“Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Inú: Ìwé-ìtàn àwọn Ìwé inú Májẹ̀mú Láéláé,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Ìwé-ìtàn àwọn Ìwé inú Májẹ̀mú Láéláé,” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Inú
Ìwé-ìtàn àwọn Ìwé inú Májẹ̀mú Láéláé
Àwọn ìwé ti Jóṣúà nípasẹ̀ Ẹ́stérì níti àṣà ni a mọ̀ bí “ìwé-ìtàn àwọn ìwé” ti Májẹ̀mú Láéláé. Èyí kò túmọ̀sí pé àwọn ìwé mìíràn nínú Májẹ̀mú Láéláé kò ní iyì ti ìwé-ìtàn. Ṣùgbọ́n, àwọn ìwé ti ìwé-ìtàn ni a pè bẹ́ẹ̀ nítorí kókó ìlépa ti ònkọ̀wé wọn ni láti fi ọwọ́ Ọlọ́run hàn nínú ìwé-ìtàn ti àwọn ènìyàn Ísráẹ́lì. Èrèdí náà kìí ṣe láti fi ìtẹ̀lé-ìlànà òfin Mósè hàn, bí Lẹ́fítíkù àti Deuterónómì ti ṣe. Kìí ṣe láti fi ìyìn fún tàbí ráhùn nínú ọ̀rọ̀ ewì, bí Orin Dáfídì àti Ẹkún Jeremíàh ti ṣe. Kìí sì íṣe láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì sílẹ̀, bí àwọn ìwé ti Ísáíàh àti Èsèkíẹ́lì ti ṣe. Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn ìwé ti ìwé-ìtàn náà sọ àwọn ìtàn.
Ọ̀ràn Ìrísí Kan
Níti àdánidá, àwọn ìtàn wọ̀nyí ni a wí fúnni láti ìwò àmì kan pàtó. Gẹ́gẹ́bí kò ti ṣeéṣe láti wo òdòdó, àpáta, tàbí igi ní púpọ ju igun kan lọ ní àkokò kan, kò ṣeéṣe kí àkọsílẹ̀ ti ìwé-ìtàn fi ìrírí ti ẹni náà tàbí ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n nkọọ́ hàn. Nínú ìrísí yí ni àsopọ̀ ti àwọn ònkọ̀wé sí orílẹ̀ èdè tàbí ẹ̀yà àti àwọn àṣà ọ̀làjú àti ìgbàgbọ́ wọn wà. Mímọ èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye pé àwọn ònkọ̀wé àti alákọ́jọ ti àwọn ìwé ti ìwé-ìtàn kọjúsí àwọn àlàyé kíníkíní nígbàtí wọ́n bá nfi àwọn ẹlòmíràn sílẹ̀. Wọ́n ṣe àròsínú pé àwọn ẹlòmíràn kì bá ti ṣe. Wọ́n sì wá sí èrò píparí tí ó dálé àwọn àlàyé wọ̀nyí àti àròsínú. Àní a lè rí àwọn ìrírsí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ káàkiri àwọn ìwé ti Bíbélì (àti nígbàmíràn nínú irú ìwé kannáà). Bí a bá ṣe nní ìfura àwọn ìrírsí wọ̀nyí si, ni a ṣe lè ní òye dáradára ti ìwé-ìtàn àwọn ìwé náà.
Ìrísí kan tí ó wọ́pọ̀ sí gbogbo àwọn ìwé ti ìwé-ìtàn Májẹ̀mú Láéláé ni ìrísí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ wọn nínú Olúwa nràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ọwọ́ Rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn àti nínú àwọn ìṣe ti orílẹ̀-èdè wọn. Nígbàtí àwọn ìwé ti ìwé-ìtàn ẹ̀kọ́ kò ní ìtẹ́sí láti rí àwọn nkan ní ọ̀nà yí, ìrísí ti ẹ̀mí yí ni ara ohun tí ó nmú àwọn ìwé ti ìwé-ìtàn Májẹ̀mú Láéláé jẹ́ oníyelórí sí àwọn ènìyàn tí wọ́n nwá láti gbé ìgbàgbọ́ ti ara wọn ga nínú Ọlọ́run.
Àkóónú fún Ìyókù Májẹ̀mú Láéláé
Àwọn ìwé ti ìwé-ìtàn bẹ̀rẹ̀ níbití ìwé ti Deuterónómì ti kúrò, pẹ̀lú àwọn ọdún ìrìnkiri àwọn Ísráẹ́lì nínú aginjù tí ó fẹ́ parí. Ìwé ti Jóṣúà fihàn pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ṣetán láti wọnu Kenáánì, ilẹ̀ ìlérí wọn, ó sì ṣe àpèjúwe bí wọn ó ti gbàá. Àwọn ìwé tí ó tẹ̀le, àwọn Onídàájọ́ dé 2 Króníkà, fi ìrírí ti Ísráẹ́lì hàn ní ilẹ̀ ìlérí, láti àkokò tí wọ́n yanjú rẹ̀ títí di àkokò tí a ṣẹ́gun wọn nípasẹ̀ Àssíríà àti Bábílónì. Àwọn ìwé Ẹ́srà àti Nehemíàh sọ nípa ìpadàbọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ti àwọn Ísráẹ́lì sí olú-ìlú wọn, Jérúsálẹ́mù, ní àwọn díkédì lẹ́hìnnáà. Ní ìgbẹ̀hìn, ìwé Éstérì bá ìtàn àwọn Ísráẹ́lì gbígbé ní lílé kúrò nílú lábẹ́ akóso Persian.
Èyí sì ni ibi tí ìtàn Májẹ̀mú Láéláé parí sí. Àwọn ònkàwé ìgbà-àkọ́kọ́ ti Bíbélì ni ó yàlẹ́nu láti ri pé lódodo wọ́n ti parí kíka ìtàn Májẹ̀mú Láéláé ṣíwájú kí wọ́n tó ka púpọ̀ síi ju ìlàjì àwọn ojú-ewé rẹ̀. Lẹ́hìn Éstérì, a kò ní ìwífúnni púpọ̀ nípa ìwé-ìtàn ti àwọn Ísráẹ́lì. Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn ìwé náà tẹ̀le—nípàtàkì àwọn ìwé ti àwọn wólíì—ní ìbámu sínú àkokò-yíyẹ tí àwọn ìwé ti ìwé-ìtàn gbékalẹ̀. Iṣẹ́́ ìrànṣẹ́ ti wòlíì Jeremíàh, fún àpẹrẹ, ṣẹlẹ̀ ní ìgbà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọsílẹ̀ nínú 2 Àwọn Ọba 22–25 (àti àkọsílẹ̀ bíbáramu nínú 2 Króníkà 34–36). Mímọ èyí lè ní ipa ní ọ̀nà tí ẹ fi nka méjèèjì ìròhìn ìwé-ìtàn àti àwọn ìwé ti Wòlíì.
Nígbàtí Ohunkan Kò Bá Báramu
Nígbàtí kíka Májẹ̀mú Láéláé, bíiti ìwé-ìtan eyikeyi, tí ẹ lè ti ka nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n nṣe tàbí sọ àwọn ohun tí, ó dàbí àjèjì tàbí àní dídàmú, sí ojú òde òní. A níláti retí èyí—tí àwọn ònkọ̀wé Májẹ̀mú Láéláé ti rí ayé láti inú ìrísí kan tí ó wà, ní àwọn ọ̀nà kan, tí ó yàtọ̀ gan kúrò ní tiwa. Ipá, ìbátan ẹ̀yà, àti àwọn ojúṣe obìnrin tí o´ kàn jẹ́ àwọn ọ̀ràn tí àwọn ònkọ́wé àtijọ́ lè ti rí ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ju bí a ti ṣe ní òní.
Nítorínáà kínni ohun tí a ó ṣe nígbàtí a bá bá ẹsẹ ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́ tí ó dàbí o ndaniláàmú? Àkọ́kọ́, ó lè ṣèrànwọ́ láti yẹ ẹsẹ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan wò nínú àkóónú tó gbòòrò. Báwo ni ó ṣe bá ètò ìgbàlà Ọlọ́run mu? Báwo ni ó ṣe bá ohun tí ẹ mọ̀ nípa ìwà-ẹ̀dá ti Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì? Báwo ni ó ṣe wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òtítọ́ tí a fihàn nínú àwọn ìwé mímọ́ míràn tàbí pẹ̀lú ìkọ́ni àwọn wòlíì alààyè? Báwo sì ni ó ṣe wà ní ìbámu pẹ̀lú ìkùnsíni ti Ẹ̀mí sí ọkàn àti inú ti ara yín.
