Come, Follow Me
Oṣù Kẹrin 27–Oṣù Karun 3. “Ìwà mímọ́ sí Olúwa”: Ẹ́ksódù 35–40; Lẹ́fítíkù 1; 4; 16; 19


“Oṣù Kẹ́rin 27–Oṣù Karun 3. ‘Ìwà mímọ́ sí Olúwa: Eksodu 35–40; Lẹ́fítíkù 1; 4; 16; 19,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kẹrin 27–Oṣù Karun 3. ‘ìwà mímọ́ sí Olúwa,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Tẹ́mpìlì Rio de Janeiro Brazil

Tẹ́mpìlì Rio de Janeiro Brazil

Oṣù Kẹrin 27–Oṣù Karun 3: “Ìwà mímọ́ sí Olúwa”

Ẹ́ksódù 35–40; Lẹ́fítíkù 1; 4; 16;19

Fífi Égíptì sílẹ̀—bí èyí ṣe jẹ́ pàtàkì tó—kò ṣe àṣeyọrí èrèdí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Isráẹ́lì ní kíkún. Àní ìgbé ayé títura ní ilẹ̀ ìlérí kìí ṣe ìlépa ìgbẹ̀hìn ti Ọlọ́run fún wọn. Ìwọ̀nyí nìkan ni àwọn ìṣísẹ̀ síwájú ohun tí Ọlọ́run nfẹ́ ní òdodo fún àwọn ènìyàn Rẹ̀: “Ẹ̀yin yíò jẹ́ mímọ́: nítorí èmi Olúwa Ọlọ́run yín mo jẹ́ mímọ́” (Lẹ́fítíkù 19:2). Báwo ni ètò Ọlọ́run láti mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ jẹ́ mímọ́ lẹ́hìn tí wọ́n ti gbé nínú ígbékùn fún àwọn ìràn? Ó pàṣẹ fún wọn láti dá ibi ìwà mímọ́ kan sílẹ̀ nínú aginjù—àgọ́ kan. Ó fún wọn ní àwọn májẹ̀mú àti òfin láti tọ́ àwọn ìṣe wọn kí ó sì yí ọkàn wọn padà. Ó sì pàṣẹ fún wọn láti ṣe irúbọ ohun-ọ̀sìn láti kọ́ wọn nípa ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Gbogbo èyí ní ó níláti fa iyè-inú, ọkàn, àti ìgbé ayé wọn síwájú Olùgbàlà. Òun ni ipa ọ̀nà òtítọ́ sí ìwà mímọ́, fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì àti fún wa. Gbogbo wa ti lo àkokò kan nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀, a sì pe gbogbo wa láti fi ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀ sẹ́hìn kí a sì tẹ̀lé Jésù Krístì ẹnití ó ṣe ìlérí pé “Èmi lè mú yín di mímọ́” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 60:7).

Fún àpapọ̀ ìwé ti Lẹ́fítíkù, wo “Lẹ́fítíkù” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ

Ẹ́ksódù 35– 40; Lẹ́fítíkù 19

àmì sẹ́mínárì
Olúwa nfẹ́ kí èmi di mímọ́.

Ẹ́ksódù 35–40 júwe ìtiraka àwọn ọmọ Ísráẹ́lì láti kọ́ àgọ́, níbití àwọn ìlànà mímọ́ yíò ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ènìyàn mímọ́. Bí ẹ ti nka àwọn orí wọ̀nyí, ẹ wá àwọn ohun tí Olúwa ní kí àwọn ènìyàn Rẹ̀ gbé sínú àgọ́. Kínni àwọn ohun-èlò wọ̀nyí lè rọ́pò? Kínni wọ́n dá àbá sí yín nípa púpọ̀si nínú ìwà mímọ́? Nípàtàkì ẹ gbèrò bí àwọn ohun èlò wọ̀nyí ṣe nyí àwọn èrò yín padà síwájú Olùgbàlà. Tábìlì bí èyí lè ràn yín lọ́wọ́:

Kínni ohun tí ẹ rí?

Kínni èyí lè rọ́pò?

Kínni ohun tí ẹ rí?

Árkù ti májẹ̀mú (Ẹ́ksódù 37:1–9; 40:20–21)

Kínni èyí lè rọ́pò?

(Wo Ẹ́ksódù 25:20–22; atọ́nà sí ìwé mímọ́, “Àpótí Májẹ̀mú”)

Kínni ohun tí ẹ rí?

Pẹpẹ ti ìkúnra (Ẹ́ksódù 40:26–27; bákannáà wo Ẹ́ksódù 30:1, 6–8)

Kínni èyí lè rọ́pò?

(Wo Ìfihàn 8:3–4)

Kínni ohun tí ẹ rí?

Igi-àbẹ́là tàbí ìdúró-fìtílà (Ẹ́ksódù 37:17–24)

Kínni èyí lè rọ́pò?

(Wo Máttéù 11:28–30; Jòhánù 16:33)

Kínni ohun tí ẹ rí?

Pẹpẹ ti ìrúbọ (Ẹ́ksódù 38:1–7; bákannáà wo Ẹ́ksódù 27:1; 29:10–14)

Kínni èyí lè rọ́pò?

(Wo Atọ́nà sí àwọn Ìwé-mímọ́, “Ìrúbọ”)

Kínni ohun tí ẹ rí?

Ládugbó (ago) omi (Ẹ́ksódù 30:17–21)

Kínni èyí lè rọ́pò?

(Wo 2 Króníkà 4:6; Ísáíàh 1:16; Jeremíàh 33:8)

Bẹ́ẹ̀ni, ó kàn wà nínú ibi mímọ́ tí kò mú wa di mímọ́. Lẹ́fítíkù 19 júwe àwọn òfin àti àṣẹ Olúwa tí a fúnni láti ran àwọn ọmọ Ísráẹ́lì lọ́wọ́ láti pọ̀si nínú ìwà mímọ́. Kínni ẹ rí nínú àwọn òfin wọ̀nyí tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti wá ìwà mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Kínni ẹ ní ìmọ̀lára ìwọnilọ́kàn láti ṣe láti gbé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí ní kíkún?

Bákannáà wo Henry B. Eyring, “Ìwà mímọ́ àti Ètò Ìdùnnú,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2019, 100–103; “Àgọ́ Náà” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

7:19

The Tabernacle

Lo orin mímọ́. Orin ní agbára títóbi láti pe ipa ti Ẹ̀mí kí ó sì gbé ìgbàgbọ́ ga nínú Jésù Krístì. Àwọn ọ̀rọ̀ inú àwọn orin ìsìn nfikún ẹ̀kọ́ nínú ìwé mímọ́ nígbàkugbà. Fún àpẹrẹ, kíkọ orin ìsìn kan bíi “Ìwà mímọ́ Síi Fi Fún Mi” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 131) lè jẹ́ àfikún sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ́ nínú Lẹ́fítíkù 19. Bákannáà ó lè ràn yín lọ́wọ́ nípa ohun tí ó túmọ̀sí láti di mímọ́ síi bíiti Olùgbàla kí ẹ sì jíròrò bí òun ṣe nràn yín lọ́wọ́ láti pọ̀si nínú ìwà mímọ́ yín.

Ẹ́ksódù 35:4–35; 36:1–7

Olúwa ní kí èmi ó ṣe ẹbọ ọrẹ mi pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́.

Nínú ọdún náà lẹ́hìn fífi Égíptì sílẹ̀, ìbáṣepọ̀ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì pẹ̀lú Jèhófàh ni a lè júwe bí àìtẹramọ́. Àti síbẹ̀, bí ẹ ti nka Ẹ́ksódù 35:4–35 àti 36:1–7, ẹ kíyèsí bí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ṣe fèsì sí òfin láti kọ́ àgọ́. Kínni ẹ lè kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti sin Olúwa?

Òun lè má bèèrè fún irin, aṣọ ọ̀gbọ̀, tàbí igi iyebíye fún àgọ́ kan. Kínni Olúwa ti fún yín, àti pé kínni Ó nbèèrè pé kí ẹ fúnni? Nígbà wo ni “ọkàn yí ti rúu [yín] sókè láti wá sínú iṣẹ́ náà”?

Bákannáà wo Àwọn Àkọlé àti Àwọn Ìbèèrè, “Ìrúbọ,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

Àwọn Ísráẹ́lì nkó ẹbọ ọ̀rẹ jọ fún àgọ́

Àwọn ọmọ Ísráẹ́lì fúnni ní ọrẹ ẹbọ fún àgọ́ pẹ̀lú “ọkàn ìfẹ́” (Ẹ́ksódù 35:5). Ìjúwe láti ọwọ́ Corbert Gauthier, © Lifeway Collection/licensed láti goodsalt.com

Ẹ́ksódù 40:12–14

Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì ni a fúnni ní àtijọ́.

Ẹ́ksódù 40:12–14 tọ́ka sí àwọn ìlànà àtijọ́ tí a npínfúnni bákannáà ní ọjọ́ wa nínú ilé Olúwa. Ní ìhín ni àwọn àfikún ẹsẹ tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti kọ́ nípa bí àwọn ìlànà wọ̀nyí ṣe lè jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì:

  • Wíwẹ̀: Orin Dáfídì 51:2; Èsèkíẹ́lì 36:25–27

  • Wíwọṣọ nínú gámẹ́ntì mímọ́: Ísáíàh 61:10; Matteu 22:11–14; Ìfihàn 19:7–8

  • Fífi àmì òróró yàn: Lúkù 4:18–19; Ìṣe àwọn Àpóstélì 10:38

Lẹ́fítíkù 1:1–9; 4;16

Nítorí ìrúbọ Jésù Krístì, a lè dáríjì mí.

Púpọ̀ lára ìwé Lẹ́fítíkù lè dàbí o ṣe àjèjì sí wa—ìrúbọ ohun-ọ̀sìn, iṣẹ̀ṣe tí ó wà pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àti omi, àti àwọn òfin tí ó nṣe àkóso àwọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ álàyé kékèké ti ayé. Ṣùgbọ́n àwọn ìṣẹ̀ṣe àti òfin wọ̀nyí ni ó yẹ kí ó kọ́ wa ní àwọn ẹ̀kọ́ ípílẹ̀ tí ó faramọ́—ìrònúpìwàdà, ìwà mímọ́, àti Ètùtù Olùgbàlà. Láti wá àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí bí ẹ ṣe nka Lẹ́fítíkù 1:1–9; 4;16, Ẹ yẹ àwọn ìbèèrè wọ̀nyí wo:

  • Kínni àwọn ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí mo rí tí ó nrán mi létí nípa Jésù Krístì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀?

  • Kínni mo kọ́ láti inú àwọn ìrúbọ wọ̀nyí nípa ìrúbọ Olùgbàlà?

  • Báwo ni mo ṣe dàbí àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣe àwọn ìrúbọ wọ̀nyí?

Olúwa kò bèèrè ìrúbọ ẹranko mọ́. Ṣùgbọ́n ó ṣì jẹ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa ìhìnrere. Láti kọ́ nípa irú ìrúbọ tí Olúwa nbèèrè, ẹ ṣe àṣàrò 3 Néfì 9:19–20; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 64:34. Báwo ni ẹ ṣe nṣe irú àwọn ìrúbọ wọ̀nyí? Kínni Mósè 5:7 kọ́ ọ yín nípa bí ẹ ṣe lè wo àwọn irúbọ yín?

Bákannáà wo “Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú: Àgọ́ àti Ìrúbọ.”

àmì abala àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Ẹ́ksódù 35:20–29; 36:1

Ọlọ́run ti fún mi ní àwọn ẹ̀bùn láti ṣèrànwọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ Rẹ̀.

  • Ní òpin ìlànà yí ni àwòrán aginjù àgọ́ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì. Ẹ lè fẹ́ láti wò ó pẹ̀lú àwọn ọmọ kí ẹ sì bèèrè lọ́wọ́ wọn àwọn ohun èlò tí wọ́n ìbá ti nílò láti kọ́ àgọ́ náà. Nígbànáà ẹ lè ka Ẹ́ksódù 35:20–29 papọ̀ láti wá bí a ti pèsè àwọn ohun èlò wọ̀nyi. Báwo ni Olúwa ti ṣe pè wá lá lọ́wọ́sí gbígbé ìjọba Rẹ̀ ga?

  • Ẹ yẹ kíka Ẹ́ksódù 36:1 pẹ̀lú wọn láti wá ohun tí Olúwa fún Bẹ́sẹ́líẹ́lì àti Áhólíábù láti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti kọ́ àgọ́. Ẹ lè bá àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ nígbànáà nípa ohun tí ẹ ní ìmọ̀lára pé Olúwa ti fún wọn láti ṣèrànwọ́ láti gbé ìjọba Rẹ̀ ga. Báwo ni a ṣe lè lo àwọn ohun wọ̀nyí láti bùkún àwọn ẹlòmíràn?

Tẹ́mpìlì Rome Italy

Tẹ́mpìlì Rome Italy

Ẹ́ksódù 40:17–34

Mo lè ní ìmọ̀lára wíwà níwájú Olúwa nínú àwọn ibi mímọ́.

  • Ẹ́ksódù 40:17–34 ẹ ṣe ìtòsílẹ̀ àwọn ohun tí ó jẹ́ ara àgọ́ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì. Bóyá ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè wá wọn nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí àti nínú àwòrán àgọ́ ní òpin ìlànà yí. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa bí ara kọ̀ọ̀kan ti àgọ́ ṣe lè kọ́ni nípa Olùgbàlà tàbí Baba Ọ̀run. Fún àpẹrẹ, ark ti ẹ̀rí lè rán wa létí nípa àwọn òfin Ọlọ́run, pẹpẹ lé rán wa létí nípa ìrúbọ Jésù Krístì, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

  • Àwọn ibi mímọ́ wo ni a ní ní òní tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára láti súnmọ́ Jésù Krístì. Bí ara ìbárasọ̀rọ̀ yí, ẹ lè papọ̀ wo fídíò “Àwọn Tẹ́mpìlì” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Ẹ lè kọ orin kan bíi “Àwọn Ibi Mímọ́” (Ibi-ìkàwé ìhìnrere). Ẹ pín pẹ̀lú ara yín bí ẹ ṣe ní ìmọ̀lára nípa àwọn ibi mímọ́ bíiti tẹ́mpìlì.

5:41

What Is a Temple?

Lẹ́fítíkù 1:1–4

Nítorí ìrúbọ Jésù Krístì, a lè dáríjì mí.

  • Ìrúbọ ohun-ọ̀sin tí a júwe nínú Májẹ̀mú Láéláé ni ó yẹ kí ó kọ́ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nípa ìdáríjì nípasẹ̀ Jésù Krístì. Ẹ yẹ bí kíkà nípa ìrúbọ wọ̀nyí fi lè ṣe ohunkànnáà fún àwọn ọmọ yín. Ẹ lè fi àwọn àwòrán Jésù Krístì ní Gẹ́tsémánè àti lórí àgbélèbú hàn (wo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, àwọn nọmba. 56,57) bí ẹ ṣe nkàá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lẹ́fítíkù 1:1–4. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá àwọn ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó nrán wọn létí ìrúbọ Jésù Krístì.

  • Ẹ lè ka 3 Néfì 9:19–20 papọ̀ láti rí ohun tí a pàṣẹ fún wa láti rúbọ̀ dípò àwọn ẹranko. Kínni ó túmọ̀sí láti fi ìrora ọkàn ati ẹ̀mí ìròbínújẹ́ fún Olúwa? Wo atọ́nà sí àwọn ìwé mímọ́, “Ọkàn Ìròbìnújẹ́” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere) fún ṣíṣe ìrànwọ́ láti dáhùn àwọn ìbèèrè yí.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .

àgọ́ àtijọ́

Àgọ́ Àtijọ́, láti ọwọ́ Bradley Clark

Ojú-ewé ìṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Mo lè ní ìmọ̀lára wíwà níwájú Ọlọ́run ní àwọn ibi mímọ́