Come, Follow Me
Oṣù Karun 4–10. “Ẹ Máṣe Ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, Tàbí Bẹ̀rù”: Númérì 11–14; 20–24; 27


“Oṣù Karun 4–10. ‘Ẹ Máṣe Ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, Tàbí Bẹ̀rù: Númérì 11–14; 20–24; 27,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Karun 4–10. “Ẹ Máṣe Ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, Tàbí Bẹ̀rù,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026

Fọ́tò ti Wadi Rum

Ijù nítòsí Penisula Sínáì

Oṣù Karun 4– 10: “Ẹ Máṣe Ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, Tàbí Bẹ̀rù”

Númérì 11– 14; 20–24;27

Àní lórí ẹsẹ̀, kò ní gba ogójì ọdún láti rin ìrìnàjò láti aginjù Sínáì lọ sí ilẹ̀ ìlérí ní Kénánì. Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ni àwọn ọmọ Isráẹ́lì ṣe nílò tó—kìí ṣe láti rin àlàfo agbègbè ṣùgbọ́n láti rin àlàfo ti ẹ̀mí: àlàfo ní àárín ẹnití wọ́n jẹ́ àti ẹnití wọ́n le dàbí àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run.

Ìwé ti Númérì júwe àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ogójì ọdún náà, pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ tí àwọn ọmọ Isráẹ́lì nílò láti kó ṣaájú wíwọ ilẹ̀ ìlérí náà. Wọ́n kọ́ nípa jíjẹ́ olotitọ́ sí àwọn ìránṣẹ́ Olúwa (wo Númérì 12). Wọ́n kọ́ nípa gbígbẹ́kẹ̀lé agbára Olúwa (wo Númérì 13–14). Wọ́n sì kọ́ ẹ̀kọ́ pé jíjẹ́ aláìgbàgbọ́ nmú ìpalára ti ẹ̀mí wá, ṣùgbọ́n wọ́n lè ronúpìwàdà kí wọ́n sì wo Olùgbàlà fún ìwòsàn (wo Númérì 21:4–9).

Gbogbo wa dàbí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ní àwọn ọ̀nà kan. A mọ bí ó ti rí láti wà nínú aginjù ti ẹ̀mí, àti pé àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ láti wọ ilẹ̀ ìlérí wa: ìyè ayérayé pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run.

Fún àkópọ̀ ìwé ti Númérì, wo “Númérì” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ

Númérì 11:11–17, 24–29;12

Ìfihàn wà ní àrọ́wọ́tó sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n Ọlọ́run nṣe átọ́nà Ìjọ Rẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀.

Nínu Númérì 11:11–17, 24–29, ẹ kíyèsí wàhálà tí Mósè kojú àti ojútùú tí Ọlọ́run dá ní àbà. Kínni ẹ rò pé ó túmọ̀sí fún Mósè nígbàtí ó wípé òun nfẹ́ “pé gbogbo ènìyàn Olúwa ìbá ti jẹ́ wòlíì”? (ẹsẹ 29). Bí ẹ ti njíròrò ìbèèrè yí, ẹ wá àwọn ìdáhùn tí ó ṣeéṣe nínú ọ̀rọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson “Ìfihàn fún Ìjọ, Ìfihàn fún Ayé Wa” (Làìhónà, Oṣù Karun 2018, 93–96).

Ní sísọ pé gbogbo wa ni a lè gba ìfihàn, bákannáà, kò túmọ̀sí pé gbogbo wa lè darí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ọ̀nà tí Mósè ṣe. Ìṣẹ̀lẹ̀ nínú Númérì 12 mú èyí hàn kedere. Kínni ìkìlọ̀ tí ẹ rí nínú orí yí? Kínni ìmọ̀lára tí ẹ ní pé Olúwa nfẹ́ kí ẹ ní òye nípa ìfihàn araẹni àti títẹ̀lé wòlíì Rẹ̀?

Bákannáà wo 1 Néfì 10:17; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 28:1–7; Dallin H. Oaks, “Ìlà Méjì ti Ìbáraẹnisọ̀rọ̀,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2010, 83–86.

Fojú sí ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ. Àwọn ènìyàn nní ìbonimọ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn àbá kíkàwé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú Wá, Tẹ̀lé Mi. Bí ẹ ti ntún àwọn ìlànà yẹ̀wò, ẹ tẹ̀lé Ẹ̀mí. Ẹ yẹ ìnílò ti ara yín wò nípa àwọn ènìyàn tí ẹ lè máa kọ́. Níní òye àti lílo ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kan ní kíkún ní ọ̀sẹ̀ kan lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ síi ju kíkà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orí nìkan ní òférè.

Númérì 12: 3

“Mósè jẹ́ ọlọ́kàn-tútù gidi.”

Ó ya àwọn ènìyàn lẹ́nu láti kọ́ pé Mósè, olùdarí títóbi tí ó dúró níwájú Fáráò tí ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu yíyani-lẹ́nu pẹ̀lú agbára Olúwa, bákannáà jẹ́ “ọlọ́kàn-tútù gidi” (Númérì 12:3). “Kínni ó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọlọ́kàn-tútù? Ẹ yẹ àlàyé Alàgbà David A. Bednar wò nínú “Ọlọ́kàn-tútù àti onírẹ̀lẹ̀” (Làìhónà, Oṣù Karun 2018, 30–33) tàbí “Ọlọ́kàn-tútù, Ọkàn-tútù” nínú atọ́nà sí àwọn ìwé mímọ́ (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere).

Kínni ẹ kọ́ láti inú àwọn àpẹrẹ ọkàn-tútù Mósè nínú Ẹ́ksódù 18:13–25; Númérì 11:26–29; Númérì 12; Hébérù 11:24–27; àti Mósè 1:10–11? Bákannáà ẹ lè jíròrò bí Olùgbàlà ṣe fi ọkàn-tútù hàn (wo Matteu 11:29; 27:11–14; Lúkù 22:41–42; Jòhánnù 13:4–5). Kínni àwọn àpẹrẹ wọ̀nyí kọ́ọ yín?

Númérì 13–14

Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Olúwa, mo lè ní ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la.

Bí ẹ ti nka Númérì 13–14, ẹ gbìyànjú láti fi ara yín sí ipò àwọn ọmọ Ísráẹ́lì. Kínni ìdí tí ẹ fi rò pé ó fẹ́ láti “padà sí Isráẹ́lì”? (Númérì 14:3). Báwo ni ẹ yíò ṣe júwe “ẹ̀mí” míràn Númérì 16:28 Kínni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa ìgbàgbọ́ Kélẹ́bù àti Jóṣúà, àti bí ẹ ṣe lè lo àwọn àpẹrẹ wọn sí àwọn ipò tí ẹ kojú?

Mósè àti àwọn kan lára àwọn ọmọ Isráẹ́lì ṣe amí

Mẹwa lára àwọn amí ọmọ Isráẹ́lì bẹ̀rù; Jóṣúà àti Kélẹ́bù ní ìgbàgbọ́. Jóṣúà àti Kélẹ́bù: Àwọn Amí Olùgbọ́ran, nípasẹ̀ Douglas Klauba. © Lifeway Collection/licensed láti goodsalt.com

Númérì 21: 4–9

àmì sẹ́mínárì
Bí mo bá wo Jésù Krístì nínú ìgbàgbọ́, Ó lè wò mí sàn níti ẹ̀mì.

Àwọn wòlíì Ìwé ti Mọ́mọ́nì mọ ìtàn tí a rí nínú Númérì 21:4–9 àti láti ní òye pàtàkì ti ẹ̀mí rẹ̀. Ẹ ka àwọn ìkọ́ni wọn nípa ìtàn yí ní 1 Néfì 17:40–41; Álmà 33:18–22; àti Hẹ́lámánì 8:13–15. Ní ìhín ni àwọn ìbèèrè láti jíròrò bí ẹ ti nṣe:

  • Kínni ejò idẹ lè rọ́pò?

  • Kínni bíbùjẹ ejò náà lè rọ́po?

  • Àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ní láti “[kíyèsi] ejo idẹ” (Númérì 21:9) láti di wíwòsàn. Kínni ìdí tí ẹ fi ronú pé àwọn ènìyàn kọ láti wò? Njẹ́ ohun kan náà ti ṣẹlẹ̀ rí sí yín?

  • Kínni ẹ ní ìmọ̀lára ìmísí láti ṣe síi ní kíkún “ẹ wo Ọmọ Ọlọ́run pẹ̀lú ìgbàgbọ́” kí ẹ di wíwòsàn? (Hẹ́lámánì 8:15).

Kíka àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ẹ lè rán ara yín létí nípa àwọn àkokò míràn nínú ìwé mímọ́ nígbàtí àwọn ènìyàn bá nílò láti tẹramọ́ ìfojúsí wọn lórí Krístì. Fún àpẹrẹ, ẹ ṣe àfiwé ọ̀rọ̀ ti Númérì 21:4–9 pẹ̀lú Matteu 14:25–31 àti 1 Néfì 8:24–28 (bákannáà wo àwọn àwòrán ní òpin ìlànà ọ̀sẹ̀ yí). Kínni ó ntẹ́sí fífà wá kúrò ní ọ̀dọ̀ Krístì? Báwo ni Ó ti nbùkún àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ìfojúsí I?

Bákannáà wo “Jésù, Èrò ti Yín Gan” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 141).

Númérì 22–24

Mo lè tẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run, àní bí àwọn míràn ṣe ngbìyànjú láti rọ̀ mí láti má ṣé.

Nígbàtí Bálákì, ọba Móábù, kọ́ pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nbọ̀, ó pe Báláámù, ọkùnrin kan tí a mọ̀ fún kíkéde àwọn ìbùkún àti ègún. Bálákì nfẹ́ kí ó gé ègún fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì. Ẹ kíyèsí bí Bálákì ṣe gbìyànjú láti rọ Báláámù (wo Númérì 22:5–7, 15–17), kí ẹ sì ronú nípa àwọn ìdánwò tí ẹ lè kojú láti lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Kínni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa àwọn ìdáhùn Báláámù nínú Númérì 22:18,38; 23:8, 12, 26; 24:13? Pẹ̀lú ìbànújẹ́, Báláámù nígbẹ̀hìn jọ̀wọ́-ara sí ìfipámú ó sì dalẹ̀ Isráẹ́lì (wo Númérì 31:16; Jude 1:11). Ẹ jíròrò bí ẹ ṣe lè dúró ní òtítọ́ sí Olúwa pẹ̀lú ìfipá mú láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn.

àmì abala àwọn ọmọdé

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Númérì 11: 4–10

Mo lè dúpẹ́ fún ohun tí Ọlọ́run ti fún mi.

  • Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n bá rántí àwọn iṣẹ́ tí Olúwa ṣe láti ran àwọn Ísráẹ́lì lọ́wọ́ (wo “Àwọn Ìyọnu ti Égíptì” àti “Ìrékọjá” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 67–74). Nígbàtí ẹ kò bá lè ṣe àkópọ̀ fún wọn Númérì 11:4–10, ní títẹnumọ pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ti gbàgbé àwọn ìbùkún wọn wọ́n sì nkùnsínú. Kínni àwọn ìbùkún tí à ngbàgbé nígbà míràn?

  • Bí ẹ ti nkọrin tàbí fetísílẹ̀ sí orin kan nípa ìmoore, bí irú “Ẹ Ka àwọn Ìbùkún Yín” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 241),Àwọn ọmọ yín lè ya àwọn àwòrán ti ìbùkún tí Olúwa ti fún wọn.

Númérì 13–12

Olúwa nfẹ́ kí èmi tẹ̀lé wòlíì Rẹ̀.

  • Láti fi Númérì 12, hàn ẹ lè sọ fún àwọn ọmọ yín pé inú Olúwa kò dùn pẹ̀lú Áárónì àti Míríámù, arákùnrin àti arábìnrin Mósè. Pè wọ́n láti ka Númérì 12:1–8 láti wá ìdí rẹ̀. Ẹ yẹ lílo Ìwé Ọnà Ìhìnrere láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti wá àwọn àpẹrẹ ti àwọn ènìyàn nínú ìwé mímọ́ tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún wòlíì Olúwa kí wọ́n sì di alábùkúnfún. Báwo ni a ṣe ndi alábùnkúnfún nígbàtí a bá tẹ̀lé wòlíì Olúwa?

Númérì 21: 6–9

Èmi lè wo Jésù Krístì.

  • Ẹ lè lo “Mósè àti Ejò Idẹ” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 83–84, láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú Númérì 21:6–9. Báwo ni ejò idẹ ṣe dàbí Jésù Krístì? (wo Jòhánnù 3:14–15). Àwọn ọmọ yín lè gbádùn ṣíṣe ejò kan láti inú bébà kí wọ́n sì kọ̀ àwọn ohun ìrọ̀rùn tí wọ́n lè ṣe sí orí rẹ̀ “wo Ọmọ Ọlọ́run pẹ̀lú ìgbàgbọ́” (Hẹ́lámánì 8:15).

    1:2

    Moses and the Brass Serpent

  • Àwọn ọmọ tó dàgbà jù lè yan ọ̀kan lára àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí kí wọ́n sì pín ohun tí ó fikún níní òye wọn nípa ìtàn náà: 1 Néfì 17:41; Álmà 33:18–20; Hẹ́lámánì 8:13–15; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 6:36.

Ejò idẹ

Ejò Idẹ, láti ọwọ́ Brent Evans

Númérì 22–24

Mo lè tẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run, àní bí àwọn míràn ṣe ngbìyànjú láti rọ̀ mí láti má ṣé.

  • Ṣe àkópọ̀ Númérì 22:1–18 fún àwọn ọmọ yín, ní títẹnumọ bí Báláámù ṣe kọ̀ láti fi àwọn ọmọ Ọlọ́run gé ègún, àní bíótilẹ̀jẹ́pé Bálákì, ọba Móábù, fún un ní ọlá àti àwọn ọrọ̀. Nígbànáà ẹ lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti wá áwọn ẹsẹ wọ̀nyí fún àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ní ìmọ̀lára pé ó fihàn pé Báláámù fẹ́ láti tẹ̀lé Ọlọ́run: Númérì 22:18; 23:26; 24:13. Bóyá àwọn ọmọ yín lè mú gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n sì kọ ọ́ sórí káàdì láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rántí láti gbọ́ran sí Olúwa.

Fún púpọ̀ síi, ẹ wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .

àpapọ̀ àwòrán nfi Jésù hàn lórí àgbélèbú, ejò idẹ, Jésù tí ó nran Pétérù lọ́wọ́ láti rìn lórí omi, àti ìran Léhì

Òkè òsì: Ìkànmọ́ àgbélèbú Krístì. Òkè ọ̀tún: Moses and the Brass Serpent, by Judith Mehr. Bottom left: Aláṣeparí Ìgbàgbọ́, láti ọwọ́ Kelsy àti Jesse Lightweave. Ìsàlẹ̀ ọ̀tún: Àlá Lehi, láti ọwọ́ Jerry Thompson

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Èmi lè wo Jésù Krístì.