“Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Inú: Àgọ́ Náà àti Ìrúbọ,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Àgọ́ àti Ìrúbọ Náà,” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Inú
Àgọ́ àti Ìrúbọ Náà
Bí a ti nka Májẹ̀mú Láéláé, nígbàmíràn a lè rí àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ gígùn nípa àwọn ohun tí ó jẹ́ pàtàkì kedere sí Olúwa ṣùgbọ́n tí ó lè má jẹ́ pàtàkì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sí wa ní òní. Ẹ́ksódù 25–30; 35–40 àti Lẹfítíkù 1–9; 16–17 ni àwọn àpẹrẹ. Àwọn orí wọ̀nyí ṣe àpèjúwe ní àlàyé àgọ́ Ísráẹ́lì ní kíníkíní nínú aginjù àti ìrúbọ̀ ẹranko láti ṣe níbẹ̀. Àgọ́ náà jẹ́ tẹ́mpìlì tó ṣe gbé, ibi ibùgbé Olúwa ní àárín àwọn Ènìyàn Rẹ̀.
Àwọn tẹ́mpìlì wa ode òní pín àwọn ìfarajọ pẹ̀lú àgọ́ Ísráẹ́lì, ṣùgbọ́n dájúdájú wọn kò bá ìjúwe rẹ̀ nínú Ẹ́ksódù mu. Akìí sìí pa ẹranko nínú àwọn tẹ́mpìlì wa—Ètùtù Olùgbàlà parí ìrúbọ ẹranko ní bíi ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́hìn. Síbẹ̀ bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí wà, iyì nlá wà ní òní ní kíkà nípa ìrísí ìjọsìn ti Ísráẹ́lì àtijọ́, nípàtàkì bí a bá rí wọn bí àwọn ènìyàn Ọlọ́run nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti ṣe—ní ọ̀nà kan “láti fún ìgbàgbọ́ wọn nínú Krístì lókun” (Álmà 25:16). Nígbàtí a bá ní òye ti àmì nípa àgọ́ àti ìrúbọ̀ ẹranko, a lè jèrè ìjìnlẹ̀ òye tí yíò fún ìgbàgbọ́ wa nínú Krístì lókun bákannáà.
Ẹbọ Ọrẹ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, láti ọwọ́ Robert T. Barrett
Àgọ́ Nfún Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Lókún
Nígbàtí Ọlọ́run pàṣẹ fún Mósè láti kọ́ àgọ́ nínú ìpàgọ́ àwọn ará Ísráẹ́lì: “kí Èmi ó lè gbé ní àárin wọn” (Ẹ́ksódù 25:8). Nínú àgọ́, wíwà ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a rọ́pò nípa àpótí ti májẹ̀mu—igi àpótí kan, tí a bò pẹ̀lú idẹ, tí ó ní àwọn àkọsílẹ̀ kíkọ́ ti májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Rẹ̀ nínú. Àpótí náà ni a pamọ́ sínú yàrá mímọ́ jùlọ, nínú jùlọ, ní ìyapa kúrò nínú ìyókù ti àgọ́ nípa ìbòjú kan. Ìbòjú yí lè fi àmì ìyapa kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nítorí Ìṣubú, bákannáà bí ọ̀nà wa padà sí I—nípasẹ̀ Olùgbàlà.
Yàtọ̀ sí Mósè, a mọ ẹnìkanṣoṣo tí ó lè wọ “ibi mímọ́ jùlọ” (Ẹ́ksódù 26:34)—àlùfáà gíga. Bíiti àwọn àlùfáà míràn, ó kọ́kọ́ níláti jẹ́ wíwẹ́ àti fífi àmì òróró yàn tí a sì wọ̀ ní aṣọ mímọ́ ní àmì ti ipò iṣẹ́ rẹ̀. Ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, ní ọjọ́ tí a pè ní Ọjọ́ Ètùtù, àlùfáà gíga yíò rú ẹbọ ọrẹ ní ìtìlẹhìn àwọn ènìyàn ṣíwájú dídá wọ inú àgọ́. Ní ibi ìbòjú, òun yíò jó tùràrí. Òórùn èéfín náà yíò gòkè re ọ̀run ní ìrọ́pò àwọn àdúrà ti àwọn ènìyàn tí ó ngòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Lẹ́hìnnáà àlùfáà gíga, ó gbé ẹ̀jẹ̀ láti inú ẹbọ ọrẹ ẹranko kan, yíò sì kọjá nínú ìbòjú yíò sì dé ìtẹ́ Ọlọ́run, fi àmì nípa àpótí ti májẹ̀mú hàn.
Ní mímọ ohun tí ẹ mọ̀ nípa Jésù Krístì àti ojúṣe Rẹ̀ nínú ètò Baba Ọ̀run, njẹ́ ẹ lè rí bí àgọ́ ṣe nnawọ́ wa sí Olúgbàlà? Gẹ́gẹ́bí àgọ́, àti àpótí inú rẹ̀, rọ̀pò wíwà Ọlọ́run ní àárín àwọn ènìyàn Rẹ̀, Jésù Krístì ni wíwà Ọlọ́run ní àárín àwọn ènìyàn Rẹ̀. Bíiti àlùfáà gíga, Jésù Krístì ni Onílàjà ní àárín wa àti Ọlọ́run Baba. Ó kọjá nínú ìbòjú láti ṣe àgbàwí fún wa nípa agbára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ọrẹ ti ara Rẹ̀.
Àwọn ìrísí ti àgọ́ Ísráẹ́lì kan dàbí ó lè jẹ́ mímọ̀ sí yín, nípàtàkì bí ẹ bá ti lọ sí tẹ́mpìlì láti gba àwọn ìlànà ti arayín. Tẹ́mpìlì ni ilé Olúwa—ibi ibùgbé Rẹ̀ ní àárín àwọn Ènìyàn Rẹ̀. Bíiti àgọ́ ti ibi mímọ́ jùlọ, yàrá sẹ̀lẹ́stíà ti tẹ́mpìlì nrọ́pò wíwà ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Láti wọlé, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ wíwẹ̀ kí a gba àmì òróró. À nwọ aṣọ mímọ́. A ndá àwọn májẹ̀mú. A gbàdúrà níbi pẹpẹ láti inú èyí tí àwọn àdúrà nkògè lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. A sì kọjá nínú ìkelè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nígbẹ̀hìn.
Bóyá pàtàkì jùlọ ríríbákannáà ní àárín àwọn tẹ́mpìlì òde òní àti àgọ́ àtijọ́ ni pé méjèèjì, bí a bá ní òye déédé, nfún ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì lókun ó sì nkún inú wa pẹ̀lú ìmoore fún ẹbọ ọ̀rẹ ètùtù Rẹ̀. Ọlọ́run nfẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ wọlé wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀; Ó nfẹ́ “ìjọba àwọn àlùfáà kan” àti àwọn àlùfáà obìnrin (Ẹ́ksódù 19:6). Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ndí wa lọ́wọ́ kúrò ní gbígba ìbùkún náà, nítorí “kò sí ohun àìmọ́ kankan tí ó lè gbé pẹ̀lú Ọlọ́run” (1 Néfì 10:21). Nítorínáà Ọlọ́run Baba rán Jésù Krístì, “àlùfáà gíga ohun gbogbo tí ó nbọ̀” (Hébérù 9:11). Ó pín ìbòjú fún wa ó sì ró gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run lágbára láti “wá sí ìbi ìtẹ́ oore ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà” (Hébérù 4:16).
Ní òní, èrèdí àwọn tẹ́mpìlì pọ̀ ju gbígba ìgbéga fún arawa. Lẹ́hìn gbígba àwọn ìlànà ti arawa kí a sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, a lè dúró ní ipò ti àwọn babanlá wa kí a sì gba àwọn ìlànà ní ìtìlẹhìn wọn. Nínú ọgbọ́n kan, a lè di ohunkan bíiti àlùfáà gíga àtijọ́—àti pé Àlùfáà Gíga Nlá—nṣí ọ̀nà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn.
Ẹbọ Ọrẹ Nfún Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù Krístì Lókun.
Àwọn ẹkọ́ ìpìlẹ̀ ètùtù àti pé bíbálàjà ni a kọ́ni pẹ̀lú agbára nínú ìṣe àtijọ́ ti ẹbọ ọrẹ ẹranko, èyítí ó ti wà fún ìgbà pípẹ́ ṣaájú òfin Mósè. Ádámù àti Éfà rú ẹbọ ọrẹ. Wọ́n ní òye pé àmì rẹ̀ tọ́ka sí ẹbọ ọrẹ Olùgbàlà. Wọ́n sì fi èyí kọ́ àwọn ọmọ wọn.
Àmì ti ẹbọ ọrẹ ẹránko lè ti dàbí dídùnmọ́ni nípàtàkì ní Ọjọ́ Ètùtù ti Ísráẹ́lì àtijọ́ (“Yom Kippur” ní èdè Hébérù). Ìnílò fún ayẹyẹ ọdọọdún yí ni a fihàn nínú Lẹ́fítíkù 16:30: “Ní ọjọ́ náà ni a ó ṣe ètùtù fun yín, láti wẹ̀ yín mọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín níwájú Olúwa.” Èyí gba wíwá ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti dúró ní àárín àwọn ènìyàn náà. Ètùtù yí ni a ṣe yọrí nípasẹ̀ onírúurú àwọn ayẹyẹ. Ní ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí, a pa ewúrẹ́ kan bí rírú ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn náà, àti pé àlùfáà gíga gbé ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà sínú ibi mímọ́ jùlọ. Lẹ́hìnnáà, àlùfáà gíga gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ewúrẹ́ ààyè yíò sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì—pẹ̀lú àmì fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọnnì lọ sí ara ewúrẹ́. Ewúrẹ́ náà ni a ó lé jáde ìpàgọ́ ti Ísráẹ́lì lẹ́hìnnáà.
Nínú àwọn ọ̀nà ẹ̀sìn wọ̀nyí, àwọn ewúrẹ́ fi àmì Jésù Krístì hàn, ní gbígba ipò àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀. A kò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀ṣẹ̀ láàyè ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n dípò píparun tàbí lílé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jáde, Ọlọ́run pèsè ọ̀nà míràn—ewúrẹ́ kan yíò di pípa tàbí lílé jáde dípò bẹ́ẹ̀. “Ewúrẹ́ náà yíò sì gba gbogbo àìṣedéédé wọn lé orí ara rẹ̀” (Lẹ́fítíkù 16:22).
Àwọn ọ̀nà ẹ̀sìn wọ̀nyí nawọ́ sí ọ̀nà tí Ọlọ́run ti pèsè láti mú wa padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀—Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀. Olùgbàlà ni ó “ru ìbànújẹ́ wa, ó sì gbé ìkáàánú wa lọ,” àní “àìṣedéédé gbogbo wa” (Ísáíàh 53:4, 6). Ó dúró ní ipò wa, Ó fúnni ní ayé Rẹ̀ láti san ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀, àti nígbànáà láti ṣẹ́gun ikú nípasẹ̀ Àjíìnde Rẹ̀ . Ẹbọ ọrẹ ti Jésù Krístì ni “ẹbọ ọrẹ nlá a`ti ìgbẹ̀hìn; bẹ́ẹ̀ni, kìí ṣe ẹbọ ọrẹ ti ènìyàn. Tàbí ti ẹranko” ṣùgbọ́n “ẹbọ ọrẹ àìlópin àti ayérayé” (Álmà 34:10). Òun ni olùmúṣẹ ti ohun gbogbo tí àwọn ẹbọ ọrẹ àtijọ́ nawọ́ sí.
Fún èrèdí yí, lẹ́hìn tí ìrúbọ Rẹ̀ parí, Ó wípé “Ẹ̀yin kòsì ní rú ẹbọ ìtàjẹ̀sílẹ̀ sí mi mọ́; bẹ́ẹ̀ni, àwọn ọrẹ ẹbọ yín … yíò dópin. … Ẹ̀yin yíò sì rú ẹbọ ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ sí mi fún ọrẹ ẹbọ” (3 Néfì 9:19–20).
Nitorínáà nígbàtí ẹ bá rí àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ nínú Májẹ̀mú Láéláé nípa ẹbọ ọrẹ àti àgọ́ (tàbí, lẹ́hìnnáà, tẹ́mpìlì)—ẹ ó sì rí púpọ̀ lára wọn—ẹ rántí pé kókó èrèdí ti gbogbo rẹ̀ ni láti fún ìgbàgbọ́ yín nínú Mèssíàh, Jésù Krístì lókun. Ẹ so ohun tí ẹ̀ nkà àti kíkọ́ pọ̀ mọ́ ìjọsìn yín nínú ilé Rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín yípadà sí I. Ẹ jíròrò ohun tí Ó ti ṣe láti mú yín padà wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—àti ohun tí ẹ ó ṣe láti tẹ̀lé E.