Come, Follow Me
Oṣù Karun 18–24. “Jẹ́ Alágbára kí o sì ní Ìgboyà Rere”: Joṣúà 1– 8; 23– 24


“Oṣù Karun 18–24. ‘Jẹ́ Alágbára kí o sì ní Ìgboyà Rere: Jóṣúà 1–8; 23–24,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Karun 18–24. ‘Jẹ́ Alágbára kí o sì ní Ìgboyà Rere,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Mósè nbùkún Jóṣúà

Mósè Nfi Àmì Òróró Yan Jóṣúà, láti ọwọ́ Darrell Thomas (detail)

Oṣù Karun 18– 24: “Jẹ́ Alágbára kí o sì ní Ìgboyà Rere”

Jóṣúà 1:8; 23– 24

Ó ti gba ọ̀pọlọpọ̀ àwọn ìràn, ṣùgbọ́n ìlérí Olúwa ni ó fẹ́ di mímúṣẹ: àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nígbẹ̀hìn yíò jogún ilẹ̀ ìlérí. Ṣùgbọ́n ní ọ̀nà wọn ní Odò Jọ́dánì dúró sí, àwọn odi Jẹ́ríkò, àti àwọn ẹ̀nìyàn alágbára tí wọ́n ti kọ Olúwa sílẹ̀ (wo 1 Néfì 17:35). Wọn yíò sì níláti kojú gbogbo ohun èyí láìsí olùdarí àyànfẹ́ wọn Mósè. Ipò náà lè ti mú àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísráẹ́lì di aláìlera àti ẹlẹ́rù, ṣùgbọ́n Olúwa wípé, “Jẹ́ Alágbára kí o sì ní Ìgboyà Rere.” Kínni èrèdí tí wọ́n ní láti ní ìgboyà? Kìí ṣe nítorí ti agbára ti ara wọn—àní tàbí ti Mósè tàbí Jóṣúà—ṣùgbọ́n nítorí “Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ bá nlọ” (Jóṣúà 1:9). Nígbàtí a bá ní àwọn odò ti ara wa láti sọdá àti àwọn odi láti mú wálẹ̀, àwọn ohun ìyànu lè ṣẹlẹ̀ nínú ayé wa “Olúwa yíò ṣe àwọn ohun yíyanilẹ́nu ní àárín [wa]” (Jóṣúà 3:5).

Fún àkópọ̀ ìwé ti Ẹ́ksódù, wo “Ẹ́ksódù, ìwé ti” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ

Jóṣúà 1: 1– 9

Ọlọ́run yíò wà pẹ̀lú mi bí mo ti ntiraka láti jẹ́ olóòótọ́ sí I.

Ẹ ro ohun tí ìbá ti jẹ́ láti pe Jóṣúà láti rọ́pò Mósè. Ẹ kíyèsí ohun tí Olúwa sọ nínú Jóṣúà 1:1–9 láti gbà á níyànjú. Ẹ ronú nípa àwọn ìpènijà tí ẹ̀ nkojú; kíní ó fún yín ní ìgboyà nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí?

Orúkọ náà Jóṣúà (Yehoshua tàbí Yeshua ní Hébérù) túmọ̀sí “Jèhófà gbàlà.” Orúkọ náà Jésù wá láti inú Yeshua. Nítorínáà bí ẹ ti nkà nípa Jóṣúà, ẹ yẹ ojúṣe rẹ̀ wò ní dídárí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì sọdá Odò Jọ́dánì àti sínú ilẹ̀ ìlérí. Báwo ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ti jọra sí ohun tí Krístì ṣe fún wa?

Jóṣúà 1:5

àmì sẹ́mínárì
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè mú kí ọ̀nà mi ṣerere.

Bí Ó ti gba Jóṣúà níyànjú, Olúwa fúnni ní àmọ̀ran nínú Jóṣúà 1:8 nípa àwọn ìwé mímọ́, tàbí “ọ̀rọ̀ ti òfin.” Yíyẹ ojúṣe wíwúwo, kínni ìdí tí ìmọ̀ràn yí ti lè fi ṣèrànwọ́ nípàtàkì?

Nígbàtí Olúwa pè wá láti ka àwọn ìwé mímọ́, Ó máa nlo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọjá kíkàwé lásán. Bákannáà Ó ṣe ìlérí àwọn ìbùkún títóbi. Tábìlì ìsàlẹ̀ lè ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àwárí àwọn ìfipè wọ̀nyí àti ìlérí àwọn ìbùkún:

Ìfipè

Àwọn ìlérí ìbùkún

Jóṣúà 1:8

Ìfipè

Ẹ jíròrò ní ọ̀sán àti ní òru

Àwọn ìlérí ìbùkún

1 Néfì 15:23–24

Ìfipè

Àwọn ìlérí ìbùkún

2 Néfì 32:3

Ìfipè

Àwọn ìlérí ìbùkún

Mòsíàh 1:7

Ìfipè

Àwọn ìlérí ìbùkún

Ṣerere nínú ilẹ̀ náà.

Hẹ́lámánì 3:29–30

Ìfipè

Àwọn ìlérí ìbùkún

Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:85

Ìfipè

Àwọn ìlérí ìbùkún

Russell M. Nelson, “Gbọ́ Tirẹ̀,” Làìhónà, Oṣù Karun 2020, gbólóhùn ọ̀rọ̀ tó kẹ́hìn ní ojú-ewé 89

Ìfipè

Àwọn ìlérí ìbùkún

Báwo ni Olúwa ṣe nmú àwọn ìlérí wọ́nyí ṣẹ nínú ayé yín? Ìsisìyí lẹ̀ jẹ́ àkokò rere láti yẹ ìwà ṣíṣe àṣàrò ìwé mímọ wò. Kínni ó nlọ dáradára? Kínni ẹ ní ìmọ̀lára ìmísí láti ṣe láti ní àwọn ìrírí onítumọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

Bákannáà wo “Bí Mo ti Nṣe Ìwákiri àwọn Ìwé mímọ́,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 277.

Jóṣúà 2

Méjèèjì ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ jẹ́ pàtàkì fún ìgbàlà.

Àwọn Krìsténì Májẹ̀mú Titun rí Ráhábù bí àpẹrẹ agbára ti méjèèjì ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ (wo Hébérù 11:31; Jákọ́bù 2:25). Bí ẹ ti nka Jóṣúà 2, ẹ yẹ ojúṣe ti ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ Ráhábù wò ní gbígba ararẹ̀, ẹbí rẹ̀, àti àwọn amí ará Ísráẹ́lì là. Kínni èyí kọ́ yín nípa bí ìgbàgbọ́ yín nínú Krístì àti àwọn iṣẹ́ yín fi lè ní ipa lórí ara yín àti àwọn ẹlòmíràn?

Ráhábù nwo òde láti inú fèrèsé

Ráhábù ní ibi fèrèsé rẹ̀ Dídúró fún Ìlérí náà, láti ọwọ́ Elspeth Young (detail)

Jóṣúà 3– 4

Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, mo lè ní ìrírí “àwọn ìyanu ti Ọlọ́run.”

Olúwa nṣiṣẹ́ ìyanu ní àárín àwọn ènìyàn Rẹ̀ bí Ó ti darí wọn sínú ilẹ̀ ìlérí, Ó sì lè ṣe bákannáà fún yín. Ní ìhín ni àwọn ìbèèrè láti ṣe atọ́nà àṣàrò yín ti Jóṣúà 3–4:

  • Kínni ìdí tí ẹ fi rò pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nílò láti sọ arawọn di mímọ́ ṣíwájú kí wọ́n tó sọdá Odò Jọ́dánì? wo Jóṣúà 3:5).

  • Ẹ kíyèsi pé odò náà pínyà lẹ́hìn “tí àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn àlùfáà … ti tẹ etí omi” (Jóṣúà 3:13, 15). Kínnidí tí èyíìni fi jẹ́ pàtàkì?

  • Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì míràn ṣẹlẹ̀ ní Odò Jọ́dánì—wo 2 Àwọn Ọba 2:6–15; 5:1–14; àti Márkù 1:9–11. Kínni àwọn ìsopọ̀ tí ẹ rí ní àárín àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí?

  • Báwo ni Olúwa ti ṣe “àwọn ìyanu” nínú ayé yín? (Jóṣúà 1:5). Báwo ni ẹ ṣe lè ní ìrírí—tàbí dá—àwọn ìyanu wọnnì mọ̀ síi léraléra? (Fún àpẹrẹ, wo Jóṣúà 3:17).

Jóṣúà 6– 8

Ìgbọràn npe agbára Ọlọ́run wá sínú ayé mi.

Jóṣúà 6–8 kojú àwọn ogun lórí àwọn ilẹ̀ Jẹ́ríkò àti Áì. Bí ẹ ṣe nka àwọn orí wọ̀nyí, ẹ yẹ bí ẹ ṣe lè jagun ìdánwò (fún àpẹrẹ, wo Jóṣúà 7:10–13). Kínni ẹ lè ṣe láti kọ́ nípa bí Ọlọ́run ti lè ràn yín lọ́wọ́ kínni ẹ sì nílò láti ṣe láti ní ààyè sí agbára Rẹ̀? Fún àpẹrẹ, kínni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa àwọn ìkọ́ni Olúwa fún gbígba Jẹ́ríkò? (wo Jóṣúà 6:1–5). Bóyá àkọsílẹ̀ náà nínú Jóṣúà 7 yíò mísí yín láti pinnu bí “ohun ìyàsọtọ̀ kan nbẹ ” nínú ayé yín tí ẹ níláti bn (Joshua 7:13).

Jóṣúà 23– 24

“Ẹ yan ẹnití ẹyin ó sìn ní òní.”

Àwọn Ìkọ́ni ìgbẹ̀hìn ti Jóṣúà sí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nínú Jóṣúà 23–24 pẹ̀lú àwọn ìkìlọ̀, ìmọ̀ràn, àti ìlérí àwọn ìbùkún. Bóyá ẹ lè ṣe ìtòsílẹ̀ kan nípa ohun tí ẹ rí. Yíyẹ ohun gbogbo tí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ti là kọjá wo, kínni ìdí tí ẹ fi rò pé Jóṣúà yàn láti sọ àwọn ohun wọ̀nyí fún wọn ní òpin ayé rẹ̀? Kínni ẹ rí tí ó mísí yín láti “rọ̀mọ́ Olúwa”? (Jóṣúà 1:5).

Bákannáà wo Dale G. Renlund, “Ìwọ Yàn Ní Òní Yí,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2018, 104-6.

àmì abala àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Joshua 1–4;6

“Jẹ́ Alágbára kí o sì ní Ìgboyà Rere.”

  • Ní ìhín ni ọ̀nà kan láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ “jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà rere” (Jóṣúà 1:6) nípasẹ̀ Jésù Krístì. Pè wọ́n láti rí gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan tí sọ léraléra nínú Jóṣúà 1:6, 9, àti18, kí ẹ sì kọ wọ́n sílẹ̀ tàbí kọ́ ọ sórí. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú àwọn ipò nínú èyítí wọ́n lè nílò ọ̀rọ̀ yí, gẹ́gẹ́bí Jóṣúà ti ṣe. Bákannáà ẹ lè ṣe àyẹ̀wò ti àwọn ìtàn papọ̀ nínu Jóṣúà 1–4;6 (bákannáà wo “Jóṣúà Wòlíì náà” àti “Ráhábù àti àwọn Amín” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 85–91). Báwo ni àwọn ènìyàn nínú àwọn ìtàn wọ̀nyí ṣe fi ìgboyà àti okun nínú Olúwa hàn?

    2:59

    Joshua the Prophet

    1:39

    Rahab and the Spies

Jóṣúà 1:5

Ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ nmú àwọn ìbùkún wá fún mi.

  • Kíka Jóṣúà 1:8 lè mísí àwọn ọmọ yín láti ka àwọn ìwé mímọ́ ní ayè ara wọn. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá àwọn ọ̀rọ̀ nínú ẹsẹ yí tí ó kọ́ wọn àti ìdí tí a fi níláti ka àwọn ìwé mímọ́. Wọ́n lè wá irú ohun kannáà 1 Néfì 15:23–24; 2 Néfì 31:20; 32:3; Jákọ́bù 4:6; Hẹ́lámánì 3:29–30. Ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ bákannáà láti ṣe àti láti gbé ètò kan jáde láti ka àwọn ìwé mímọ́.

Jóṣúà 3–4

A gbọ́dọ̀ rì mi bọmi láti wọ ìjọba ọ̀run.

  • Ẹ lè lo ìtàn náà nípa àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nsọdá Odò Jọ́dánì bí àmì ìrìbọmi—fífi ìgbé ayé wa àtijọ́ sílẹ̀ nínú a`ginjù kí a sì bẹ̀rẹ̀ ọ`kan titun nínú májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorínáà bí ẹ ti nka Joshua 3–4 papọ̀ (tàbí “Jóṣúà wòlíì náà” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 85–89), bákannáà ẹ lè wo àwòrán ti Jésù tí à nṣe ìrìbọmi fún tí a sì ṣe àlàyé pé Jésù nṣe ìrìbọmi nínú irú odò kannáà tí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì sọdá. Nígbànáà ẹ lè kọ orin kan bí irú “Ìrìbọmi” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 100–101). Ẹ pín pẹ̀lú ara yín bí ṣíṣe ìrìbọmi ṣè dàbí bíbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé titun nínú ìjọba Jésù Krístì.

    2:59

    Joshua the Prophet

Àpapọ̀ àwòrán nfi Jésù tí ó nṣe ìrìbọmi àti ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó nṣe ìrìbọmi hàn

Jóṣúà 24:15

Èmi lè lè yàn láti sin Jésù Krístì.

  • Kínni ẹ lè ṣe láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ láti yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì, bí Jóṣúà ṣe pe àwọn ọmọ Ísráẹ́lì láti ṣe? Ẹ lè pè wọ́n láti:

    • Kọ́ gbólóhùn ọ̀rọ̀ kúkurú kan sórí láti inú Jóṣúà 24:15. Ẹ gbìyànjú láti mú un jẹ́ ìgbádùn fún àwọn ọmọ yín. Iye àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ́ sórí lè dálé ọjọ́ orí wọn.

    • Ẹ wá àwọn ìtàn nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n yàn láti sin Jésù Krístì. Wọ́n lè wo inú ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì , Ìwé Ọnà Ìhìnrere, tàbí Àwọn Ìtan Májẹ̀mú Láéláé àti àwọn ìwé ìtàn ìwé mímọ́.

    • Ẹ ṣe eré àwọn ipò nínú èyítí wọ́n yàn láti tẹ̀lé àti láti sin Olùgbàlà.

Ẹ lo oríṣiríṣi àwọn ṣíṣe. “Gbogbo àwọn ọmọ yàtọ̀, bí wọ́n sì ti ndàgbà, àwọn ìnílò wọn yíò yípadà. Onírúurú àwọn ọ̀nà kíkọ́ni yín yíò ràn yín lọ́wọ́ láti pàdé àwọn oríṣiríṣi ìnílò wọn” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,31).

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .

agba-ààyè-sílẹ̀

Àwọn Ìṣísẹ̀ Àkọ́kọ́ sínú Jọ́dánì, láti ọwọ́ Trent Gudmundsen

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Mo gbọ́dọ̀ ṣe ìrìbọmi láti wọ inú ìjọba ọ̀run