“Oṣù Kẹ́ta 16–22. ‘Ọlọ́run Mọ̀ Ọ́ sí Rere’: Gẹ́nẹ́sísì 42–50,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kẹ́ta 16–22. ‘Ọlọ́run Mọ̀ Ọ́ sí Rere’,” Wá Tẹ̀lé Mi: 2026
Ìdáríjì, láti ọwọ́ Megan Rieker
Oṣù Kẹ́ta 16– 22: “Ọlọ́run Mọ̀ Ọ́ sí Rere”
Gẹ́nẹ́sísì 42–50
Ó ti jẹ́ bí ọdún méjìlélógún látìgbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ ti tàá sí oko ẹrú. Jósẹ́fù ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àdánwò, pẹ̀lú ẹ̀sùn ìrọ́ àti ìtìmọ́lé. Ní òpin nígbàtí ó rí àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi, Jósẹ́fù ni gómìnà ti gbogbo Egípítì, igbá kejì nìkàn sí Fáráò. Ó ti gba ẹ̀san ní ìrọ̀rùn lórí àwọn arákùnrin rẹ̀, àti pé yíyẹ ohun tí wọ́n ti ṣe sí Jósẹ́fù wò, ìyẹn lè dàbí ó yéni. Síbẹ̀síbẹ̀ Jósẹ́fù sì dáríjì wọ́n. Kìí ṣe ìyẹn nìkàn, ṣùgbọ́n ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí èrèdí àtọ̀runwá nínú ìjìyà rẹ̀. “Ọlọ́run Mọ̀ Ọ́ sí Rere” (Gẹ́nẹ́sísì 50:20), ó wí fún wọn pé, nítorí ó fi òun sí ipò kan láti gba “gbogbo ilé baba òun là” (Gẹ́nẹ́sísì 47:12) kúrò nínú ìyàn.
Ní ọ́pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà, Jósẹ́fù dàbí Jésù Krístì. Àní bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fa ìjìyà nlá fún Jésù, Ó fi ìdáríjì fúnni, ní gbígba gbogbo wa sílẹ̀ lọ́wọ́ àyànmọ́ tí ó burú ju ìyàn lọ. Bóyá a nílò láti gbà ìdáríjì tàbí kí a fi í fúnni—ní àwọn ààyè kan gbogbo wa nílò láti ṣe méjèèjì—àpẹrẹ Joseph tọ́ka wa sí Olùgbàlà, orísun tòótọ́ ti ìwòsàn àti ìlàjà.
Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ
Gẹ́nẹ́sísì 45:5–7; 47:12
“Ọlọ́run rán mi ṣíwájú yín láti gbà yín là.”
Njẹ́ ẹ ti kíyèsí irú ìbáramu ní àárín ìgbésí ayé Jósẹ́fù àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ètùtù ti Jésù Krístì bí? Láti rí àwọn àpẹrẹ ti ìbáramu wọ̀nyí, ẹ gbìyànjú fífiwé:
-
Gẹ́nẹ́sísì 37:3 pẹ̀lú Matteu 3:17.
-
Gẹ́nẹ́sísì 37:26–28 pẹ̀lú Matteu 26:14–16.
-
Gẹ́nẹ́sísì 45:5–7 pẹ̀lú Lúkù 4:18.
-
Gẹ́nẹ́sísì 47:12 pẹ̀lú Jòhánnù 6:35.
Kínni àwọn ìtẹ̀mọ́ra tí ẹ ní nípa Olùgbàlà àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ bí ẹ ti nka àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ wọ́nyí?
Gẹ́nẹ́sísì 45; 50:15–21
Ìdáríjì nmú ìwòsàn wá.
Kíkà nípa Jósẹ́fù tí ó ndáríji àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa àwọn ohun búburú tí wọ́n ti ṣe lè ṣíi yín létí láti ronú nípa ẹnìkan tí ẹ̀ ntiraka láti dáríjì. Àwọn ìbèèrè wọ̀nyí lè ṣèrànwọ́ bí ẹ ti ngbìyànjú láti lo ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí.
-
Kínni ìdí tí ó fi lè tilè fún Jósẹ́fù láti dáríji àwọn arákùnrin rẹ̀? (Láti ṣe àtúnyẹ̀wò ohun tí wọ́n ṣe sí i, wo Gẹ́nẹ́sísì 37). Kíní àwọn ìrírí tàbí ìhùwasí tí ó ti lè fún Jósẹ́fù ní okun láti dáríjì? (Fún àpẹrẹ, wo, Gẹ́nẹ́sísì 45:1–15 tàbí 50:15–21).
-
Kínni àwọn ìbùkún tí ó nwá látinú ìdáríjì Jósẹ́fù ti àwọn arákùnrin rẹ̀? Fún àpẹrẹ, fi àwọn ìbáṣepọ̀ nínú ẹbí Jákọ́bù ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn náà wé (Fún àpẹrẹ, wo, Gẹ́nẹ́sísì 37:3–11) àwọn ìbáṣepọ̀ ní ìgbẹ̀hìn (wo Gẹnẹ́sísì 45:9–15; 50:15–21). Báwo ni àbájáde àwọn nkan ó ṣe yàtọ̀ bí Jósẹ́fù kò bá ti ní ìfẹ́ láti dáríjì.
-
Ẹ yẹ kíkọ orúkọ ẹnìkan tí ó lè nílò ìdáríjì yín sílẹ̀—bóyá tàbí wọ́n ti bèèrè fún ìdáríjì. Kínni ẹ lè ṣe láti pe agbára ìwòsàn Olùgbàlà sínú ipò náà? Bí ìdáríjì bá dàbí ó ṣòro, ẹ yẹ títún ìmọ̀ràn ti Alàgbà Gerrit W. Gong wò nínú àwọn gbólóhùn kẹfà àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó gbẹ̀hìn “Ìdùnnú àti Títíláé” (Làìhónà, Nov. 2022, 85). Kínni ẹ rí tí ó nfún yín ní ìrètí pé ẹ lè dáríjì?
Bákannáà wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 64:9–11; “Ìdáríjì: Ẹrù Mi Di Fífúyẹ́” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Forgiveness: My Burden Was Made Light
Gẹ́nẹ́sísì 49
Jákọ́bù fún ẹbí rẹ̀ ní àwọn ìbùkún ti wòlíì.
Àwọn ìbùkún Jákọ́bù sí ìran rẹ̀ ní àwòrán híhàn nínú, ṣùgbọ́n kò rọrùn láti ní òye wọn. Pẹ̀lú ọpẹ́, ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere nfún wa ní àwọn ìrànlọ́wọ́. Nígbàtí ẹ bá ka ìbùkún sí Jósẹ́fù nínú Gẹ́nẹ́sísì 49:22–26, ẹ ka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí pẹ̀lú, kí ẹ sì rí àwọn ìwòye tí wọ́n pèsè: 1 Néfì 15:12; 2 Néfì 3:4–5; Jákọ́bù 2:25; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 50:44.
Bí ẹ ti nkà nípa ìbùkún Júdàh nínú Gẹ́nẹ́sísì 49:8–12, ẹ rántí pé Jésù Krístì ni àtẹ̀lé ti Júdàh. Kínni ẹ rí nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí tí ó nrán yín létí nípa Olùgbàlà? (Bákannáà wo Ìfihàn 5:5–6, 9; 1 Néfì 15:14–15; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 45:59; 133:46–50).
Kíka àwọn ìbùkún wọ̀nyí lè mísí yín láti ṣe àtúnyẹ̀wò ìbùkún ti babanlá yín—tàbí, bí ẹ̀yín kò bá ní ọ̀kan, láti gba ọ̀kan. Kínni àwọn ọ̀rọ̀ àti àwọn gbólóhùn-ọ̀rọ̀ nínú ìbùkún yín tí ó nyí àwọn èrò yín padà sí Jésù Krístì?
Bákannáà wo Randall K. Bennett, “Ì̀bùkún ti Babanlá Yín—Ìmísí Dídarí láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run,” Làìhónà, May 2023, 42–44.
Gẹ́nẹ́sísì 50:19-21
Ọlọ́run lè ràn mi lọ́wọ́ láti rí ìtumọ̀ nínú àwọn àdánwò mi.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má tilẹ̀ yéni ìdí tí ó fi nlà á kọjá, Jósẹ́fù nígbẹ̀hìn lè wo ẹ̀hìn lórí ìpọ́njú rẹ̀ ní Egípítì kí ó sì ri pé “Ọlọ́run Mọ̀ Ọ́ sí Rere” (Gẹ́nẹ́sísì 50:20). Ká ní ẹ̀yin bá lè bẹ̀ Jósẹ́fù wò nígbàtí ó wà nínú ihò tàbí nínú túbú, báwo ni ẹ̀yín ìbá ti tù ú nínú? Báwo ni Gẹ́nẹ́sísì 50:19–21 ṣe lè ràn yín lọ́wọ́ ní àwọn àkokò àdánwò?
Bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú122; “Báwo Ni Ìpìlẹ̀ ṣe Dúró Gbọingbọin,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 85.
Jósẹ́fù Smith ní àárín àwọn Wòlíì, láti ọwọ́ Paul Mann (àlàyé)
Gẹ́nẹ́sísì 50:24-25
“Aríran kan ni Olúwa Ọlọ́run mi yíò gbé dìde.”
Bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 50:24–25 àti Ìyírọ̀padà Jósẹ́fù Smith, Gẹ́nẹ́sísì 50:24–38 (nínú àlẹ̀mọ́ Bíbélì), ẹ jíròrò ìdí tí yíò fi ṣe pàtàkì fún Jósẹ́fù láti mọ̀ nípa Mósè àti Jósẹ́fù Smith ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ sẹ́ntúrì níwájú. Báwo ni Jósẹ́fù Smith ṣe mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ti Jósẹ́fù ṣẹ nípa rẹ̀? (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 1:17–23; 20:7–12; 39:11; 135:3).
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé-ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Gẹ́nẹ́sísì 42–44; 45:4–15
Mo lè fi ìfẹ́ àti ìdáríji hàn sí ẹbí mi.
-
Ó lè jẹ́ ìgbádùn fún àwọn ọmọ yín láti tún ìtàn náà sọ nípa Jósẹ́fù tó ntún àwọn ẹbí rẹ̀ dàpọ̀ (wo Gẹnẹ́sísì 42–44). Tàbí wọ́n lè lo “Jósẹ́fù àti Ìyàn náà” (nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 57–60) tàbí àwọn àwòrán nínú ìlànà yí láti kọ́ ìtàn náà sí ara wọn. Ní ìhìn ni àwọn ìbèèrè tí ó lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú ìtàn náà:
-
Kíní Jósẹ́fù ṣe láti fi ìfẹ́ hàn fún ẹbí rẹ̀? (wo Gẹnẹ́sísì 45:4–15).
-
Kínni ẹ rò pé ó jẹ́ kí Jósẹ́fù dáríji àwọn arákùnrin rẹ̀?
-
Báwo ni ẹ ṣe rò pé àwọn arákùnrin Jósẹ́fù ṣe ní ìmọ̀ara sí nígbàtí wọ́n ri pé Jósẹ́fù ti dáríjì wọn? Tani ó nílò láti gba ìdáríjì nínú ayé yín? Báwo ni ẹ ṣe le fi ìfẹ́ àti ìdáríjì hàn?
2:26Joseph and the Famine
-
Bí ẹ ti nmúrasílẹ̀ láti kọ́ni, ẹ bèèrè, “Kínni àwọn ọmọ mi yíò ṣe láti kọ́ ẹ̀kọ́?” Fún àpẹrẹ, nínú ìṣe yí àwọn ọmọ yín nṣe ìṣe jáde tàbí tún ìtàn kan sọ. Ṣíṣe èyí yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rántí méjèjì ohun tó ṣẹlẹ̀ àti àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà nínú ìtàn náà.
-
Ẹ̀yin tàbí àwọn ọmọ yín lè fẹ́ láti pín ìrírí kan nígbàtí wọ́n dáríji ẹnìkan tàbí nígbàtí ẹnìkan dáríjì wọ́n. Nígbànáà ẹ lè kọ orin kan bí irú “Ẹ Fẹ́ràn Ara yín” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 136) tàbí “Ràn Mí Lọ́wọ́, Baba Ọ̀wọ́n” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 99).
Gẹ́nẹ́sísì 48:8-9
Olúwa nràn mí lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn ìbùkún oyè àlùfáà.
-
Ẹ̀yin àti ọmọ yín lè wo àwòrán Jákọ́bù tí ó nbùkún ọmọ rẹ̀ ní òpin ìlànà yí kí ẹ sì sọ̀ ohun tí ó nṣẹlẹ̀ (wo Gẹnẹ́sísì 48:8–9). Bí ìnílò bá wà, ẹ ṣe àlàyé pé Jákọ́bù, baba Jósẹ́fù, fẹ́ láti fi àwọn ìbùkún oyè àlùfáà fún ẹbí rẹ̀. Bóyá ẹ lè pín ìrírí eyikeyi tí ẹ ti ní tí ẹ̀ ngba ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìbùkún oyè àlùfáà pẹ̀lú ara yín. Kínni àwọn èrèdí tí ẹ lè fi bèèrè fún ìbùkún oyè àlùfáà?
Gẹ́nẹ́sísì 45:5-11
Baba Ọ̀run rán Jésù Krístì wá láti gbà mi là.
-
Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí Olùgbàlà nínú ìtàn ti Jósẹ́fù tí ó ngba ẹbí rẹ̀ là kúrò nínú ìyàn. Ẹ gbèrò ṣíṣe àlàfo ìkọ́ni kan pẹ̀lú ààyè méjì tí a kọ àkọlé Jósẹ́fù àti Jésù Krístì sí. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti wá àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ méjì-méjì wọ̀nyí kí wọn ó sì kún inú àlàfo ìkọ́ni náà pẹ̀lú àwọn ohun tí Jósẹ́fù àti Jésù fi jọra: Gẹ́nẹ́sísì 37:3 àti Matteu 3:17; Gẹ́nẹ́sísì 37:26–28 àti Matteu 26:14–16; Gẹ́nẹ́sísì 45:5–7 àti Lúkù 4:18; àti Gẹ́nẹ́sísì 47:12 àti Jòhánnù 6:35.
-
Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín ohun tí ó túmọ̀ sí láti gbàlà tàbí gbà ẹnìkan sílẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni lára wọn bá ti ní ìrírí jíjẹ́ gbígbàlà tàbí gbígbàsílẹ̀ láti inú ewu, ẹ pè wọ́n láti ṣe àbápín. Báwo ni Jósẹ́fù ṣe gba àwọn arákùnrin rẹ̀ là? (wo Gẹnẹ́sísì 42:1–3; 45:5–7). Nígbànáà ẹ lè wo àwòrán kan nípa Olùgbàlà papọ̀ kí ẹ sì ní kí àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ti gbà wá là.
Fún púpọ̀ síi, ẹ wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .