Come, Follow Me
Oṣù Kejì 2–8. “Olúwa Pè Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Ní Síónì”: Mósè 7


“Oṣù Kejì 2–8. ‘Olúwa Pè Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Ní Síónì’: Mósè 7,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)

“Oṣù Kejì 2–8. ‘Olúwa Pè Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Ní Síónì’,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026

Énọ́kù nní ìran kan nípa Jésù Krístì

Énọ́kù Rí Ìgbà Ìríjú Àkokò, láti ọwọ́ Jennifer Paget

Oṣù Kejì 2– 8: “Olúwa Pè Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Ní Síónì”

Mósè 7

Nínú gbogbo ìwé-ìtàn, àwọn ènìyàn ti gbìyànjú láti ṣe àṣeyege ohun tí Énọ́kù àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣeyọrí: gbígbé àwùjọ déédé dìde níbití kò sí àìní tàbí ipá. Bí àwọn ènìyàn Ọlọ́run, à npín ìfẹ́ yí. À pèé ní gbígbé Síónì ga, ó sì wà pẹ̀lú—ní àfikún láti ṣe ìtọ́jú fún àwọn ènìyàn nínú àìní àti mímú àlàáfíà gbèrú—dídá àwọn májẹ̀mú, gbígbé papọ̀ nínú òdodo, àti dída ọ̀kan pẹ̀lú ara wa àti pẹ̀lú Jésù Krístì, “Ọba Síónì” (Mósè 7:53). Bí àgbáyé, ìletò yín, tàbí ẹbí yín kò bá rí bí ẹ ṣe fẹ́ kí ó jẹ́ gan, ó jẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti bèèrè pé, Báwo ni Énọ́kù àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ti ṣe é? Báwo ni wọ́n ṣe di “ti ọkàn kan àti inú kan” (Mósè 7:18) pẹ̀lú ìjà ní àyíká wọn? Ní àárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àláyé kíníkíní tí Mósè 7 nfún wa nípa Síónì, ọ̀kan oníyelórí nípàtàkì fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn lè jẹ́ èyí: Síónì kìí ṣe ìlú kan lásán—ó jẹ́ ipò ti ọkàn àti ẹ̀mí. Síónì, bí Olúwa ti kọ́ni, ni “ọlọ́kàn mímọ́” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 97:21). Nítorínáà ọ̀nà dídárajùlọ láti gbé Síónì ga ni láti bẹ̀rẹ̀ nínú ọkàn àti àwọn ibùgbé ti ara wa.

àmì àṣàrò

Àwọn èrò fún Kíkọ́ni ní Ilé àti Ìjọ

Mósè 7:16–21, 27, 53, 62–69

àmì sẹ́mínárì
Mo lè ṣèrànwọ́ láti gbé Síónì ga.

Nígbàtí Wòlíì Jósẹ́fù Smith kọ́kọ́ kọ́ nípa Énọ́kù àti Ìlú ti Ìwàmímọ́ rẹ̀, ó ní ìmísí. Ó “mọ̀ pé ọjọ́ náà ti dé nígbàtí Olúwa yíò gbé Síónì kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lẹ́ẹ̀kansíi” (Àwọn Ènìyàn Mímọ́, 1:108–9), ó sì bẹ̀rẹ̀ ìgbìrò ìgbésí ayé kan láti gbé Síónì ga. Kíka Mósè 7 lè mísí yín láti tẹ̀síwájú nínú ìtiraka náà ní òní.

Ẹ lè bẹ̀rẹ̀ nípa wíwá àwọn ìbéèrè náà kiri “Kínni Síónì jẹ́?” àti “Báwo ni ó ṣe yàtọ̀ sí ìyókù ayé?” Ẹ yẹ títòsílẹ̀ àwọn ìdáhùn tí ó nwá sí yín bí ẹ ti nṣe àṣàrò Mósè 7, nípàtàkì nínú àwọn ẹsẹ 16–21, 27, 53, 62–69.

Àwọn ìdáhùn yín sí àwọn ìbèèrè wọ̀nyí lè fi hàn kedere pé a ṣì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ láti ṣe láti gbé Síónì ga. Nítorínáà báwo ni a ó ti ṣe? Ó lè ṣèrànwọ́ láti ronú nípa àwọn àkokò nígbàtí ẹ ti ní ìmọ̀lára pé ẹ jẹ́ “ti ọkàn kan àti inú kan” pẹ̀lú ẹnìkan (Mósè 7:18). Bóyá ó jẹ́ nínú wọ́ọ̀dù kan, ẹbí, tàbí ní ibi-iṣẹ́ tàbí ilé-ìwé. Kínni àwọn ènìyàn ṣe láti dá ìdàpọ̀ òdodo sílẹ̀?

Ní ìhín ní àwọn ohun èlò tí ẹ lè wákiri láti rí àwọn èrò àti ìmísí. Ẹ mú ọ̀kan tàbí púpọ̀ síi láti ṣe àṣàrò, kí ẹ sì kọ àwọn ohun tí ẹ ní ìmọ̀lára ìmísí láti ṣe láti gbé Síónì ga sílẹ̀:

Àwọn ọ̀rẹ́ ntu ara wọn nínú ẹgbẹ́ kíláàsì

Ọlọ́run nfẹ́ kí àwọn ènìyàn Rẹ̀ jẹ́ “ti ọkàn kan àti inú kan” (Mósè 7:18).

Mósè 7:53

Jésù Krístì ni “Ọba Síónì.”

Kínni ó túmọ̀sí fún yín láti ní Jésù Krístì bí Ọba yín? Ẹ kíyèsí àwọn àkọlé míràn nínú ẹsẹ yí. Kínni wọ́ kọ́ yín nípa Rẹ? Kínni ẹ rò pé ó túmọ̀sí láti wọlé “ní ẹnu ọ̀nà kí ẹ sì [gun] òkè nípasẹ̀ [Rẹ̀”?

Bákannáà wo “Wá, Áà Ìwọ Ọba àwọn Ọba,” Àwọn Ìwé-orin Ìsìn, nọ́mbà 59.

Mósè 7:28–69

Ọlọ́run máa nsọkún—Ó sì máa nyọ ayọ̀—fún àwọn ọmọ Rẹ̀.

Àwọn ènìyàn kan rí Ọlọ́run bí ẹni jíjìnà kan tí kìí ní ìmọ̀lára ẹ̀dùn ọkàn nípa ohun tí ó nṣẹlẹ̀ sí wa. Énọ́kù jèrè ìwò yíyàtọ̀ nípa Ọlọ́run nínú ìran tí a kọsílẹ̀ nínú Mósè 7. Kínni òun kọ́ nípa Ọlọ́run—kínni ẹ̀yin sì kọ́—nínú àwọn ẹsẹ 28–40? Kínni ìdí tí ẹ fi rò pé Énọ́kù ní ìyanilẹ́nu láti ri tí Ọlọ́run sọkún? Kínni ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì fún yín láti mọ ohun tí Ó máa nṣe?

Bí ìran ṣe tẹ̀síwájú, Énọ́kù sọkún pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bákannáà pín àwọn èrèdí láti yọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ wá wọn nínú Mósè 7:41–69. Kínni ẹ kọ́ láti inú ìran Énọ́kù tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti “gbé ọkàn yín sókè, kí ẹ sì ní inúdídùn,” pẹ̀lú “ìkorò” nínú ìgbésí ayé yín (ẹsẹ 44)?

Jeffrey R. Holland, “Ọlánlá ti Ọlọ́run,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2003.

Mósè 7:59–67

Jésù Krístì yíò wá lẹ́ẹ̀kansíi ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn.

Ìran Énọ́kù, nípàtàkì ohun tí a kọsílẹ̀ nínú Mósè 7:59–67, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìwé-ìtàn àkọ́kọ́ ti Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olùgbàlà. Kínni ó wọ̀ yín lọ́kàn nípa ọ̀nà tí àwọn ẹsẹ wọ̀nyí fi ṣe àpèjúwe àwọn ọjọ́ ìkẹhìn? Fún àpẹrẹ, ẹ ṣe àyẹ̀wò bí ẹ ti ní ìmọ̀lára pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ láti inú ẹsẹ 62 ṣe ndi mímúsẹ. Kínni àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kọ́ọ yín nípa iṣẹ́ Ọlọ́run ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn?

Bákannáà ẹ wo Henry B. Eyring, “Àwọn Arábìnrin ní Síónì,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2020, 67–69.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ .

àmì ìpín àwọn ọmọdé 01

Àwọn èrò fún Kíkọ́ Ọmọdé

Mósè 7:18–21, 62–63, 68–69

Ọlọ́run nfẹ́ kí a jẹ́ “ti ọkàn kan àti inú kan.”

  • Láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ nípa Énọ́kù àti Síónì, ẹ lè lo “Wòlíì Énọ́kù” nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé (19–21) tàbí ẹsẹ “Ẹ Tẹ̀lé Wòlíì” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 110–11). Lẹ́hìnnáà ẹ lè ní kí àwọn ọmọ yín ràn yín lọ́wọ́ láti tún ìtàn náà sọ ní àwọn ọ̀rọ̀ ara wọn. Àwọn àwòrán ti Énọ́kù nínú ìlànà yí lè ṣèrànwọ́.

  • Ní ìhín ni ọ̀nà kan láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òye ohun tí ó túmọ̀sí láti jẹ́ “ọkàn kan àti inú kan” (Mósè 7:18): Mú bébà ọkàn kí ẹ sì gé e sí àwọn ẹ̀là, tí ó tó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ láti ní ọ̀kan. Ẹ jẹ́ kí wọ́n kọ orúkọ wọn sórí ẹ̀là wọn kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ papọ̀ láti fi ọkàn náà papọ̀. Bí wọ́n ti nṣe é, ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ẹ fẹ́ràn nípa ọmọ kọ̀ọ̀kan.

ìyá nrọ̀mọ́ ọmọbìnrin
  • Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ka oye ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà “Síónì” hàn nínú Mósè 7:18–21, 62–63, 68–69. Ìgbà kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá rí ọ̀rọ̀ náà, ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwárí ohun tí ẹsẹ náà sọ nípa Síónì “Síónì,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere). Báwo ni a ṣe lè dàbí àwọn ènìyàn tí a júwe nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí síi?

Ẹ gbìyànjú àṣàrò ìwé mímọ araẹni. Bóyá ẹ̀ nkọ́ ẹbí yín ní ilé tàbí kílásì ní Ọjọ́ Ìsinmi, ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí ó dárajùlọ tí ẹ fi lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gbé ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ga pẹ́títí ni láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ ìhùwàsí wíwá àwọn ìrírí ti araẹni pẹ̀lú àwọn ìwé mímọ́. Ẹ pín àwọn ìrírí tí ẹ nní pẹ̀lú àwọn ìwé mímọ́, kí ẹ sì gba ẹbí tàbí àwọn ọmọ kíláàsì níyànjú láti pín àwọn ìrírí wọn. Nígbàtí a bá gbọ́ nípa bí kíka àwọn ìwé mímọ́ ṣe nbùkún àwọn ẹlòmíràn, à nní ìmísí léraléra láti wá irú àwọn ìbùkún wọ̀nyí kannáà láti ọ̀dọ̀ Olúwa. (Wo Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà,25.)

Mósè 7:32–33

Baba Ọ̀run nfẹ́ kí èmi yàn láti tẹ̀lé Òun.

  • Láti fi Mósè 7:32–33 hàn sí àwọn ọmọ yín, ẹ lè bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àṣàyàn kan tí wọ́n ti níláti ṣe láìpẹ́. Lẹ́hìnnáà ẹ lè ka àwọn ẹsẹ náà papọ̀ láti wá ohun tí Baba Ọ̀run nfẹ́ kí a yàn. Kínni àwọn àṣàyàn tí ẹ lè ṣe láti fihàn pé a yàn Án. Bóyá àwọn ọmọ yín lè yípo ní ṣíṣe àwọn àṣàyàn wọ̀nyí nígbàtí àwọn ẹlòmíràn nṣe àròsọ ohun tí ìṣe náà dúró fún.

Mósè 7:59–67

Jésù yíò padà wá sí ilẹ̀ ayé.

  • Nínú Mósè 7:59, Énọ́kù béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ Olúwa. Ẹ pe àwọn ọmọ yín láti wá a, àti nígbànáà ẹ sọ fún wọn láti wá ìdáhùn nínú ẹsẹ 60. Bákannáà ẹ lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn nípa àkokò kan nígbàtí wọ́n nreti kí ẹnìkan padà wálé. Ẹ béèrè lọ́wọ́ wọn bí wọ́n ṣe nímọ̀lárá sí àti ohun tí wọ́n ṣe láti múra sílẹ̀. Báwo ni a ṣe lè múra sílẹ̀ fún Jésù láti padàwá?

  • Ẹ ṣe àgbéyẹ̀wò fífi àwọn àwòrán ti àwọn àkokò nígbàtí Olùgbàlà ti farahan sí àwọn ènìyàn bí irú Ìwé Ọnà Ìhìnrere, àwọn nọ́mba. 60, 82, 83, àti84). Kínni àwọn ènìyàn nṣe nínú àwọn àwòrán náà? Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe nímọ̀lára sí nígbàtí wọ́n pàdé Jésù? Ẹ lè kọ orin kan bákannáà nípa Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olùgbàlà, bí irú “Nígbàtí Ó Bá Wá Lẹ́ẹ̀kansíi” (Iwé-orin àwọn Ọmọdé, 82–83), kí ẹ sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ohun tí wọ́n rò pé yíò dàbí nígbàtí Jésù bá wá lẹ́ẹ̀kansi. Ẹ jẹ́kí àwọn ọmọ pín bí wọ́n ṣe ní ìmọ̀lára sí nípa wíwo Jésù nígbàtí Ó bá wá lẹ́ẹ̀kansi.

Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì .

Énọ́kù àti àwọn ènìyàn láti ìlú Síónì ni à nyí padà

Ilú Síónì ni a Yípadà, láti ọwọ́ Del Parson

Ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Ọlọ́run nfẹ́ kí a fẹ́ràn ara wa