Come, Follow Me
Oṣù Kejì 16–22. “Láti Jẹ́ Ọmọẹ̀hìn Títóbijù ti Òdodo”: Gẹ́nẹ́sísì12–17; Ábráhámù 1–2


“Oṣù Kejì 16–22. ‘Láti Jẹ́ Ọmọẹ̀hìn Títóbijù ti Òdodo’: Gẹ́nẹ́sísì 12–17; Ábráhámù 1–2,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àtiÌjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kejì 16–22. ‘Láti Jẹ́ Ọmọẹ̀hìn Títóbijù ti Òdodo’,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026

Mẹlkisédékì ngbe ọwọ́ rẹ̀ lé orí Ábrámù láti bùkún rẹ̀

Mẹlkisédékì Nbùkún Ábrámù, láti ọwọ́ Walter Rane (àlàyé)

Oṣù Kejì 16– 22: “Láti Jẹ́ Ọmọẹ̀hìn Títóbijù ti Òdodo”

Gẹ́nẹ́sísì 12–17; Ábráhámù 1–2

Nítorí májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú rẹ̀, Ábráhámù ni a pè ní “baba àwọn olódodo” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 138:41) àti “Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run” (Jákọ́bù 2:23). Àwọn míllíọ́nù ní òní nbu-ọlá fún un bí babanlá wọn tààrà, àti pé àwọn míràn ni a ti gbàtọ́ sínú ẹbí rẹ̀ nípasẹ̀ ìyípadà sí ìhìnrere Jésù Krístì. Síbẹ̀ Ábráhámù fúnrarẹ̀ wá láti inú ẹbí kan tí ó ní ìdààmú—baba rẹ̀, ẹnití ó ti pa ìjọ́sìn òtítọ́ Ọlọ́run tì, gbìyànjú láti fi Ábráhámù rúbọ sí àwọn ọlọ́run èké. Pẹ̀lú èyí, ìfẹ́ Ábráhámù ni “láti jẹ́ ọmọẹ̀hìn títóbijù ti òdodo” (Ábráhámù 1:2), àkọsílẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ si fihàn pé Ọlọ́run bu-ọlá fún ìfẹ́ rẹ̀. Ìgbésí ayé Ábráhámù dúró bí ẹ̀rí tí ó jẹ́ pé ohun èyíówù kí ìwé-ìtàn ẹbí ẹnìkan jẹ́, ọjọ́ ọ̀la lè kún fún ìrètí.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ

Ábráhámù 1:1– 19

Ọlọ́run yíò bùkún mi fún ìfẹ́ ìgbàgbọ́ àti òdodo.

“Gbogbo wa ní ipa nípa àwọn ẹbí wa [àti] àṣà wa,” Alàgbà Neil L. Andersen kọ́ni pé, “àti síbẹ̀ mo gbàgbọ́ pé ibìkan wà nínú wa tí à nṣe àkóso àti tí a ndá sílẹ̀ bíi ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ní àrà ọ̀tọ̀. … Ní ìgbẹ̀hìn, ìfẹ́ inú wa ni fífi ìyè fúnni a sì nrí wọn nínú àwọn àṣàyàn àti nínú àwọn ìṣe wa” (“Ẹ Kọ́ àwọn Ìfẹ́-inú Yín, ni Alàgbà Andersen Dámọ̀ràn,” ChurchofJesusChrist.org). Ẹ gbèrò bí Ábráhámù 1:1–19 ṣe júwe ohun tí Alàgbà Andersen kọ́ni. Àwọn ìbèèrè bí ìwọ̀nyí lè ṣèrànwọ́:

  • Kínni Ábráhámù ní ifẹ́-inú sí? Báwo ni àwọn ìfẹ́-inú rẹ̀ ṣe hàn nínú àwọn ìṣe rẹ̀? Báwo ni Ọlọ́run ṣe nti àwọn ìfẹ́-inú wa lẹ́hìn?

  • Kínni àwọn ìfẹ́-inú yín? Báwo ni wọ́n ṣe hàn nínú àwọn ìṣe yín? Báwo ni Ọlọ́run ṣe tì yín lẹ́hìn?

  • Kínni ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ní fún àwọn ènìyàn tí ọmọ ẹbí wọn kò ní ìfẹ́-inú òdodo?

Ọkàn lára ìfẹ́-inú títóbijùlọ ti Ábráhámù àti Sáràh—láti ní ọmọ kan—láìní ìmúṣẹ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọdún (wo Gẹ́nẹ́sísì 15:1–6). Kínni ẹ kọ́ láti inú Hébérù 11:8–13 nípa bí Ábráhámù àti Sáràh ṣe kojú àdánwò yí? Báwo ni Olùgbàlà ṣe nràn yín lọ́wọ́ láti “rọ̀mọ́” àwọn ìlérí Rẹ̀, àní bí wọ́n ṣe“jìnnà réré”?

Bákannáà wo “Ìdándè ti Ábráhámù” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

1:38

Deliverance of Abraham

Gẹ́nẹ́sísì 12:1–3; 13:15–16; 15:1–6; 17:1–8, 15–22; Ábráhámù 2:6–11

àmì sẹ́mínárì
Ọlọ́run nfẹ́ kí èmi dá kí nsì pa àwọn májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú Rẹ̀.

Kínni ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì fún yín láti mọ̀ nípa májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú Ábráhámù? Nítorí Ọlọ́run nfẹ́ láti dá irú májẹ̀mú kannáà pẹ̀lú yín. Ó ṣe ìlérí pé májẹ̀mú yí yíò tẹ̀síwájú nínú àtẹ̀lé Ábráhámù, tàbí “irú-ọmọ,” àti pé “bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí wọ́n ti gba Ìhìnrere yí ni a ó … kà wọ́n bí irú-ọmọ rẹ̀” (wo Ábráhámù 2:10–11). Ní ọ̀rọ̀ míràn—nígbàtí májẹ̀mú bá tẹ̀síwájú nínú yín—nígbàtí ẹ bá ṣe ìrìbọmi àti ní ìparí nígbàtí ẹ bá dá májẹ̀mú nínú tẹ́mpìlì (wo Gàlátíà 3:26–29; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 132:30–32).

Fún èrèdí náà, ẹ lè fẹ́ láti ṣe àṣàrò Ábráhámù 2:6–11 kí ẹ sì ṣe ìtòsílẹ̀ ohun, tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Ábráhámù àti Sáràh (bákannáà wo Gẹ́nẹ́sísì 12:1–3; 13:15–16; 15:1–6; 17:1–8, 15–22). Báwo ni àwọn ìbùkún wọ̀nyí ṣe lè wúlò sí yín?

Àwọn kan lára ìlérí wọ̀nyí ní ìbámu ayérayé. Báwo ni àwọn ìlérí ṣe dàbí ilẹ̀ ogún tàbí àtẹ̀lé títóbi láti ṣe ìmúṣẹ ti ayérayé? (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 131:1–4; 132:20–24, 28–32).

Ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ìbùkún tí a ṣe ìlérí, Ọlọ́run sọ fún Ábráhámù láti “jẹ́ alábùkún kan” (Gẹ́nẹ́sísì 12:2; àfikún àtẹnumọ́). Kínni ẹ rò pé ìyẹn túmọ̀sí? Báwo ni ṣe jẹ́ alábùkúnfún kan? (wo Ábráhámù 2:11).

Láti kọ́ni nípa àwọn májẹ̀mú, Alàgbà Dale G. Renlund sọ̀rọ̀ ti ìjì omi nínú Odò Amazon, Ààrẹ Emily Belle Freeman sì sọ̀rọ̀ nípa ipa ọ̀nà àpáta pẹ̀lú orókún kíkán (wo “Níní Ààyè Sí Agbára Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn Májẹ̀mú,” Làìhónà, Oṣù Karun 2023, 35–37; “Rírìn nínú Ìbáṣepọ̀ Májẹ̀mú pẹ̀lú Krístì,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2023, 76–79). Wá ọ̀kan tàbí méjèèjì àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ẹ̀là ọ̀rọ̀ tí ó lè ṣèrànwọ́ láti dáhùn ìbèèrè náà “Kídìní tí Ọlọ́run fẹ́ kí ndá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Òun?”

Pè àwọn ènìyàn láti kọ́ arawa. Bí ẹ bá nkọ́ ẹbí yín tàbí kílásì Ìjọ kan nípa a`wọn májẹ̀mú, ẹ yẹ fífún ẹni kọ̀ọ̀kan ní apákan ti ọ̀rọ̀ Alàgbà Relund tàbí Ààrẹ Freeman láti ṣe àṣàrò. Lẹ́hìnnáà wọ́n lè ṣe àbápín pẹ̀lú ìyókù ẹbí tàbí kílásì ohun tí wọ́n kọ́. Èyí fi ààyè gba àwọn ènìyàn láti jẹ́ ẹ̀rí láti àti láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ ara wọn, kí wọ́n sì pe Ẹ̀mí. (Wo Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,26.)

Bákannáà wo àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Májẹ̀mú ti Ábráhámù,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere; “Àwọn Èrò láti Pamọ́ nínú Iyè-inú,” nínú ohun èlò yí.

Ábráhámù àti Sáràh

Májẹ̀mú ti Ábráhámù, láti ọwọ́ Dilleen Marsh (àlàyé kíníkíní)

Gẹ́nẹ́sísì 14:18–19; Ìyírọ̀padà Jósẹ́fù Smith, Gẹ́nẹ́sísì 14:25–40

“Mẹlkisédékì ọkùnrin Ìgbàgbọ́.”

Ẹ ròó bí ẹ bá nfi Mẹlkisédékì hàn sí ẹnìkan tí kò mọ̀ ọ́. Kínni ẹ yíò sọ? Ẹ wá Ìyírọ̀padà Jósẹ́fù Smith, Gẹ́nẹ́sísì 14:26–27, 33–38 (nínú àlèmọ́ Bíbélì); Álmà 13:13–19; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 107:1–4. Kínni àwọn ìwà bíiti Krístì tí ẹ rí nínú àwọn ìjúwe wọ̀nyí nípa Mẹlkisédékì? Báwo ni àṣàrò ìgbésí ayé ti Mẹlkisédékì yín fi ní ipa lórí ọ̀nà tí ẹ fi nwo Oyè Àlùfáà Melkísédékì?

Gẹ́nẹ́sísì 14:18–24; Ìyírọ̀padà Jósẹ́fù Smith, Gẹ́nẹ́sísì 14:36–40

Ábráhámù san idamẹwa.

Kínni ẹ kọ́ nípa ìhùwàsí Ábráhámù sí ọrọ̀ látinú Gẹ́nẹ́sísì 14:18–24 àti Ìyírọ̀padà Joseph Smith, Gẹ́nẹ́sísì 14:36–40 (nínú àlẹ̀mọ́ Bíbélì)? Fún àpẹrẹ, ẹ kíyèsí èsì rẹ̀ sí ọbọ Sódómù nínú Gẹ́nẹ́sísì 14:23. Báwo ni gbígbọ́ran sí àṣẹ idamẹwa ṣe ní ipá lórí ìwò ti owó?

Gẹ́nẹ́sísì 12

Ọlọ́run ngbọ́ mi.

Bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 16, ẹ lè ronú nípa àkokò kan nígbàtí ẹ nimọ̀lára pé a tọ́jú yín ní àìdára, bí Hágárì ti ṣe. Ẹ kíyèsi pé “Íṣmáẹ́lì” túmọ̀sí“ Ọlọ́run ngbọ́.” Báwo ni Ọlọ́run ṣe ti fihàn yín pé Òun ti gbọ́ ọ yín?

Bákannáà wo “Àdúrà Ikọ̀kọ̀,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 144.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé 01

Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé

Ábráhámù 1:18; 2:8

Jésù Krístì yíò darí mi nípa ọwọ́.

  • Bí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín ṣe nka Ábráhámù 1:18 àti 2:8, ẹ lè pè wọ́n láti fetísílẹ̀ fún apákan ti ara èyí tí a dárúkọ nínú àwọn ẹsẹ méjèèjì. Bóyá ẹ lè ṣe eré nínú èyí tí ọmọ kan ó di ojú wọn tí ẹ ó sì darí ọmọ kan níbìkan nípa ọwọ́. Lẹ́hìnnáà ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa bí ó rí láti ní Jésù Krístì láti darí wọ nípa ọwọ́ tàbí dá ààbò bò wá.

Gẹ́nẹ́sísì 13:5-12

Èmi lè jẹ́ onílàjà kan.

  • Àwọn ọmọ yín lè gbádùn ṣíṣe eré ìtàn náà jáde látinú Gẹ́nẹ́sísì 13:5–12, ní dídibọ́n láti jẹ́ Ábráhámù, Lọ́tì, àti àwọn darandaran. Báwo ni a ṣe lè tẹ̀lé àpẹrẹ ti Ábráhámù ti jíjẹ́ onílàjà pẹ̀lú ẹbí wa tàbí àwọn ọ̀rẹ́? Ẹ gbìyànjú ṣíṣe eré àwọn ìdáhùn wọn.

Ábráhámù nsọ̀rọ̀ sí Lọ́tì

Àṣàyàn Lọ́tì, láti ọwọ́ William Fredericks © Providence Collection/licensed láti goodsalt.com

Gẹ́nẹ́sísì 13:16; Gẹ́nẹ́sísì 15:1–6; 17:1–8; Ábráhámù 2:9–11

Ọlọ́run nfẹ́ kí èmi dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀.

  • Ẹ yẹ fífi agolo ti erùpẹ̀, àwọn ìràwọ̀ nínú àwọ̀sánmọ̀ òru, tàbí àwòrán ní òpin ìlànà yí han àwọn ọmọ yín wò. Èyí lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní òye àwọn ìlérí Ọlọ́run nínú Gẹ́nẹ́sísì 13:16; 15:1–6. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ ṣe kọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìlérí Ọlọ́run, àní nígbàtí wọ́n dàbí kò ní ṣeéṣe.

  • Láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa àwọn májẹ̀mú, ẹ ní kí wọ́n sọ fún yín nípa àkokò kan nígbàtí wọ́n ṣe ìlérí kan tàbí ẹnìkan ṣe ìlérí fún wọn. Bí ó bá ṣèrànwọ́, ẹ pín àwọn àpẹrẹ ti ara yín—pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú tí ẹ dá pẹ̀lú Ọlọ́run níbi ìrìbọmi tàbí nínú tẹ́mpìlì. Báwo ni àwọn májẹ̀mú yín ṣe nní ipá lórí ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Ọlọ́run? Ẹ yan àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ látinú Gẹ́nẹ́sísì 15:1–6; 17:1–8; Ábráhámù 2:9–11 láti pín díẹ̀ lára ìlérí àwọn ìbùkún Ọlọ́run sí Ábráhámù àti Sáràh.

  • Láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ láti dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú Ọlọ́run nígbàtí wọ́n bá ṣe ìrìbọmi àfikún A tàbí àfikún B.

Ábráhámù 1:12–17; Gẹ́nẹ́sísì 16:7–11

Ọlọ́run ngbọ́ mi.

  • Nígbàtí ìgbé ayé Ábráhámù wà nínú ewu, ó pe Ọlọ́run. Nígbàtí Hágárì dánìkanwà nínú aginjù, ó kọ́ ẹ̀kọ́ pé Ọlọ́run gbọ́ ọ. Ẹ yẹ pípín àwọn ìtàn méjì wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ yín wò: “Ábráhámù àti Sáràh” àti “Hágárì” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 28–31, 32–33. Lẹ́hìnnáà ẹ lè kọ́ nípa Ọlọ́run látinú àwọn ìtàn wọ̀nyí? Lẹ́hìnnáà ẹ lè pín àwọn ìrírí ìgbà tí ẹ ti ní ìmọ̀lára pé Ọlọ́run gbọ́ yín pẹ̀lú ara yín. Orin kan bíiti “Àdúrà Ọmọ Kan” (Ìwé Orin àwọn Ọmọdé, 12–13) lè tún ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí sọ.

2:20

Abraham and Sarah

1:23

Hagar

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde Oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .

Sáràh nwo àwọn ìràwọ̀ ní òkè

Jíròrò Ìlérí ti Ọlọ́run, láti ọwọ́ Courtney Matz

Ojú-ewé ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Ọlọ́run nfẹ́ kí n dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