“Oṣù Kínní 26 sí Oṣù Kejì 1. ‘Ẹ Fi àwọn Ohun Wọ̀nyí Kọ́ àwọn Ọmọ Yín Lọ́fẹ̀ẹ́: Gẹ́nẹ́sísì 5, Mósè 6,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kínní 26 sí Oṣù Kejì 1. ‘Ẹ Fi àwọn Ohun Wọ̀nyí Kọ́ àwọn Ọmọ Yín Lọ́fẹ̀ẹ́’,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026
Dídára Ju Párádísè, láti ọwọ́ Kendal Ray Johnson
Oṣù Kínní 26 sí Oṣù Kejì 1: “Ẹ Fi àwọn Ohun Wọ̀nyí Kọ́ àwọn Ọmọ Yín Lọ́fẹ̀ẹ́”
Gẹ́nẹ́sísì 5; Mósè 6
Púpọ̀jùlọ ti Gẹ́nẹ́sísì 5 jẹ́ ìtòsílẹ̀ nípa àwọn ìran láàrin àkókò Ádámù àti Éfà àti Nóà. A ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ, ṣugbọ́n a kò kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ nípa wọn. Lẹ́hìnnáà a ka ilà àìlè ṣe àlàyé ṣùgbọ̀n yíyanilẹ́nu yí: “Énọ́kù sì bá Ọlọ́run rìn: òun kò sì sí; nítorítí Ọlọ́run mú u lọ” (Gẹ́nẹ́sísì 5:24). Dájúdájú ìtàn kan wà ní ẹ̀hìn ẹsẹ náà! Ṣùgbọ́n láìsí àlàyé síwájú síi, ìtòsílẹ̀ àwọn ìran ti bẹ̀rẹ̀.
Pẹ̀lú ọpẹ́, Mósè 6 fi àlàyé ìtàn Énọ́kù hàn—ó sì jẹ́ ìtàn gan. A kọ́ nípa ìrẹ̀lẹ̀ Énọ́kù, àìní-ààbò rẹ̀, ìlèṣe tí Ọlọ́run rí nínú rẹ̀, àti iṣẹ́ nlá tí ó ṣe bíi wólíì Ọlọ́run. Bákannáà a gba àwòrán hihàn kedere kan nípa ẹbí Ádámù àti Éfà bí wọ́n ti nní ìlọ̀síwájú nínú àwọn ìran. A kà nípa “agbára gíga” ti Sátánì ṣùgbọ́n bákannáà nípa àwọn òbí tí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ “ní àwọn ọ̀nà Ọlọ́run” (Mósè 6:15, 21). Iyebíye nípàtàkì ni ohun tí à kọ́ nípa ẹ̀kọ́ tí àwọn òbí wọ̀nyí kọ́ni: ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, àti gbígba Ẹ̀mí Mímọ́ (wo Mósè 6:50–52). Ẹ̀kọ́ náà, bíi ti oyè àlùfáà tí ó nba rìn, “wà ní àtètèkọ́ṣe yíò [sì] wà ní òpin ayé bákannáà” (Mósè 6:7).
Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti ní Ìjọ
Ẹ̀ṣẹ̀ nṣe àdínkù agbára mi láti rí, láti ní ìmọ̀lára, àti láti gbọ́ àwọn ohun Ọlọ́run.
Bí ẹ ti nṣe àṣàrò Mósè 6:26–36, kínni ẹ kọ́ nípa àwọn àbájáde ẹ̀ṣẹ̀? Báwo ni ẹ ti rí àwọn àbájáde wọ̀nyí? Kínni àwọn ìhùwàsí tí Énọ́kù ní tí ó ràn án lọ́wọ́ láti borí àwọn àbájáde wọ̀nyí? Báwo ni Ọlọ́run ṣe bùkún un bí àyọrísí?
Ọlọ́run npè mí láti ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ ni àìka àwọn àìlera mi sí.
Bí ẹ bá ní ìmọ̀lára bíbonimọ́lẹ̀ pẹ̀lú ohun tí Olúwa ti pè yín láti ṣe, ẹ kò dá nìkàn wà. Àní Énọ́kù ní ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ nígbàtí Olúwa pè é láti jẹ́ wòlíì. Bí a ti nka Mósè 6:26–36, wá ìdí tí Énọ́kù fi ní ìmọ̀lára ìbonimọ́lẹ̀ àti ohun tí Olúwa wí láti fun ní ìgboyà.
Nínú àwọn ẹsẹ 37–47, ẹ lè wá àwọn ọ̀nà tí Olúwa fi ti Énọ́kù lẹ́hìn tí Ó sì ró o lágbára láti ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ (bákannáà wo Mósè 7:13). Ẹ lè ṣe àfiwé ìrírí Énọ́kù pẹ̀lú ti àwọn wòlíì míràn tí wọ́n ní ìmọ̀lára àìkúnjú-ìwọ̀n, bí irú ti Mósè (wo Ẹ́ksódù 4:10–16), Jeremíàh (wo Jeremíàh 1:4–10), Néfì (wo 2 Néfì 33:1–4), àti Mórónì (wo Ẹtérì 12:23–29). Kínni ẹ ní ìmọ̀lára pé Ọlọ́run nfẹ́ kí ẹ kọ́ láti inú àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí nípa iṣẹ́ tí Ó ti fún yín láti ṣe.
Aríran Kan Ni Olúwa ti Gbé Dìde (Mósè 6:36), láti ọwọ́ Eva Timothy
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpóstélì àti àwọn wòlíì òde-òní ti fi ìmọ̀lára tí ó dábí irú ti Énọ́kù hàn nígbàtí wọ́n júwe bí ó ti rí láti gba ìpè wọn. Fún àpẹrẹ, wo ẹ̀rí Alàgbà Ulisses Soares nínú “Àwọn Wòlíì Nsọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Agbára Ẹ̀mí Mímọ́” (Làìhónà, Oṣù Karun 2018, 98–99).
Kínni ẹ lè kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn àpóstélì àti àwọn wòlíì wọ́nyí nípa ìmọ̀lára àìkúnjú-ìwọn yín? Nígbà wo ni ẹ ti ní ìmọ̀lára pé Olùgbàlà ràn yín lọ́wọ́ nígbàtí Ó ní kí ẹ ṣe àwọn ohun líle kan? Ẹ yẹ kíkọ́ àwọn ìrírí díẹ̀ sílẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la yín nígbàtí ẹ bá nílò láti gbáralé ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà. Báwo ni ẹ ṣe lè ṣe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì.
Bákannáà wo David A. Bednar, “Gbé nínú Mi, àti Èmi nínú Rẹ; Nítorínáà Rìn pẹ̀lú Mi,” Làìhónà, Oṣù Karun 2023, 123–25; “Èmi Ó Lọ Ibi Tí Ó Bá Fẹ́ Kí Nlọ,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 270.
Ìhìnrere Jésù Krístì ni a kọ́ni láti àtètèkọ́ṣe.
Nítorí a ní ìwé ti Mósè, a mọ̀ pé Ọlọ́run ti nkọ́ àwọn ọmọ Rẹ̀ bí wọn ó ti rí ìràpadà láti ìgbà Ádámù àti Éfà. Bí ẹ ti nṣe àṣàrò Mósè 6:48–68, ẹ wá kiri fún ohun tí a gbọ́dọ̀ mọ̀ àti láti ṣe láti di rírapadà. Kíyèsí ìbèèrè Ádámù ní ẹsẹ 53. Njẹ́ èyí ti yà yín lẹ́nu rí bí? Kínni ẹ kọ́ láti inú ìdáhùn Olúwa nínú àwọn ẹsẹ 53–65? Ẹ lè ronú nípa àwọn ẹsẹ wọ̀nyí bíi ọ̀rọ̀ Olúwa níbi ìsìn ìrìbọmi Ádámù. Kínni ẹ kọ́ nípa ìrìbọmi láti inú ọ̀rọ̀ Rẹ̀? Kínni ìdí tí ẹ fi ronú pé Ó ṣe àfiwé ìrìbọmi sí jíjẹ́ “àtúnbí”? (ẹsẹ 59). Kínni ẹ lè ṣe láti tẹ̀síwájú láti jẹ́ “àtúnbí” ní gbogbo ayé yín?
Ẹ wá àwọn àmì. Nínú àwọn ìwé mímọ́, àwọn nkan tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lè fi ìgbàkugbà dúró fún tàbí ṣe àmì àwọn òtítọ́ ti ẹ̀mí nípàtàkì àwọn òti´tọ́ nípa Olùgbàlà (wo Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,7). Àwọn àmì wọ̀nyí lè bùkún òye yín nípa Rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Fún àpẹrẹ, kínni ẹ kọ́ láti inú àwọn àmì ti ọkàn àti etí nínú Mósè 6:27, ojú àti amọ̀ nínú Mósè 6:35, tàbí omi nínu Mósè 6:59–60?
“Ẹ fi àwọn ohun wọ̀nyí kọ́ àwọn ọmọ yín lọ́fẹ̀ẹ́.”
Lẹ́hìn kíkọ́ Adámù ní àwọn òtítọ́ ìhìnrere Jésù Krístì, nínú Mósè 6:51–6, Olúwa wí fún Ádámù láti fi wọ́n kọ́ àwọn ìran ọjọ́ ọ̀la. Ẹ yẹ ṣíṣe ìtòsílẹ̀ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí wò. (Ó lè ṣèrànwọ́ láti pín ẹsẹ ọ̀rọ̀ náà sí àwọn ẹsẹ kékèké ẹsẹ 51–52, 53–57, 58–60, 61–63). Kínni ìdí tí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí fi níye lórí sí ìran tí ó ndìde ní òní? Kínni ohun míràn tí ẹ lè kọ́ láti inú àwọn ìkọ́ni Olúwa sí àwọn òbí nínú Mòsíàh 4:14–15 àti Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 68:25–28; 93:40–50?
Kíka nípa “ìwé ìrántí” tí ẹbí Ádámù àti Éfà ti fi pamọ́ lè mísíi yín tàbí ẹbí yín láti ṣe ìwé ìrántí ti ara yín. Kínni ẹ ní ìmọ̀lára pé Olúwa yíò fẹ́ kí ẹ fi kún un? Ẹ ṣe àyẹ̀wò fífi ìwífúnni pamọ́ láti inú ìwé ìrántí yín sí orí FamilySearch.org.
Bákanáà wo Dieter F. Uchtdorf, “Jésù Krístì Ni Okun àwọn Òbí,” Làìhónà, Oṣù Karun 2023, 55–59; “Jíjẹ́ Òbí: Fífi Ọwọ́ Tọ́ Ọkàn àwọn Ọ̀dọ́ Wa,” “Ṣùgbọ́n Kínni ìdí?” (àwọn fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Fún púpọ̀ síi, wo àwọn àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé-ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́.
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Jésù lè ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ohun líle
-
Nígbàtí a pè Énọ́kù láti wàásù ìhìnrere, ó dààmú pé òun yíò kùnà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ràn án lọ́wọ́. Ẹ ka ìtàn yí papọ̀ nínú Mósè 6:26–34 (bákannáà wo “Énọ́kù Wòlíì Náà” nínú àwọn ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 19–21). Kínni ìdí tí Énọ́kù fi ní ìmọ̀lára pé òun kò lè wàásù ìhìnrere? (wo Mósè 6:31). Báwo ni Ọlọ́run ṣe ran Énọ́kù lọ́wọ́? (wo Mósè 6:32–34; 7:13).
-
Àwọn ọmọ yín lè gbádùn pípín tàbí ṣíṣé àwọn àpẹrẹ míràn jáde nípa ìgbà tí Ọlọ́run ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ohun líle—fún àpẹrẹ, Nóà, Dáfídì, Ámọ́nì, tàbí Sámúẹ́lì ara Lámánì (wo Ìwé Iṣẹ́-ọnà Ìhìnrere, àwọn nọ́mbà. 7, 19, 78,81). Bákannáà ẹ lè pín ìrírí kan nípa ti ara yín kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ohun líle.
Ìgbàgbọ́ nínú Krístì, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, àti gbígba Ẹ̀mí Mímọ́ nmúra mi sílẹ̀ láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
-
Ọlọ́run kọ́ Ádámù ní ohun tí a nílò láti ṣe láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀—ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ronúpìwàdà, jẹ́ rírìbọmi, àti láti gbà ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí nínú Mósè 6:52, 57. Lẹ́hìnnáà ẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ ọ̀rọ̀ kúkurú nípa ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí. Ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan lè wà pẹ̀lú ìwé mímọ́ kan látinú Mósè 6, ìrírí kan, àti ẹ̀rí kan. Ẹ jẹ́ kí wọ́n pín ọ̀rọ̀ wọn pẹ̀lú ara wọn.
-
Bákannáà ẹ lè fi àwọn àwòrán hàn tí ó rọ́pò ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ ti ìhìnrere (wo nkan ìgbàgbọ́ ìkẹ́rin). Fi wọ́n sí orí ìlà tí ó ndarí lọ sí àwòrán Jésù Krístì kan. Bí ẹ ti nka Mósè 6:52, àwọn ọmọ yín lè dúró ní ẹ̀gbẹ́ sí àwòrán tó tọ́ nígbàtí wọ́n bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí àwòrán náà rọ́pò.
-
Àwọn ọmọ yín lè gbádùn kíkọ àwọn orin tí ó kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ náà nínú Mósè 6:52, bí irú “Ìgbàgbọ́,” “Nígbatí Mo Ba Ṣe Ìrìbọmi,” àti “Ẹ̀mí Mímọ́.” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 96–97, 103, 105). Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí nínú Mósè 6:52.
Baba Ọ̀run nfẹ́ kí àwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn.
-
Láti gba àwọn ọmọ yín níyànjú láti ti àwọn òbí wọn lẹ́hìn nínú ojúṣe bí olùkọ́ni ìhìnrere, ẹ ṣe àyẹ̀wò wíwí fún ọmọ kan láti ka Mósè 6:58 kí ó sì ṣe ìdámọ̀ òfin tí Ọlọ́run fún àwọn òbí. Nígbànáà ẹ lè fi àwòrán Ádámù àti Éfà tí wọ́n nkọ́ àwọn ọmọ wọn hàn (bíiti ọ̀kan ní òpin ìlànà yí) kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọmọ yín sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n rí nínú àwòrán náà. Àwọn ọmọ yín lè ya àwọn àwòrán ẹbí wọn tí wọ́n nka ìwé mímọ́ papọ̀, ngbàdúrà papọ̀, tàbí ṣeré papọ̀.
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .