“Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú: Kíka Májẹ̀mú Láéláé,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ilé àti Ìjọ: Májẹ̀mú Láéláé 2026 (2026)
“Kíka Májẹ̀mú Láéláé,” Wá, Tẹ̀lé Mi: 2026
Àwọn Èrò láti Pamọ́ sí Iyè-inú
Kíka Májẹ̀mú Láéláé
Nígbàtí Néfì nfẹ́ láti mísí arákùnrin rẹ̀ láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, ó pín àwọn ìtàn nípa Mósè àti àwọn ìkọ́ni láti inú Ísáíáh. Nígbàtí Àpóstélì Páùlù fẹ́ láti gba àwọn Krìstẹ́nì ìṣaájú níyànjú láti ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, ó rán wọn létí nípa ìgbàgbọ́ Nóà, Ábráhámù, Sárà, Ráhábù, àti àwọn ẹlòmíràn. Àti pé nígbàtí Jésù Krístì wí fún àwọn olùdarí àwọn júù láti “wá inú àwọn ìwé mímọ́,” ní ṣíṣe àlàyé pé wọ́n “jẹ́ ẹ̀rí nípa mi” (Jòhánnù 5:39), àwọn ìwé mímọ́ tí Ó nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni àwọn àkọsílẹ̀ tí a pè ní Májẹ̀mú Láéláé.
Ní ọ̀rọ̀ míràn, nígbàtí ẹ bá ka Májẹ̀mú Láéláé, ẹ nka àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti mísíni, tùni-nínú, tí ó sì gba àwọn ènìyàn Ọlọ́run níyànjú fún bíi ẹgbẹgbẹ̀rún ọdún.
Ṣùgbọ́n njẹ́ ohun kan tí a kọ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn le ràn yín lọ́wọ́ lódodo láti wá ojúùtú sí àwọn wàhálà ti òní? Bẹ́ẹ̀ni, ó lè ṣe é! Pàápàá bí ẹ bá rántí ẹni tí Májẹ̀mú Láéláé jẹ́ nípa rẹ̀ nítòótọ́.
Ẹ̀rí Kan ti Jésù Krístì
Èyikeyi àwọn ìpènijà tí ẹ̀yin àti ẹbí yín lè máa kojú, ìdáhùn náà nígbàgbogbo ni Jésù Krístì. Nítorínáà láti rí àwọn ìdáhùn nínú Májẹ̀mú Láéláé, ẹ wá A. Kò ní fi ìgbàgbogbo rọrùn. Ẹ lè nílò láti jíròrò pẹ̀lú sùúrù kí ẹ sì wá atọ́nà ti ẹ̀mí. Nígbà míràn àwọn atọ́ka sí I ndàbí tààrà gan-an, bíi ti inú ìkéde Ísáíàh, “A bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa: … orúkọ rẹ̀ ni a ó sì pè ní … Ọmọ-Aládé Àlàáfíà” (Isaiah 9:6). Ní àwọn Ibì kan, Olùgbàlà ni a rọ́pò jù lábẹ́lẹ̀, nípa àwọn àmì àti ìbáramu—fún àpẹrẹ, nípasẹ̀ àpèjúwe àwọn irúbọ ẹran ọ̀sìn tàbí àkọsílẹ̀ Jósẹ́fù tí ó ndáríji àwọn arákùnrin rẹ̀ tí ó sì gbà wọ́n là kúrò nínú ìyàn.
Ìmọ́lẹ̀ Ayé, láti ọwọ́ Scott Sumner
Bí ẹ bá nwá ìgbàgbọ́ títóbijù nínú Olùgbàlà bí ẹ ti nṣe àṣàrò Májẹ̀mú Láéláé, ẹ yíò rí i. Bóyá èyí lè jẹ́ ìlépa àṣàrò yín ní ọdún yí. Ẹ gbàdúrà pé Ẹ̀mí yíò ṣe atọ́nà yín láti rí àti láti fojúsí àwọn ẹsẹ, àwọn ìtàn, àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí yíò mú yín súnmọ́ Jésù Krístì síi.
Ìpamọ́ Àtọ̀runwá
Ẹ máṣe retí kí Májẹ̀mú Láéláé fúnni ní ìwé-ìtàn ẹ̀dá ènìyàn ní pípé àti ní pàtó. Èyí kìí ṣe ohun tí àwọn ònkọ̀wé àti àwọn alákòójọ ngbìyànju láti dá sílẹ̀. Àníyàn wọn títóbijù ni láti kọ́ni ní ohun kan nípa Ọlọ́run—nípa ètò Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀, nípa ohun tí ó túmọ̀sí láti jẹ́ àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ, àti nípa bí wọ́n ṣe lè rí ìràpadà nígbàtí wọ́n bá kùnà. Nígbàmíràn wọ́n ṣe é nípa ṣíṣe ìbámu àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ onítàn bí wọ́n ti ní òye wọn, pẹ̀lú àwọn ìtàn láti inú ìgbé ayé àwọn wòlíì nlá. Gẹ́nẹ́sísì ni àpẹrẹ kan nípa èyí, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ìwé bíi Jóṣúà, àwọn Onídàájọ́, àti àwọn Ọba 1 àti 2. Ṣùgbọ́n ònkọ̀wé míràn ti Májẹ̀mú Láéláé kò fojúsùn láti jẹ́ onítàn rárá. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ́ni nínú àwọn iṣẹ́ ọnà bíi ewì àti àtẹ̀kọ. Àwọn Orin Dáfídì àti Òwe bá ẹ̀ka yí mu. Àti nígbànáà àwọn ọ̀rọ̀ iyebíye ti àwọn wòlíì wà, bí irú Ísáíàh àti Málákì, tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ọmọ Isráẹ́lì àtijọ́—àti, nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu ti Bíbélì, wọ́n ṣì nbá wa sọ̀rọ̀ ní òní.
Njẹ́ gbogbo àwọn wòlíì, akéwì, àti alákòójọ wọ̀nyí mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ wọn yíò jẹ́ kíkà nípasẹ̀ àwọn ènìyàn ní gbogbo ayé ní ẹgbẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́hìnwá. A kò mọ̀. Ṣùgbọ́n a ní ìyàlẹ́nu pé èyí ni déédé ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè dìde wọ́n sì ṣubú, àwọn ìlú ni a ṣẹ́gun, àwọn ọba gbé láyé wọ́n sì kú, ṣùgbọ́n Májẹ̀mú Láéláé wà kọjá gbogbo wọn, láti ìran dé ìran, láti akọ̀wé dé akọ̀wé, láti ìyírọ̀padà dé ìyírọ̀padà. Bẹ́ẹ̀ni àwọn ohun kan ti sọnù tàbí di títúnṣe, àti pé síbẹ̀ bákan a ti pa púpọ̀ mọ́ pẹ̀lú ìyanu.
Wòlíì Májẹ̀mú Láéláé, láti ọwọ́ Judith A. Mehr (àlàyé)
Ìwọ̀nyí ni àwọn ohun díẹ̀ péré láti pamọ́ sí inú rẹ̀ bí ó ti nka Májẹ̀mú Láéláé ní ọdún yìí. Ọlọ́run pa àwọn ohun kíkọ àtijọ́ wọ̀nyí mọ́ nítorí Ó mọ̀ yín àti ohun tí ẹ̀ nlà kọjá. Ó ti múra ọ̀rọ̀ ti ẹ̀mí kan sílẹ̀ fún yín nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, èyí tí yíò fà yín súnmọ́ Ọ síi tí yíò si mú ìgbàgbọ́ yín nínú ètò Rẹ̀ àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ dàgbà. Bóyá Òun yíò darí yín sí ẹsẹ ọ̀rọ̀ kan tàbí ìwòye tí yíò bùkún ẹnìkan tí ẹ mọ̀—ọ̀rọ̀ kan tí ẹ lè pín pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan, ọmọlẹ́bí kan, tàbí akẹgbẹ́ Ènìyàn Mímọ́ kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìleṣe ni ó wà. Njẹ́ èyí kò ha dùn mọ́ni láti ronú nípa rẹ̀ bí?
Néfì wípé, “Ọkàn mi yọ̀ nínú ìwé mímọ́” (2 Néfì 4:15). Bóyá ẹ lè ní ìmọ̀lára ní ọ̀nà kannáà bí ẹ ṣe nka ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kannáà tí Néfì kà—ohun tí a pè ní Májẹ̀mú Láéláé nísisìyí.
Àwọn ìwé inú Májẹ̀mú Láéláé
Nínú púpọ̀jù àwọn ẹ̀yà Krìstẹ́nì ti Májẹ̀mú Láéláé, àwọn ìwé ni a ṣètò lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ kúrò ni bí a ti tò wọ́n nígbàtí a kọ́kọ́ kó wọn jọ sínú àkópọ̀ kan. Nítorínáà nígbàtí Bíbélì Hébérù kó àwọn ìwé náà jọ sínú àwọn ẹ̀ka mẹ́ta—òfin náà, àwọn wòlíì, àti àwọn ohun kíkọ—púpọ̀jù àwọn Bíbélì Krìstẹ́nì to àwọn ìwé náà jọ sí ẹ̀ka mẹ́rin: òfin (Gẹ́nẹ́sísìs–Deuterónómì), ìwé-ìtàn (Jóṣúà–Éstérì), àwọn ìwé ewì (Jobu–Orin Solómọ́nì), àti àwọn wòlíì (Ísáíáh–Málákì).
Kínni ìdí tí àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí fi jẹ́ pàtàkì? Nítorí mímọ̀ irú ìwé tí ẹ̀ nkà lè ràn yín lọ́wọ́ láti ní òye bí ẹ ó ti kàá.
Ní ìhìn ni ohun kan láti pamọ́ sí iye-inú bí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí ka “òfin náà,” tàbí àwọn ìwé márun àkọ́kọ́ ti Májẹ̀mú Láéláé. Àwọn ìwé wọ̀nyí, èyí tí a fi pẹ̀lú àṣà kàsí fún Mósè, ṣeéṣe kí ó gba ọwọ́ ọwọ́ onírúurú àwọn akọ̀wé àti alákòópọ̀ kọjá bí àkókò ti nlọ. A sì mọ̀ pé, ní àwọn sẹ́ntúrì, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn abala èyí tí ó ṣe kedere ati iyebíye jùlọ” ni a mú kúrò nínú Bíbélì (wo 1 Néfì 13:23–26). Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ìwé ti Mósè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìmìsí Ọlọ́run, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n—bí eyikeyi iṣẹ́ Ọlọ́run tí a firánṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn ẹni kíkú—wà lábẹ́ àwọn àìlera ẹ̀dá ènìyàn (wo Móse 1:41; Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:8). Àwọn ọ̀rọ̀ Mórónì, tí ó ntọ́ka sí àkọsílẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì mímọ́ tí ó ṣèrànwọ́ kójọ, jẹ́ kíkún fún ìrànlọ́wọ́ ní ìhìn: “Bí àṣìṣe bá wà wọ́n jẹ́ àṣìṣe ti àwọn ènìyàn; nítorínáà, ẹ máṣe dá àwọn ohun ti Ọlọ́run lẹ́bi” (ojú-ewe àkọlé Ìwé ti Mọ́mọ́nì). Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, ìwé ti ìwé mímọ́ kan kò nílò láti jẹ́ òmìnira kúrò nínú àṣìṣe ti ènìyàn láti jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.