Oṣù Kẹrin 20–26. ‘Gbogbo Èyítí tí Olúwa Wí Ni A Ó Ṣe’: Ẹ́ksódù 19–20; 24; 31–34,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
Oṣù Kẹrin 20–26. “Gbogbo Èyítí tí Olúwa Wí Ni A Ó Ṣe,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Mósè àti àwọn Wàláà, láti ọwọ́ Jerry Harston (àlàyé)
Oṣù Kẹrin 20–26: “Gbogbo Èyítí tí Olúwa Wí Ni A Ó Ṣe”
Ẹ́ksódù 19–20;24; 31–34
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ti ráhùn tí wọ́n sì yẹsẹ̀ ní àtẹ̀hìnwá, nígbàtí Mósè ka àṣẹ ní ẹsẹ̀ Òke Sínáì, wọ́n dá májẹ̀mú: “Gbogbo èyítí Olúwa wí ni a ó ṣe, àwa ó sì gbọ́ran” (Ẹ́ksódù 24:7). Nígbànáà Ọlọ́run pe Mósè sórí òkè, ó wí fún kí ó kọ́ àgọ́ kan kí “èmi ó lè gbé ní àárín wọn” (Ẹ́ksódù 25:8).
Ṣùgbọ́n nígbàtí Mósè wà ní orí òkè ní kíkọ́ bí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ṣe lè ní wíwà Ọlọ́run ní àárín wọn, àwọn ọmọ Ísráẹ́lì wà ní ìsàlẹ̀ òkè tí wọ́n nya èrè wúrà láti sìn dípò bẹ́ẹ̀. Láìpẹ́ lẹ́hìnnáà tí wọ́n ti ṣe ìlérí láti “máṣe ní ọlọ́run míràn,” wọ́n “yípadà kánkán” kúrò nínú ìlérí wọn (Ẹ́ksódù 20:3; 32:8; bákannáà wo Ẹ́ksódù 24:3). Ó jẹ́ ìyípadà yíyanilẹ́nu, ṣùgbọ́n a mọ̀ láti inú ìrírí pé ìgbàgbọ́ àti ìfarajìn nígbàmíràn ni àìní-sùúrù, ẹ̀rù, iyèméjì lè borí. Bí a ti nwá wíwà Ọlọ́run nínú ayé wa, ó jẹ́ ìgbani-níyànjú láti mọ̀ pé Olúwa kò fi àwọn Ísráẹ́lì àtijọ́ sílẹ̀ Òun kì yíò sì fi wá sílẹ̀ àti àwọn tí a fẹ́ràn—nítorí Òun jẹ́ “aláàánú àti olóre-ọ̀fẹ́, onípamọ́ra, àti ẹni tí ó pọ̀ ní ore àti òtítọ́” (Ẹ́ksódù 34:6).
Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ
Ẹ́ksódù 19:3–6
Awọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa ni ìṣura sí I.
Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni: “Nínú Májẹ̀mú Láéláé, ọ̀rọ̀ náà Hébérù láti inú èyí tí a ti ṣe ìyírọ̀padà pàtàkì sí ni ségúllàh, èyí tí ó túmọ̀ sí ‘ohun-ìní oníyelórí,’ tàbí ‘ìṣúra.’ … Fún wa láti jẹ́ dídámọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa bí àwọn ènìyàn pàtàkì rẹ̀ ni oríyín ti èrò gígajùlọ” (“Àwọn Ọmọ ti Májẹ̀mú,” Ẹ́nsáìnì, Oṣù Karun 1995, 34). Báwo ni ọ̀rọ̀ Ààrẹ Nelson ti ṣe ní ipa sí ọ̀nà tí ẹ fi ní òye Ẹ́ksódù 19:3–6? Báwo ni Olúwa ti fi hàn yín pé ẹ jẹ́ ìṣúra sí I?
Ẹ́ksódù 19:10–11, 17
Àwọn ìrírí mímọ́ nílò ìmúrasílẹ̀.
Olúwa wí fún Mósè pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nílò láti múrasílẹ̀ ṣíwájú kí wọ́n lè “pàdé Ọlọ́run” (Ẹ́ksódù 19:10–11, 17) kí wọ́n sì pa májẹ̀mú kan mọ́ pẹ̀lú Rẹ̀ (wo Ẹ́ksódù 19:5). Báwo ni ẹ ṣe nmúrasílẹ̀ fún àwọn ìrírí ti-ẹ̀mí, pẹ̀lú àwọn ìlànà ti oúnjẹ́ Olúwa àti tẹ́mpìlì? Báwo ni ẹ ṣe lè ràn àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀? Kínni ẹ kọ́ nípa ìmúrasílẹ̀ láti inú Lúkù 6:12–13; Énọ́sì 1:2–6; Álmà 17:2–3?
Òkè yí ní Égíptì níti àṣà ni a gbàgbọ́ pé ó jẹ́ Òkè Sínáì.
Ẹ́ksódù 20:1–17
Ìgbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run nmú àwọn ìbùkún wá.
Nígbàtí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì kórajọ ní ìsàlẹ̀ Òkè Sínáì, wọ́n gbọ́ ohùn Ọlọ́run tí ó nfún wọn ní àwọn Òfin Mẹ́wa (wo Deuterónómì 4:12–13). Bẹ́ẹ̀ni, ìwọ̀nyí, nìkan kọ́ ni àwọn òfin Ọlọ́run—àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ míràn wa nínú ìwé mímọ́. Nítorínáà bí ẹ ti nka Ẹ́ksódù 20:1–17, ẹ bi ara yín léèrè ìdí tí Ọlọ́run fi tẹnumọ́ àwọn mẹwa wọ̀nyí ní pàtàkì. Ní ìhìn ni àpẹrẹ tábìlì kan tí ẹ̀yin yíò lò bí ẹ ti njíròrò pàtàkì àwọn òfin Mẹ́wa nínú ayé yín.
|
Òfin |
Ní ọ̀rọ̀ míràn, Olúwa nbèèrè lọ́wọ́ mi láti … |
Àwọn ìbùkún tí ó nwá láti inú gbígbé òfin yí |
|---|---|---|
-
Báwo ni pípa àwọn òfin mẹwa wọ̀nyí mọ́ ṣe nràn yín lọ́wọ́ láti pa òfin méjì nlá tí Jésù fúnni nínu Matteu 22:34–40mọ́?
-
Kínni àwọn ohun tí ẹ lè ti ní ìdánwò láti gbé síwájú Ọlọ́run? Àwọn ìbùkún wo ni ẹ ti rí láti inú fífi Ọlọ́run ṣíwájú?
-
Báwo ni ẹ ṣe fèsì sí ẹnìkan tí ó wípé àwọn Òfin Mẹ́wa ni a fúnni ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn àti pé kò wúlò fún ọjọ́ òní? Kínni àwọn àpẹrẹ láti inú ayé yín tí ẹ fẹ́ láti pín bí ara ìfèsì yín? Báwo ni orin ìsìn “Báwo ni àwọn Àṣẹ Ọlọ́run ti Rọ̀ Tó” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 125) ṣe lè ní ipa ní ọ̀nà tí ẹ fi nṣàlàyé àwọn òfin Ọlọ́run sí àwọn ẹlòmíràn?
-
Báwo ni Olúwa ṣe nmú ìlérí Ẹ́ksódù 20:6 ṣẹ nínú ayé yín?
Bákannáà wo “Òfin Nlá—Fẹ́ràn Olúwa,” nínú Ìkọ́ni àwọn Ààrẹ Ìjọ: Ezra Taft Benson (2014), 37–45; Dallin H. Oaks, “Kò Sí Ọlọ́rún Míràn,” Làìhónà, Nov. 2013, 72–75; Àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Àwọn Òfin,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Ẹ́ksódù 24:1–11
Dídá àwọn májẹ̀mú fi ìfẹ́ mi hàn láti gbọ́ràn sí àṣẹ Ọlọ́run.
Bí ẹ ti nka Ẹ́ksódù 24:3–8, ẹ yẹ àwọn májẹ̀mú tí ẹ ti dá pẹ̀lú Ọlọ́run wò. Nígbàtí májẹ̀mú Ísráẹ́lì wà pẹ̀lú àwọn ìlànà ìsìn tí ó yàtọ̀ kúrò ní ohun tí Ọlọ́run nfẹ́ ní òní, ẹ lè ṣe àkíyèsí àwọn ìbáramu. Fún àpẹrẹ, àwọn ẹsẹ 4, 5, àti 8 tí a mẹ́nuba pẹpẹ, àwọn ìrúbọ ohun-ọ̀sìn, àti ẹ̀jẹ̀. Kínni àwọn ohun wọ̀nyí rọ́pò, àti pé báwo ni wọ́n ṣe bá àwọn májẹ̀mú yín mu?
Ẹ́ksódù 32– 34
Ẹ̀ṣẹ̀ ni yíyí kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; ìrònúpìwàdà ni yíyí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti kúrò nínú ibi.
Ẹ gbìyànjú láti fi ara yín sí ipò àwọn ọmọ Ísráẹ́lì—ẹ wà nínú aginjù, Mósè ti lọ fún ogójì ọjọ́, tí ìdojúkọ pẹ̀lú àwọn ará Kénánì lórí ilẹ̀ ìlérí sì wà nínú ọjọ́ ọ̀là yín (wo Ẹ́ksódù 32:1–8). Kínni ìdí tí ẹ fi rò pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì nfẹ́ ère wúrà? Kínni ó mísí yín nípa ẹ̀bẹ̀ Mósè sí Olúwa nínú Ẹ́ksódù 33:11–17?
Nígbàtí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísráẹ́lì le gidi, bákannáà ìtàn yí wà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti àánú àti ìdáríjì. Kínni Ẹksódù 34:1–10 kọ́ọ yín nípa Olùgbàlà? (wo Ẹ́ksódù 32:30–32; Mòsíàh 14:4–8; 15:9; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 45:3–5).
Ẹ́ksódù 31:13–16
Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ àmì kan
Ààrẹ Russell M. Nelson ṣe àlàyé: “Ní àwọn ọdún ti mo ṣì kéré ju báyi lọ, mo kọ́ iṣẹ́ àwọn ẹlòmiràn tí wọ́n ti ṣe àkójọ àwọn àtòsílẹ̀ àwọn ohun tí ó le jẹ́ ṣíṣe àti àwọn ohun tí kò le jẹ́ ṣíṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ní ìgbẹ̀hìn gbẹ́hín ni mo kọ́ láti inú àwọn ìwé mímọ́ pé ìṣe àti ìwà mi ní Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ àmì kan ní àárín èmi àti Baba mi Ọrun [wo Ẹ́ksódù 31:13; Èsèkíẹ́lì 20:12, 20]. Pẹ̀lú òye náà, èmi kò nílò àwọn àtòsílẹ̀ mọ́ nípa àwọn ṣíṣe àti àwọn máṣe. Nígbàtí mo bá níláti ṣe ìpinnu kan bóyá ìṣe kan dára tó fún Ọjọ́ Ìsinmi tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, mo kàn máa nbi ara mi léèrè pé, ‘Irú àmì wo ni mo fẹ́ láti fifún Ọlọ́run?’ Ìbéèrè yi mú àwọn yíyàn mi nípa Ọjọ́ Ìsinmi ṣe kedere bíi kírísítà.” (“Ọjọ́ Ìsinmi Jẹ́ Adùn,” Làìhónà, Oṣù Karun 2015, 130). Ẹ jíròrò irú àmì tí ẹ fẹ́ láti fífún Ọlọ́run pẹ̀lú ṣíṣe àkíyèsí Ọjọ́ Ìsinmi.
Ẹ́ksódù 34:1–4
Kínni ìyàtọ́ ní àárín àwọn wàláà òkútà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Mósè ṣe?
Nígbàtí Mósè wá sísàlẹ̀ láti òkè, ó mú òfin kíkọ́ lórí àwọn wàláà òkúta wá. Lẹ́hìn ríri pé àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ti já májẹ̀mú wọn, Mósè fọ́ àwọn wàláà náà (wo Ẹ́ksódù 31:18; 32:19). Lẹ́hìnnáà, Ọlọ́run pàṣẹ fún Mósè láti ṣe àwọn wàláà òkúta míràn (wo Ẹ́ksódù 34:1–4). Ìyírọ̀padà Jósẹ́fù Smith ti Ẹ́ksódù 34:1–2 (nínú àfikún Bíbélì) ṣe àrídájú pé àwọn wàláà òkútà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àkọ́kọ́ wà pẹ̀lú àwọn ìlànà ti Ọlọ́run “èrò mímọ́,” tàbí Oyè Àlùfáà Melkísédékì. Ìkejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wà pẹ̀lú “àṣẹ ti òfin ara.” Èyí ni àṣẹ kíkéréjù tí a fi fúnni nípa “oyè àlùfáà kíkéréjù” (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:17–27), èyí tí ó túmọ̀ sí mímúra àwọn ọmọ Ísráẹ́lì sílẹ̀ fún àṣẹ gígajù àti oyè àlùfáà gígajù kí wọ́n lè wọ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí nínú àwọn ìwé-ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Ẹ́ksódù 20:3–17
Ọlọ́run fún mi ní àwọn òfin nítorí Òun fẹ́ kí nní inú dídùn.
-
Báwo ni ẹ ṣe lè mú kíkọ́ni nípa àwọn òfin mẹ́wa jẹ́ ìgbádùn fún àwọn ọmọ yín? Bí a ti nka Ẹ́ksódù 20:3–17 papọ̀, ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín ràn yín lọ́wọ́ láti rí tàbí ya àwòrán kan láti rọ́pò ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn Òfin Mẹwa. Nígbànáà àwọn ọmọ yín lè yí yíyan àwòrán kan àti sísọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ti lè gbé òfin náà. Ẹ pín pẹ̀lú ara yín bí gbígbé òfin náà ṣe nmú ìnú dídùn wá fún yín.
-
Bákannáà ẹ lè kọ orin kan bíi “Pa àwọn Òfin Mọ́” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 146–47). Ẹ ran àwọn omodé lọ́wọ́ láti rí àwọn ọ̀rọ̀ orin tí ó nkọ́ wọn ní ìdí tí Ọlọ́run fi fẹ́ kí a pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.
Nígbàtí àwọn ọmọ bá pín àwọn ìrírí ti-ẹ̀mí, ẹ̀rí wọn ó dàgbà si. Àwọn ìbèèrè tí ẹ bèèrè lè gba àwọn ọmọ yín níyànjú láti pín bí wọ́n ṣe ní ìmọ̀lára nípa Olùgbàlà àti bí gbígbé ìhìnrere ṣe bùkún wọn (wo Ìkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,32). Nígbàtí wọ́n bá ṣe èyí, wọ́n njẹ́ ẹ̀rí. Ẹ yẹ bí ẹ ti lè ṣe èyí wò bí ẹ ti nsọ̀rọ̀ àwọn ìbùkún tí ó nwá láti inú gbígbé àwọn òfin mẹwa.
Ẹ́ksódù 14:29
Olúwa nfẹ́ kí èmi bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí mi.
-
Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ gbólóhùn “Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ” (Ẹ́ksódù 20:12). Ẹ lè fẹ́ láti ṣe àlàyé pé láti “bọ̀wọ̀” fún ẹnìkan lè túmọ̀ sí fifi ọlá hàn fún wọn tàbí láti mú ìnú dídùn wá fún wọn. Kínni Jésù ṣe láti bọ̀wọ̀ fún ìyá ti ayé ikú Rẹ̀ àti Baba Ọ̀run? (wo Lúkù 2:48–51; Jòhánnù 19:26–27). Bóyá àwọn ọmọ yín lè yí ṣíṣe ìṣe ti àwọn ohun tí wọ́n nṣe ká láti bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn, nígbàtí àwọn ọmọ míràn bá ṣe àròsọ ohun tí wọ́n nṣe.
Ẹ́ksódù 31:13, 16–17
Bíbọ̀wọ̀ fún Ọjọ́ Ìsinmi ni àmì ti ìfẹ́ mi fún Olúwa.
-
Àwọn ọmọ yín lè gbádùn wíwo àwọn àpẹrẹ ti àwọn àmì—bí irú àwọn àmì òpópónà tàbí àwọn àmì ti kíkọ́lé. Kínni àwọn èrèdí ti àwọn àmì? Àwọn ọmọ yín lè rí ọ̀rọ̀ náà “àmì” ní Ẹ́ksódù 31:13, 16–17. Kínni Olúwa wípé ó jẹ́ àmì kan ní àárín wa àti Òun? Ẹ pín àwọn ọ̀nà tí ẹ̀yin àti ẹbí yín fi gbìyànjú láti fi ìfẹ́ yín hàn fún Olúwa ní Ọjọ́ Ìsinmi pẹ̀lú ara yín.
Ìjúwe ti Mósè tí ó ndi àwọn Òfin Mẹ́wa mú, láti ọwọ́ Sam Lawlor (àlàyé)
Ẹ́ksódù 32:1–8, 19–24; 34:6–7
Èmi kò ní “yípadà” kúrò ní àwọn ọ̀nà Ọlọ́run.
-
Yẹ lílo “Mósè lórí Òkè Sínáì” (nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 77–82) láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ ìtàn náà nínú Ẹ́ksódù 32:1–8, 19–24. Kínni ìdí tí kò fi tọ́ fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì láti jọ́sìn ère dípò Ọlọ́run?
2:55Moses on Mount Sinai
-
Ó lè dùn láti dá ipa ọ̀nà kan sílẹ̀ lórí ilẹ̀ (tàbí rí ọ̀kan nítòsí ilé yín) sí ìjúwe àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti inú Ẹ́ksódù 32:8: “Wọ́n yípadà kánkán kúrò ní ipa-ọ̀nà.” Nígbàtí à nrìn lórí ipa-ọ̀nà, àwọn ọmọ wa lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìdánwò tí a kọjúsí láti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Kínni ó nràn wá lọ́wọ́ láti dúró lórí ipa-ọ̀nà Ọlọ́run—àti láti padà sí i bí a bá ṣákolọ? (wo Ẹ́ksódù 34:6–7).
Fún púpọ̀ síi, ẹ wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .