“Oṣù Kínní 19-25. ‘Ìṣubú Ádámù àti Éfà: Mósè 4–5,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Oṣù Kínní 19-25. Ìṣubú Ádámù àti Éfà,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026
Adámù àti Éfà, láti ọwọ́ Douglas M. Fryer
Oṣù kínní 19– 25: Ìṣubú Ádámù àti Éfà
Gẹ́nẹ́sísì 3–4; Mósè 4–5
Ní àkọ́kọ́, ìtàn Ìṣubú Ádámù àti Éfà lè dàbí àjálù. Ádámù àti Éfà ni a jù síta Ọgbà Édẹ́nì rírẹwà. A rán lọ sínú ayé ìrora, ìkorò, àti ikú (wo Gẹ́nẹ́sísì 3:16–19). A sì pín wọn níyà kúrò ní ọ̀dọ̀ Baba wọn Ọ̀run. Ṣùgbọ́n àwọn òtítọ́ tí a múpadàbọ̀sípò nípasẹ̀ Wòlíì Jósẹ́fù Smith nínú ìwé ti Mósè fún wa ní ìrísí àrà ọ̀tọ̀ lórí Ìṣubú.
Bẹ́ẹ̀ni, Ọgbà Édẹ́nì jẹ́ rírẹwà. Ṣùgbọ́n Ádámù àti Éfà nílò ju àwọn àyíká rírẹwà lọ. Wọ́n nílò—gbogbo wa sì nílò—ànfàní láti dàgbà. Fífi Ọgbà Édẹ́nì sílẹ̀ ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ pàtàkì síwájú pípadà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ní ìgbẹ̀hìn láti dàbíi Rẹ̀. Èyí túmọ̀sí kíkojú àtakò, ṣíṣe àṣàyàn, ṣíṣe àṣìṣe, kíkọ́ láti ronúpìwàdà, àti láti gbẹ́kẹ̀lé Olùgbàlà enití Ètùtù rẹ̀ mu ìlọsíwájú ṣeéṣe àti “ayọ̀ ìràpadà” (Mósè 5:11). Nítorínáà nígbàtí ẹ bá kà nípa Ìṣubú Ádámù àti Éfà, ẹ máṣe fojúsùn sí dídàbí àjálù ṣùgbọ́n lórí àwọn ìṣeéṣe—kìí ṣe lórí párádísè tí Ádámù àti Éfà pàdánù ṣùgbọ́n lórí ògo tí yíyàn wọn fi ààyè gba wá láti gbà.
Àwọn èrò fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ní Ilé àti ní Ìjọ
Gẹ́nẹ́sísì 3; Mósè 4
Ìṣubú náà jẹ́ ara pàtàkì ètò ti Ọlọ́run.
Ó jẹ́ òtítọ́ pé yíyàn Ádámù àti Éfà darí sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣòro tí à nní ìrírí nínú ayé ikú. Ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀sí pé a kábàámọ̀ yíyàn wọn. Bí ẹ ti nka Gẹ́nẹ́sísì 3 àti Mósè 4, ẹ lè bi ara yín léèrè pé, kínni ìdí tí Ìṣubú náà fi ṣe pàtàkì sí ètò Ọlọ́run?
Ní ìbámu sí Mósè 5:9–12, báwo ni Ádámù àti Éfà ṣe mọ̀lára nípa Ìṣubú náà? Báwo ni ẹ ṣe lè lo àwọn ọ̀rọ̀ wọn sí àwọn ìrírí nínú ayé ṣíṣubú yí? Ohun míràn wo ni ẹ kọ́ láti inú 2 Néfì 2:19–25?
Bákannáà wo Mòsíàh 3:19; Álmà 12:21–37; àti Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 29:39–43.
Fífi Edẹ́nì sílẹ̀, láti ọwọ́ Annie Henrie Nader
Gẹ́nẹ́sísì 3:1–7; Mósè 4:22–31; 5:4–15
Jésù Krístì fúnni ní ìrètí àti ìràpadà.
Ìtàn Ádámù àti Éfà jẹ́ ọ̀kan ti ìrètí àti ìràpadà nípasẹ̀ Jésù Krístì. Láti rí ìdí, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ nípa ìwákiri fún àwọn àbájáde Ìṣubú nínú Gẹ́nẹ́sísì 3:1–7; Mósè 4:22–31 kí ẹ sì fi àmì sí tàbí ṣe títòsílẹ̀ ohun tí ẹ rí. Báwo ni àwọn àbájáde wọ̀nyí ṣe kàn yín? Nígbànáà ẹ lè ṣe ìwákiri Mósè 5:4–15, ní wíwá ètò Ọlọ́run láti rà wá padà kúrò nínú àwọn àyọrísí wọ̀nyí. Kínni ìdí tí Ádámù àti Éfà ṣe ní “ìdùnnú” lẹ́hìn tí àngẹ́lì bẹ̀ wọ́n wò? Kínni ohun tí ẹ kọ́ láti ọ̀dọ̀ wọn nípa ètò Baba Ọ̀run?
Bákannáà wo “Nítorí Rẹ̀” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Because of Him
Gẹ́nẹ́sísì 3:16; Mósè 4:22
Kínni ó túmọ̀sí pé Ádámù níláti “ṣe àkóso lórí” Éfà?
Ẹsẹ ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ yìí ni ó ti fi ìgbà míràn jẹ́ yíyeni sódì láti túmọ̀sí pé ọkọ kan jẹ́ dídáláre ní lílo ìyàwó rẹ̀. pẹ̀lú àìní àánú Ní ọjọ́ wa, àwọn wòlíì Olúwa ti kọ́ni pé ọkọ àti aya níláti rí ara wọn bíi ẹnìkejì dídọ́gba ní mímú àwọn ojúṣe tọ̀run wọn ṣẹ nínú ẹbí (wo “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àráyé” [Ibi-ìkàwé Ìhìnrere]). Alàgbà Dale G. Renlund àti Arábìnrin Ruth Lybbert Renlund ṣe àlàyé pé ọkọ olódodo kan “yíò lépa láti ṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́; òun yíò dá àṣìṣe mọ̀ yíò sì wá ìdáríjì; òun yíò yára láti fúnni ní ìyìn; òun yíò ní ìfiyèsí ààyò ti ọmọ ẹbí; òun yíò ní ìmọ̀lára ìwọ̀n nlá ti ojúṣe láti pèsè ‘àwọn kòṣeémánìí ayé àti ààbò’ fún ẹbí rẹ̀; òun yíò tọ́jú ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àpọ́nlé nlá àti ọ̀wọ̀. … Òun yíò bùkún ẹbí rẹ̀” (Oyè àlùfáà Melchizedek: Níní òye Ẹ̀kọ́, Gbígbé Ìgbé Ayé àwọn Ìpìlẹ̀ Ẹ̀kọ́ náà [2018], 23.
Mo nílò agbára láti yàn àti àtakò láti dàgbà.
Bí Alàgbà Renlund ti kọ́ni, “Ìlépa ti Baba wa Ọrun nínú ṣíṣe òbí kìí ṣe láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣe ohun tí ó tọ́; ó jẹ́ láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀ yàn láti ṣe ohun tí ó tọ́ ati nígbẹ̀hìn kí wọn ó le dà bíi Rẹ̀” (”Ẹ Yàn Ní Òní,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2018, 104). Kínni ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì nínú ètò Baba Ọ̀run pé kí a yàn láti ṣe ohun tí ó tọ́?
Bí ẹ ti ka Mósè 4:1–4, ẹ wá ohun tí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ṣe láti dá ààbò bo ẹ̀tọ́ yín láti yan—agbára òmìnira yín. Báwo ni ẹ ṣe lè ní ààyè sí dídá ààbò bo agbára wọn? Fún àwọn èrò, ẹ yẹ ṣíṣe àṣàrò ipín náà wo “Ẹ ṣe àwọn yíyàn ìmísí” nínú Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́na kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn (4–5).
Bákannáà ẹ yẹ kíkà nípa Léhì tí ó nkọ́ nípa agbára òmìnira nínú 2 Néfì 2:11–20, 25–30. Kínni ìdí tí àtakò fi jẹ́ pàtàkì fún agbára òmìnira? Báwo ni ẹ ṣe lè fi ìmọyì yín hàn sí Jésù Krístì fún mímú yín “ní òmìnira láti yàn”? (2 Néfì 2:27).
Bákannáà wo Dallin H. Oaks, “Àtakò nínú Ohun Gbogbo,” Làìhónà, Oṣù Karun 2016, 114–17; Àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Agbára Láti Yàn,” Ibi-ìkàwé Ìhìnrere; “Yan Èyití Ó Tọ́,” Àwọn Orin Ìsìn, nọ́mbà 239.
Mú kíkópa pọ̀ si. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ ṣíṣe kíkọ́ ẹ̀kọ́ ni a lè ṣe bí olúkúlùkù, ẹbí, tàbí kíláàsì; nínú àwọn ẹgbẹ́ kékèké; tàbí ní méjì méjì. Ẹ lo onírúurú àwọn ìlànà láti fi ààyè gba àwọn ènìyàn láti kópa àwọn tí wọ́n lè má tilẹ̀ ní ààyè kan. Fún ṣíṣe yí, ẹ lè pe ẹnìkan tàbí ẹgbẹ́ láti ka Mósè 4 àti atọ́nà Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ nígbàtí ẹgbẹ́ míràn nṣe àṣàrò àwọn ẹsẹ nínú 2 Néfì 2. Nígbànáà wọ́n lè kọ́ ara wọn ní ohun tí wọ́n kọ́ nínú ìpín kọ̀ọ̀kan wọn.
Sátánì nwá “láti tàn mí jẹ àti láti fọ́” mi lójú.
Bí ẹ ti nka Mósè 4:4–12; 5:13–33, ṣe àyẹ̀wò títo àwọn ọ̀nà tí Sátánì fi gbìyànjú láti dán Ádámù àti Éfà àti àwọn ọmọ wọn wo sílẹ̀. Báwo ni ó ṣe ngbìyànjú àwọn ohun kannáà ní òní? Báwo ni Baba Ọ̀run ṣe nràn yín lọ́wọ́ láti tako àwọn ẹ̀tàn Sátánì?
“Èmi, Olúwa Ọlọ́run … wọ̀ wọ́n ní aṣọ.”
Lẹ́hìn ṣíṣe àbápín ti èso èèwọ̀, Ádámù àti Éfà gbìyànjú láti bo ìhòhò ara wọn. Lẹ́hìnnáà, Olúwa gbà láti wọ̀ wọ́n ní aṣọ. Bí ẹ ti nka Mósè 4:13–16, 27, ẹ ṣe àyẹ̀wò ìwọ̀nyí:
-
Ẹ jíròrò ohun tí ìhòhò àti wíwọṣọ lè rọ́pò nínú àwọn ìwé mímọ́ (wo, fún àpẹrẹ, Ìfihàn 7:9, 13–15; 2 Néfì 9:14; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 109:22–26, 76). Kínni ẹ kọ́ látinú ìrírí Ádámù àti Éfà pẹ̀lú ìhòhò àti wíwọṣọ?
-
Bí ẹ bá ti gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, ẹ ṣe àyẹ̀wò ohun tí Ádámù àti Éfà lè wí fún yín nípa pàtàkì ẹ̀wù tẹ́mpìlì yín àti ohun tí ó dúró fún.
Bákannáà wo “Wíwọṣọ Tẹ́mpìlì Mímọ́” (fídíò), Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Sacred Temple Clothing
Ọlọ́run yíò tẹ́wọ́gba àwọn ìrúbọ mi bí mo bá fi wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́ àti ìgbọràn.
Bí ẹ ti nṣe àṣàrò Mósè 5:4–9, 16–26, ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn ìhùwàsí Ádámù àti Éfà àti àwọn ọmọ Káìnì àti Ábẹ́lì sí ìrúbọ. Kínni ìdí tí Olúwa fi tẹ́wọ́gba ìrúbọ Ábẹ́lì ṣùgbọ́n tí kò gba ti Káìnì?
Kínní Olúwa ní kí ẹ fi ṣe ìrúbọ? Njẹ́ ohunkóhun wà nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí tí ó nṣe àtúnwò ọ̀nà tí ẹ fi nronú nípa àwọn ìrúbọ wọnnì?
Fún púpọ̀ síi, ẹ wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti àwọn ìwé-ìròhìn Làìhónà àti Fún Okun Ọ̀dọ́.
Àwọn Èrò fún Kíkọ́ àwọn Ọmọdé
Jésù Krístì gbà wá là kúrò nínú Ìṣubú náà.
-
Láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní òyè Iṣubú Ádámù àti Éfà dáradára síi, ẹ lè ṣe ẹ̀dà àwọn àwòrán láti inú “Ádámù àti Éfà” (nínú Àwọn Ìtàn Májẹ̀mú Láéláé, 13–16) kí ẹ sì gé wọn jáde. Nígbànáà ẹ lè ṣiṣẹ́ papọ̀ láti to àwọn àwòrán náà léra bí ẹ ti nsọ̀ àwọn ìrírí Ádámù àti Éfà. Bí ẹ ti nṣe é, ẹ sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí ó fi jẹ́ pàtàkì, nínú ètò Baba Ọ̀run, fún Ádámù àti Éfà láti fi Ọgbà Édẹ́nì sílẹ̀.
-
Àwọn ọmọ yín lè ní ìmọ̀lára ìmoore fún Ètùtù Jésù Krístì bí wọ́n ṣe nní òye bí Òun ti borí àwọn àbájáde Ìṣubú náà. Bí ẹ ti nka Mósè 4:25; 6:48; Àwọn ará Rómù 5:12; 2 Néfì 2:22–23, papọ̀ ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ wá àwọn ọ̀nà láti parí ẹ̀là ọ̀rọ̀ yí: “Nítorí Ìṣubú, Èmi …” Nígbànáà, bí ẹ ti nka Mósè 5:8–11, 14–15; 6:59; Álmà 11:42, papọ̀ wọ́n lè parí ẹ̀là ọ̀rọ̀ yí: “Nítorí ti Jésù Krístì, Èmi …” Ẹ ṣe àbápín ìmoore fún Jésù Krístì pẹ̀lú ara yín.
Mo lè yan ohun tó tọ́.
-
Ẹ yẹ nkan ìrọ̀rùn ẹ̀kọ́ kan wò láti fi ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ agbára láti yàn hàn: ẹ pe àwọn ọmọ yín láti kun ojú-ewé iṣẹ́ ṣíṣe ti ọ̀sẹ̀ yí, ṣùgbọ́n ẹ fún wọn ní àwọ̀ kanṣoṣo láti lò. Kínni ìdí tí yíò fi dára síi láti ní àwọn àṣàyàn? Nígbànáà ẹ lè ka Mósè 4:1–4 papọ̀ kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Ọlọ́run fi nfẹ́ kí a lè yàn ní àárín títọ́ àti àṣìṣe. Báwo ni Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ṣe nràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn yíyàn rere?
-
Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ronú nípa àti láti ya àwọn àwòrán nípa àwọn yíyàn rere tí wọ́n lè ṣe láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Tàbí ẹ lè kọ orin papọ̀ nípa ṣíṣe àwọn yíyàn rere, bí irú “Yan Ọ̀nà Tó Tọ́” (Ìwé-orin àwọn Ọmọdé, 160–61). Ẹ lè wí fún ara yín nípa àkokò kan nígbàtí ẹ bá ṣe yíyàn rere kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ ti ní ìmọ̀lára lẹ́hìnnáà.
Ìṣubú Náà, láti ọwọ́ Robert T. Barrett
Mo lè gbàdúrà sí Baba Ọ̀run
-
Nígbàtí Ádámù àti Éfà ní láti fi Ọgbà Édẹ́nì sílẹ̀, wọn kò lè wà pẹ̀lú Baba Ọ̀run mọ́. Ẹ ka Mósè 5:4, 8 pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, kí ẹ sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá ohun tí Ádámù àti Éfà ṣe láti ní ìmọ̀lára súnmọ́ Ọ àti láti gbọ́ Ọ. Kínni àwọn ohun tí a lè wí fún Baba Ọ̀run nínú àdúrà wa?
Fún púpọ̀ síi, wo àtẹ̀jáde oṣù yí ti ìwé-ìròhìn Fríẹ́ndì .
Ní àfijọ Ìrúbọ Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Baba, láti ọwọ́ Mike Malm (wo Mósè 5:5–9)