Ní àwọn ọ̀ràn kan, ẹsẹ ọ̀rọ̀ náà lè dàbí kò wà ní ìbámu dáadáa pẹ̀lú eyikeyi ti ìwọ̀nyí. Nígbàmíràn ẹsẹ ọ̀rọ̀ náà lè dàbí ẹ̀là ìrújú kan tí kò dàbí ó ní ààyè ní àárín àwọn ẹ̀là tí ẹ ti tòjọ tẹ́lẹ̀. Gbígbìyànjú láti fi ipá fi ẹ̀là sí ìbámu kìí ṣe ọ̀nà dídárajùlọ. Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀náà ni fífi gbogbo ìrújú náà sílẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ lè nílò láti gbé ẹlà náà sẹgbẹ fún àkokò kan. Bí ẹ ti nkọ́ púpọ̀ síi tí ẹ sì nmú ìrújú púpọ̀ papọ̀, ẹ lè rí bí àwọn ẹplà náà ṣe wà ní ìbámu dára dára.
Bákannáà ó lè ṣèrànwọ́ láti rántí pé ní àfikún sí níní òpin sí ìrísí pàtàkì kan, ìwé mímọ́ ti àwọn ìwé-ìtàn ní ó jẹ́ ti àṣìṣe ènìyàn. Fún àpẹrẹ, ní àwọn sẹ́ntúrì díẹ̀, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun kedere àti iyebíye [ni a] ti mú kúrò nínú [Bíbélì],” pẹ̀lú àwọn òtítọ́ pàtàkì nípa ẹ̀kọ́, ìlànà, àti májẹ̀mú (1 Néfì 13:28; bákannáà wo àwọn ẹsẹ 26, 29, 40). Ní àkokò kannáà, a níláti ní ìfẹ́ láti gbà pé ìrísí ti arawa bákannáà ní òpin: àwọn nkan yíò wà nígbàgbogbo tí a kò ní òye rẹ̀ ní kíkún àti ìbèèrè tí a kò lè dáhùn síbẹ̀.
Àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ lè dàbí àwọn ẹ̀là ìrújú tí a kò mọ̀ bí a ó ṣe fi wọ́n sí ìbámu pẹ̀lú ìyókù àwọn ìrújú.
Wíwá àwọn Dídára-lọ́pọ̀lọpọ̀
Ṣùgbọ́n ní àkokò díẹ̀, àwọn ìbèèrè àìlèdáhùn kò níláti pa wá mọ́ kúrò nínú dídára-lọ́pọ̀lọpọ̀ iyebíye ti òtítọ́ ayérayé tí a rí nínú Májẹ̀mú Láéláé—àní bí a`wọn dídará-lọ́pọ̀lọpọ̀ wọ̀nyí bá fi ìgbàmíràn pamọ́ sínú ilẹ̀ àpáta ti àwọn ìrírí ìdàmú àti àṣàyàn buburú tí a ṣe nípasẹ̀ àwọn àìpé ènìyàn. Bóyá iyebíye jùlọ ti dídára-lọ́pọ̀lọpọ́ wọ̀nyí ni àwọn ìtàn àti ẹsẹ ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ Ọlọ́run—nípàtàkì àwọn tí ó nawọ́ wa síwájú ẹbọ ọrẹ Jésù Krístì. Ní ìwò láti igun eyikeyi, àwọn dídára-lọ́pọlọpọ̀ bí ìwọ̀nyí ntàn gẹ́gẹ́bí ó ti ndán gidi ní òní bí wọ́n ti ṣe nígbànàá sẹ́hìn. Àti nítorí àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí sọ nípa májẹ̀mú àwọn ènìyàn Ọlọ́run—àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ní àìlera tí wọ́n ṣì fẹ̀ràn tí wọ́n ṣì nsin Olúwa—àwọn dídára-lọ́pọlọpọ̀ ti òtítọ́ gbé nínú àwọn ìwé ti ìwé-ìtàn Májẹ̀mú Láéláé.