Come, Follow Me
Oṣù Kẹ́ta 23–29. “Mo Ti Rántí Májẹ̀mú Mi”: Ẹ́ksódù 1–6


“Oṣù Kẹ́ta 23–29. ‘Mo Ti Rántí Májẹ̀mú Mi’: Ẹ́ksódù 1–6,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kẹ́ta 23–29. ‘Mo Ti Rántí Májẹ̀mú Mi’,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026

Mósè àti ìgbẹ́ jíjó

Mósè àti Ìgbẹ́ Jíjó, láti ọwọ́ Jerry Thompson

Oṣù Kẹ́ta 23– 29: “Mo Ti Rántí Májẹ̀mú Mi”

Ẹ́ksódù 1– 6

Ìfipè láti gbé ní Égíptì gba ẹbí Jákọ́bù là. Ṣùgbọ́n lẹ́hìn ọgọọ́gọ̀rún ọdún, àwọn àtẹ̀lé wọn wà lóko ẹrú àti dídẹ̀rùbà nípasẹ̀ Fáráò titun tí “kò mọ Jósẹ́fù” (Ẹ́ksódù 1:8). Ìbá ti jẹ́ ìwà-ẹ̀dá fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì láti ní ìyanu ìdí tí Ọlọ́run fi fi ààyè gba èyí láti ṣẹlẹ̀ sí wọn, àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀. Njẹ́ Ó rántí májẹ̀mú tí Òun ti dá pẹ̀lú wọn? Ṣé wọ́n ṣì jẹ́ àwọn ènìyàn Rẹ̀ síbẹ̀? Njẹ́ Òun ríi bí wọ́n ṣe njìyà tó?

Àwọn àkokò lè wà nígbàtí ẹ ti ní ìmọ̀lára ti bíbèèrè irú àwọn ìbèèrè kannáà. Ó lè yà yín lẹ́nu, “Ṣé Ọlọ́run mọ̀ ohun tí mò nlà kọjá? Njẹ́ Òun lè gbọ́ àwọn ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́?” Ìdándè ti Isráẹ́lì kúrò ní Égíptì dáhùn irú àwọn ìbèèrè bẹ́ẹ̀ kedere: Ọlọ́run kìí gbàgbé àwọn ènìyàn Rẹ̀. Ó nrántí àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ pẹ̀lú wa yíò sì mú wọn ṣẹ ní àkokò àti ọ̀nà ti ara Rẹ̀. “Èmi yíò rà yín padà pẹ̀lú apá nínà jáde,” Ó kéde. “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, èyí tí ó mú yín jáde kúrò lábẹ́ ẹrù [yín]” (Ẹ́ksódù 6:6–7).

Fún àkópọ̀ ìwé ti Ẹ́ksódù, wo “Ẹ́ksódù, ìwé ti” nínú Ìtumọ̀ Bíbélì.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ

Ẹ́ksódù 1– 2

Ọlọ́run lè ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ mi láti mú àwọn èrèdí Rẹ̀ ṣẹ.

Kínni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa àwọn obìnrin tí a júwe nínú Ẹ́ksódù 1–2? Báwo ni wọ́n ṣe ṣèrànwọ́ láti mú ètò Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ ṣẹ? Kínni ìtiraka wọn kọ́ yín nípa iṣẹ́ ìsìn nínú iṣẹ́ Ọlọ́run?

Ẹ́ksódù 1– 3

Jésù Krístì ni Olùdándè mi.

Ṣíwájú kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí nka Ẹ́ksódù, ẹ lè ronú nípa ìnira tí ẹ̀ nlà kọjá—ohunkan tí ẹ nírètí pé Olúwa yíò túu yín sílẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Kínni àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn ọ̀rọ̀ nínú Ẹ́ksódù 1–3 tí ó dún bákannáà sí ìgbèkùn ti ẹ̀mí tàbí àwọn ohun míràn tí a nkojú ní òní? Bákannáà ṣe àkíyèsí bí àwọn ọmọ Isráẹ́lì ṣe wá ìdándè àti bí Olúwa ṣe fèsì (fún àpẹrẹ, wo, Ẹ́ksódù 2:23–25; 3:7–8). Báwo ni Olúwa “ti ṣe ìdándè” yín?

Ní gbogbo inú ìwé Ẹ́ksódù, bákannáà ẹ lè kíyèsí àwọn ìjọra ní àárín Mósè àti Jésù Krístì (wo Deuterónómì 18:18–19; 1 Néfì 22:20–21). Fún àpẹrẹ, kínni ìjọra tí ẹ rí ní àárín Ẹ́ksódù 1:22; 2:1–10 àti Matteu 2:13–16? Tàbí ní àárín Ẹ́ksódù 24:18 àti Matteu 4:1–2? Kínni ìmọ̀lára tí ẹ ní pé Olúwa nfẹ́ kí ẹ ní òye nípa Ararẹ̀ àti agbára Rẹ̀?

Ẹ wá àwọn àmì tí ó jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì. “Ẹ lè … rí ìbámu sí ìgbésí ayé Olùgbàlà nínú ayé àwọn wòlíì àti àwọn olotitọ ọkùnrin àti obìnrin míràn nínú ìwé mímọ́. [Ṣíṣe bẹ́ẹ̀] nfi àwọn òtítọ́ hàn nípa Olùgbàlà ní àwọn ibi tí ẹ ti lè fojú fò hàn” (Wo Ìkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà7; bákannáà wo Hóséà 12:10).

àwọn obìnrin nfa apẹ̀rẹ̀ jáde láti inú odò

Ìgbàgbọ́ ní Etí Omi, láti ọwọ́ Anne Marie Oborn

Ẹ́ksódù 3:1–6

àmì sẹ́mínárì
Mo lè fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ohun àti ibi mímọ́.

Njẹ́ ẹ lè ronú nípa àkokò tí ohunkan ti kún inú yín pẹ̀lú ọlá àti ìyanu bí? Báwo ni ẹ ṣe fèsì? Báwo ni ẹ ó ṣe júwe àwọn ẹ̀dùn ọkàn tí ẹ mọ̀lára?

Pẹ̀lú èyí ní inú, ẹ ka Ẹ́ksódù 3:1–6. Kínní ó wọ̀ yín lọ́kà nípa ìrírí onimisi ti Mósè? Kínni Mósè ṣe láti fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run hàn? Kínni àwọn ìsopọ̀ tí ẹ rí ní àárín àwọn ìṣe rẹ̀ àti ọ̀wọ̀ fún àwọn ohun mímọ́?

Kíka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí lè ṣí yín létí láti ronú nípa àwọn ohun mímọ́ àti ibi mímọ́ nínú ayè yín. Kínni ìdí tí wọ́n fi jẹ́ mímọ́ sí yín? Báwo ni ẹ ṣe ntọ́jú wọn ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kúrò nínú àwọn ohun tí ó wọ́pọ̀? Láti ṣe tọ́ ìjíròrò yín sọ́nà, ẹ lè tọ́ka sí ìpín tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Rírántí àwọn Ìlérí” nínú ọ̀rọ̀ Alàgbà David A. Bednar “Títayọ àwọn Ìlérí Iyebíye àti Nlá” (Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2017, 91–93). Bákannáà ẹ lè kọrin tàbí fetísílẹ̀ sí orin ìsìn tí ó nmú ìmísí ọlá wá, bíiti “Mo Dúró nínú Gbogbo Ìyanu” (Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 193) kí ẹ sì jíròrò ohun tí ó yà yín lẹ́nu nípa ìhìnrere.

Bẹ́ẹ̀ni, àní nígbàtí a ti ní àwọn ìrírí yíyanilẹ́nu ti ẹ̀mí, ewu wà ní dída yẹpẹrẹ jù nípa àwọn ohun mímọ́. Báwo ni ẹ ó ti yẹra fún èyí? Ní ìhín ni àwọn ọ̀rọ̀ méjì tí ó yanjú ọ̀ràn yí: mú ọ̀kan, kí ẹ sì wá àwọn ẹ̀là ọ̀rọ̀ tí ó nràn yín lọ́wọ́: Ulisses Soares, “Nínú Ìyanu ti Krístì àti Ìhìnrere Rẹ̀” (Làìhónà, May 2022, 115–17); Gérald Caussé, “Njẹ́ Ó Ṣì Jẹ́ Ìyanu Sí Yín Bí?” (Làìhónà, Oṣù Karun 2015, 98-100).

Bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:10–12; 63:64.

Exodus 3-4

Ọlọ́run nfi agbára fún àwọn ènìyàn tí Ó pè láti ṣe iṣẹ́ Rẹ̀.

Ní òní a mọ Mósè bí wòlíì nlá àti olùdarí. Ṣùgbọ́n Mósè kò rí ara rẹ̀ ní ọ̀nà náà nígbàtí Olúwa kọ́kọ́ pè é. Bí ẹ ti nka Ẹ́ksódù 3–4, ẹ to àwọn àníyàn Mósè àti bí Olúwa ti fèsì sí ọ̀kọ̀ọ̀kan sílẹ̀. Kínni ẹ rí nínú àwọn orí wọ̀nyí tí ó lè mísí yín nígbàtí ẹ bá ní ìmọ̀lára àìkúnojú-ìwọ̀n. Ìgbà wo ni ẹ ti rí tí Ọlọ́run ro yín lágbára tàbí àwọn ẹlòmíràn láti ṣe iṣẹ́ Rẹ̀?

Bákannáà wo “Ìjọ Nfún Wa Ní Àwọn Ànfàní láti Ṣèrànwọ́ nínú Isẹ́ Olúwa” nínú “Ìṣètò Ìjọ” nínú àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

Exodus 5-6

Àwọn èrèdí Olúwa ni a ó múṣẹ ní àkokò ti Ararẹ̀.

Ó lè jẹ́ àìní-ìyànjú nígbàtí àwọn ìtiraka òdodo wa láti ṣe rere kò bá dàbí ó nṣiṣẹ́—nígbàtí a bá ngbìyànjú láti ṣe ìfẹ́ Olúwa ṣùgbọ́n tí a kò rí àwọn èsì tí à nretí. Láti kọ́ nípa ìrírí jíjọra tí Mósè ní, ẹ ka Ẹ́ksódù 5:4–9, 20–23. Báwo ni Olúwa ṣe ran Mósè lọ́wọ́ láti borí ìmọ̀lára rẹ̀ nípa àìní-ìyànjú? (wo Ẹ́ksódù 6:1–13). Báwo ni Olúwa ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti tẹramọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Rẹ̀?

Bákannáà wo Jeffrey R. Holland, “Dídúró de Olúwa,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2020, 115–17.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé-ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun Ọ̀dọ́ .

àmì abala àwọn ọmọdé 01

Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé

Nítorí Ọjọ́ Ìsinmi yí ni Ọjọ́ Ìsinmi Karun ti oṣù náà, àwọn olùkọ́ni Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni a gbà níyànjú láti lo àwọn ṣíṣe nínú “Àfikún B: Mímúra àwọn Ọmọdé Sílẹ̀ fún Ìgbé-ayé lórí Ipa-ọ̀nà Májẹ̀mú Olúwa.”

Ẹ́ksódù 1– 2

Ọlọ́run lè ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ mi láti mú àwọn èrèdí Rẹ̀ ṣẹ.

  • Mósè ní kókó ojúṣe ní títú Isráẹ́lì kúrò nínú ìdè. Ṣùgbọ́n òun kì bá ti lè ṣe àṣeyọrí èyí bí ìyá rẹ̀, arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin Fáráò, àti àwọn obìnrin olódodo míràn kì bá ti dá ààbò bò kí wọ́n sì ṣe ìtọ́jú fún un. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ nípa àwọn obìnrin wọ̀nyí nínú Ẹ́ksódù 1:15–20; Ẹ́ksódù 2:2–10 (bákannáà wo Númérì 26:59); àti Ẹ́ksódù 2:16–21. Bákannáà ẹ lè lo ojú-ewé ṣíṣe ọ̀sẹ̀ yí àti “Ọmọ-ọwọ́ Mósè” (nínú àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 61–63) láti sọ àwọn ìtàn yí. Báwo ni àwọn obìnrin wọ̀nyí ṣe ṣèrànwọ́ láti mú ètò Ọlọ́run ṣẹ? Ẹ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ara yín nípa àwọn ènìyàn míràn tí ẹ fẹ́ràn tí wọ́n ṣèrànwọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ Ọlọ́run, pẹ̀lú ní àwọn ọ̀nà kékèké àti ìrọ̀rùn. Báwo ni a ṣe lè tẹ̀lé àpẹrẹ wọn?

    1:36

    Baby Moses

Ẹ́ksódù 3:1–5

Mo lè tọ́jú àwọn ibi mímọ́ pẹ̀lú ọ̀wọ̀.

  • Lẹ́hìn kíka Ẹ́ksódù 3:1–5 papọ̀, ẹ ní kí àwọn ọmọ yín ṣe àkópọ̀ àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ní àwọn ọ̀rọ̀ ara wọn (bákannáà wo “Mósè Wolíì náà” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 64–66). Báwo ni Mósè ṣe fi ọ̀wọ̀ hàn ní iwájú Olúwa? Báwo ni Olúwa ṣe fẹ́ kí a fi ọ̀wọ̀ hàn? Bákannáà ẹ lè ní kí àwọn ọmọ yín ràn yín lọ́wọ́ láti rí (tàbí ya) àwọn àwòrán ti àwọn ibi mímọ́ tàbí ṣíṣe níbití a níláti ní ọ̀wọ̀. Kínni a lè ṣe láti mú kí ilé wa jẹ́ ibi mímọ́?

    1:26

    Moses the Prophet

  • Ẹ kọ orin kan papọ̀ nípa ọ̀wọ̀, bí irú “Ọ̀wọ̀ Ni Ìfẹ́” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 31). Bí ẹ ti nṣe é, àwọn ọmọ yín lè rí àwọn ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe àlàyé ohun tí ó túmọ̀sí láti ní ọ̀wọ̀. Bí a bá nmú ọ̀rẹ́ kan wá sí ilé-ìjọsìn fún ìgbà àkọ́kọ́, báwo ni a ó ti ṣe àlàyé ohun tí ó túmọ̀sí láti ní ọ̀wọ̀?

Mósè àti Árọ́nì sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn

Mosè àti Árọ́nì Bá àwọn Ènìyàn Sọ̀rọ̀, láti ọwọ́ James J. Tissot

Exodus 3-4

Nígbàtí Olúwa bèèrè lọ́wọ́ mi láti ṣe ohunkan, Òun yíò ràn mi lọ́wọ́ láti ṣe é.

  • Lílo àkọsìlẹ̀ nínú Ẹ́ksódù 3; 4:1–17, ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín díbọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti jẹ́ Mósè. Ó lè jẹ́ ìgbádùn láti fi àwọn nkan pẹ̀lú tàbí àwọn prọ́pù rírọrùn, bí irú ìmọ́lẹ̀-fúláṣì àti ohun ọ̀gbìn kan láti rọ́pò jíjó ìgbẹ́. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àwárí bí Mósè ṣe ní ìmọ̀lára nípa ìyànsíṣẹ́ tí Olúwa fun (wo Ẹ́ksódù 3:11; 4:1, 10). Bóyá ẹ lè pin pẹ̀lú ara yín ní àwọn àkokò nígbàtí ẹ ti ní ìmọ̀lára jíjọra. Kínni ìmọ̀ràn tí a ó pín pẹ̀lú Mósè láti ràn án lọ́wọ́? Ẹ kà nípa bí Olùwa ti gba Mósè níyànjú nínú Ẹ́ksódù 3:12; 4:2–9, 11–12. Ẹ wí fún àwọn ọmọ bí Olùgbàlà ṣe ràn yín lọ́wọ́ láti mú ìpè yín ṣẹ, tẹ̀lé ìṣílétí, tàbí ṣe ohunkan míràn tí ó le fún yín.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ̀ndì .

Ìyá Mósè

Ìyá Mósè, láti ọwọ́ Simeon Solomon

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣé Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Mo lè dáríjì