Come, Follow Me
Oṣù Karun 11–17. “Ẹ Ṣọ́ra Kí Ẹ Má Bàá Gbàgbé Olúwa”: Deuterónómì 6–8; 15; 18; 29–30; 34


“Oṣù Karun 11–17. ‘Ẹ Ṣọ́ra Kí Ẹ Má Bàá Gbàgbé Olúwa’: Deuterónómì 6–8; 15; 18; 29–30; 34,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Karun 11–17. ‘Ẹ Ṣọ́ra Kí Ẹ Má Bàá Gbàgbé Olúwa,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Mósè lórí Òke Nébò

Mósè lórí Òke Nébò, láti ọwọ́ John Steel, © Providence Collection/licensed láti goodsalt.com

Oṣù Karun 11– 17:“Ẹ Ṣọ́ra Kí Ẹ Má Bàá Gbàgbé Olúwa”

Deuterónómì 6– 8; 15; 18; 29–30;34

Iṣẹ́́ ìrànṣẹ́ Mósè bẹ̀rẹ̀ ní orí òkè, nígbàtí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ sí i láti inú i`gbẹ́ jíjó (wo Ẹ́ksódù 3:1–10). Bákannáà ó sì parí ní orí òkè, ju ogójì ọdún lẹ́hìnnáà, nígbàtí Ọlọ́run fún un ní ìwò ilẹ̀ ìlérí láti orí Òke Nébò (wo Deuterónómì 34:1–4). Mósè ti lo ìgbé ayé rẹ̀ ní mímúra àwọn ọmọ Ísráẹ́lì sílẹ̀ láti wọnú ilẹ̀ ìlérí náà, ìwé Deuterónómì sì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìkọ́ni ìgbẹ̀hìn, ìránnilétí, ìyànjú, àti àwọn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísráẹ́lì. Kíka àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mu hàn kedere pé ohun òdodo ti iṣẹ́ ìrànṣẹ́ Mósè—ìmúrasílẹ̀ tí àwọn ènìyàn nílò—kíi ṣe nípa yíyè ní aginjù, ṣíṣẹ́gun àwọn ọ̀tá, tàbí gbígbé orílẹ̀-èdè ga. Ó jẹ́ nípa kíkọ́ láti fẹ́ràn Ọlọ́run, àti dídúró ní òtítọ́ sí I. Ìyẹn ni ìmúrasílẹ̀ tí gbogbo wa nílò láti wọnú ilẹ̀ ìlérí ti ìyè ayérayé. Nítorínáà bíótilẹ̀jẹ́pé Mósè kò fi ẹsẹ̀ kan “ilẹ̀ tí ó nṣàn fún wàrà àti oyin” (Ẹ́ksódù 3:8), nítorí ti ìgbàgbọ́ àti ìṣòtítọ́, ó wọnú ilẹ̀ ìlérí tí Ọlọ́run ti múrasílẹ̀ fún gbogbo àwọn tí wọ́n tẹ̀le É.

Fún àpapọ̀ ìwé ti Lẹ́fítíkù, wo “Lẹ́fítíkù” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ

Deuterónómì 6:4–7; 8:2–5, 11–17; 29:18–20; 30:6–10, 14–20

àmì sẹ́mínárì
“Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.”

Òfin Mósè wà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ayẹyẹ òde àti ọ̀nà-ìsìn. Bí ẹ ti ri nínú ìmọ̀ràn Mósè nínú Deuterónómì, Olúwa ni àníyàn bákannáà nípa ipò inú ti àwọn ènìyàn Rẹ̀—ipò ti ẹ̀mí ọkàn wọn.

Nínú ẹsẹ ọ̀rọ̀ ìsàlẹ̀, ẹ wá ọ̀rọ̀ náà ọkàn, kí ẹ sì jíjíròrò ohun tí èyí lè fihàn. Ẹ lè ronú nípa àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bí irú ìyẹ̀wò ti ẹ̀mí nínú ọkàn yín. Irú àyẹ̀wò wo ni ẹ yíò fún arayín? Ìrú ìtọ́jú wo ni ẹ yíò júwe láti mú ìlera ti ẹ̀mí ọkàn yín dára si? Ẹ kọ àwọn ìwọnilọ́kàn yín sílẹ̀.

  • Deuterónómì 6:4–7:

  • Deuterónómì 8:2-5:

  • Deuterónómì 8:11–17:

  • Deuterónómì 29:18–20:

  • Deuterónómì 30:6-10:

  • Deuterónómì 30:14-20:

Ọ̀nà kan láti kó àwọn èrò yín jọ lè jẹ́ láti ya ọkàn yín kí ẹ sì kọ̀ àwọn ohun tí Olúwa ní kí ẹ ní nínú ọkàn yín sínú rẹ̀. Nígbàtí ẹ lè kọ àwọn ohun tí ẹ níláti pamọ́ kúrò nínú ọkàn yín sí òde rẹ̀.

Báwo ni ẹ ó ti fihàn pé ẹ fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín? Fún àwọn èrò, ẹ wo “Fẹ́ràn Ọlọ́run, fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ” nínú Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́na kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn, 10–12.

Bákannáà wo M. Russell Ballard, “Ìwọ Fẹ́ Mi Ju àwọn Wọ̀nyí Lọ Bí?,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2021, 51–53.

Ẹ wá àwọn ìwòye ti ẹ̀mí ti ara yín. Wá, Tẹ̀lé Mi dá àbá àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ àti ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ láti fojúsí àwọn ìwé mímọ́, ṣùgbọ́n máṣe jẹ́ kí èyí dín àṣàrò yín kù. Bí ẹ ti nka Deuterónómì, ẹ lè ṣe àwárí ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kan tí a kò ṣàfihàn rẹ̀ ní ìhín. Ẹ jẹ́ kí Ẹ̀mí ṣe atọ́nà yín sí ohun tí ẹ nílò láti kọ́.

Deuterónómì 6:4-12, 20– 25

“Ẹ Ṣọ́ra Kí Ẹ Má Bàá Gbàgbé Olúwa.”

Púpọ̀jù lára àwọn ọmọ Ísráẹ́lì tí wọ́n wọnú ilẹ̀ ìlérí kò tíì rí àwọn ìyọnu ní Égíptì tàbí sọdá Òkun Pupa. Mósè mọ̀ pé àwọn—àti pé àwọn ìran ọjọ́ ọ̀la— yíò nílò láti rántí àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run àti àwọn òfin Ọlọ́run láti dúró bí àwọn ènìyàn Ọlọ́run.

Ìmọ̀ràn wo ni ẹ rí nínú Deuterónómì 6:4–12, 20–25 tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti rántí àwọn ohun nlá tí Ọlọ́run ti ṣe fún yín? Kínni ẹ ní ìmísí láti ṣe kí ọ̀rọ̀ Olúwa lè “wà ni ọkàn yín ní ojojúmọ́”? (ẹsẹ 6).

Bákannáà ẹ lè ṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Jan E. Newman “Títọ́jú Ohùn àwọn Ènìyàn Májẹ̀mú nínú Ìran Tó Ndìde” (Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2023, 36–38) kí ẹ sì ṣe àyẹ̀wò bí ẹ ó ti fi ìgbàgbọ́ yín nínú Krístì ṣọwọ́ sí àwọn ìran ọjọ́ ọ̀la.

Bákannà wo Deuterónómì 11:18–21; Dale G. Renlund, “Ẹ Gbèrò Inúrere àti Títóbijùlọ Ọlọ́run,” Làìhónà, Oṣù Karun 2020, 41–44; Ìtumọ̀ Bíbélì, “Àwọn Ọjọ́ Ìgbà Iwájú tàbí Ìgbátí Aṣọ.”

Deuterónómì 15:1-15

Ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ nínú àìní wà pẹ̀lú ọwọ́ inúrere àti ọkàn ìfẹ́.

A kò tíì dé síbẹ̀ ní ọjọ́ náà “nígbàtí kò ní sí òtòṣì ní àárín yín” (Deuterónómì 15:4), nítorínáà àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ nípa ríran àwọn òtòṣì lọ́wọ́ nínú Deuterónómì 15 ṣì níyì, àní bí àwọn ìṣe kan ní pàtó bá yípadà. Kíyèsí ohun tí àwọn ẹsẹ 1–15 kọ́ni nípa ìdí tí a fi nran àwọn ènìyàn nínú àìní lọ́wọ́ àti ohun tí ìhùwàsí wa níláti jẹ́ nípa rẹ̀.

Kínni ó tú mọ̀sí láti “la ọwọ́ rẹ” sí àwọn ènìyàn nínú àìní? (àwọn ẹsẹ 8, 11). Kínni ohun tí ẹ kọ́ láti inú àpẹrẹ Olúwa nípa ríran àwọn ènìyàn nínú àìní lọ́wọ́? (wo ẹsẹ 15).

Bákannáà “Njẹ́ Mo Ti Ṣe Ohun Rere Kankan?,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 223.

Deuterónómì 18:15–19

Mósè “dàbí” Jésù Krístì.

Pétérù, Néfì, Mórónì, àti Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ gbogbo wọn sọ̀rọ̀ lórí àsọtẹ́lẹ̀ nínú Deuterónómì 18:15–19 (wo Àwọn Ìṣe 3:20–23; 1 Néfì 22:20–21; Ìwé-ìtàn—Jósẹ́fù Smith 1:40; 3 Néfì 20:23). Kínni ẹ kọ́ nípa Olùgbàlà láti inú ẹsẹ wọ́nyí? Ẹ ronú nípa ohun tí ẹ ti kà nípa Mósè ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó kọjá. Báwo ni Mósè ṣe “dàbí” Jésù Krístì?

Jésù nkọ́ àwọn ará Néfì

Jésù Krístì wí fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ ní Amẹ́ríkà àtijọ́ pé, “Èmi ni ẹni náà tí Mósè sọ nípa rẹ̀” (3 Néfì 20:23).

Deuterónómì 29:9; 30:15–20

Olúwa pè mi láti yàn ní àárín rere àti ibi.

Ó lè jẹ́ wíwuni láti ṣe àfiwé àwọn ọ̀rọ̀ Mósè nínú Deuterónómì 29:9; 30:15–20 pẹ̀lú àwọn ìkọ́ni ìgbẹ̀hìn Léhì sí ẹbí rẹ̀ nínú 2 Néfi 2:26–29; 4:4. Báwo ni Léhì ṣe mú ohun tí Mósè kọ́ gbòòrò? Kínni ẹ rí nínú àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí ó mísí yín láti “yan ìyè”? (Deuterónómì30:19)

àmì abala àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Deuterónómì 6:5

Mo lè fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.

  • Láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye Deuterónómì 6:5, ẹ lè ya ọkàn kan, ìlànà ti ara kan, àti apá tó lágbára. Àwọn ọmọ yín lè nawọ́ sí àwòrán náà bí ẹ ti nka àwọn ọ̀rọ̀ “ọkàn,” “ẹ̀mí,” àti “okun” nínú ẹsẹ náà. Báwo ni a ó ṣe fihàn Olúwa pé a fẹ́ràn Rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ẹ̀mí, àti okun wa?

Deuterónómì 6:6–15

Mo lè pa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ nínú ọkàn mi.

  • Ẹ kà ìmọ̀ràn Olúwa sí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì pẹ̀lú àwọn ọmọ yín láti fi àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ sí ibi tí wọn yíò ti rí wọn ní ojojúmọ́ (wo Deuterónómì 6:6–9). Èyí lè mísí yín àti àwọn ọmọ yín láti ronú àwọn ọ̀nà láti mu dájú pé ẹ kò “gbàgbé Olúwa” (ẹsẹ 12) àti láti rántí ohun tí Ó ti ṣe fún yín.

  • Ẹ lè fihàn pé Deuterónómì 6:13, 16 àti 8:3 ran Olùgbàlà lọ́wọ́ ní ìgbà àkokò pàtàkì kan nínú ayé Rẹ̀. Láti ri bẹ́ẹ̀, ẹ ka papọ̀ Matteu 4:1–10. Nígbànáà ẹ lè pín àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ tí ó ti ràn yín lọ́wọ́ ní àkokò àìní pẹ̀lú ara yín.

ọ̀dọ́mọkùnrin nka àwọn ìwé mímọ́

Deuterónómì 18:15–18

Àwọn wòlíì kọ́ni nípa Jésù Krístì.

  • Bí ẹ ti nka Deuterónómì 18:18 papọ̀, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye pé Wòlíì bíiti Mósè nínú ẹsẹ yí ni Jésù Krístì. Bóyá ẹ lè wo àwọn àwòrán ohun tí Mósè ṣe àti àwọn ohun tí Jésù Krístì ṣe, kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mú wọn báramu (wo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, àwọn nọmba. 15, 16, 38,39). Kínni àwọn wòlíì wa ní o`ní kọ́ wa nípa Olùgbàlà?

Deuterónómì 29:12–13; 30:8–10

Nítorí àwọn májẹ̀mú mi, mo jẹ́ ara àwọn ènìyàn Ọlọ́run.

  • Sísọ̀rọ̀ nípa Deuterónómì 29:12–13 pèsè ànfàní kan fún yín àti àwọn ọmọ yín láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn májẹ̀mú tí wọn yíò dá tàbí ti dá pẹ̀lú Baba Ọ̀run. Kínni ó túmọ́sí láti jẹ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run? Báwo ni àwọn ìlérí wa ṣe nmú wa jẹ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run? (wo ẹsẹ 13; nákannáà wo Mòsíàh 18:8–10).

  • Bí àwọn ọmọ yín bá nílò ìrànlọ́wọ́ láti ní òye ohun tí májẹ̀mú jẹ́, ẹ dá àbá pé kí wọ́n wá ìtumọ̀ nínú “Májẹ̀mú” nínú Atọ́nà sí àwọn ìwé mímọ́ (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Kínni àwọn ìlérí tí Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ṣe pẹ̀lú ara wọn nínú Deuterónómì 30:8–10? Kínni àwọn ìlérí tí a dá pẹ̀lú Ọlọ́run? (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 20:37, 77). Báwo ni àwọn ìlérí wọ̀nyí ṣe so wá mọ́ Ọ? Ẹ gbèrò kíkọ orin kan papọ̀ nípa àwọn májẹ̀mú “Dídúró lórí àwọn Ìlérí” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere).

Fún púpọ̀ síi, ẹ wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .

Mósè nwo iwájú sí Ilẹ̀ ìlérí

Olúwa Fi Gbogbo Ilẹ̀ náà Hàn Án, láti ọwọ́ Walter Rane

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Mo lè pa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ nínú ọkàn mi.