Come, Follow Me
Oṣù Kejì 9–15. “Nóà Rí Oore Ọ̀fẹ́ ní Ojú Olúwa”: Gẹ́nẹ́sísì 6–11; Mósè 8


Oṣù Kejì 9–15. ‘Nóà Rí Oore Ọ̀fẹ́ ní Ojú Olúwa’: Gẹ́nẹ́sísì 6–11; Mósè 8,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

Oṣù Kejì 9–15. ‘Nóà Rí Oore Ọ̀fẹ́ ní Ojú Olúwa’,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026

àwọn ẹranko nfi àpótí sílẹ̀ pẹ̀lú Nóà àti ẹbí rẹ̀ tí wọ́n ndúró lórí àpáta

Jéhófàh Pa Ílérí kan Mọ́, láti ọwọ́ Sam Lawlor

Oṣù Kejì 9–15: “Nóà Rí Oore Ọ̀fẹ́ ní Ojú Olúwa”

Gẹ́nẹ́sísì 6–11; Mósè 8

Gbígbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, a ní èrèdí pàtàkì láti fojúsí ìtàn ti Àgbàrá. Nígbàtí Jésù Krístì kọ́ni bí a ṣe níláti ṣọ́nà fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀, “Bí ó ti wà ní àwọn ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ni yíò rí pẹ̀lú ní bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn” (Jósẹ́fù Smith—Máttéù 1:41). Ní àfikún, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe àpèjúwe ọjọ́ Nóà, bíiti “ìbàjẹ́” tí ó sì “kún fún ìpá,” ni ó kàn lè ṣe àpèjúwe ìgbà tiwa ní ìrọ̀rùn (Gẹ́nẹ́sísì 6:12–13; Mósè 8:28). Ìtàn ti Ilé Ìṣọ́ Gíga bákannáà dàbí ó wúlo sí ọjọ́ wa, pẹ̀lú ìjúwe rẹ̀ ti ìgbéraga nípa ìdàmú àti ìpinya wọn.

Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ jẹ́ oníyelórí kìí ṣe nítorípé wọ́n kàn fi hàn wá pé ìwà búburú ntún ara rẹ sọ jákè-jádò àwọn ìtàn. Ní pàtàkì jù, wọ́n kọ́ wa ní ohun tí a ó ṣe nípa rẹ̀. Nóà “rí oore ọ̀fẹ́ ní ojú Olúwa” (Mósè 8:27). Àti pé àwọn ẹbí Járẹ́dì àti arákùnrin rẹ̀ yípadà sí Olúwa a sí á ààbò bò wọ́n kúrò lọ̀wọ́ ìdàmú àti ìpinyà ní Bábélì (wo Étérì 1:33–43). Bí a bá nròó bí a ó ti pa arawa àti ẹbí wa mọ́ ní ààbò ní ìgbà ìdibàjẹ́ àti ipá, àwọn ìtàn inú àwọn orí wọ̀nyí ní púpọ̀ láti kọ́ wa.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ

Gẹ́nẹ́sísì 6; Mósè 8

àmì sẹ́mínárì
Ààbò ti ẹ̀mí wà nínú títẹ̀lé wòlíì Olúwa.

Ṣe ẹ rí ohunkóhun nínú ìjúwe ti ọjọ́ Nóà tí ó dàbí ó jẹ́ irúkannáà sí àwọn ipò ní ọjọ́ wa? Ní pàtàkì, wòó nínú Mósè 8:15–24, 28. Àwọn àkórí wo ni ẹ rí tí wọ́n túnsọ?

Ọ̀kan pàtàkì irúkannáà tí ẹ ó rí ni pé Ọlọ́run pe Nóà láti jẹ́ wòlíì kan, Ó sì ti pe wòlíì kan ní òní. Ẹ gbèrò ṣíṣe ìtòsílẹ̀ àwọn òtítọ́ tí ẹ kọ́ nípa àwọn wòlíì láti inú Mósè 8:13–30. Báwo ni wòlíì alààyè wa ṣe dàbí Nóà? Bẹ́ẹ̀ni, wòlíì Olúwa ní òní kìí kìlọ̀ nípa Àgbàrá tàbí pípè wá wá láti ṣèrànwọ́ láti kọ́ àpótí. Ṣùgbọ́n kínni ohun tí ó nkìlọ̀ fún wa nípa rẹ̀? Kí sì ni ohun tí òun npè wá láti ṣe? Láti ṣèrànwọ́ dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ lè tún orí kan wò láti inú Ìkọ́ni ti àwọn Ààrẹ Ìjọ ní Ibi-ìkàwé Ìhìnrere, nípàtàkì ìpín “Àwọn Ìfipè àti àwọn Ìbùkún Tí A Ṣèlérí ”. Bóyá ẹ lè mú ìkìlọ̀ kan àti ìfipè kan tí ó dàbí pé ó ṣe pàtàkì sí yín nípàtàkì.

Alàgbà Allen D. Haynie kọ́ni pé, “olùfẹ́ni àti ẹni pípé Baba ní Ọ̀run kan ti yan àwòṣe ti fífi òtítọ́ hàn sí àwọn ọmọ Rẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì kan” (“Wòlíì Alààyè kan fún àwọn Ọjọ́-ìkẹhìn,” Làìhónà, Oṣù Karun 2023, 25). Ẹ gbèrò ṣíṣe àṣàrò ọ̀rọ̀ Alàgbà Hynie, wíwá àwọn èrèdí fún níní wòlíì kan ni àmì ti ìfẹ́ Baba Ọ̀run. Báwo ni títẹ̀lé wòlíì Olúwa ṣe nràn yín lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ààbò gbígbé ní àwọn ọjọ́-ìkẹhìn?

Bákannáà wo àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Wòlíì,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere; “Kínni ìdí Tí A Fi Ní àwọn Wòlíì?” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

1:37

Why Do We Have Prophets?

Gẹ́nẹ́sísì 6:5-13

Àgbàrá náà jẹ́ ìṣe àánú ti Ọlọ́run.

Àwọn ènìyàn kan nronú ìdáláre Ọlọ́run ní rírán Ìkún Omi láti “pa ènìyàn run” (Gẹ́nẹ́sísì 6:7). Alàgbà Neal A. Maxwell ṣe àlàyé pé ní àkokò Ìkún Omi náà, “ìdibàjẹ́ ti dé àmì píparun-agbára òmìnira tí àwọn ẹ̀mí kò lè, nínú ìdáláre, di rírán wá sí ìhín” (A Yíò Dán Wọn Wò Níbíyíì [1982], 58). Ẹ lè yẹ bí Àgbàrá ṣe jẹ́ ìṣe àánú kan. Kínni ẹ rí nínú Gẹ́nẹ́sísì 6:5–13 tí ó fi ìfẹ́ àti ìrọ́nú àánú Olúwa han fún àwọn ènìyàn?

Gẹ́nẹ́sísì 9:8-17

Àwọn àpẹrẹ tàbí àmì nràn mí lọ́wọ́ láti rántí àwọn májẹ̀mú mi pẹ̀lú Olúwa.

Gẹ́gẹ́bí Gẹ́nẹ́sísì 9:8–17, kínni òṣùmàrè le mú wá sí inú yín? Kínni ohun tí Ìyírọ̀padà Jósẹ́fù Smith, Gẹ́nẹ́sísì 9:21–25 (nínú àlẹ̀mọ́ Bíbélì) fikún òye yín? Bákannáà ẹ lè yẹ ṣíṣe ìtòsílẹ̀ kan nípa àwọn ohun míràn (bìiti àwọn àmì, nkan, tàbí ohunkóhun míràn) tí Ọlọ́run ti fún yín láti rán yín létí nípa májẹ̀mú yín. Kínni àwọn ohun wọ̀nyí kọ́ọ yín? Báwo ni wọ́n ṣe nràn yín lọ́wọ́ láti rántí?

Bákannáà wo Gerrit W. Gong, “Rántí Rẹ̀ Nígbà gbogbo,” Làìhónà, Oṣù Karun 2016, 108–11; “Pẹ̀lú Ọ̀wọ̀ àti Ọkàntútù Nísisìnyí,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 185.

ilé ìṣọ́ gíga pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí wọ́n ngun òkè pẹ̀lú okun kan àti àwọn àtẹ̀gùn

Ilé Ìṣọ́ Gíga Bábélì, láti ọwọ́ David Green

Gẹ́nẹ́sísì 11:1-9

Títẹ̀lé Jésù Krístì ni ọ̀nà kanṣoṣo sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run.

Àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn Bábélì tí wọ́n nkọ́ ilé ìṣọ́ gíga kan pèsè ìlòdìsí wíwuni sí àkọsílẹ̀ ti Énọ́kù àti àwọn ènìyàn tí wọ́n nkọ́ Síónì, èyí tí ẹ ṣe àṣàrò ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá. Méjèèjì àwọn ẹgbẹ́ ti àwọn ènìyàn tí wọ́n ngbìyànjú láti dé ọ̀run ṣùgbọ́n ní àwọn ọ̀nà yíyàtọ̀. Báwo ni àwọn ènìyàn Síónì ṣe dé ọ̀run? (wo Mósè 7:18–19, 53, 62–63, 69). Kínni ẹ kọ́ látinú Gẹ́nẹ́sísì11:1–9 àti Hẹ́lámánì 6:26–28 nípa àwọn ènìyàn bábélì? Kínni èyí kọ́ wa nínú ìtiraka ti arawa láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Kínni Ọlọ́run ti pèsè láti ràn wá lọ́wọ́ láti “dé ọ̀run”? (Gẹ́nẹ́sísì 11:4; bákannáà wo Jòhánnù 3:16).

Kọ́ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú aápọn. Kíkọ́ ẹ̀kọ́ lè ní púpọ̀ síi nínú ju kíkàwé tàbí fífetísílẹ̀ Fún àpẹrẹ, nígbàtí wọ́n nkọ́ ẹ̀kọ́ nípa Ilé Ìṣọ́ Gíga ti Bábélì, ẹ̀yin àti ẹbí yín tàbí kíláàsì lè kọ̀wé, sórí ìwé pélébé ti bébà, àwọn ohun tí ó nmú wa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Nígbànáà, lórí ìwé pélébé míràn, ẹ lè kọ àwọn ohun tí ó nmú wa súnmọ́ Ọlọ́run síi. Ẹ ṣètò àwọn àkójọ bébà àkọ́kọ́ nínú àwòrán ti ilé ìṣọ́ gíga àti àkójọ kejì nínú àwòrán tẹ́mpìlì.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

ìpín àmì àwọn ọmọdé 01

Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé

Gẹ́nẹ́sísì 6:14–22; 7–8; Mósè 8:16–24

Títẹ̀lé wòlíì Olúwa yíò bùkún èmi àti ẹbí mi.

  • Àwọn ọmọ púpọ̀ fẹ̀ràn ìtàn Nóà àti àpótí náà. Ẹ yẹ fífún àwọn ọmọ yín ní àwọn ànfàní láti pín ohun tí wọ́n mọ̀ nípa rẹ̀. Láti ràn wọ́n lọ́wọ́, ẹ lè lo àwọn àwòrán nínú ìlànà yí, “Nóà àti Ẹbí Rẹ̀” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé (22–25), àti ẹsẹ kẹta ti “Tẹ̀lé Wòlíì náà” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 110–11). Àwọn ọmọ yín lè gbádùn ṣíṣe àwọn apá ìtàn náà—fún àpẹrẹ, nípa dídíbọ́n láti lo ohun èlò kan láti kọ́ àpótí náà tàbí rírìn bíiti àwọn ẹranko tí ó nwọnú àpótí.

  • Bí ẹ ti nsọ̀rọ̀ nípa Nóà papọ̀, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti rí bí wọn ṣe di alábùkún tó láti ní wólíì Ọlọ́run ní òní. Ẹ ran ọmọ yín lọ́wọ́ láti wá Mósè 8:16–24 láti rí àwọn ohun tí Nóà kọ́ni tí àwọn wòlíì Olúwa ṣì nkọ́ni ní òní. Báwo ni a ṣe di alábùkún tó nígbàtí a gbọ́ran sí àwọn ìkọ́ni wọ̀nyí?

Gẹ́nẹ́sísì 9:15–16

Ọlọ́run yíò pa àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́ sí mi.

  • Àwọn ọmọ yínlè gbádùn tàbí kun òṣùmàrè kan nígbàtí ẹ̀ nsọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó rọ́pò (wo Ìyírọ̀padà Jósẹ́fù Smith, Gẹ́nẹ́sísì 9:21–25 [nínú àlẹ̀mọ́ Bíbélì]). Kínni ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí Nóà àti ẹbí rẹ̀ rònú nípa rẹ̀ nígbàkugbà tí wọ́n bá rí òṣùmàrè kan.

  • Bákannáà ẹ lè fi ohunkan tí ẹ ní tí ó nrán yín létí nípa ohunkan pàtàkì nínú ayé yín han àwọn ọmọ yín, bí irú òrùka ìgbeyàwó, àwòrán kan, tàbí ìwé-ìròhìn kan. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín pín àwọn àpẹrẹ ti ara wọn. Èyí lè darí sí i`bárasọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ó nràn wá lọ́wọ́ láti rántí àwọn májẹ̀mú wa, bí irú oùnjẹ Olúwa, èyí tí ó nrán wa létí láti tẹ̀lé Jésù Krístì (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 20:75–79).

òṣùmàrè méjì

Ọlọ́run wí fún ẹbí Nóà pé òṣùmàrè yíò jẹ́ “àpẹrẹ májẹ̀mú èyí tí mo ṣe ní àárin mi àti ẹ̀yin” (Gẹ́nẹ́sísì 9:12).

Gẹ́nẹ́sísì 11:1-9

Títẹ̀lé Jésù Krístì ni ọ̀nà kanṣoṣo sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run.

  • Ó lè jẹ́ ìgbádùn láti kọ́ ilé ìṣọ́ gíga látinú àwọn búlọ́kù tàbí àwọn nkan míràn pẹ̀lú àwọn ọmọ. Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ṣe àlàyé pé àwọn ènìyàn ti Bábélì rò pé wọ́n lè dé ọ̀run nípa kíkọ́ ilé ìṣọ́ gíga. Lẹ́hìnnáà ẹ lè wo àwòrán nípà Olùgbàlà papọ̀ kí ẹ sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín bí Òun ṣe nràn wá lọ́wọ́ láti dé ọ̀run. Lẹ́hìnnáà ẹ lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ara yín nípa àwọn ohun tí ẹ lè ṣe láti tẹ̀lé Olùgbàlà.

  • Ní àfikún láti ka ìtàn ilé ìṣọ́ gíga ti Bábélì nínú Gẹ́nẹ́sísì 11:1–9, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ kí ẹ lè ka Hẹ́lámánì 6:28. Gẹ́gẹ́bí ẹsẹ yí, kínni ìdí tí àwọn ènìyàn Bábélì fi kọ́ ilé ìṣọ́ gíga? Kínni ìdí tí kíkọ́ ilé ìṣọ́ yí fi jẹ́ ọ̀nà àṣìṣe láti dé ọ̀run? Nígbànáà ẹ lè wá 2 Néfì 31:20–21 àti Hẹ́lámánì 3:28 láti wá ọ̀nà títọ́ láti dé ọ̀run. Kínni ìmọ̀ràn tí ẹ yíò fún àwọn ènìyàn Bábélì?

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .

Àpótí Nóà

Àpótí ti Noah, láti ọwọ́ Adam Klint Day. adamdayart.com

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Títẹ̀lé wólíì yíò bùkún èmi àti ẹbí mi.