èyí kọ́ yín nípa Jésù Krístì?
Àwọn Onídàájọ́ 4:1–15
Mo lè mísí àwọn ẹlòmíràn láti ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa.
Nígbàmíràn ìgbàgbọ́ ẹnìkan lè mísí ìgbàgbọ́ nínú ọ̀pọ̀lọpọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nínú Àwọn Onídàájọ́ 4, pé ẹnìkan ni Dèbórà. Ẹ kà nípa rẹ̀ nínú Àwọn Onídàájọ́ 4:1–15, kí ẹ sì kíyèsí ipa tí ó ní lórí àwọn ènìyàn ní àyíká rẹ̀. Ní ìhìn ni àwọn ìbèèrè láti ràn yín lọ́wọ́ láti yẹ bí ìrírí rẹ ti lè wúlò sí ayé yín:
-
Báwo ni ẹ̀yin ó ti júwe ipò tí àwọn ará Ísráẹ́lì wà ní àkokò náà? (wo àwọn ẹsẹ 1–3). Kínni àwọn ìjọra tí ẹ rí sí àwọn ipò ní òní—nínú àwọn olúkúlùkù àti àwùjọ?
-
Àwọn ọ̀rọ̀ wo tàbí ìṣe ti Dèbórà ni ó fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa? Báwo ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe ní ipa lórí àwọn ẹlòmíràn? Ohun míràn wo ni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa rẹ̀?
-
Kínni ẹ rò pé Dèbórà nsọ nípa ìbèèrè rẹ̀ nínú ẹsẹ 14: “Ṣe Olúwa kò ha ti jáde lọ ṣaájú rẹ bí?” Báwo ni Olúwa “ti njáde lọ ṣaájú” yín? (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 84:87–88).
Ẹ jíròrò bí ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì ṣe lè bùkún àwọn ẹlòmíràn ní ọ̀nà tí ìgbàgbọ́ Dèbórà fi bùkú Bárákì àti àwọn ará Ísráẹ́lì míràn. Láti ràn yín lọ́wọ́ láti ronú nípa èyí ẹ lè ṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Elder Neil L. Andersen “A Sọ̀rọ̀ Nípa Krístì” (Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2020, 88–91). Ẹ ṣe ìwákiri ọ̀rọ fún (1) àwọn èrèdí láti sọ̀rọ̀ ní gbàngbà síí nípa Olùgbàlà àti (2) àwọn ọ̀nà láti ṣe é.
Lẹ́hìnnáà ẹ lè ṣe ìtòsílẹ̀ àwọn ohun tí ẹ mọ̀ nípa Jésù Krístì—láti inú àwọn ìwé mímọ́, láti inú.àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè, àti láti inú ìrírí ara ẹni yín. Tani ó nílò láti mọ èyí? Báwo ni ẹ ó ti pín in?
Bákannáà wo Matteu 5:14–16; 1 Pétérù 3:15; “Ìgbé-ayé Kọ̀ọ̀kan tí ó fi Ọwọ́ Kàn Tiwa fún Rere,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 293.
Ẹ pè fún pípín. Bí ẹ bá jẹ́ olùkọ́—ní ilé àti ìjọ—“ẹ fún àwọn akẹkọ ní ànfààní láti pín ohun tí wọ́n kọ́ nípa Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ̀ pẹ̀lú ara wọn. Ṣíṣe èyí yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi àwọn òtítọ́ náà tí a kọ́ sínú àti láti fi wọ́n hàn” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,26). Fún àpẹrẹ, nígbàtí a bá nṣe àṣàrò Àwọn Onídàájọ́ 4 papọ̀, ẹ lè fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akẹkọ ní ohun kan pàtó làti wá nínú orí náà àti lẹ́hìnnáà kí ẹ pè wọ́n láti pín ohun tí wọ́n rí pẹ̀lú ara wọn.
Àwọn Onídàájọ́ 6– 8
Olúwa lè ṣe iṣẹ́ ìyanu nígbàtí mo bá ní ìgbẹ́kẹlé nínú àwọn ọ̀nà Rẹ̀.
Bí ẹ ti nka Àwọn Onídàájọ́ 6–8, ẹ ṣe àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ti àwọn àpẹrẹ níbití Olúwa ti ní kí Gídéónì gbàgbọ́ nínú ohunkan tí o´ lè dàbí àìṣeéṣe. Ṣe Ó ti bèèrè ohunkan jíjọra lọ́wọ́ yín rí?
Kínni ẹ rò pé Olúwa ngbìyànjú láti kọ́ yín pẹ̀lú àkọsílẹ̀ yí? Báwo ni ẹ ti ri tí Olúwa nṣe iṣẹ́ Rẹ̀ ní àwọn ọ̀nà tí ó dàbí kó ṣeéṣe?
Àwọn Onídàájọ́ 13– 16
Ọlọ́run ó fún mi lókun bí èmi bá jẹ́ olóòótọ́ sí àwọn májẹ̀mú mi.
Sámsónì ju méjèèjì okun ti ara rẹ̀ àti okun ti ẹ̀mí rẹ̀ sọnù nítorí ó ṣẹ̀ sí àwọn májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, wo Númérì 6:1–6; Àwọn Onídàájọ́ 13:7). Bí ẹ ti nkà nípa Sámsónì nínú Àwọn Onídàájọ́ 13–16, ẹ kíyèsí àwọn ẹsẹ tí ó fihàn pé Olúwa wà pẹ̀lú Sámsónì, bákannáà bí àwọn ẹsẹ tí ó fihàn pé Sámsónì kò farajìn ní kíkún sí Olúwa.
Ẹ lè jíròrò àwọn májẹ̀mú tí ẹ ti dá pẹ̀lú Olúwa bákanáà. Báwo ni àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí ṣe mú agbára Rẹ̀ wá sínú ayé yín? Kínni ẹ kọ́ láti inú ìrírí Sámsónì tí ó mísí yín láti dúró nítòótọ́ sí àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Ọlọ́run.
Arábìnrin Ann M. Dibb kọ́ni: “Sámsónì ni a bí pẹ̀lú agbára ìlèṣe nlá. A ṣe ìlérí fún ìyá rẹ̀, ‘Òun ó bẹ̀rẹ̀sí gba Ísráẹ́lì ní ọwọ́ àwọn Filístínì [Àwọn Onídàájọ́ 13:5]. Ṣùgbọ́n bí Sámsónì ti dàgbà, ó wo àwọn ìdánwò ayé síi jù sí ìdarí Ọlọ́run lọ. Ó ṣe àwọn àṣàyà nítorí ‘ó wù [ú] gidigidi’ [Àwọn Onídàájọ́ 14:3] sànju nítorí pé àwọn àṣàyàn wọnnì jẹ́ títọ́. Léraléra, àwọn ìwé mímọ́ lo gbólóhùn ọ̀rọ̀ ‘ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ’ [Àwọn Onídàájọ́ 14:7] bí wọ́n ṣe sọ nípa ìrìnàjò, ìṣe, àti àwọn àṣàyàn. Dípò dídìde àti títàn jáde láti mú agbára ìlèṣe nlá rẹ̀ ṣẹ, Sámsónì ni a ṣẹ́gun nípa ayé, ó sọ agbára tí Ọlọ́run fun nù, ó sì kú ikú oró, ikú kùtùkùtù” (“Ẹ Dìde kí ẹ sì Tàn Jáde,” Làìhónà, Oṣù Karun 2012, 118).
Bákannáà wo Dallin H. Oaks, “Àwọn Májẹ̀mú àti Ojúṣe,” Làìhónà, Oṣù Karun 2024, 93–96; Ulisses Soares, “Májẹ̀mú Ìgbẹ́kẹ̀lé nípasẹ̀ Jésù Krístì,” Làìhónà, Oṣù Karun 2024, 17–21.
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Nítorí Ọjọ́ Ìsinmi yí ni Ọjọ́ Ìsinmi àkọ́kọ́ oṣù, àwọn olùkọ́ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni a gbà níyànjú láti lo àwọn iṣẹ́ ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú “Àfikún B: Mímúra àwọn Ọmọdé Sílẹ̀ fún Ìgbé Ayé Lórí Ipa Ọ̀nà Májẹ̀mú Ọlọ́run.”
Àwọn Onídàájọ́ 3; 7–9, 12–15
Jésù Krístì ni Olùdándè mi.
-
Àwọn Onídàájọ́ 3 júwe àwòṣe kan tí ó kọ́ni nípa agbára Olùgbàlà láti gbà wá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Láti ràn yín lọ́wọ́ láti dá àwóṣe yí mọ̀, ẹ lè kọ àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀: “ṣe ibi,” “kígbe sí Olúwa,” àti “gbé olùdándè dìde.” Lẹ́hìnnáà àwọn ọmọ yín lè wá àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nínú Àwọn Onídàájọ́ 3:7–9 àti Àwọn Onídàájọ́ 3:12–15. Kínni a kọ́ nípa Olúwa láti inú àwòṣe yí?
-
Láti tẹnumọ pé Jésù Krístì ni Olùdándè wa, ẹ lè kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àwòrán ti àwọn ènìyàn jọ, pẹ̀lú àwòrán ti Jésù kan, kí ẹ sì dojú wọn bolẹ̀. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ ṣí àwọn àwòràn náà sókè ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Nígbàtí wọ́n bá rí àwòrán Jésù, kí wọ́n kọ̀ orin kan nípa Rẹ̀, bí irú “Ó Rán Ọmọ Rẹ̀” (Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 34–35), kí ẹ sì sọ fún àwọn ọmọ yín nípa bí Ó ṣe gbà yín sílẹ̀.
Àwọn Onídàájọ́ 4:1–15
Mo lè mísí àwọn ẹlòmíràn láti ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa.
-
Ẹ lè lo “Dèbórà Wòlíì Obìnrin” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 92–95, láti sọ ìtàn náà fún àwọn ọmọ yín nínú Àwọn Onídàájọ́ 4. Ẹ pín ohun tí ẹ fẹ́ràn nípa Dèbórà pẹ̀lú ara yín. Báwo ni ìgbàgbọ́ rẹ nínú Olúwa ṣe bùkún àwọn ènìyàn ní àyíká rẹ̀? Kínni a lè ṣe láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ síi nínú Jésù Krístì?
2:9Deborah the Prophetess
Àwọn Onídàájọ́ 7:1–21
Olúwa lè lo àwọn ohun kékeré láti ṣe iṣẹ́ nlá.
-
Ẹ lo Àwọn Onídàájọ́ 7:4–7, ní ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe ti ọ̀sẹ̀ yí, tàbí “Àwọn Ọmọ Ogun ti Gídéónì” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 96–99, láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa bí Olúwa ti mú àwọn ọmọ ọgun Ísráẹ́lì di kékeré síi. Kínni ìdí tí Olúwa fi fẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Gídéónì di kékeré gidi? (wo Àwọn Onídàájọ́ 7:2).
2:37The Army of Gideon
-
Àwọn ọmọ yín lè ya àwòrán ọ̀kọ̀, igbàyà, fèrè, fìtílà, àti ago omi kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa nkan wọ̀nyí tí wọn yíò fẹ́ nínu ogun. Lẹ́hìnnáà wọ́n lè ka Àwọn Onídàájọ́ 7:16 láti kọ́ ohun tí Olúwa sọ fún àwọn ọmọ ogun Gídéónì láti lò. Bí ẹ ti nkà nípa ogun náà nínú Àwọn Onídàájọ́ 7:19–21, ẹ pín ohun tí ẹ kọ́ nípa Olúwa láti inú ìtàn yí pẹ̀lú ara yín.
Sámsónì Fa àwọn Òpó Lulẹ̀, láti ọwọ́ James Tissot and others
Àwọn Onídàájọ́ 13:5
Pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ nfún mi ní okun.
-
Májẹ̀mú Sámsónì pẹ̀lú Olúwa fún ní okun ti-ara, gẹ́gẹ́bí àwọn májẹ̀mú wa ṣe nfún wa ní okun. Àwọn ọmọ yín lè gbádùn ṣíṣe àwọn ìdárayá ti ara àti sísọ bí àwọn ìdárayá wọnnì ṣe lè mú kí ara wa le. Báwo ni pípa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ ṣe nmú ẹ̀mí wa le? (wo Mòsíàh 18:8–10; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 20:77, 79).
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .