“Oṣù Kejì 23 sí Oṣù Kẹ́ta 1 ‘Njẹ́ Ohun Kankan Ṣòro fun Olúwa Bí?’: Gẹ́nẹ́sísì 18–23,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kejì 23 sí Oṣù Kẹ́ta 1 “Njẹ́ Ohun Kankan Ṣòro fun Olúwa Bí?’,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026
Sárà àti Ísáákì, láti ọwọ́ Scott Snow
Oṣù Kejì 23 sí Oṣù Kẹ́ta 1:“Njẹ́ Ohun Kankan Ṣòro fun Olúwa Bí?”
Gẹ́nẹ́sísì 18–23
Ìgbé ayé Ábráhámú àti Sáràh, kún fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì ìrora-ọkàn àti ìmóríyá, ni ẹ̀rí òtítọ́ tí Ábráhámù kọ́ nínú ìran kan—pé a wà ní ayé láti jẹ́ dídánwò, “láti ri bóyá [wọn] yíò ṣe gbogbo ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run [wọn] yíò pàṣẹ” (Ábráhámù 3:25). Ṣé Ábráhámù àti Sáràh yíò jẹ́ olóòótọ́ bí? Ṣé wọn yíò tẹ̀síwájú láti ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí àtẹ̀lé títóbi ti Ọlọ́run, àní nígbàtí wọ́n ṣì wà ní àrọ̀mọbí ní ọjọ́ ogbó wọn? Àti nígbátí a bí Ísáákì, ṣé ìgbàgbọ́ wọn yíò farada àìlèrò náà—àṣẹ láti rúbọ ọmọ náà gan nípasẹ̀ ẹnití Ọlọ́run ti ṣe ìlérí láti mú májẹ̀mú náà ṣẹ?
Ábráhámú àti Sáràh gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, Òun sì gbẹ́kẹ̀lé wọn (wo Gẹnẹ́sísì 15:6; Àwọn ará Rómù 4:3). Nínú Gẹ́nẹ́sísì 18–23, a rí àwọn ìtàn látinú ìgbé ayé Ábráhámù, Sáràh, àti àwọn míràn tí ó lè ṣí wa létí láti ronú nípa níní ìfẹ́ ti ara wa láti gbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, láti fi ìwà búburú sílẹ̀ kí a má sì ṣe wo ẹ̀hìn mọ́, kí a sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láìka ìrúbọ̀ rẹ̀ sí. Ní dídán wa wò, bákannáà Ọlọ́run nmú wa dára si.
Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti Ìjọ
Gẹ́nẹ́sísì 18:9–14; 21:1–7
Olúwa nmú àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ ní àkokò ti ara Rẹ̀.
Olúwa ti ṣe àwọn ìlérí ológo sí àwọn olóòótọ́, ṣùgbọ́n nígbàmíràn àwọn ìpò ti ìgbé ayé wa nmú wa ronú bí àwọn ìlérí wọ̀nyí ṣe lè di mímúṣẹ. Ábráhámù àti Sáràh lè ti ní ìmọ̀lára ọ̀nà yí. Kínni ẹ kọ́ láti inú àwọn ìrírí wọn. Ó lè jẹ́ rírannilọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ àṣàrò yín nípa títún ohun tí Olúwa ti ṣe ìlérí rẹ̀ wò nínú Gẹ́nẹ́sísì 17:4, 15–22. Báwo ni Ábráhámù àti Sáràh ti ṣe? (wo Ìyírọ́padà Jósẹ́fù Smith, Gẹ́nẹ́sísì 17:23 [nínú Gẹ́nẹ́sísì 17:17, àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ìsàlẹ̀b]; Gẹ́nẹ́sísì 18:9–12). Báwo ni Olúwa ṣe fèsì sí ìrànlọ́wọ́ wọn láti ní ìgbàgbọ́ títóbijù nínú àwọn ìlérí Rẹ̀? (wo Gẹ́nẹ́sísì 18:14).
Kínni ẹ rí nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí tí ó ngbé ìgbàgbọ́ yín ga? Kínni àwọn ìrírí míràn—nínú ayé yín tàbí ẹlòmíràn—ti ó ti fún ìgbàgbọ́ wọn lókun pé Olúwa yíò mú àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ ní àkokò àti ọ̀nà ti ara Rẹ̀? Bákannáà ẹ lè jíròrò bí ẹ ṣe lè ṣèmúdúró ìgbàgbọ́ yín nígbàtí ẹ kò bá gba ìlérí àwọn ìbùkún nínú ayé yí. Kínni ìmọ̀ràn tí ẹ lè rí nínú Hébérù 11:8–13 àti ọ̀rọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson “Krístì ti Jíìnde; Ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ Yíò Ṣí àwọn Òkè Nídí”? Làìhónà,, Osù Karun 2010, 101–4).
Bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 88:68.
Gẹ́nẹ́sísì 19:12–29
Olúwa pàṣẹ fún mi láti fi ìwà búburú sílẹ̀ kí nsì máṣe wo sẹ́hìn.
Kínni àwọn ẹ̀kọ́ tí ẹ kọ́ nípa fífi ìwà búburú sílẹ̀ bí ẹ ṣe nkà nípa Lọ́tì àti ẹbí rẹ̀? Fún àpẹrẹ, kínni ó wọ̀ yí lọ́kàn nípa ohun tí àwọn àngẹ́lì wí tí wọ́n sì ṣe láti ran Lọ́tì lọ́wọ́ àti ẹbí rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ọ̀nà àbáyọ sí ìparun? (wo Gẹ́nẹ́sísì 19:12–17). Báwo ni Olúwa ti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín àti ẹbí yín láti sákúrò tàbí rí ààbò kúrò nínú àwọn ààbò ibi nínú ayé? Ẹ ronú nípa àwọn ipò níbití ẹ ti lè jẹ́ dídánwò láti “[padà] sẹ́hìn” (ẹsẹ 26) nígbàtí o´ yẹ kí ẹ máa wo iwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà. Kínni Lúkù 9:62 fikún òye yín nípa ìrò yí?
Bákannáà wo Ìyírọ̀padà Jósẹ́fù Smith, Gẹ́nẹ́sísì 19:9–15 (nínú àlẹ̀mọ́ bíbélì).
Gẹnẹsisi 19:26
Kínni ìyàwó Lọ́tì fi ṣe àṣìṣe?
Alàgbà Jeffrey R. Holland kọ́ni pé:
“Ní híhàn kedere, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó Lọ́tì ni pé kìí ṣe pé ó nwo ẹ̀hìn nìkàn; nínú ọkàn rẹ̀ ó nfẹ́ láti lọ padà. Yíò hàn pé àní ṣíwájú ó ti kọjá àmì ìlú náà, ó ti ndárò ohun tí Sódómù àti Gòmórà ti fi fún un. …
“Ó ti ṣeéṣe pé kí ìyàwó Lọ́tì ti wo ẹ̀hìn pẹ̀lú ikorira síwájú Olúwa fún ohun tí Ó ní kí òun fi sílẹ̀ sẹ́hìn. … Nítorí náà kìí ṣe pé ó wo ẹ̀hìn nìkan; ó wo ẹ̀hìn pẹ̀lú ìpòngbẹ. Ní kúkúrú, lílẹ̀mọ́ rẹ sí àtẹ̀hìnwá ju ìwọ̀n ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú ọjọ́ ọ̀la. Ìyẹn, ní híhàn gidi, jẹ́ ara ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
“… Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti máṣe dúró sí àwọn ọjọ́ tí ó ti lọ nísisìyí tàbí láti ní ìyọ́nú lásán sí ohun àná, bíótiwù kí ohun àná ti lè dára tó. Àtẹ̀hìnwá ni láti kọ́ ẹ̀kọ́ nínú rẹ̀ ṣùgbọ́n kìí ṣe láti gbé nínú rẹ̀. À nwo ẹ̀hìn láti gba àwọn ògúná kúrò nínú àwọn ìrírí dídán ṣùgbọ́n kìí ṣe èérú. Àti pé nígbàtí a ti kọ́ ohun tí a nílò láti kọ́ àti láti mú ohun dídárajùlọ wá pẹ̀lú wa tí a ti ní ìrírí, nígbàtí a bá wo ìwájú tí a sì rántí pé ìgbàgbọ́ máa nnawọ́ síwájú nígbàgbogbo sí ọjọ́ ọ̀la. …
“… Gbígbé ní àtẹ̀hìnwá ìgbé ayé, wà pẹ̀lú àwọn àṣìṣe àtẹ̀hìnwá, kò tọ́ rárá! Kìí ṣe ìhìnrere Jésù Krístì. …
“Sí gbogbo [ènìyàn] ti gbogbo ìran, mo pè yín jáde, ‘Ẹ rántí ìyàwó Lọ́tì’ [Lúkù 17:32]. Ìgbàgbọ́ wà fún ọjọ́ ọ̀la. Ìgbàgbọ́ tí a gbé lé àtẹ̀hìnwá ṣùgbọ́n tí kìí pẹ́ ní dídúró níbẹ̀ rárá. Ìgbàgbọ́ ni ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run ní àwọn ohun títóbi ní ìṣura fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa àti pé Krístì nítòótọ́ ni ‘àlùfáà gíga àwọn ohun tí ó nbọ̀’ (Hébérù 9:11)” (“Dídárajùlọ Ṣì Nbọ̀ Síbẹ̀,” Ẹ́nsáínì, Oṣù Kínní. 2010, 24, 26–27).
Ábráhámù àti Ísáákì, láti ọwọ́ Harold Copping
Gẹ́nẹ́sísì 22:1-19
Níní ìfẹ́ ti Ábráhámù láti rúbọ Ísáákì ni àfijọ ti Ọlọ́run àti Ọmọ Rẹ̀.
Bíótilẹ̀jẹ́pé a kò mọ̀ gbogbo èrèdí tí Ọlọ́run fi pàṣẹ fún Ábráhámù láti fi Ísáákì rú ẹbọ kan, a mọ̀ pé ó jẹ́ ìdánwòti ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ọlọ́run. Bákannáà a mọ̀ pé ó jẹ́ “àfijọ Ọlọ́run àti Ọmọ Bíbí rẹ Kanṣoṣo” (Jákọ́bù 4:5). Bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 22:1–19, ẹ lè wá àwọn àmì tàbí àwọn ìjọra ní àárín ẹbọ-ọrẹ Ábráhámù ti Ísáákì àti ẹbọ-ọrẹ Baba ti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Ẹ yẹ kíkọ ohun tí ẹ rí nínú àpẹrẹ kan bí èyí wò:
|
Ábráhámù àti Ísáákì |
Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì |
|---|---|
Ábráhámù àti Ísáákì Ísáákì ni ọmọ bíbí kanṣoṣo ti Ábráhámù àti Sáràh (Gẹ́nẹ́sísì 22:2; bákannáà wo Hébérù 11:17) | Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì Jésù ni Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Baba (Jòhánnù 3:16) |
Ábráhámù àti Ísáákì Ísáákì ni a fẹ́ fi sílẹ̀ ní ipò ọ̀dọ́-àgùtàn (Gẹ́nẹ́sísì 22:7–9) | Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì Jésù Krístì ni Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run (Jòhánnù 1:29) |
Àwọn àmì wo tàbí ìjọra sí ìrúbọ ètútú Olùgbàlà ni ẹ rí tí ó nítumọ̀ jùlọ? Ẹ yẹ kíkọrin tàbí kíka àwọn ẹsẹ orin ìsìn kan tí ó fi ìfẹ́ Baba Ọ̀run hàn fún wa, bí irú “Olúwa Fẹ́ràn Wa, Nítorínáà Ó Rán Ọmọ Rẹ̀,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 187. Bákannáà ẹ lè ṣe àkọsílẹ̀ ìmọ̀lára yín nípa Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì àti ìrúbọ Wọn fún yín.
Bí ẹ bá fẹ́ ṣe àṣàrò síi nípa ìrúbọ Olùgbàlà wa, ẹ yẹ kíka ọ̀rọ̀ Ààrẹ Jeffrey R. Holland wo “Kíyèsí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run” (Làìhónà, Oṣù Karun 2019, 44–46). Kínni ìdí tí ọ̀dọ́-àgùtàn kan fi jẹ́ àmì alágbára ti Ọmọ Ọlọ́run? Kínni Ààrẹ Holland kọ́ni pé o´ nmú ọ̀wọ̀ yín fún ẹ̀bùn Baba Ọ̀run pọ̀ si?
Bákannáà wo “Akedah (Sísopọ̀ Náà)” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Akedah (The Binding)
Lo wíwòran láti kọ́ni. Láti fi oríṣiríṣi kún ìkọ́ni àti ikẹkọ, ẹ lè lo ọ̀kan tàbí púpọ̀ síi ti àwọn àwòrán nínú ìlànà yí bí ẹ ti nṣe àṣàrò àwọn ìtàn nínú Gẹ́nẹ́sísì 18–23. Fún àpẹrẹ, ẹ̀yin àti ẹbí yín tàbí kílásì lè ṣe àkíyèsí ní kíkún nínú àwọn àwòrán ti Ábráhámù àti Ísáákì. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí àwọn àlàyé wọ̀nyí fi ṣe pàtàkì sí ìtàn náà, kí ẹ sì wá àwọn àlàyé nínú àwọn ìwé mímọ́. Báwo ni wọ́n ṣe nfi àmì ìtàn náà hàn nípa ìrúbọ Ọmọ Ọlọ́run?
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé-ìròhìn Làìhónà àti fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Gẹ́nẹ́sísì 17:15–21; 18:14; 21:1–7
Mo lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láti pa àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́.
-
Láti kọ́ nípa ìgbẹ́kẹ̀lé Ábráhámù àti Sáràh nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè sọ̀rọ̀ nípa àkokò nígbàtí wọ́n ní láti dúró fún ohunkan tí wọ́n nfẹ́ lódodo. Nígbànáà ẹ lè wo àwòrán Sáràh àti Ísáákì ní ìbẹ̀rẹ̀ ìlànà yí kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún un àti Ábráhámù (bákannáà wo “Ábráhámù àti Sáràh,” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 28–31). Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún wa bí a bá jẹ́ olóòótọ́. Ẹ gbà wọ́n níyànjú láti ní sùúrù àti ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run yíò pa àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́.
2:20Abraham and Sarah
-
Láti ràn àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ òtítọ́ pàtàkì náà nínú Gẹ́nẹ́sísì 18:14, ẹ lè kọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan látinú ẹ̀là ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ ti ẹsẹ náà lórí ẹ̀la bébà yíyàtọ̀. Nígbànáà ẹ rú àwọn bébà pọ̀, kí ẹ sì pè àwọn ọmọ yín láti fi àwọn ọ̀rọ̀ náà si nínú ní èrò tótọ́. Ẹ̀yin àti ọmọ yín nígbànáà lè ka Gẹ́nẹ́sísì 17:15–21; 21:1–7 láti wá àpẹrẹ ohunkan tí Olúwa ṣe tí ó dàbí kò ṣeéṣe. Ẹ pín ìgbàgbọ́ yín pé Olúwa yíò mú àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, àní bí wọ́n bà dàbí kò ṣeéṣe tàbí gba àkokò pípẹ́.
Gẹ́nẹ́sísì 19:15–26
Mo lè sá fún ìwà búburú.
-
Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín nípa àwọn ipò nínú èyí tí ẹnìkan fi lè pè wọ́n láti ṣe ohunkan tí wọ́n mọ̀ pé kò tọ́. Báwo ni a ó ṣe “sá” nínú àwọn ipò wọ̀nyí? Ṣe àkópọ̀ Gẹ́nẹ́sísì 19:15–26 nípa ṣíṣe àlàyé pé ẹbí Lọ́tì gbé nínú ìlú búburú gan àwọn ángẹ́lì sì kìlọ̀ fun wọn láti kúrò. Bí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín ṣe nka àwọn ẹsẹ 15–17, 26, ẹ bèèrè lọ́wọ́ ohun tí ó lè túmọ̀sí fún wa ní òní láti “ní ọ̀nà àbáyọ” kúrò nínú ibi àti “wíwo ẹ̀hìn” (ẹsẹ 17).
Sódómù, láti ọwọ́ Julius Schnorr von Carolsfeld
Gẹ́nẹ́sísì 22:1-14
Ábráhámù gbọ́ran sí Olúwa
-
Lílò àwọn àwòrán ti Ábráhámù àti Ísáákì àti ìkànmọ́ àgbélèbú (wo Ìwé Ọnà Ìhìnrere, àwọn nọ́mbà. 9,57) lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ṣe àfiwé ìtàn náà nínú Gẹ́nẹ́sísì 22 pẹ̀lú ìrúbọ Olùgbàlà (wo Matteu 27:26–37). Kínni a lè kọ́ nípa Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì látinú àkọsílẹ̀ ti Ábráhámù àti Ísáákì àti ìkànmọ́ àgbélèbú? (Bákannáà wo “Ábráhámù àti Ísáákì,” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 34–37.)
2:0Abraham and Isaac
-
Njẹ́ ẹ lè ronú nípa eré irọ̀rùn kan láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ yín tí ó gba kí wọ́n tẹ̀lé ìdarí? Bóyá àwọn ìdarí náà lè dárí sí ìpamọ́ àwòrán ti Olùgbàlà. Eré náà lè mú ìbárasọ̀rọ̀ kan wá nípa àwọn ohun tí Baba Ọ̀run ti pàṣẹ fún wa láti ṣe kí a lè gbé pẹ̀lú Rẹ̀ àti Jésù Krístì lẹ́ẹ̀kansi. Ẹ yẹ kíkọ orin kan bí irú “Pa àwọn Òfin Mọ́” (Ìwé Orin àwọn Ọmọdé, 146–47). Ojú-ewé ṣíṣe ọ̀sẹ̀ yí tí ó lè ṣerànwọ́ bákannáà.
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .