“Oṣù Kẹta 30 sí Oṣù Kẹrin 5. ‘Òun Yíò Gbé Ikú Mì nínú Ìṣẹ́gun’: Ọdún-Àjínde,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹta 30 sí Oṣù Kẹrin 5. ‘Òun Yíò Gbé Ikú Mì nínú Ìṣẹ́gun,’” Wá, Tẹ̀lé Mi: Májẹ̀mú Láéláé 2026
Ìjúwe ibojì tó ṣófo
Oṣù Kẹta 30 sí Oṣù Kẹrin 5: “Òun Yíò Gbé Ikú Mì nínú Ìṣẹ́gun” Ọdún Àjínde
Ọdún-Àjínde
Ìgbésí ayé Jésù Krístì “ni àárín-gbungbun sí ìwé-ìtàn gbogbo ènìyàn” (“Krístì Alààyè: Ẹ̀rí àwọn Àpóstélì,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Kínni ìyẹn túmọ̀ sí? Ní apákan, ó túmọ̀sí pé ìgbé ayé Olùgbàlà nní ipá lórí àyànmọ́ ayérayé ti gbogbo ẹnití ó ti gbé rí tàbí yíò gbé láéláé. Bákannáà ẹ lè wọ pé Àjínde Jésù Krístì, ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọdún Àjínde àkọ́kọ́, so gbogbo ènìyàn ní gbogbo ìwé-ìtàn: àwọn wọnnì tí a bí ṣíwájú Àjínde Rẹ̀ nwo iwájú sí i pẹ̀lú ìgbàgbọ́ (wo Jákọ́bù 4:4), àti àwọn wọnnì tí a bí lẹ́hìnnáà wo ẹ̀hìn lórí rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Bí a ti nka àwọn àkọsílẹ̀ Májẹ̀mú Láéláé àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀, a kò rí orúkọ Jésù Krístì rí, ṣùgbọ́n a rí ẹ̀rí ti ìgbàgbọ́ àwọn onígbàgbọ́ àtijọ́ nínú àti ní ìfojúsọ́nà fún Mèsíàh àti Olùràpadà wọn. Nítorínáà àwa ẹni tí a pè láti rántí Rẹ̀ lè ní ìsopọ̀ ìmọ̀lára kan pẹ̀lú àwọn ẹnití wọ́n nfojúsọ́nà sí I. Nítorí lódodo Krístì ru “àìṣedéédé wa gbogbo” (Ísáíàh 53:6; àtẹnumọ́ àfikún), àti “nínú Krístì ni gbogbo ènìyàn yíò di yíyè” (1Kọ́ríntì 15:22; àtẹnumọ́ àfikún).
Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ
Àwọn wòlíì àtijọ́ àti òde òní jẹ́ ẹ̀rí nípa ìrúbọ̀ ètùtù Olùgbàlà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ nínú Májẹ̀mú Láéláé nawọ́ sí iṣẹ́́ ìrànṣẹ́ àti ètùtù ìrúbọ ètùtù. Tábìlì ìsàlẹ̀ ṣe ìtòsílẹ̀ àwọn ẹsẹ wọ̀nyí. Bí ẹ ti nka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, kínni ìwọnilọ́kàn tí ó nwá síi yín nípa Olùgbàlà?
|
Májẹ̀mú Láéláé |
Májẹ̀mú Titun |
|---|---|
Májẹ̀mú Láéláé Sekaríà 9:9 | Májẹ̀mú Titun Máttéù 21:1–11 |
Májẹ̀mú Láéláé Sekaríà 11:12–13 | Májẹ̀mú Titun Máttéù 26:14–16; 27:3–8 |
Májẹ̀mú Láéláé Ìsàíàh 53:4 | Májẹ̀mú Titun Máttéù 8:16–17; 26:36–39 |
Májẹ̀mú Láéláé Ìsàíàh 53:7 | Májẹ̀mú Titun Márkù 14:60–61 |
Májẹ̀mú Láéláé Orin Dáfídì 22:16 | Májẹ̀mú Titun Jòhánnù 19:17–18; 20:25–27 |
Májẹ̀mú Láéláé Orin Dáfídì 22:18 | Májẹ̀mú Titun Máttéù 27:35 |
Májẹ̀mú Láéláé Orin Dáfídì 69:21 | Májẹ̀mú Titun Máttéù 27:34, 48 |
Májẹ̀mú Láéláé Orin Dáfídì 118:22 | Májẹ̀mú Titun Máttéù 21:42 |
Májẹ̀mú Láéláé Ìsàíàh 53:9, 12 | Májẹ̀mú Titun Máttéù 27:57–60; Márkù 15:27–28 |
Májẹ̀mú Láéláé Ìsàíàh 25:8 | Májẹ̀mú Titun Márkù 16:1–6; Lúkù 24:6 |
Májẹ̀mú Láéláé Dáníẹ́lì 12:2 | Májẹ̀mú Titun Máttéù 27:52–53 |
Àní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó kọ́ni nípa Olùgbàlà tilẹ̀ jẹ́ púpọ̀ àti kedere nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ẹ gbèrò bí ìgbàgbọ́ yín ṣe ngba ìfúnlókun nípa àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ bí ìwọ̀nyí : 1 Néfì 11:31–33; 2 Néfì 25:13; Mòsíàh 3:2–11; Álmà 7:10–13.
Àwọn wòlíì ọjọ́-ìkẹhìn tẹ̀síwájú láti jẹ́ ẹlẹ́rìí pàtàkì ti Jésù Krístì àti iṣẹ́ ìránṣẹ ètùtù Rẹ̀. Bí ẹ ṣe nfetísílẹ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ní opin ọ̀sẹ̀ Ọdún Àjínde yí, ẹ ṣe àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ti àwọn ẹ̀rí ti Jésù Krístì tí ẹ gbọ́. Kínni wọ́n kọ́ yín nípa Rẹ?
Jésù Krístì nfún mi ní àlàáfíà àti ayọ̀.
Ọdún Àjínde jẹ́ àkókò aláyọ̀, nítorí ó jẹ́ àkókò láti ṣe ayẹyẹ Ètùtù àti Àjínde Olùgbàlà. Àti síbẹ̀, àní ní àkokò Ọdún Àjínde, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn wà tí wọn nímọ̀lára ayọ̀ fún àwọn èrèdí oríṣiríṣi. Kínni ẹ lè ṣe láti tan àlàáfíà àti ayọ̀ Olùgbàlà ní Ọdún Àjínde yí?
Èrò kan ni láti wá àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ nínú àwọn ìwé mímọ́ nípa àlàáfíà àti ayọ̀ tí Jésù Krístì fúnni, bíiti ìwọ̀nyí: Orin Dáfídì 16:8–11; 30:2–5; Ísáíàh 12; 25:8–9; 40:28–31; Jòhánnù 14:27; 16:33; Álmà 26:11–22. Ẹ gbèrò bí ẹ ṣe lè pín àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Fún àpẹrẹ, bóyá ẹ lè dá káàdì Ọdún Àjínde sílẹ̀ láti pín, tí ó dálé àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ẹ máa gbàdúrà nípa ẹni tí ó nílò láti gba ìkínni Ọdún Àjínde yín. Bákannáà ẹ lè pinnu láti pín ẹsẹ ọ̀rọ̀ yín lórí ìbákẹ́gbẹ́ àwújọ, níbití ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti lè rí wọn.
Àwọn orin ìsìn nípa Krístì àti Àjínde náà, bí irú “Ó Ti Jínde!” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà.199), bákannáà lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára àlàáfíà àti ayọ̀ ní Ọdún Àjínde. Ẹ wá àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ nínú orin isìn tí ó fi ayọ̀ Ọdún Àjínde hàn, nínú èrò yín.
Bákannáà wo Jeffrey R. Holland, “Kíì ṣe bí Ayé tií Fúnni,” Làìhónà, Oṣù Karun 2021, 35–38; Mark S. Palmer, “Ìkorò Wa Yíò Yípadà sí Ayọ̀,” Làìhónà, Oṣù Karun 2021, 88–90.
Kínniṣe tí Ìwọ fi Nsọkún, láti ọwọ́ Simon Dewey (àlàyé)
Nítorí Ètùtù Rẹ̀, Jésù Krístì ní agbára láti ràn mí lọ́wọ́ láti borí ẹ̀ṣẹ̀, ikú, àdánwò, àti àìlera.
Ní ìhín ni iṣẹ́ ṣíṣe kan tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún tí ó nwá nípasẹ̀ Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀. Ẹ ka àwọn ìwé mímọ́ ìsàlẹ̀ nípa ohun tí Jésù Krístì ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ láti borí. Ẹ gbìyànjú láti toàwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ sínú ẹ̀ka ìwọ̀nyí: ẹ̀ṣẹ̀, ikú, àwọn àdánwò àti àìlera (àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ tí ó lè ní ìbámu síi ju ẹ̀ka kan lọ). Bí ẹ ti nkàá, kínni ìwọnilọ́kàn tí ẹ ní nípa agbára Olùgbàlà?
-
Ìsàíàh 61:1–3
-
Èsèkíẹ́lì 36:26–28
-
Máttéù 11:28–30
-
Lúkù 1:46-55
-
Rómù 8:35–39
Báwo ni ẹ yíò ti ṣe àlàyé sí ọ̀rẹ́ kan tí kìí ṣe Krìsténì ìdí tí Jésù Krístì fi jẹ́ pàtàkì sí yín? Ọ̀rọ̀ Alàgbà Ahmad S. Corbitt “Ṣé Ẹ Mọ Ìdí Tí Èmi Bíi Krìstẹ́nì Ṣe Gbàgbọ́ Nínú Krístì?” (Làìhónà, Oṣù Karun 2023, 119–21) lè ṣèrànwọ́.
Bákannáà wo Reyna I. Aburto, “Isà-òkú Kò Ní Ìṣẹ́gun Mọ́,” Làìhónà, Oṣù Karun 2021, 85–87; Àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Ètùtù,” “Àjínde,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Jésù Krístì san iye ìgbẹ̀hìn fún ìgbàlà mi.
Kínni ẹ kọ́ láti inú àwọn ẹsẹ ìwọ̀nyí nípa iye tí Jésù Krístì san fún ìgbàlà yín: Ìsàíàh 53:3–5; Mòsíàh 3:7; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 19:16–19? Kínni iye tí Baba Ọ̀run sàn? (wo Jòhánnù 3:16).
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde òṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé
Jésù Krístì jìyà Ó sì kú fún mi.
-
Ọ̀sẹ̀ Àjínde ni àkokò rere láti kọ́ àwọn ọmọ nípa ohun ti Olùgbàlà ṣe fún wa ní Gẹ́tsémánè àti lórí àgbélèbú. Ẹ lè bẹ̀rẹ̀ nípa fífi àwọn àwòrán ìsàlẹ̀ hàn wọ́n kí ẹ sì jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó nṣẹlẹ̀ nínú àwọn àwòrán nàà. Nígbàtí àwọn ọmọ yín bá nwo àwọn àwòràn náà, ẹ lè ka àwọn ẹsẹ tí ó ṣe àpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí (wo Máttéù 26:36–46; 27:35–50; Lúkù 22:39–46; Jòhánnù 19:16–30). Àwọn ọmọ yín lè mú àwọn àlàyé kíníkíní jádé nínú àwọn àwòrán tí wọ́n gbọ́ nínú ẹsẹs náà.
Òsì: Krístì ní Gẹ́tsémánì, láti ọwọ́ Harry Anderson. Ọ̀tún: Ìkànmọ́ àgbélèbú, láti ọwọ́ Harry Anderson
-
Báwo ni a ṣe ndi alábùkúnfún tó nítorí ìrúbọ Jésù fún wa? Ẹ ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti wá àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó dáhùn ìbèèrè yí nínú Ísáíàh 53:4–12; Álmà 7:11–13; àti Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:16–19. Ẹ pín bí ẹ ṣe nní ìmọ̀lára nípa Olùgbàlà lẹ́hìn kíka àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú ara yín.
Jésù Krístì Jínde fún mi.
-
Ẹ lè lo ojú-ewé ṣíṣe ọ̀sẹ̀ yí tàbí àwọn àwòràn míràn nínú ìlànà yí láti sọ ìtàn ti Àjínde fún àwọn ọmọ yín (bákannáà wo “Jésù Ti Jínde,” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 139–44). Lẹ́hìnnáà ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ sọ ìtàn náà padà sí yín.
-
Ẹ gbèrò bí ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ nínú Krístì ní Ọdún Àjínde yí. Fún àpẹrẹ, ẹ lè kọ orin ìsìn Ọdún Àjíìde kan tí ó jẹ́ ààyò, bí irú “Krístì Olúwa Ti Jínde Ní Òní” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 200) or “Gẹ́tsémánè” (Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Láti wá àwọn orin nípa Àjínde, ẹ lè wo inú ìtọ́ka ti Àwọn Orin Ìsìn àti Ìwé orin àwọn Ọmọdé. Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín le pín ìdí tí ẹ fi fẹ́ràn àwọn orin wọ̀nyí àti bí ẹ ṣe nímọ̀lára nígbàtí ẹ bá nkọ wọn pẹ̀lú arayín. Kínni àwọn orin wọ̀nyí kọ́ wa nípa Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì?
Àwọn ọmọ lè ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí ṣùgbọ́n wọ́n lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti dá ipa Rẹ̀ mọ̀. “Ẹ kọ́ àwọn ọmọ nípa àwọn ọ̀nà yíyàtọ̀ tí Ẹ̀mí nbá wa sọ. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dá ohùn Rẹ̀ mọ̀ bí Ó ṣe nbá wọn sọ̀rọ̀. Èyí yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìwà ti lílépa àti ṣíṣe ìṣe lórí ìfihàn araẹni gbèrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn” (Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,32). Fún àpẹrẹ, bí ẹ ṣe nkọ àwọn orin nípa Olùgbàlà pẹ̀lú àwọn ọmọ yím, ẹ wo àwọn àwòrán Rẹ̀, tàbí ka àwọn ìtàn nípa Rẹ̀, ẹ pín àwọn ìmọ̀lára ti ẹ̀mí míràn tí ẹ ní pẹ́lú arayín.
-
Ibi-ìkàwé Ìhìnrere ní àkópọ̀ ti Àwọn fídíò Ọdún Àjínde tí àwọn ọmọ yín lè gbádùn. Bóyá ẹ lè jẹ́ kí wọ́n mú ọ̀kàn láti wò. Bèèrè lọ́wọ́ wọn ohun tí wọ́n kọ́ nípa Jésù Krístì látinú fídíò náà. Bákannáà ẹ lè ní kí wọ́n ṣe àkópọ̀ ọ̀rọ̀ ti fídíò náà ní ẹ̀là ọ̀rọ̀ kan.
Àwọn wòlíì jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀.
-
Bí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín ṣe nwo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò papọ̀ ní òpin ọ̀sẹ̀ Ọdún Àjínde yí, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kíyèsí ìgbàtí àwọn ẹlẹri pàtàkì Olùgbàlà bá jẹ́ ẹ̀rí nípa Àjínde. Bóyá ẹ lè ṣe eré kan nípa rẹ̀—ẹ pè wọ́n láti dúró nígbà gbogbo tí wọ́n bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ bíiti Ọdún Àjínde tàbí Ètùtù tàbí Àjínde. Ẹ pín ìdí tí ẹ fi moore fún ẹ̀rí àwọn wòlíì alààyè nípa Olùgbàlà pẹ̀lú ara yín.
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .