“Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú: Májẹ̀mú Náà,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Májẹ̀mú Náà,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026
Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú
Májẹ̀mú Náà
Nínú gbogbo Májẹ̀mú Láéláé, ẹ ó ka ọ̀rọ̀ náà májẹ̀mú. Ní òní a nronú púpọ̀ nípa àwọn Májẹ̀mú bí àwọn ìlérí pẹ̀lú Ọlọ́run ṣùgbọ́n ní ayé àtijọ́, àwọn májẹ̀mú bákannáà jẹ́ arakan pàtàkì ti ìbaráṣe àwọn ènìyàn pẹ̀lú ara wọn. Fún ààbò wọn àti yíyè, àwọn ènìyàn nílò láti lè gbẹ́kẹ̀lé ara wọn, àti pé àwọn májẹ̀mú ni ọ̀nà kan láti ṣe ìmúdúró ìgbẹ́kẹ̀lé náà.
Nítorínáà nígbàtí Ọlọ́run bá Énọ́kù, Nóà, Mósè, àti àwọn míràn sọ̀rọ̀ nípa àwọn májẹ̀mú, Ó npè wọ́n láti wọnú ìbáṣepọ̀ ti ìgbẹ́kẹ̀lé kan pẹ̀lú Òun. A pè májẹ̀mú yí ní májẹ̀mú titun ati ti àìlópin tàbí májẹ̀mú ti Ábráhámù—atọ́ka kan sí májẹ̀mú tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú Ábráhámù àti Sáràh àti nígbànáà tí wọ́n ṣe àtúnṣe pẹ̀lú àwọn àtẹ̀lé wọn Ísáákì àti Jákọ́bù (bákannáà tí a pè ní Isráẹ́lì). Nínú Májẹ̀mú Láéláé, a mọ̀ọ́ lásán bí “májẹ̀mú náà.” Ẹ ó ri pé Májẹ̀mú Láéláé ni ìpìlẹ̀ ìtàn ti àwọn ènìyàn tí wọ́n rí ara wọn bí àwọn ajogún májẹ̀mú yí—àwọn ènìyàn májẹ̀mú.
Májẹ̀mú ti Ábráhámù ntẹ̀síwájú láti jẹ́ pàtàkì ní òní, nípàtàkì sí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Kínni ìdí? Nítorípé a jẹ́ àwọn ènìyàn májẹ̀mú bákannáà, bóyá tàbí kìí ṣe pé a jẹ́ àwọn àtẹ̀lé tààrà ti Ábráhámù, Ìsáákì, àti Jákọ́bù. Fún èrèdí yí, ó ṣe pàtàkì láti ní òye ohun tí májẹ̀mú ti Ábráhámù jẹ́ àti bí ó ti wúlò sí wa ní òní.
Kínni Májẹ̀mú ti Ábráhámù Jẹ́?
Ábráhámù nfẹ́ “láti jẹ́ àtẹ̀lé títóbijù ti òdodo” (Ábráhámù 1:2), nítorínáà Ọlọ́run pè é sínú májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ kan. Ábráhámù kìí ṣe àkọ́kọ́ láti ní ìfẹ́ yí, òun kìí sì iṣe àkọ́kọ́ láti gba májẹ̀mú kan. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, ó jẹ́, májẹ̀mú àìlópin kan. Ábráhámù wá “àwọn ìbùkún ti àwọn baba” (Ábráhámù 1:2)—àwọn ìbùkún tí a fi fúnni nípasẹ̀ májẹ̀mú ti Ádámù àti Éfà àti lẹ́hìnnáà sí àwọn ènìyàn tì wọ́n nwá nfi ìtara wá àwọn ìbùkún wọ̀nyí.
Májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú Àbráhámù ṣe ìlérí àwọn ìbùkún ìyanu: ogún kan nípa ilẹ̀, ìran títóbi kan, ààyè sí àwọn ìlànà oyè àlùfáà, àti orúkọ kan tí a ó fi bu ọlá fún àwọn ìran tí ó nbọ̀. Ṣùgbọ́n ìdojúkọ májẹ̀mú yí kìí ṣe lórí àwọn ìbùkún tí Ábráhámù àti ẹbí rẹ̀ yíò gbà lásán ṣùgbọ́n bákannáà lórí ìbùkún tí wọn yíò jẹ́ sí ìsinmi àwọn ọmọ Ọlọ́run. “Ìwọ yíò jẹ́ ìbùkún,” Ọlọ́run kéde, “àti nínú rẹ ni gbogbo àwọn ẹbí ti ilẹ̀ ayé yíò di alábùkún fún” (Gẹ́nẹ́sísì 12:2–3).
Ṣé májẹ̀mú èyí fún Ábráhámù, Sárà, àti àwọn àtẹ̀lé wọn ní ipò ànfàní ní àárín àwọn ọmọ ti Ọlọ́run bí? Nínú ọgbọ́n nìkan pé ó jẹ́ ànfàní kan láti bùkún àwọn ẹlòmíràn. Ẹbí ti Ábráhámù ní láti “gbé iṣẹ́ ìránṣẹ́ yí àti Oyè àlùfáà lọ sí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè,” ní pípín “àwọn ìbùkún Ìhìnrere, èyí tí ó jẹ́ àwọn ìbùkún ìgbàlà, àní ti ìyè ayérayé” (Ábráhámù 2:9, 11). Jíjẹ́ àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run kò túmọ̀ sí pé wọ́n dára ju àwọn ẹlòmíràn; ó túmọ̀ sí pé wọ́n ní ojúṣe kan láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti dára si.
Májẹ̀mú yí ni ìbùkún tí Ábráhámù ti nfojúsọ́nà fún. Lẹ́hìn gbígbà á, Ábráhámù wí nínú ọkàn rẹ̀, “Ìránṣẹ́ rẹ ti fi ìtara wá ọ; nísisìyí èmi ti rí ọ” (Ábráhámù 2:12).
Tí ó jẹ́ ẹgbẹgbẹẹ̀rún ọdún sẹ́hìn, ṣùgbọ́n májẹ̀mú yí ni a ti múpadàbọ̀sípò ní ọjọ́ wa. Ó sì jẹ́ mímúṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Mímúṣẹ ti májẹ̀mú náà ni gbígbéga ipa ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn bí iṣẹ́ Ọlọ́run ti nlọsíwájú, ní bíbùkún àwọn ẹbí ní gbogbo ayé. Ẹnikẹ́ni bíiti, Ábráhámù, tí ó nfẹ́ láti jẹ́ àtẹ̀lé títóbi jù ti òdodo—ẹnikẹ́ni tí ó bá nfi ìtara wá Olúwa—lè jẹ́ apákan rẹ̀.
Kínni Májẹ̀mú ti Ábráhámù Túmọ̀ Sí fún Mi?
Ẹ̀ jẹ́ ọmọ májẹ̀mú kan. Ẹ̀ ndá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run nígbàtí ẹ ṣe ìrìbọmi àti nígbàtí ẹ bá ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa. Ẹ̀ ó sì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ìlànà mímọ́ ti tẹ́mpìlì.
Nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti ìlànà wọ̀nyí, a ndi àwọn ènìyàn Ọlọ́run. A so wá pọ̀ mọ́ Ọ “pẹ̀lú sísopọ̀ ayérayé.” “Níwọ̀n ìgbàtí a bá ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run,” Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni, “à nfi ààyè wíwà ní àárín sílẹ̀ títíláé. Ọlọ́run kò ní pa ìbáṣepọ̀ Rẹ̀ tì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti fi irú ìsopọ̀ kan bẹ́ẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. Nítóótọ́, gbogbo àwọn tí wọ́n ti dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú Ọlọ́run ní ààyè sí irú ìfẹ́ àti àánú pàtàkì kan. … Nítorí májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Òun kò ní ṣàárẹ̀ láé nínú àwọn ìtiraka Rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́, a kò sì ní tán An ní sùúrù tó kún fún àánú Rẹ̀ pẹ̀lú wa láé.” Ẹ ó rí èyí nínú ìwé-ìtàn ti àwọn ènìyàn májẹ̀mú ti Ọlọ́run nínú Májẹ̀mú Láéláé, ẹ ó sì rí i nínú ìgbésí ayé ti ara yín bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ májẹ̀mú Rẹ̀.
Ẹ Máṣe bẹ̀rù, láti ọwọ́ Dan Wilson
Èyí ni iyebíye níní òye tí a fi fún wa nítorí Ìmúpadàbọ̀sípò ti májẹmú Ábráhámù nípasẹ̀ Wòlíì Jósẹ́fù Smith. Nítorínáà nígbàtí ẹ bá kà nípa àwọn májẹ̀mú nínú Májẹ̀mú Láéláé, ẹ máṣe ronú lásán nípa ìbáṣepọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú Ábráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù. Bákannáà ẹ ronú nípa ìbáṣepọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú yín. Nígbàtí ẹ bá kà nípa ìlérí ti àìlónkà ìran, ẹ máṣe ronú lásán nípa àwọn míllíọ́nù tí wọ́n npe Ábráhámù ní baba wọn ní òní. Bákannáà ẹ ronú nípa ìlérí Ọlọ́run sí yín nípa àwọn ẹbí ayérayé àti àníkún ayérayé. Nígbàtí ẹ bá kà nípa ìlérí ti ilẹ̀ ogún kan, ẹ máṣe ronú lasán nípa ilẹ̀ ìlérí náà sí Ábráhámù. Bákannáà ẹ ronú nípa àyànmọ́ sẹ̀lẹ́stíà ti ilẹ̀ ayé fúnra rẹ̀—ogún kan tí a ṣe ìlérí rẹ̀ sí “ọlọ́kàn-tútù” tí wọ́n “ndúró dé Olúwa” (Matteu 5:5; Òrin Dáfídì 37:9, 11). Àti nígbàtí ẹ bá kà nípa ìlérí pé àwọn ènìyàn májẹ̀mú Ọlọ́run yíò bùkún “gbogbo àwọn ẹbí ilẹ̀ ayé” (Ábráhámù 2:11), ẹ máṣe ronú lásán nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Ábráhámù tàbí àwọn wòlíì tí wọ́n nsọ̀kalẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Bákannáà ẹ ronú nípa ohun tí ẹ lè ṣe—bí àtẹ̀lé onímájẹ̀mú ti Jésù Krístì—láti jẹ́ ìbùkún sí àwọn ẹbí ní àyíká yín.